Ọlọ́pàá ṣàwárí obìnrin tó sọnù láti ọdún 1962

Ọlọ́pàá ṣàwárí obìnrin tó sọnù láti ọdún 1962

Fẹ́mi Akínṣọlá

Obìnrin kan tó ti sọnù láti odún 1962 ni wọ́n ti ṣàwárí báyìí láyọ̀ àti àlàáfíà lẹ́yìn tí ilé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Wisconsin gbé Ìwádìí tuntun dìde lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ẹni ogun ọdun ni Audrey Backeberg nigba to kuro nile niluu Reedsburg lọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 1962.

Ninu atẹjade kan ti ọlọpaa fi lede, wọn ni oun funra rẹ lo fi ẹsẹ ara rẹ rin kuro nile, ati pe bo ṣe poora ko lọwọ iwa ipa tabi iwa ọdaran kankan ninu.
Ileeṣẹ naa ni ilu kan lẹyin odi Wisconsin lo n gbe bayii amọ wọn ko darukọ agbegbe naa.

Ajọ kan to n ṣewadii awọn to sọnu nipinlẹ ọhun, Wisconsin Missing Persons Advocacy, sọ pe obinrin naa ti ṣe igbeyawo, bẹẹ o si ti bi ọmọ meji ko to di awati.

Ajọ ọhun sọ pe lọjọ meji ko to di awati, o ti kọkọ lọ fi ẹjọ ọkọ rẹ sun ọlọpaa pe o n na oun ati pe o dunkoko pe oun yoo gbẹmi oun.

Ọmọ ọdun marundinlogun lo wa nigba to lọ sile ọkọ, o si ti pe eni ọdun mejilelọgọrin bayii.

Lọjọ to poora, o ni oun n lọ ibi iṣẹ lati lọ gba owo oṣu oun.

Ẹni to n ba tọju ọmọ rẹ lọdun naa lọhun sọ fun ọlọpaa pe, Backeberg lọ silu Madison to jẹ olu ilu ipinlẹ naa, nibi to ti tẹkọ leti lọ siluu Indianapolis, nipinlẹ Indiana to jẹ ọpọlọpọ kilomita sibi ti wọn n gbe.

Ọjọ naa ni wọn ri obinrin ọhun kẹyin, ọlọpaa ṣe ọpọ iwadii lati ṣawari rẹ amọ gbogbo igbiyanju wọn lo ja si pabo fun ọpọ ọdun.

Ọlọpaa to pada ṣawari rẹ, Isaac Hanson, sọ pe oju opo ti wọn n kọ orukọ awọn iran si lori ayelujara ṣe iranlọwọ fun oun lati ṣawari rẹ.

Hanson ni inu rẹ dun si igbesẹ to gbe lati fi ilu silẹ lasiko ti oun ba sọrọ bẹẹ si ni ko kabamọ kankan pe oun salọ.