Kessington Adebutu: Baba Ijebu tii fi owo saanu!

Adebutu

OPOMULERO YORUBA

Ti a ba n soro nipa omo Ijebu ti o gbajumo, ti o n ba awon eeyan se kaakiri gbogbo orileede agbaye, ti o ni owo ti oruko re si wa lenu awon eeyan lojoojumo, okan gboogi ni Oloye Kessington Adebukunola Adebutu je.

Baba yii bere aye re laifi bee ri nnkan pupo ponla, sugbon won tepa mo ise ti won yan laayo julo. Baba ni nigba ti awon ko ri iie se ni awon wa n wa okowo ti o see bere pelu owo die ni aye igba yen, seni awon ati ore won ti oje ore timotimo julo Oloogbe Solomon Adebayo Ayoku lo bere nnkan ti awon eeyan npe ni puulu (pool). Sugbon laarin odun die awon mejeeji ti di ilu mooka.

Leyin eyi ni won ko owo won lo si inu ise agbe, ile-kiko, sise awon ohun ero ti won npe ni manufacturing. Kope pupo ti baba yii bere awon nnkan wonyi ni o ba bere si fi owo owo re se aanu awon eeyan. Idi ni pe baba yii mo nnkan ti oju awon ti ko nii ma n ri, fun idi yii ni baba ba bere Kessington Adebukunola Adebutu Foundation lati maa fi ran gbogbo awon eeyan lowo.

Musulumi ni awon obi baba yii sugbon Adebukunola di Kristeni fun ra re, eyi si je oun to je ko tun rorun fun baba lati ran gbogbo elesin lowo lai yo enikan kuro. Kessington Adebutu ni o gba Gateway Hotels  fun odun marundinlogun bayi ti o tun je alaga fun Premier Lotto. Gege bi omo bibi ti ilu Iperu Remo, baba ijebu ni awon eeyan ma n pe baba naa, sugbon baba Ijebu ti ko mo ila ti owo ko nila fi ran awon eeyan lowo ni.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here