Àwo̩n àgbe̩ f’òǹtè̩ lu Tinubu

Àwo̩n àgbe̩ f’òǹtè̩ lu Tinubu

Yínká Àlàbí

E̩gbe̩ awo̩n agbe̩ lorisiirisii to wa ni ile Hausa lo n fi Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu lo̩kan bale̩ pe ti ibo ba ti ya lo̩dun to n bo̩, Asiwaju ni awo̩n maa te̩ ika fun.
Awo̩n e̩gbe̩ agbe̩ naa ni –  Maize Association of Nigeria, Miyetti Allah Keutal Hore, Rice Farmers Association of Nigeria and Federation of Agricultural Commodity Association of Nigeria.
Eyi naa mu ki Tinubu fi wo̩n o̩kan bale̩ pe ti oun ba ti wo̩le ibo, awo̩n naa ti bo̩ saye niye̩n, Tinubu ni oun maa je̩ ki orileede pada si olounje̩ yafun-yafun ti wo̩n mo̩ Naijiria si te̩le̩ ki o to di pe epo de.
Tinubu ni oun maa je̩ ki ipinle̩ ko̩o̩kan ni ounje̩ ti a maa mo̩ wo̩n si ni eyi to maa je̩ ki o ro̩run fun gbogbo agbe̩ lati di aladanla.
Ara awo̩n eniyan jankan-jankan to peju pese̩ sibi ipade naa yato̩ si Tinubu ni – alaga e̩gbe̩ naa Abdullahi Adamu, olugbalejo Abdullahi Sanni-Bello, Abubarka Badaru tii se gomina ipinle̩ Jigawa, Hon Umar Bago ti se oludije du ipo gomina labe̩  e̩gbe̩ oselu APC ni ipinle̩ Niger, Igbakeji oludije du ipo Aare̩ Se̩neto̩ Kashim Settima ati awo̩n eniyan janka-jankan miiran.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here