CBN’ gbéná wojú àwọn báǹkì tó ń kó owó náírà àtijọ́ sínú ATM wọn dánrin

‘CBN’ gbéná wojú àwọn báǹkì tó ń kó owó náírà àtijọ́ sínú ATM wọn dánrin

 

Ọrẹ Òtítọ́jù

Báńkì àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí ti sọ pé òun ò ní-ín bojú fi wẹ̀yìn, láti fimú àwọn ilé ìfowópamọ́ tó ń kó owó o náírà àtijọ́ sínú ẹrọ ATM wọ́n ní ìpínlẹ̀ Ogun dánrin.

Ọdun to kọja ni CBN kede owo igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira tuntun to si sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2023 yii ni opin yoo de ba nina owo naira atijọ.

Ni bayii to ku nnkan bii ọsẹ meji ki gbedeke ti CBN fi lede lori owo atijọ naa pe, ọpọ araalu ni ko tii ri owo naa gba.
Ẹwẹ, adari CBN niluu Abeokuta, Lanre Wahab sọ pe awọn yoo fi imu ile ifowopamọ to ba ṣi n ko owo atijọ sinu ẹrọ rẹ danrin.

O ni “Banki apapọ yoo fi iya jẹ ile ifowopamọ to ba ṣi n fun awọn araalu ni owo atijọ ninu ATM wọn.”

Wahab ni CBN yoo bẹrẹ si n yẹ awọn ẹrọ ATM wo lati ri daju pe owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ lo wa ninu rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2023 ni CBN ti paṣẹ ki awọn ile ifowopamọ dẹkun ati maa fun araalu ni owo atijọ.

O fikun pe “Eyikeyi ile ifowopamọ ti a ba fiya jẹ lori ọrọ yii, iya naa tọ si irufẹ banki bẹẹ, nitori a ti kilọ fun wọn ṣaaju.”

Wahab wa rọ awọn araalu lati maṣe bẹru lati na owo tuntun naa nitori o gba ontẹ ijọba.

Lẹyin naa lo rọ wọn ki wọn tete lọ paarọ owo nairan atijọ si tuntun ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 ti wọn yoo fopin si nina rẹ kaakiri Naijiria.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here