INEC ṣàfikún ọjọ́ tí àwọn aráàlú lè fi gba PVC wọn

INEC ṣàfikún ọjọ́ tí àwọn aráàlú lè fi gba PVC wọn

Ọrẹ Akínṣọlá

Àjọ elétò ìdìbò, INEC, ti ṣe àfikún ọjọ́ tí àwọn aráàlú lè fi gba káàdì ìdìbò alálòpẹ́, ẹ PVC, wọn.

Ṣaájú ni INEC ti kọ́kọ́ sọ pé ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Kínní ọdún yìí ni àwọn yóó fòpin sí gbíga PVC náà kó tó sún síwájú pẹ̀lú ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn.

Ni bayii, INEC tun ti sọ pe awọn araalu le maa gba PVC ọhun titi di ọjọ karun un, oṣu Keji, ọdun 2022 yii.
Ninu atẹjade kan ti INEC fi ṣọwọ si awọn akọroyin lẹyin ipade kan to waye niluu Abuja lo ti kede bẹẹ.

Kọmiṣọna ajọ naa, Festus Okoye ni alaga ajọ ọhun, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ ki awọn eeyan le ri gba kaadi naa gba.

Atẹjade naa ni “Lẹyin awọn iroyin to n tẹ wa lọwọ kaakiri awọn ọọfisi wa, a ti pinnu lati fi ọsẹ kan kun iye ọjọ ti awọn araalu le fi gba PVC wọn.”

“Nitori naa, awọn araalu lanfani lati maa gba kaadi naa titi di ọjọ karun un, oṣu keji, ọdun 2023 yii.”

Okoye fi kun pe “Igba keji ree ti ajọ yii yoo sun ọjọ ti gbigba kaadi naa yoo dopin siwaju kaakiri Naijiria, eyii si ni igba ikẹyin ti yoo ṣe bẹẹ.

Yatọ si pe INEC ṣe afikun ọjọ ti awọn eeyan le gba PVC wọn, ajọ naa tun fi wakati meji kun iye akoko ti awọn eeyan le maa gba kaadi naa.

To n tumọ si pe ni bayii, gbigba kaadi naa yoo bẹrẹ lati aago mẹsan an aarọ titi di aago marun un irọlẹ ni gbogbo ọjọ to wa ninu ọsṣe, lai yọ ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku silẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here