Kò sí ohun tí ènìyàn lè se àyájó̩ lé lórí ní orílèèdè yìí – Wizkid

Kò sí ohun tí ènìyàn lè se àyájó̩ lé lórí ní orílèèdè yìí – Wizkid

Seunfúnmi Fágbohùn

Gbajugbaja olorin ni, Wizkid, ti so̩ro̩ lori rogbodiyan ti o n lo̩ ni orileede yii.
Bi o ti salaye, ko si ohun ti o seese ajoyo̩ le lori ni orile ede yi.
Nigba ti o n gboriyin fun bi onikaluku ti n se ohun ribiribi, o gbe osuwon ti o re̩le̩ fun orileede yi, bi o ti se ileri lati le gbogbo awo̩n agba oselu se̩hin ni o̩dun 2023.
Ninu ifo̩ro̩-wani-lenu wo pe̩lu Guardian ni UK’, ni o ti wi pe, ” Ko si ohun kan ti o seese ajo̩yo̩ le lori (ni Nigeria) yato̩ si pe awo̩n eniyan (Nigeria) je̩ akinkanju ninu orin kiko̩, ere idaraya, ide̩rin paniyan ati ninu gbogbo awo̩n eto idanilaraya lapapo̩. Awo̩n o̩do̩ Nigeria ni o se e fi yangan kaakiri agbalaye. Mo ni awo̩n o̩re̩ ti o yanile̩nu, ti wo̩n si n se ohun iyale̩nu.
“Ko ju be̩e̩ lo̩. Ko si ohun miiran. Sugbo̩n mo ni ireti pe iyipada yoo de. Bawo ni o se le pe̩ si? Mi o mo̩. Sugbo̩n o̩po̩lo̩po̩ nnkan ni o ti yi pada bi mo se n dagba sii.
Nigba ti o n pe gbogbo awo̩n o̩mo̩ Nigeria lati so̩ro̩ odi si ijo̩ba, olorin Essense ni “oun yoo ri tiwo̩n ro ni idibo ti o n bo̩ yi. Gbogbo awo̩n arugbo gbo̩do̩ gbe agbara sile̩ ni asiko yi. Wo̩n nilo lati lo̩ si ile awo̩n arugbo lati lo gbafe̩.”
Nigba ti o n gba awo̩n o̩je̩ oloselu niyanju lati fi oselu sile̩, olugbegba oroke ni e̩ye̩ Grammy se ileri lati gbogun ti wo̩n titi ti wo̩n yoo fi gbe agbara sile̩ ni eto idibo to n bo̩ lo̩na.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here