Àwo̩n olósèlú ń jà fún àǹfàní ara wo̩n ni, kìí se fún àwo̩n o̩mo̩ Naijiria -Actor Okon Lagos
Mary Fágbohùn
Osere alawada, Bishop Umoh, ti a mo si Okon Lagos, ti so pe awon oloselu nja fun anfaani ara won kii se fun anfaani awon omo Naijiria lori oro owo titele ti won o na mo.
O so eyi di mimo ni oju awe Instagram re ni aaro ojo Friday.
Osere naa so wi pe atunse ofin owo naira o kii se lati fi iya je awon mekunnu, sugbon dipo bee won se lati rii daju pe eto idibo to n bo lona yi waye lai si ejanbakan ninu, o fikun n pe awon oloselu ti won fowo rabo ni owo titele ti won o na mo lowo.
O ko o wi pe, “Ko si oloselu to n rabo ni tooto to ka yin si. Ija won lati ma a na owo titele kii se fun yin!
“Bi o ba je N200, N100, N50, N20, N10 ati N5 nikan lo wa nle. Yoo to na fun gbogbo nnkan ti onikalulu nilo.
“Nkan ti awon oloselu to n rabo ni naa ni owo titele ti won o na mo (N1000 and N500).
“E fara bale eyin eniyan, e je ki idibo tan. Ija yi kii se lati fi iya je awon mekunnu! E jowo e ma binu. Gbogbo re yoo dopin laipe!”