Ojoojúmó̩ ló ye̩ kí a máa sàjo̩yò̩ o̩dún olólùfé̩ – Kunle Afod

Ojoojúmó̩ ló ye̩ kí a máa sàjo̩yò̩ o̩dún olólùfé̩ – Kunle Afod

Mary Fágbohùn

Ilumooka osere tiata, oludari ati agberejade, Kunle Afod ti lo si ori ayelujara re lati fi aworan oun ati iyawo re, Desola Afod lede bi won se n se ajoyo ayajo ololufe. Ninu aworan naa, awon tokotaya naa wo iru aso kan naa ti won si denge niwaju ayaworan. Kunle so pe ojoojumo lo ye ki won maa se ajoyo ayajo ololufe, o fikun un pe gbogbo igba ni oun yoo yan iyawo oun gege bi ololufe oun. Oro ifori naa ka bayii pe, “Ojoojumo lo ye ki won maa se ajoyo ayajo ololufe, o fikun un pe gbogbo igba ni oun yoo yan o gege bi ololufe oun.”

Awon aworan awotunwo yii ni o ti fa ki awon afenifere ati awon ilumooka ma a kegbe pe eyi wu mi o. Ewe, won tun fi ifesi ife ranse si awon ti n ko iha si aworan won. Iyawo Kunle Afod, Desola fi ami ife kan sile o wi pe, “O se fun pe o je ara mi. Ku oriire ayajo ololufe ife mi. Maa ri o laipe”. Osere tiata, Adebimpe Akintunde tun fi ami ife ranse.

Ni osu die seyin, Kunle Afod ni oro re suyo ninu iwe irohin wi pe igbeyawo re ti fori sanpon. To si je pe leyinwa eyi ni irohin tun jade pe iro banta ni oro naa ati pe won si n gbe nigbe lokolaya pelu iduunu.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here