Àwọn tísà kan máa ń lù mi bí ẹni máa kú ní nítorí pé mo jẹ́ ọmọ Fela – Femi Kuti

Femi Kuti
Mary Seunfunmi Fagbohun
Femi Kuti, omokunrin agba oje olorin afrobeat, Fela Anikulapo-Kuti, ti se afihan iriri re nipa bi awon eniyan se korira re nigba ti o n dagba nitori pe o je omokunrin Fela.
Femi fi eyi han ni ori abala eto kan ti a mo si #withChude ni ose yi. O si tun soro bi oun se je baba ti o n danikan toju omo, pipadanu obi, ati ipa ti o ko ninu aye re.
O se iranti ohun ti oju re ri gegebi omokunrin Fela, nigba ti o n dagba, Femi wi pe “awon eniyan ko feran mi nitori pe mo je omo Fela. Ile iwe lilo wa di ohun ibanuje okan fun mi nitori awon oluko kan wa ti won feran baba mi, nigba ti awon kan ko feran re. Nitorina, ti mo ba se si okan lara awon oluko ti ko feran baba mi, oluko naa yoo na mi bi eni ma ku ni, nitori pe won ko feran baba mi. Nigbana awon omo olowo kan wa ni ile iwe ti mo n lo ti won ko feran mi nitori pe mo je omokunrin Fela. Fun idi eyi, gbogbo akoko mi ni ile iwe ni mo fi n ja.”
Iriri ibanuje miran ti oju re ri bo ti  se n dagba gegebi o se so ni pe baba oun ma n na oun nigba ti oun wa ni omode.
Femi tun so ohun ti o koju pelu ibanuje leyin iku awon ti o feran, ni pataki julo iya re. “Mo ni iriri iku naa. Iku iya mi ni o je akoko ti o buru ju nitori pe opomulero ni iya mi je fun mi, nigba ti o ku, mo sonu. Fun bi odun meta abi merin ni maa ji lowuro ti ma fe lo ki iya mi, e duro na! Fela sese lo, aburo mi obinrin ti lo, ibatan mi ti lo. Awon eniyan kan so asotele pe mejila ninu wa ni yoo ku, mo wa n ronu wi pe, se asotele yi yoo wa si imuse ni?
Nigbana na ni wahala de ninu ebi mi, iyamo mi ko mi sile, won wa n so wi pe, ‘Femi ti n ya were’. Sugbon mo dupe pe mo bori gbogbo re, mo ro wi pe eyi ni o so mi di eniyan gidi.”
Lori ibasepo pelu omokunrin re, ìyẹn Made, o wi pe “Nigba ti mo n to omokunrin mi, oro re jemil ogun gidi. Mo ti padanu iya mi, iyawo mi ti lo, Made wa je ayo fun mi. Fela ti lo, ohun kan ti mo ri diromo ni omokunrin mi. O tun je ki n ranti igba odo mi, awon eniyan ro wi pe nitori pe a je omo Fela, o je ohun ti o dara. Nitori naa, mo wa so wi pe, kinni ohun aburu ti Fela se gan ninu aye mi? Nibo ni mo ro pe o ti se asise, maa se atunse pelu omokunrin mi, ati ni ibi ti mo ro pe o ti se ohun ti o to, maa tenumo ati pe maa to ki oye le e ye pe mi o pe bii baba.”
Bi o se n tesiwaju, o fikun pe: “Nígbà tí o n dagba, a lo odun mefa ni ojubo Shrine nitori ti won n ran awon ipata ati olopaa lati maa lo kaakiri agbegbe naa. Mo ko gbogbo awon omo ti mo n gbato ati omokunrin mi si ori oke nigbana, enikan wa so fun mi pe, bi won ba pa omokunrin mi nko? Nitorina, mo ro wi pe ise iranse oselu ni nitori ti mo n se oselu gidi ni igba naa. Ko si ero ayelujara bi ti ode oni. Nitorina, awon eniyan yoo lo kaakiri, olopa naa yoo lo laakiri ojubo naa. Ko si eni ti yoo soro, awon onirohin n dite mi fun idi ti won mo laaye ara won. Gbogbo ohun ti mo ni ni omokunrin mi, egbon mi obinrin ati omobinrin re. Sugbon omokunrin mi sunmo mi gidi nitori pe o je omo mi. Nitorina, mo muu gidi, mo si fun ni gbogbo anfaani ti mi o ni ninu orin kiko ati bibeko. Nitorina, gbogbo eniyan ro pe mo n to bii akebaje, won a si maa so wi pe mo n baa je. Maa dahun pe: “Bi ododo lori o; emi ni mo n fun ni oorun, ti mo si n bomi rin.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here