Alabi Ogundepo gbe awo ijala jade lori iku Alaafin

Ogundepo

Agba oje ninu ere ijala, Alagba Alabi Ogundepo, ti se awo ijala kan jade, to fi se’daro iku Alaafin ti Oyo, Ikubaba Yeye, Oba Lamidi Adeyemi.

Ogbontarigi akewi naa ti pe eni odun mokanlelogorin bayii.

Se Yoruba bo won ni eni to gbele lo sinku, ariwo lasan ni elekun n su., to si tun je pe ni to soju eni ko da bi eni to seyin eni.

Ninu awo tuntun naa, Ogundepo, eni to ti n sun ijala nigba to ti wa ni omo agbekorun, se sadankaata Alaafin naa.

O se alaye ipa ribiribi ti Kabiyesi ko ninu idagbasoke ile Adulawo, ti Naijiria ati, ni pataki, ti ile Yoruba.

Onijala naa wa ki Oba deyemi bii ki Kabiyesi o ji dide, sugbon iku ko je bee.

Ko le ya opo eniyan lenu pe Alabi Ogundepo pinnu lati se eye ikeyin fun Oba Adeyemi.

Idi ni pe Kabiyesi ana naa feran oun ati ijala re daadaa, to si maa n pe e fun aseye.

Bakan naa, Oba Adeyemi fi ife han si Ogundepo nigba ti onijala naa di eni ogorin odun ni odun to lo – 2021.

Kabiyesi naa wa pelu Alabi Ogundepo ni ile Saki Ogun o roke, agbade o ro baba, nibi ti won ti se aseye naa, se omo Saki ni, Ogundepo, o kan fi Osogbo se ibujokoo ni.

Lojo ayeye naa, Oba Adeyemi se ileri lati fun Ogundepo ni ilaji ilionu naira (N500,000), labala ifilole iwe kan ti won gbe jade lori akewi naa.

Kabiyesi fi kun un pe, losoosu, awon yoo maa fun Ogundepo ni owo iranwo.

Sugbon iku ko je bee, ko je ki akewi naa jegbadun awon ileri naa, gege bi o se fi enu ara re wi fun magasininni OSUMARE.

Ki Olorun te Alaafin Adeyemi si afefe rere.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here