Kosi ibaṣepọ láàárín èmi àti àwọn tì inú bii nínú ẹgbẹ òṣèlú PDP….Goodluck Jonathan.
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ààrẹ àná fún orílẹ̀èdè yìí, Goodluck Jonathan ti kéde pé kòsí ìbáṣepọ̀ kankan láàrin òun àti àwọn igun ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí wọ́n fi ọwọ́ jánú nínú ẹgbẹ́ náà àti wí pé àwọn igun náà kò jà fún ẹ̀tọ́ òhun.
Jonathan so eyi ninu atẹjade kan ti agbẹnuso rẹ Ikechuckwu Eze gbẹ jade.
Awọn gomina marun-un kan to pe ara n ni G5, Nyesom Wike ti Rivers,Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Samuel Ortom lati ipinlẹ Benue, Okezie Ikpeazu ti Abia, ati Ifeanyi Ugwuayi ti Enugu n ki Iyorchi Ayu fi ipo si gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ PDP.
Eyi kọ ṣẹyin bi oludije ṣipo aarẹ ẹgbẹ naa, Atiku Abubakar ati alaga ẹgbẹ se wa lati igun orilẹede kan naa.
Ṣugbọn, Ayu fi apa janu pe ohun yoo paari saa oun gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.
Eleyi lo mu ariyanjiyan ati awuyewuye wa wi pe awọn ẹgbẹ G5 nja fun etọ Goodluck Jonathan, eleyi ti aarẹ ana kọrọ oju sii.
Jonathan sọ ninu atẹjade naa wi pe ohun ko ni ikun sinu sii Atiku Abubakar nitori pe oun kopa ninu awọn ipolongo rẹ lati dii aarẹ lọdun 2019.
Bakan naa lo ni oun tẹle lo si ipinlẹ Rivers ati Bayelsa ninu ipolongo ẹto idibo ọdun naa.
Goodluck Jonathan ti wa pe fun ijiroro laarin awọn igun mejeji.
O si rọ awọn to n gbe iroyin ofege nipa rẹ ati ẹgbẹ oṣelu PDP lati jawọ nitori ki irẹpọ ati alaafia le fẹsẹ mulẹ ninu ẹgbẹ naa ni oun n ja fun.