Ẹ má fẹ̀mí-in yín ṣòfò nítorí olóṣèlú kankan– Matthew Kukah
Ọrẹ Òtítọ́jù
Bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Àgùdà ìpínlẹ̀ Sokoto, Mathew Kukah ti ké sí àwọn olólùfẹ́ àwọn olóṣèlú láti má pa ara wọn nítorí olóṣèlú kankan.
Kukah lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels lẹyin wakati diẹ ti aworan kan jade nibi ti Bola Tinubu ati Atiku Abubakar ti n yọ mọ ara wọn ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe to wa niluu Abuja.
O ni ọrẹ ni gbogbo awọn oloṣelu, ohun ti wọn yoo si jẹ ni wọn n wa, ko si yẹ ki awọn ololufẹ wọn maa ba ara wọn ja lori ọrọ oṣelu.
Alufa naa ni o yẹ ki awọn to n tẹle awọn oloṣelu kẹkọọ lara Tinubu ati Atiku ti wọn di mọ ara wọn lai si ikunsinu kankan lasiko ti wọn pade ni papakọ ofurufu.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o n tumọ si pe awọn ololufẹ awọn oloṣelu naa gbọdọ gba alaafia laaye ninu eto oṣelu ti wọn n ṣe.
O ni “Gbogbo aye wọn lawọn oloṣelu yii n fi n wa bi wọn yoo ṣe jẹ lara Naijiria, ti wọn yoo si pin laarin ara wọn.”
“Awọn eeyan to n tẹle wọn si gbọdọ mọ pe awọn oloṣelu yii mọ ara wọn.”