Ilé aṣòfin America buwọ́lu ìgbèyáwò akọsákọ, abosábo.

Ilé aṣòfin America buwọ́lu ìgbèyáwò akọsákọ, abosábo.

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí òpin ayé bá ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n,àgbọ́damiẹnu ìròyìn letí yóó má á gbọ́.
Ṣùgbọ́n o,òfin tí a fi dá ìlú n náà la fi í ṣèlú, èyí ló díá fún bílé aṣòfin àgbà ní orílẹ̀-èdè America, ti buwọ́lu òfin tí yóó dáàbò bo ìgbéyàwó àwọn èèyàn tó ń fẹ́ irú wọn, àti ìgbéyàwó àwọn tí kìí se ẹ̀yà kan náà.

Ofin naa yoo lọ si ile igbimọ asoju-sofin, ti ireti wa pe yoo buwọlu, ti yoo si fi ranṣẹ si Aarẹ Biden lati fi àṣẹ si. Àwọn to ṣe agbatẹru ofin naa ni ireti pe yoo di àṣẹ, saaju kí ẹgbẹ́ oṣelu Republican to gbakoso ile aṣòfin ni oṣu Kínní. Sugbọn ṣa, ofin naa ko fi dandan si pe gbogbo ipinlẹ gbọdọ fi ontẹ lu igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin. Ofin tuntun yii fi ẹsẹ mulẹ lasiko ti ile ẹjọ́ to ga julọ ni America wọgile òfin ìjọba apapọ to n ṣe atilẹyin fun oyún ṣiṣẹ. Lati igba naa ni awọn to n polongo igbeyawo LGBT ti n fi ibẹru han pe igbeyawo naa le koju idunkoooko lọjọ iwaju. Asofin mẹtadinlọgọrun lo dibo lọjọ Iṣẹgun, ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu Republican mejila ninu wọn silo faramọ. Àwọn aṣòfin Republican kan fi ara mọ lẹyin ti wọn ṣe atunse si lati faaye gba ominira ẹ̀sìn.

Olori ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu to pọju nílé aṣòfin agba, Chuck Schumer, gbóríyìn fun igbeṣẹ awọn aṣòfin, to si sapejuwe òfin tuntun naa gẹgẹ bi igbeṣẹ si igbe aye to dọgba. “Bi buwọ lu ofin yii tumọ si pe gbogbo ọmọ America lo ni ẹtọ kan naa, lai naani iru eeyan ti wọn jẹ tabi ẹni tí wọ́n nifẹ si – ìwọ naa ni ẹtọ si itọju kan naa ati apọnle lábẹ́ òfin.” Sẹnetọ Tammy Baldwin, ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu Democrats, to jẹ Sẹnetọ akọkọ to fi ara rẹ han ni ẹni tó fẹ́ràn ìbálòpọ̀ ọkùnrin si ọkùnrin, lo ṣe agbatẹru òfin naa. O ni ofin tuntun yii yoo daabo bo akitiyan fun anfaani kan naa fun orisirisi igbeyawo ni America.

Òfin tuntun yii ni yoo ka ile ẹjọ́ to ga julọ lápá kò, to ba gbiyanju lati wọgile igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tàbí obìnrin si obìnrin lọjọ iwaju. Ofin tuntun naa tako òfin ti wọn ṣe lọdun 1996, Defense of Marriage Act, eyi to pàṣẹ pe laarin ọkùnrin ati obinrin nìkan ni igbeyawo gbọdọ ti ma a waye. Ile ẹjọ́ to ga julọ dajọ lọdun 2013 pe òfin naa ko ba òfin òfin orile-ede mu. Ofin tuntun yii tún pa a ni dandan fun awọn ipinlẹ lati tẹwọgba igbeyawo LGBT ti wọn ṣe ni ipinlẹ mii, kí wọ́n si fun tọkọtaya naa ni àwọn anfaani ijọba apapọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here