Peter Obi fẹ̀yìn-in Tinubu àti Atiku janlẹ̀ láwọn ibùdó ìdìbò kan l’Ékòó

Peter Obi fẹ̀yìn-in Tinubu àti Atiku janlẹ̀ láwọn ibùdó ìdìbò kan l’Ékòó

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ó jọ pé omi tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP fojú rénà ti fẹ́ máa gbé wọn lọ báyìí pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ṣe tún ń léwájú ní àwọn ibùdó ìdìbò kan ní ìpinlẹ Èkó, níbi tí ẹgbẹ́ APC ti ń ṣèjọba.

Ni ọpọlọpọ agbegbe ibudo idibo ni Lẹkki, oludije funpo aarẹ ẹgbẹ Labour lo n rọwọ mu ju lọ nibẹ. Lara awọn agbegbe ti wọn ti ka, to si jẹ Peter Obi lo n lewaju ni ibudo idibo 035, 005 ati 005. Ni ibudo idibo mẹtẹẹta yii, Peter Obi ni ibo ẹgbẹrin le laaadọta(850), nigba ti ẹgbẹ APC ni ibo mẹtadinlogun, ti ẹgbẹ PDP si ni ibo marun-un pere.

Ọrọ ko si fi bẹẹ yatọ ni ibudo idibo Ilasan, Jakande ati Mopol Zone, ẹgbẹ Labour ti Peter Obi naa lo lewaju. Ibo mẹta lelaaadọwaa (193) ni Obi ni, ẹgbẹ APC ni ibo mẹtadinlọgọta (57), ti ẹgbẹ PDP ko si ni nnkan kan.

Bakan naa lọmọ ṣori lawọn esi ibo to jade ni ibudo idibo 046, Wọọdu E1, ni Mazamaza, nijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, ẹgbẹ oṣelu Labour ni ibo mọkandinlaaadọsan-an (169) ẹgbẹ APC ni ibo mejilelọgbọn (32), nigba ti PDP ni ibo ọgọrin (80).

Bẹẹ naa lọrọ ri ni Wọọdu E1, to wa ni Benster Crescent, ni Mazamaza, l’Amuwo Ọdọfin. Labour ni ibo to fi marun-un din ni igba (195), ẹgbẹ APC ni ibo meji (2), nigba ti PDP ni ẹyọ kan (1)

Ẹgbẹ́ Peter Obi náà ló léwájú ní Yúníìtì kejilelaaadọfa, níjọba ìbílẹ̀ Koṣọfẹ, ní Ogudu, pẹ̀lú ibo mẹtadinlọgọta (57), tí APC si ni ìbò mẹsan-an, PDP ní ìbò ẹyo kan péré.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here