Ojude Oba ti di ọjà àgbáyé – Dapo Abiodun

Ojude Oba ti di ọjà àgbáyé – Dapo Abiodun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọọba Dàpọ̀ Abíọ́dún ti ṣe àlàyé pé ayẹyẹ ọlọ́dọọdún tó máa ń wáyé nílùú Ìjẹ̀bú Òde, ‘Ojúde Ọba’ ti di ọjà tí gbogbo ayé n ná, ọjà yìí sì ti pakún ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ògùn l’ápapọ̀.

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ayẹyẹ Ojude Ọba t’ọdun yii to waye lọjọ Aiku ni gbagede Ọba ti ọpọ eeyan mọ si ‘Pavilion’, Gomina Abiọdun ni gbogbo ile itura to n bẹ niluu Ijebu Ode ati ayika rẹ ni awọn alejo to wa fun ayẹyẹ naa gba tan, bẹẹ sini awọn oniṣẹ ọwọ naa ri ti aje ṣe.

Abiọdun fi kun ọrọ rẹ pe ayẹyẹ Ojude Ọba t’ọdun yii lo tobi julọ lati igba ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ naa nitori ọkan ọpọlọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ati ni oke okun ti fa si ajọdun naa.
Gomina ipinlẹ Ogun fi kun ọrọ rẹ pe Ojude Ọba kii ṣe ibi ayẹyẹ ti a ti n rin yan fanda ninu aṣọ alaranbara nikan, bikoṣe akanṣe eto ọlọdọdun ti a fi n ṣe akọsilẹ itan fun awọn iran to n bọ lẹyin.

O ni ayẹyẹ naa ti fi orukọ ilu Ijẹbu Ode ati ipinlẹ Ogun si ẹnu ọpọlọlọpọ eeyan lode agbaye, gẹgẹ bi o ṣe n pa kun eto ọrọ aje ipinlẹ naa.
Nitori idi eyii si ni ipinlẹ naa yoo si fi tẹsiwaju lati maa jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ ati ajọ ti o le mu okiki ipinlẹ Ogun lokiki si i lode agbaye.

O ni gbagede ti wọn lo fun Ojude Ọba ko gba ero mọ, o si ṣe ileri wi pe ijọba oun yoo wa nnkan ṣe si i.

Gomina Abiọdun dupẹ lọwọ igbimọ to ṣe eto Ojude Ọba ọdun yii fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe, o gbe oṣuba kare fun Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna ati awọn alejo pataki to fi ara han nibi ipejọpọ naa.
Lara wọn ni Minisita fun aṣa ati idagboke eto ọrọ aje nipasẹ ọgbọn atinuda, Hannatu Musawa, igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Olayide Adelami, Gomina tẹlẹri n’ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Oṣọba, Olori Awujale ilẹ Ijẹbu, Adekemi Adetona ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn oṣere tiata bii Wale Ojo, Adedimeji Lateef ati Femi Branch ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.

Ọkanojọkan idile ati ẹgbẹ ẹlẹṣin to wọ aṣọ alaranbara lo rin yan fanda niwaju awọn alejo pataki to fi ara ha nibi ayẹyẹ naa.