E̩ni tí kò dìbò, kò lé̩nu ò̩rò̩- Dangote
Yínká Àlàbí
Gbaju-gbaja onisowo to lowo ju ni ile̩ Afirika. Aliko Dangote ni o n salaye yii fun awo̩n oniroyin ni kete to dibo re̩ tan.
Adugbo Victoria Island ni ipinle̩ Eko ni o ti dibo naa ni nnkan bii aago kan aabo̩.
Dangote tun fi idunnu re̩ han bi awo̩n eniyan se tu yaayaa jade lati dibo fun e̩ni ti o̩kan wo̩n yan.
Eyi naa lo je̩ ko salaye pe e̩ni ti ko jade lati dibo, ko ni e̩to̩ kankan lati bu e̩nu ate̩ lu ijo̩ba kankan nitori pe ko se ojuse tire̩ naa.
Dangote tun gbe osuba fun ijo̩ba ati ajo̩ INEC fun imo̩ igbalode ti wo̩n tun gbe wo̩ eto idibo naa,