N’Ilaro, Abiọdun jalè ní ṣó̩ò̩ṣì, ó tún wọlé méjì jí fóònù

N’Ilaro, Abiọdun jale ni ṣọọṣi, o tun wọle meji ji foonu

Adefunkẹ Adebiyi

Ọmọkùnrin yii, Abiọdun Elegbede tọjọ orí rẹ ko ju mọkandinlogun (19) lọ lo ti wa lahaamọ awọn olópàá niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun bayii, ìyẹn lẹyin t’awọn fijilante So-Safe mu un l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kin-ni-ni ọdún yii, pe o fọ̀ ṣọọṣi jale ladugboo Agọ Ararọmi, Ilaro, bẹẹ lo sí tun ja awọn ile meji mi-in lole laduugbo kan naa.

Ọga agba fún So-Safe, Kọmandanti Sọji Ganzallo, ṣalaye ninu atẹjade ti ACC Moruf Yusuf ti i ṣe alukoro ajọ naa fọwọ si, pe awọn kan ni wọn pe So-Safe nigba ti wọn kofiri oju ọmọkùnrin kan ti wọn o mọ ri,to si jẹ awọn nnkan bii foonu merin ti dawati nibi t’awọn oninnkan ko wọn sì, ọwọ ẹlẹgiri naa ni wọn si ti ba wọn.

Nigba ti ikọọ fijilante ti SC Ọjẹrinde Wasiu ko sodi de’bẹ lo di mimọ pe Abiọdun Elegbede lọmọkunrin to jale naa n jẹ. Ati pe Ajegunlẹ lo n gbe, n’Ipobẹ, ijọba ibilẹ Ipokia nipinlẹ Ogun kan naa.
Awọn eeyan ti fi lulu da bira si i lara gidi k’awọn So-Safe too de, awọn agbofinro naa ni wọn pada gba a silẹ pẹlu foonu Itel mẹrin ti wọn ba lọwọ rẹ, kia ni wọn sì ti fa a le awọn olópàá teṣan Ilaro lọwọ fun itẹsiwaju iwadii ati bi yoo ṣe dele-ẹjọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here