Woli Arole laali ojise to so asotele iku omo Davido

Davido ati Ifeanyi

Mary Seunfunmi Fagbohun

Ilumooka aderin paniyan ni, Woli Arole, ti fi esun kan woli kan, Samueli Kig, lori bo se ni oun se asotele iku omo gbajugbaja olorin, Davido.

Oruko Woli Samueli ni o ti di ilumooka lori ero ayelujara leyin asotele ti o so nipa Davido ni ibeere odun ti a wa yi ti o si wa si imuse.

Leyin iku Ifeanyi Adeleke, iyen omo Davido, o jade lati ran gbogbo eniyan leti asotele re ti o so nipa omo naa ati pe o pe Davido ati gbogbo awon idile Adeleke lati wa oun kan, ki won ki o le da ibi ojo iwaju duro.

Woli Arole, eni ti inu re ko dun si iwa ti Woli yi hu, ni ise lo ye ki woli na gbadura ki o si ba awon idile na kedun.

Gegebi Arole se so, lati igba ti Olorun ti ba woli naa sooro nipa iku omo naa, ni se ni o ye ki o gbadura fun idile na dipo eyi ti o fi n se bi ariran.

O wi pe,”Leyin ipadanu, ohun ti o dara ju lati se bi eni emi ni lati gbadura fun idile ti oro kan ki o si bawon kedun.

Kii se akoko niyi lati so pe “Sebi Olorun ti so eyi funmi tele.

“DAKE ENU E.

Gbadura fun won, o tan.

Mase se bi ariran osi!!!!…”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here