Awọn òyìnbó Mobil kọ́kọ́ rò pé orí mi ti dàrú ni nígbà tí mo fẹ́ fisẹ́ sílẹ̀ ṣe òsèlú- Tinubu

Tinubu

Eyi ni iforo-wani-lenu-wo pataki kan ti Oludije Ipo Aare fun egbe All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu, se ni igba die seyin. Agboyanu ni awon nnkan ti Awiwaju so nibe, to si je pe iwe iroyin THE NEWS lo se iforo-wani-lenu-wo naa, ti awa si se atumo re. IROYIN OWURO ati magasini OSUMARE no lo gbe e jade ni Yoruba.

Ibeere – Bawo loselu Asiwaju se bere?

Asiwaju – Owo ni mo koko fi n ran awon oloselu lowo ni igba kan, ki o to di wi pe mo ti ara bo o ni asiko ti ijoba da ibo Ojogbon Femi Agbalajobi ati Oloye Dapo Sarumi nu. Eyin Yomi Edu ni mo wa, o si kuna ipo naa.

Awon ileese mi nibi ati ni oke okun se daadaa, ni eyi ti ko je ki n mo o lara pe a padanu ibo. Asiko yii kan naa ni ijoba Babangida bere eto Structural Adjustment Programme, iyen SAP. Emi ko fara mo eto naa rara ni eyi to mu ki n ko iwe imoran fun Babangida gege bii Aare Ologun ni igba naa. Inu re dun, o si tewo gba a.

Inu IBB dun, o si wo o pe iru eniyan bi temi lo ye ko wa ni ile igbimo asofin ki ilu le toro. Eyi naa wa lara ohun ti awon agba oje bii – Alagba Kola Oseni, Alhaji Hamzat, Busari Alebiosu, Demola Adeniji-Adele, Prince Olusi ati awon to ku ti won jo wa ninu egbee PRIMROSE naa –  ko se fi mi lorun sile. Won ni ki n je ki a jo to Orileede yii.

Oga mi , Bob Parker,  to je oga agba, Managing Director, ni Mobil ni igba naa koko ro pe ori mi ti daru ni igba ti mo dagbere fun un pe mo fe lo lo opolo mi fun oselu orileede mi.

Bee naa lo se ri lara alamojuto owo ibe naa, Ogbeni Akinyelure. Awon mejeeji o gba pe ara mi ya. Ileese Mobil ni igbagbo gidi ninu mi, won ni mo maa pada wa. Won wa seto leta igbaaye nibi ise fun odun merin peluu igbagbo pe ti oselu Naijiria ba ja jo mi loju, maa pada si enu ise mi.

Ipo wo ni e koko di mu nibi oselu?

Ipo Seneto Lagos West ni, bi o tile je pe Lagos Central lo ye ko je sugbon Lagos West ni isoro egbe wa ni igba naa. Owo si wa lowo mi daadaa ni igba naa, mo si tun lebun oro siso ni eyi ti gbogbo re sise fun mi.

Kin ni akitiyan yin ninu egbe NRC lasiko Alagba Micheal Otedola?

Mi o sakitiyan kankan nitori pe mi o tii jingiri ninu eto oselu rara. Eyi si se akoba fun egbe wa ni igba naa, nitori o ye ki a gba ijoba ni igba ti awon eleto ibo begi dina Alagba Sarumi ati Oloogbe Femi Agbalajobi. Otedola ko ba ma se jawe olubori ti won ba je ki a ri ede aiyede naa yanju. Gbogbo itu meje ti ode n pa ninu igbo ni Omooba Adeniji Adele pa titi di ale ibo ku ola sugbon eti ogbonin ni won ko sii, ni eyi to mu ki Otedola jawe olubori.

Ipa wo ni e ko ni asiko ibo MKO Abiola?

