Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń lépa ẹ̀mí-in wa- APC Osun fẹ̀sùn kàn

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń lépa ẹ̀mí-in wa- APC Osun fẹ̀sùn kàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìlú Ede, ìpínlẹ̀ Osun ti fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ìlú Ede wí pé wọ́n ń lépa ẹ̀mí àwọn.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Muftau Oyewale àti àwọn àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n mìíràn ní àwọn jàǹdùkú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yabo ilé ẹgbẹ́ àwọn tó wà ní ìlú Ede tó jẹ́ ìlú gómìnà Ademola Adeleke tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní na àwọn tí wọ́n bá níbẹ̀.

Oyewale ní àwọn jàǹdùkú náà fẹ́ gba ẹ̀mí lọ́rùn àwọn ni àmọ́ orí ló kó àwọn yọ lọ́wọ́ wọn àmọ́ àwọn ènìyàn àwọn farapa yánnayànna.

Ó ní ìkọlù ọ̀hún kò ṣẹ̀yìn ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Osun èyí tó kéde rẹ̀ pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 2022.

Ó ṣàlàyé pé kò pẹ́ púpọ̀ tí adájọ́ kéde ìdájọ́ rẹ̀ tí àwọn jàǹdùkú fi bẹ̀rẹ̀ ìkọlù wọn, tí àwọn jàǹdùkú náà sì jó ilé ẹgbẹ́ àwọn tó wà ní Èdè South níná.

Bákan náà ló ní àwọn jàǹdùkú náà tún ṣe ìkọlù sí ilé ẹgbẹ́ APC tó wà ní Ede North tí wọ́n sì ba gbogbo nǹkan tó wà níbẹ̀ jẹ́.

Àwọn àgbààgbà náà ní ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò kọjá bí àwọn ṣe gbé àkànṣe àdúrà kan kalẹ̀ lórí ìjáwé olúborí Oyetola ní Tribunal.

Àtẹ̀jáde náà tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP náà tún ń dúnkokò mọ́ àwọn pé àwọn máa pa àwọn tí àwọn yóò sì tún dáná sun ilé àwọn.

Wọ́n wá rọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn ní ìpínlẹ̀ Ọsun láti dá ààbò bo gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wà ní ìlú Ede nítorí inú fu àyà fu ni àwọn wà báyìí.

Bákan náà ni wọ́n rọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti ṣèwádìí gbogbo ìkọlù tó wáyé sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́nu ìgbà tí ìdájọ́ Tribunal ti wáyé.

Wọ́n fi kun pé kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC nítorí gbogbo ènìyàn ìlú Ede kò lè jẹ́ PDP àti pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP wà ní Iragbiji tó jẹ́ ìlú Oyetola.

“Kò sí ẹni tó ṣe ìkọlù sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP to wà ní Iragbiji kódà nígbà tí INEC kéde pé Oyetola kọ́ ló wọlé ìbò kí wá ló dé tí àwa kò ní rímú mí nítorí a jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC ní Èdè?”

Nígbà tó ń fèsì sí ẹ̀sùn APC, alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Osun, dókítà Akindele Adekunle ní irọ́ pátápátá ni gbogbo ẹ̀sùn tí APC fi kan ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.

Adekunle ní ìdààmú bá APC nítorí pé wọ́n fẹ́ jí ipò tí kìí ṣe ti wọn gbà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ àwọn ni gbogbo irọ́ tí wọ́n ń pa.

Ó ní àwọn kò ní jàǹdùkú kankan tó ń ṣiṣẹ́ fún àwọn pé àwọn kò dàbí APC tó ń ti àwọn jàǹdùkú lẹ́yìn fún ọdún mẹ́rin tí wọ́n fi wà nípò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here