O̩wó̩ te̩ àwo̩n nó̩ò̩si pè̩lú è̩yà ara òkú

O̩wó̩ te̩ àwo̩n nó̩ò̩si pè̩lú è̩yà ara òkú

Yínká Àlàbí
Yoruba bo̩ wo̩n ni, o̩jo̩ kan ni ti ole, o̩jo̩ gbogbo ni ti olohun.
Owe yi se̩ mo̩ awo̩n no̩o̩si ile-iwosan Ibadan Cenral Hospital to wa ni ilu Ibadan nigba ti o̩wo̩ palanba wo̩n segi.
Awo̩n no̩o̩si meji naa ni Muibat Olatunji o̩mo̩ o̩dun me̩tadinlo̩gbo̩n(27 years old) ati Oluwafunmilayo Omeh o̩mo̩ o̩dun mejilelogun ( 22 years old) pe̩lu awo̩n sikio̩riti meji ti ako̩ko̩ n je̩ Bamidele Bamiro o̩mo̩ o̩dun mejilelo̩gbo̩n (32 years old) ati Godwin Omomoh o̩mo̩ o̩dun mejilelogun (22 years old).
Gbogbo wo̩n lo foju ba ile-e̩jo̩ ti wo̩n si ni awo̩n e̩ya ara eniyan ti wo̩n ka mo̩ awo̩n lo̩wo̩ kii se e̩ru awo̩n.
Adajo Emmanuel Idowu ti ile-e̩jo̩ naa ti o fi ikale̩ si Iyaganku ri ilu Ibadan gba oniduro wcn pe̩lu e̩gbe̩run lo̩na igba naira fun e̩niko̩ckan.
Iwadii n te̩ siwaju, adajo̩ si sun igbe̩jo̩ naa si o̩jo̩ ko̩kandinlogun osu kejila o̩dun yii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here