Gbajabiamila fajú ro sí àwo̩n ológun tó ń fojú tó ètò ìbò

Gbajabiamila fajú ro sí àwo̩n ológun tó ń fojú tó ètò ìbò

Yínká Àlàbí

Olori ile-igbimo̩ asofin kekere, Femi Gbajabiamila  lo so̩ ero inu re̩ jade nipa awo̩n Soja to n foju to eto ibo.
Gbajabiamila ni oun ti fi ofin ja ija naa nigba kan lori idibo ipinle̩ Ekiti ti ile-e̩jo̩ da oun lare.
O ni onikaluku lo ni ise̩ tire̩ ge̩ge̩ bi a se kaso̩ si wo̩n lo̩run. O ni ohun ti agbara awo̩n o̩lo̩paa ko ba ka mo̩ ni awo̩n ologun maa n fi ise̩ ogun wo̩n yanju. O ni ko to̩na rara, ki a wa fe̩ dibo, ki a wa ko awo̩n ologun ti wo̩n di iha mo̩ra sita.
Olori ile-igbimo̩ asofin yii ni e̩ni ti ko ba lo̩kan le fa se̩yin to ba ti foju kan awo̩n ologun yii ni eyi ti ko dara to fun ijo̩ba awa-ara-wa wa ti a fe̩ ki o goke agba.
Ilu Surulere ni o ti salaye yii nigba ti o lo dibo. O si ro̩ awo̩n oludibo ki wo̩n ma se ba o̩mo̩luabi wo̩n je̩.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here