Abiola

A koko sise to po fun Oloogbe Yar Adua labe asia SDP, a ti jawe olubori ni ile igbimo asofin agba, emi ni mo fe di Senate President, gbogbo ile Yoruba ni a ti jawe olubori nigba ti olopolo pipe Alhaji Kashim Ibrahim ti ba wa wole si awon Seneto kan lara niile Hausa, Chuba Okadigbo ni ile Igbo, Iyorchia Ayu ni aaarin gbungbun. A wa peluu awon to rese wale bii Olu Falae, Biyi Dutrojaye ati Olusegun Osoba. Pelu opolo ti Olorun fun mi, mo ti ni Seneto Mejidinlogoji (38) ninu merindinlogota (56) to wa ninu egbe SDP ni igba naa.

Nigba ti ijoba ati awon eleto ibo begi dina fun Yar Adua ni Falae ati Durojaye wa ba egbe soro lati gbe ipo Aare fun ile Yoruba. Orisiirisii awuye-wuye lo n lo nigboro nigba naa. Awon iwe iroyin n gbee pe Babangida o fe fi ipo sile, koda iwe iroyin PUNCH tile gbe siwaju iwe won pe nitori asepo to dan moran to wa laarin emi ati IBB, mo n ti i leyin lati maa se fi ipo sile. Opo ni ko mo pe iro pata ni, bawo ni mo se fe fara mo ijoba ologun ju ti alagbada lo?

Nigba ti awuye-wuye yii n lo lowo ni MKO Abiola jade lati dije du ipo Aare Orileede yi. Mo kan dede rii ni ile-itura ti mo wa ni pelu Jubril Martin-kuye. Onisiro owo  bii temi naa ni, o si mowe daadaa. Mo je ki o yee pe gbogbo awon to sise ta ko Oloogbe Obafemi Awolowo ko le rowo mu ni ile Yoruba. O si salaye fun mi pe ko ri bee ati wi pe oun maa gba Ikenne lo lati lo salaye ara oun ni eyi ti mo fara mo.

Nigba ti ibo Yar Adua daru ni egbe PDP je ki ipo Aare yi kan ile Yoruba. Eyi se akoba fun ipo Olori ile igbimo asofin agba ti mo n le. Egbe je ki o ye wa bi o tile je pe emi naa mo pe, won ko le fun ile Yoruba  ni ipo Aare ki won tun fun wa ni olori ile igbimo asofin agba.

Nigba ti a ri alaale MKO Abiola, a rii pe, o ni eto rere fun Naijiria. O si tun ti we yan kanin-kanin nipa pe oun kii se ota Awolowo. Eyi mu ki a sise to po fun MKO. A panupo lori Iyiochia Ayu gege bi olori ile igbimo asofin agba. Emi naa je eni to lenu gan an ni ile igbimo naa.

Ogbon wo ni e da sii nigba ti Babangida fe ki eyin Seneto duro lati sise po pelu re?

Gbogbo ogbon ati ete Babangida ati awon ologun to ku ni a tete kefin. Eyi mu ki a gbogun ti diduro won. Yato fun ise ti awa ile igbimo asofin mejeeji se, a si tun rii pe awon oniroyin gbogun to lagbara ti won lojoojumo.

Akitiyan Ayu ko see fi owo ro seyin lasiko naa. Emi tile koko ro pe emi nikan ni mo ni Laptop  ni ile igbimo asofin ni, ase Ayu naa ni, o si le loo daadaa. Gbogbo akitiyan wa yii lo n de odo awon oniroyin wa ni Naijiria ati oke okun. Gbogbo re naa lo sise gidi fun ijoba awa-ara-wa.

Babangida

Babangida ba gbogbo eyin ile igbimo asofin soro, bawo le se wa gbena woju re?

Loooto lo ba gbogbo wa soro pelu ogbon ni eyi to mu ki n da lohun lojo naa pe, afi ki o gbe ijoba sile fun alagbada ni o niyi ti o si ni ilana manigbagbe ninu. Leyin ipade yii, Babangida wa bo mi lowo. O ni mo kare, oun si je dodo igboya mi.

