Omo Niger Delta ni iyawo mi – Bola Tinubu

Tinubu ati Remi

Mary Seunfunmi Fagbohun

Oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti se alaye pe Omo bibi agbegbe Niger Delta ni iyawo oun, Senito Remi Tinubu.

Koda, o wi pe, leyin ti oun ti gba oye ibile lati Gbaramotu ni ipinle Delta ni oun ti di okan lara won.

O fi kun un pe oun kun oju osuwon lati le je omo Niger Delta nitori iyawo oun wa lati ibe.

Ni Oporoza, Gbaramotu ni o ti so eyi, nibi ti o ti se ileri lati maa ba awon adari Niger Delta se asaro lati le seto ati se agbekale awon eto isejoba ati ipilese ti yoo mu ki agbegbe naa dagba soke.

O soro niwaju awon loba-loba ti won n dari agbegbe naa eyi ti Pere ti Gbaramotu, Kabiesi Oboro Gbaraun keji, se akoso won.

Ninu ipade naa, oludije fun ipo aare naa tun gba oye tuntun  miiran ‘Iyelawei’ ti Gbaramotu, oye yi ni o tumo si agbenaru gbegbe naa.

Nigba ti o gba Asiwaju lalejo ni aafin re, Pere ti Gbaramotu gboriyin fun oludije egbe oselu APC naa,  ti o si gbadura fun aseyori re ninu idibo fun ipo aare naa.

Gegebi oro kan lati offisi alukoro Tinubu, ti agbenuso re, Tunde Rahman, bu owo lu, Oba naa ro Tinubu pe ti won ba dibo yan, lati ri daju pe o da ibudo oko oju omi nla kan si Gbaramotu, ibudo ile ise, ati popona ti o ja geere ati afara ti o wo agbegbe naa.

Ninu ifesi re, Asiwaju Tinubu se ileri lati sise ki o le mu ki idagbasoke agbegbe naa ya ni kankan, o wi pe oun yoo ba awon adari se asaro loorekoore lati le se ipinlese ati ise akanse ti yoo ran agbegbe naa lowo.

“Okan lara yin ni mi, Omo Niger Delta ni iyawo mi. Ana yin ni mo je. Abi bee ko?’, Tinubu so fun won.

O ni oun mo si ise ti won bere sise re ni popona Warri-Escravos/Gbaramotu, o si jeje pe ise naa yoo di pipari nipa gbigba osise ti o mo nipa ise naa lati se e bo ti ye.

O tun so wi pe, bi won ba dibo yan oun, eeka ijoba Niger Delta ati ajo ti o n ri si idagbasoke Niger Delta yoo sise takuntakun fun idi ti won fi da won sile.

“Okunrin ti o duro niwaju yin yii yoo se ohunkohun ti o ba so. E nilo ooto, e nilo ifarasin lati sise. Mejeeji ni mo ni. Mo mo ona naa, ma a si ko gbogbo awon eniyan Niger Delta dani. A o se asaro pelu awon adari yin fun idagbasoke Gbaramotu ati awon agbegbe ti o so mo.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here