Ọ̀gá àgbà CBN wí tẹnu ẹ̀ lórí owó naira tuntun,níwájú àwọn aṣòfin Orílẹ̀ yìí

Nigeria's Central Bank new governor Godwin Emefiele speaks during a media briefing to announce his monetary policy in Abuja on June 5, 2014. AFP PHOTO/STRINGER (Photo by STR / AFP) (Photo by STR/AFP via Getty Images)

Ọ̀gá àgbà CBN wí tẹnu ẹ̀ lórí owó naira tuntun,níwájú àwọn aṣòfin Orílẹ̀ yìí

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà báńkì àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí, CBN, Godwin Emefiele ti sọ pé àwọn ilé ìfowópamọ̀ yóó tẹ̀síwájú láti máa gba owó náírà àtijọ́ lẹ́yìn gbèdéke iye ọjọ́ tí wọ́n kéde ṣaájú.

Ṣaaju ni CBN ti kọkọ ṣe afikun gbedeke ti awọn araalu gbọdọ lọ paarọ owo atijọ si tuntun, lẹyin ti awọn araalu fariga latari iṣoro ti wọn dojukọ lati paarọ owo naa.

Amọ lasiko to yọju siwaju ile aṣojuṣofin lori ọrọ naa, gomina banki ọhun sọ pe awọn yoo ṣi maa gba owo atijọ ti akoko ti wọn kede lati paarọ owo ọhun ba ti kọja.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ko le maa na owo naa lawujọ mọ, CBN yoo ṣi maa gba owo naa.

O ṣalaye fun awọ aṣofin naa pe oun tẹkọ leti lọ si oke okun ni ko jẹ ki oun kọkọ yọju si wọn lasiko ti wọn kọkọ kọwe pe oun.

Lẹyin naa lo rọ awọn aṣofin naa ki wọn gba ofin naira tuntun ọhun laaye lati mulẹ.

Nigba to n sọrọ lori eredi ti wọn ṣe tẹ owo tuntun, o ni ohun ti CBN n ṣe wa ni ibamu pẹlu bi aye ṣe n yi.

O fi kun pe iye owo to wa nigboro ko si ni ikawọ banki naa.

Emefiele tun ṣalaye pe wọn ko fẹ ki oloriojori maa gba owo to pọ ju lo jẹ ki wọn fi gbedeke le iye owo ti eeyan le gba lori ẹrọ ATM lojumọ kan.

O fi kun pe awọn mọ pe ilana tuntun lori gbedeke iye ti eeyan le gba lojumọ yoo pa awọn eeyan kan lara, amọ wọn ṣe ofin naa pẹlu erongba rere fun awọn araalu.

Àti pé ìlànà tuntun ọ̀hún yóó ran ìjọba lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro ètò ààbò tó ń bá Orílẹ̀ yìí fínra

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here