A sise to po fun MKO, a si rii pe o jawe olubori ibo naa. Ipinle mejilelogun (22 states) ni mo tele Abiola de lati lo polongo ibo Aare igba naa.

Olopolo pipe to mose ni Ojogbon Humphrey Nwosu. O je ki eto ibo naa lo ni irowo-irose, gbogbo awon alamojuto ibo nile ati leyin odi naa ni won gbe osuba fun un. Ife ti awon omo Naijiria ni si gbogbo wa nigba naa je ki won fowo sowo po pelu awon eleto ibo. Fun igba akoko ti oruko awon to dibo ko ju awon to foruko sile lo tabi ki o je idakeji.

Nibo le wa nigba ti Babangida wogi le ibo MKO Abiola naa?

Odo Abiola ni mo wa ti a jo n soro ti a si n reti esi ibo ipinle Taraba ki a le maa dunnu kiri pe a ti jawe olubori. Ko pe si igba ti a soro tan ni a gbo pe ijoba ti ni ki won dawo kika ibo duro. A ti n gbo ti awon egbe alatako ti n pa ohun da nipa esi ibo naa. Ko pe si asiko naa ni a dede gbo iku baba Yar Adua. Kia ni Abiola ti seto baalu ayara bi asa lati gbe mi lo ipinle Katsina lati lo soju oun nitori pe won ko ni pe sin oku naa gege ilana elesin Musulumi.  Bi Babangida se de naa ni won sin oku naa, gbogbo igbiyanju MKO lati ba ayeye isinku naa lo ja si pabo nitori papako ofurufu ti won ti nitori Aare to n koja. Igba ti Babangida pada tan ni won to si papako naa ni eyi to mu ki Abiola naa raaye koja. Nibi isinku yii ni mo ti ri Sheu Yar Adua to je aburo oloogbe ti oun ati Babangida soro pe titi. Emi tile ro pe o n parowa si i ni nitori eni to ku sugbon iyalenu lo je ni igba ti a pada de si ilu Eko ti a gbo pe ijoba ti wogi le ibo naa. Ile MKO ni mo koko gba lo, ni igba ti mo de ibe ni mo ri ero repete ni ita ti wahala nla si sele ti mo fere ma tii foju kan ri.

Nje Babangida salaye nnkankan fun yin gege bi ajose yin to dan moran?

Rara o. lati igba ti mo ti gbena wo oju re nibi ipade to ba awa ile igbimo asofin se ni oun ati awon ologun to ku ko ti gba temi mo. Emi o tile tii mo pe o maa fagi le ibo odun naa ti n ko ti fun un ni aponle bii ti tele mo. Ni igba ti a rira ni ibi isinku Yar Adua, gbogbo awon ero lo n se ranka dede re, tie mi si ko jale pe ko si ohun to jo bee mo.

Tinubu

Kin ni e le so nipa rogbodiyan wiwogi le ibo naa?

Egbinrin ote ni rogbodiyan naa. Babangida ti koko ri “oju ija ni ilasa” pe oun gbodo lo. Orisiirisii aba tun wa n waye lori bawo ni o se fe gbe ijoba sile ki enu to ko lori ijoba fidie. Isoro miran ni eni to maa je olori, eya wo lo maa je ati bee bee lo. Mo so fun Ayu pe ko le je oun. Mo mo pe inu Atiku ko dun bi won ko se fi se igbakeji MKO ati bee bee lo. Mo bere si ni n parowa fun awon eniyan to lenu loro ni okookan ki won ba Babangida soro ko gbe ijoba Abiola fun un. Mo ba Sheu Yar Adua soro pe ko je ki a gba fOlorun fun Abiola ti o ba wa di odun merin leyin re ki o wa se ijoba tire. Mo gbe mama mi Alhaja Abibat Mogaji lo si odo IBB…

Iyoku iforowanilenuwo yii n bo…

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here