Ohun tí Davido ati Chioma ń là ko̩já kò de̩rùn – Tuface

Ohun tí Davido ati Chioma ń là ko̩já kò de̩rùn – Tuface

Seunfúnmi Fágbohùn

Olokiki olorin ni, Innocent Idibia, ti gbogbo eniyan mo̩ si 2face, ni o ti fi e̩dun o̩kan re han lori ohun ti Davido ati obinrin re Chioma le e ma la ko̩ja le̩hin iku o̩mo̩ wo̩n, Ifeanyi.

Ifeanyi ni o ku le̩hin ti o ri sinu odo iwe ninu ile baba re̩ ni Banana Island to wa ni ilu Eko laipe̩ yii.

Ninu ate̩jade kan lori ayelujara ni 2face ti fi aworan awo̩n obi Ifeanyi han, ti o si ko̩ o̩ wi pe, ko si e̩ni ti ohun ti wo̩n n la ko̩ja le e ye.

O ko̩ o̩ sile̩ pe, oun ko mo̩ ohun ti oun le e so̩ ati wi pe o̩ro̩ naa dun un lati igba ti irohin ibanuje̩ naa ti jade lori ayelujara.

O so̩ pe:

“KO SI E̩NI TI O LE E YE NI TOOTO̩ OHUN TI AWO̩N O̩DO̩MO̩DE MEJI YII N LA KO̩JA LO̩WO̩LO̩WO̩”

EYI DUN NI DENU EEGUN. MI O MO̩ OHUN TI MO LE E SO̩.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here