Mr Macaroni sò̩rò̩ sí olórí ò̩dó̩ nínú e̩gbé̩ òsèlú APC
Ilumo̩o̩ka olude̩rin paniyan ni, Adebowale Adedayo, ti gbogbo eniyan mo̩ si Mr Macaroni, ti kede atile̩hin re̩ fun oludije ipo Aare̩ labe̩ asia e̩gbe̩ oselu Labour Party, Peter Obi, o so̩ro̩ idoju ija ko̩ni si olori o̩do̩ All Progressives Congress Dayo Isreali, eni ti o wi pe, e kede pe ko si anfaani yiyan e̩gbe̩ oselu miiran yato̩ si e̩gbe̩ APC.
Isreali lo so̩ wi pe oludije ipo Aare̩ ninu e̩gbe̩ oselu APC ti jawe olubori boya enikan fe̩ tabi o ko̩.
Macaroni se apejuwe re̩ ge̩ge̩ bi o̩ro̩ ipanilaya ati ti omugo̩ ti ko mu laakaye kankan wa.
Olude̩rin paniyan na ninu ate̩jade kan so̩ wi pe: ‘Emi ko mo̩ bi a ti n se ipolongo fun oloselu. Ni o̩dun 2023 ti o n bo̩ yi, Peter Obi ni e̩ni ti n o dibo yan!!! Opin re̩ niye̩n!!! O to ge̩!!!”
O fikun un pe, “afojudi olori o̩do̩ e̩gbe̩ oselu APC lo ti fihan pe awo̩n o̩mo̩ orileede Nigeria ko ni asayan kankan ninu idibo? Lati fipa mu awo̩n eniyan dibo fun wo̩n? “E̩ ko le pa gbogbo wa!!