Àwọn ará ìlú bèèrè fún ìpèsè iṣẹ́ bí Ààrẹ ṣe ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní Bauchi àti Gombe

Àwọn ará ìlú bèèrè fún ìpèsè iṣẹ́ bí Ààrẹ ṣe ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní Bauchi àti Gombe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Bauchi àti Gombe ní ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti rọ ìjọba Nàìjíríà láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà bí ìjọba yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn ènìyàn náà nígbà tí wọ́n ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ohun tó ń jẹ́ àwọn níyà ní ìpínlẹ̀ àwọn ni àìníṣẹ́.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní agbègbè Kolmani tó jẹ́ ààlà Bauchi àti Gombe.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, arákùnrin kan, Usman Tahir ní ó ti pẹ́ tí inú òun ti dùn báyìí kẹ́yìn nítorí ó ti pẹ́ tí àwọn ti ń dúró kí ètò wíwa epo rọ̀bì wáyé ní agbègbè àwọn.

Tahir ní láti ìgbà tí àwọn ti wà ní kékeré ni wọ́n ti máa ń sọ fún àwọn wí pé epo rọ̀bì wà ní ìpínlẹ̀ àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kò wà á títí di ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní àmọ́ ohun tó kù fún báyìí ni kí ìjọba bá àwọn ṣe ọ̀nà láti wá iṣẹ́ fún àwọn.

“Ìpínlẹ̀ wa wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn tí kò níṣẹ́ pọ̀ sí jùlọ àti pé ọ̀nà láti yọ àwọn ènìyàn kúrò nínú ìṣẹ́ ni ṣíṣe àwárí epo rọ̀bì náà yẹ kó jẹ́.”

Ní ti Adamu Warji ní tirẹ̀, ó rọ ìjọba láti ṣe òótọ́ láti pèsè iṣẹ́ òdodo fún àwọn ènìyàn nítorí àwọn kò fẹ́ kí irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn ààrin gbùngùn gúúsù ṣẹlẹ̀ sí àwọn náà.

“Àǹfàní ṣíṣe àwárí epo rọ̀bì la fẹ́ jẹ, a ò fẹ́ ohun tí yóò ba ilẹ̀ wa jẹ́.”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ikọ̀ ìròyìn tó wà ní Kolmani sọ, ó ní lẹ́yìn tí Ààrẹ Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ náà tán ni wíwá epo yóò tún tẹ̀síwájú láti mọ ibi tí epo rọ̀bì náà pẹ̀ka dé.

Ní ọdún 2016 ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ wíwá epo rọ̀bì ní àríwá Nàìjíríà léyìí tó ṣe àfihàn rẹ̀ wí pé epo rọ̀bì wà ní àwọn ìpínlẹ̀ Bauchi, Gombe, Borno àti Niger.

Àjọ NNPC ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo rọ̀bì tí wọn kò ì típi ṣe àwárí ló wà ní àwọn ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ni èròńgbà wà pé wọn yóò kọ́ ilé iṣẹ́ ìfọpo rọ̀bì sí agbègbè náà láti máa fọ epo rọ̀bì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here