Sanwo-Olu pelu Ara

Mary Seunfunmi Fagbohun

Gomina Babajide Sanwo-Olu ni Ojoruu, iyen Alaaruba, ni anfaani lati fi ijo re han nigba ti obinrin inilu, Ara, ba a lalejo.

Bi Ara se n lu ni Sanwo-Olu n jo, ti tapa-tese re si n ba gangan mu.

Arabinrin naa, Araoluwa Olumuyiwa lo si odo Sanwo-Olu lori awon omo alarinka to ti kojo, to n se eto iwuri fun.

Ijoba Eko lo n ran an lowo lori eto yii.

Gomina wa ro awon omobinrin ati omokunrin igboro ti won gba sile naa lati ma dekun lori ala won lati di eni nla lawujo.

Sanwo-Olu gba won niyanju ni ile ijoba ni Ikeja, Eko, nigba ti o gba alejo ayanbinrin ti oruko re gangan n je, Aralola Olumuyiwa, ati awon omo ti o n gbe popona ti o gba mora ti o si gba sile labe eto “Eko wu mi lori” eyi ti ijoba ipinle Eko n se atileyin fun.

Die lara won je eni ti awon obi won ko ko mora ati awon ti ipinya wa laarin ebi won. Awon miiran kuro nile nitori iya asilo, nigba ti awon miiran gba lati jiya loju popo leyin ti baba ati iya won ku tan.

Gbogbo ala won ati ireti won ni o di korofo, won wa di aninilara kiri adugbo, won si ri won gegebi ewu ilu ki won to gba won sile.

Awon ti oro kan naa ni igbe aye won ti n yi pada si rere nipase eto “Eko wu mi lori” ti Gomina Sanwo-Olu se atileyin fun. Gomina naa ro awon ti won gba sile naa lati mase so ireti nu lori ala won, sugbon ki won se amulo eto naa lati le e mu ki ebun abinibi won ru gege si i.

Gomina gboriyin fun ayanbinrin naa fun dida eto ti o n gba awon omo popona naa la, o si jeje lati gbaruku ti eto naa ati pe yoo lo o fun awokose rere lati mu ki awujo tesiwaju.

Sanwo-Olu fwa owosi ipese elo ise ati irinse fun ogorun lara awon omo naa ninu ise ti onikaluku won yan laayo.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here