Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń lépa ẹ̀mí-in wa- APC Osun fẹ̀sùn kàn

Ọwọ́ “ICPC” tẹ òṣèré tíátà tó ń ta owó Náírà tuntun.

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí ìwà ìbàjẹ́ bá wọ èèyàn àwùjọ kan lẹ́wù tán, tí onítọ̀ún yóó fi má a tẹ òfin Ìlú mọ́lẹ̀,kò ní-ín fura.

Àjọ tó ń rí sí ìwà ibajẹ ìbàjẹ́ àtàwọn ẹ̀sùn tó bá jọ mọ́ ọn, Independent Corrupt Practices and Other Related Offences (ICPC), ti mú ọ̀kan nínú àwọn òṣèré ilẹ̀ wa, Ọmọsẹyin Oluwadara Esther, ṣùgbọ́n tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Sinmisọla Gold, pé ó ń ta owó Náírà ilẹ̀ ẹ wa. Orí ayélujára ni òṣèré náà gbà lọ, tó ti kéde fún gbogbo ayé pé òun ń ta owó tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń dààmú láti rí níbigbogbo.

Òṣèré tí wọ́n ló tún máa n ta ìpara, epo bẹntiróòlù, bẹẹ lo tun maa n ba awọn ti wọn ba fẹẹ rin irina-ajo lọ silẹ òkèèrè ṣeto ẹ, to si tun n ṣe awọn iṣẹ oriṣiiriṣii mi-in ni Alukoro ICPC, Azuka Ogugua, ni o lo anfaani owo Naira ilẹ wa ti ko fi bẹẹ si nita lati maa ta owo naa ni gbangba, to si n kede rẹ lori ayélujára.

Ogugua sọ pé àwọn kan ni wọ́n wáá ta àwọn lólobó lọ́jọ́ kìn-ín-ní, oṣù Kejì yii, nipa ohun ti ọmọbìnrin naa n ṣe. Eyi lo jẹ ki ajọ naa jade, ti wọn si ṣọ oṣere naa titi ti wọn fi ri i mu.

Ó fi kún un pé òṣèré yìí ló lẹ̀dí àpò pọ pẹlu awọn kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ìnáwó, ti wọn wọn si n ko owo naa kuro ninu banki ati awọn ibi gbogbo ti wọn ti n san an, ti wọn si n lọọ ta a ni ita fun awọn eeyan lọna ẹburu.

Alukoro náà sọ pé wọ́n ti fi ọwọ́ òfin gbé òṣèré yìí, o si ti wa lokolo ICPC, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii wọn lori owo Naira tita ati ipalara to le mu ba ọrọ aje ilẹ wa.

Ṣùgbọn ọ̀tọ̀ lojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi wo ọ̀rọ̀ ọ̀hún, ọrọ buruku lawọn kan n sọ si ajọ naa pẹlu bi wọn ṣe mu ọmọbinrin yii, wọn ni eyi ti wọn ni ki okobo wọn bọ, wọn ko bọ ọ. Ọkunrin kan kọ ọ sabẹ iroyin naa lori sítágíràmù ICPC pé, ‘awọn ICPC yii ko le mu ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa atawọn oṣiṣẹ wọn to n ko owo naa jade fun awọn eeyan. Ẹ wa si Jobi Fẹlẹ Way, n’Ikẹja, ki ẹ waa wo bi wọn ṣe n ta owo fun awọn oloṣelu lọkunrin ati lobinrin.

Ẹnìkan toó pera ẹ̀ ní homestyle_dishes sọ pe ‘ Ṣe ni ki ẹyin eeyan wọnyi lọọ mu awọn máníjà banki ti wọn n ta owo tuntun yii nitori ìmọtara wọn nìkan. Kẹ́ ẹ tún mú awọn to n ta owo nàà láwọn kílọ́ọ̀bù ati ni patí kaakiri, ti awọn mẹ̀kúnù si wa nibẹ ti iya n jẹ wọn.

Ebi n pa awọn eeyan ku, awọn meji ni wọn ku síleéòwòsàn lánàá, alaboyun kan ti ọmọ ọdun marun-un kan, nitori ko si owo ti wọn le san silẹ lọsibitu ati eyi ti wọn le fi ra oogun. Oju opo ko si ja gaara lanaa to fi jẹ pe wọn ko le fi owo ranṣẹ si asunwọn ẹlomi-in. Ninu gbogbo ohun ti a ba n ṣe, ẹ jẹ ka maa ranti pe Ọlọrun to da wa wa laaye, yoo si ṣedajọ onikaluku lasiko to ba yẹ.’

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here