Ọmọ ogun orí omi gún ọlọ́pàá pa l’Ékòó

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọmọ ogun orí omi gún ọlọ́pàá pa l’Ékòó

 

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àrìnfẹsẹ̀sí ò nílé fún ẹni orí bá ti kọ ìjàǹbá mọ́, à fi kí Ẹlẹ́dàá ṣáà má a pawámọ́ nínú ewu
gbogbo.
Ńṣe ni ọ̀rọ̀ di bó ò lọ o yàgò fún mi nígbà tí ìjà ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́pàá àti òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ojú omi ní agbègbè Satelite Town ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ìkọlù náà ló ṣokùnfà ikú ọ̀gá ọlọ́pàá kan, ASP Abion Hezikel.

Ìròyìn ní àwọn ọmọ ogun orí omi náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Central Pay Office, Apapa tún ṣe àwọn ará ìlú mìíràn tó gbìyànjú láti pẹ̀tù sí ááwọ̀ léṣe.

Ní nǹkan bí i aago mẹ́jọ alẹ́ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá wà lẹ́nu iṣẹ́ ní agbègbè Oluti, Agboju dá àwọn òṣìṣẹ́ Navy náà dúró lórí ọ̀kadà tí wọ́n gùn wí pé wọ́n lòdì sí òfin ètò ìrìnnà.

Àwọn mẹ́rin ni àwọn ọmọ ogun orí omi tí wọ́n gbé ọ̀kadà méjì láti gba tí kìí ṣe ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà.

À mọ́ àwọn ọlọ́pàá náà kò mọ̀ wí pé ẹ̀ṣọ́ ojú omi ni wọ́n nítorí wọn kò wọ aṣọ iṣẹ́ wọn tí wọn kò sì sọ irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún.

Óṣojúmikòró kan tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàlàyé pé nígbà tí àríyànjiyàn tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọmọ ogun náà le díẹ̀ ni ọmọ ogun ọ̀hún bínú fọ ọlọ́pàá kan létí.

Steven Ogbodo nígbà tó ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wáyé fún ilé iṣẹ́ ìròyìn Daily Sun ní ọlọ́pàá ọ̀hún fi ìbínú gba ọmọ ogun ọ̀hún létí padà kí ọ̀rọ̀ ọ́hún tó di iṣu ata yán-an-yàn-an.

Ogbodo, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà bá fa ọ̀bẹ yọ tó sì fi gún ọlọ́pàá náà àti àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ tí wọ́n gbèrò láti báwọn parí ìjà tó wáyé láàárín wọn.

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n gún ṣùgbọ́n àwa tètè bá ẹsẹ̀ wa sọ̀rọ̀ nítorí àwọn ọmọ ogun náà kò kọ̀ láti pa ẹnikẹ́ni.”

Nígbà tí wọ́n fi máa gbé àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ará ìlú tó farapa dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, ASP Abion Hezikel ti darapọ̀ mérò ọ̀run.”

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣàlàyé pé ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọlọ́pàá tó tètè débẹ̀ lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ìjàmbá tí àwọn ọmọ ogun ọ̀hún kò bá ṣe kò bá jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Hundeyin ní àwọn méjì nínú àwọn ọmọ ogun mẹ́rin náà ló wà ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti fún ìwádìí kíkún.

Bákan náà ló ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó iléeṣẹ́ ológun létí àti pé àwọn ti bèrè lọ́wọ́ wọn láti fa àwọn méjì yòókù tó na pápá bora lé àwọn lọ́wọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here