Mo so̩kún bí o̩mo̩ jòjòló lórí ikú Ifeanyi- Omoni Oboli
Seunfúnmi Fágbohùn
Ge̩ge̩ bi o̩po̩lo̩po̩ eniyan, o̩re̩ ati e̩bi ti n ba gbajumo̩ olorin ni, Davido, ke̩dun, e̩ni ti o padanu o̩mo̩kunrin re̩, Ifeanyi Adeleke, oserebinrin Omoni Oboli ti fi ibake̩dun re̩ han.
Bi osere naa ti fihan, o wi pe nigba ti oun ko̩ko̩ gbo̩ irohin naa, oun ko̩ lati so̩ro̩ lee lori nitori pe oun gba ladura wi pe ko ma se je̩ ooto̩.
Lehin ti oju o̩ro̩ naa jade tan, o wi pe o̩ro̩ naa dun oun to be̩e̩ ti oun fi so̩kun bi o̩mo̩ jojolo ti o si gba oorun loju oun.
Sibe̩, o fi lede pe ko si e̩ni ti o̩ro̩ naa lee dun bi Davido ati Chioma, ge̩ge̩ bi obi o̩mo̩.
O ro̩ awo̩n o̩re̩, ati awo̩n ololufe o̩ko̩ ati iyawo naa lati je̩ ki wo̩n wa laaye ara wo̩n ni akoko yii.
“Mo tiraka lati ma te̩ ate̩jade yii, mo ro wi pe bi mo ba se be̩e̩, ko ni je̩ ooto̩”
“Mo sokun bi o̩mo̩ jojolo bo tile̩ je̩ wi pe emi pelu Davido ati Chioma o kii se o̩re̩ timo̩timo̩. N ko le sun! Mo ji lowuro̩ yii, mo rii wi pe ooto̩ ni”
“Mo fi da o̩ loju pe IWO̩ NIKAN KO̩ LO WA! Gbogbo aye n ba o̩ ke̩dun.
“Ko le dun wa bi o ti dun o̩ to, sugbo̩n o ba o̩kan wa je̩! Ki O̩lo̩run tu o̩ ninu atiwo̩ ati e̩bi re̩ ni akoko yii.
“Ki E̩mi Mimo̩ ti o n fun ni ni alaafia fun o̩ ni alaafia ti ko ye o̩mo̩ araaye ni oruko Jesu.