Òkú tó sọnù níléèwòsàn è̩kó̩ṣé̩ ìṣègùn OOUTH ni Ṣagamu gbo̩dò̩ di rírí – Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe

Òkú tó sọnù níléèwòsàn è̩kó̩ṣé̩ ìṣègùn OOUTH ni Ṣagamu gbo̩dò̩ di rírí – Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe

Láti ọwó̩ Adefunkẹ Adebiyi

Latari oku obinrin kan to deede di awati nileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo, Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital (OOUTH) to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, eyi to mu meji ninu awọn oṣiṣẹ to n ṣọ abala ibi toku naa wa sa lọ raurau, awọn alaṣẹ OOUTH ti ṣeleri pe awọn yoo wadii iṣẹlẹ naa delẹ, awọn yoo wa oku naa ri, awọn yoo si fi oju ẹnikẹni to ba jẹbi hande.

Ṣe lọjọ Ẹti to kọja ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn,oṣu kin-in-ni ọdun 2023 yii ni awọn mọlẹbi oku naa lọ sileewosan OOUTH lati gba oku wọn ki wọn si sin in.

Oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni wọn ti gbe oku naa sibẹ gẹgẹ bi awọn mọlẹbi obinrin to ṣalaisi naa ṣe sọ.

Ṣugbọn si iyalẹnu awọn ẹbi oku,niṣe lawọn oṣiṣẹ OOUTH ko ri oku naa gbe jade. Oku mọkandinlaadọrin la gbọ pe wọn ko jade fawọn eeyan oku ti wọn wa sọsibitu naa, ṣugbọn ko si ti obinrin naa nibẹ rara.

Nigba ti iṣẹlẹ ọhun yoo si mu ifura dani patapata, meji ninu awọn oṣiṣẹ to n mojuto awọn oku naa tun sa lọ raurau, ẹnikẹni ko si ri wọn pe lori aago mọ.

Iṣẹlẹ yii di tọlọpaa ipinlẹ Ogun, iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati mọ ohun to ṣẹlẹ ti oku fi sọnu, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lati ri awọn oṣiṣẹ to na papa bora naa mu.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ iyanu yii, ọga agba lọsibitu OOUTH,Dokita Oluwabunmi Fatungaṣe,ṣaleye ninu atẹjade to fi sita, pe gbogbo ipa lawọn ti n sa lati wadii ohun to fa a ti oku fi sọnu.

Dokita Fatungaṣe sọ ọ di mimọ pe awọn alaṣẹ ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun yii ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹka tọrọ kan lati fidi otitọ mulẹ.

Bẹẹ lo ni awọn ti n ṣiṣẹ lori ẹrọ ayaworan ti wọn n pe ni CCTV to wa nileewosan yii, lori awọn aworan to ti ka silẹ.

Nibi ti ati ri oku naa ṣe koko lọkan awọn alaṣẹ OOUTH de, Fatungaṣe sọ pe awọn yoo ṣe ayẹwo DNA fawọn oku to wa nibẹ, lati da oku ti wọn n wa yii mọ.

O fi kun un pe ijọba ipinlẹ Ogun ti ro ileewosan yii lagbara pẹlu awọn irinṣẹ igbalode ati ohun elo tawọn nilo, idi naa si niyẹn to fi di aayo awọn eeyan. O ni iru ohun to ṣẹlẹ yii ṣajoji pupọ,ko si ni i lọ bẹẹ lai yanju.

O waa bẹ awọn eeyan oku ati gbogbo ẹni tọrọ yii kan, pe ki wọn ni suuru pẹlu ileewosan yii, awọn yoo wa oku wọn jade, awọn yoo si gbe e fun wọn lati sin in lọna ẹyẹ laipẹ rara.

Igbiyanju wa lati ba Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọrọ lati mọ ibi to de duro labala awọn ọlọpaa ko seso rere rara,Alukoro ko gbe ipe ta a fi ṣọwọ si i.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here