Òǹkọ̀wé wọ gàù, wọ́n pè é lẹ́jọ́ fún ìwé tó kọ nípa ọmọ ààrẹ láì gba àṣẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ònkòwé ọmọ orílè-èdè Kenya kan, Webster Ochora Elijah, ló ti ń jẹ́jọ́ báyìí nítorí ìwé tó kọ nípa ọmọ Ààrẹ orílè-èdè náà, William Ruto, ìyẹn Charlene Ruto, láì gba àṣẹ kó tó kọ ọ́.
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kojá ni wọ́n fi ọwọ́ òfin mú Webster, wọ́n sì fi ẹ̀sùn pípe ara ẹni ní ohun tí kò jẹ́ kàn-án.
Iwe to pe akọle rẹ ni ‘Charlene Ruto and the Youth Uprising’, ni Charlene Ruto sọ pe ko yẹ ki onkọwe naa kọ lai sọ fun oun tẹlẹ.
Charlene sọ pe ohun ti onkọwe kọ nipa oun ko baa daa ju bẹẹ lọ, o yẹ ko kọkọ gba aṣẹ lọwọ oun ko too kọ ọ.
Ai gba aṣẹ naa lo pe ni aṣilo orukọ, to si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Iwe ipẹjọ ti wọn fi kede ẹsun naa ka pe lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un ni onkọwe kọwe naa pẹlu ero lati fi lu jibiti.
Ọun ati awọn kan ni wọn ni wọn jọ gbe igbesẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i mu awọn yẹn.
Ninu alaye awọn amoye nipa kikọ iwe nipa ẹlomi-in, wọn ni ko lodi labẹ ofin lati kọwe nipa eeyan lai kọkọ gba aṣẹ lọwọ ẹni naa.
Oloṣelu kan to tun jẹ agbẹjọrọ, Willis Otieno, ṣalaye pe “bii ẹni to n ṣi agbara ọwọ rẹ lo ni, ti eeyan ba sọ iwe kikọ di iwa ọdaran”.
“Onkọwe yii ko tako ofin nibi kankan”.
Oluyẹwo iwe, Mbugua Ngunjiri, lo ṣalaye bẹẹ lori iṣẹlẹ yii.
O tọka si bi wọn ṣe kọwe nipa aarẹ Kenya tẹlẹ, Uhuru Kenyatta, ni 2014,lai jẹ pe onkọwe naa gba aṣẹ lọwọ rẹ ko too kọ ọ.
“Miliọnu onkọwe le kọwe nipa eeyan ti wọn ko si ni i lufin nibi kankan. Ohun to le mu Charlene, ọmọ aarẹ sọrọ, ko ju ti wọn ba kọ ohun ti ko ri bẹẹ nipa rẹ”
Bẹẹ ni Mbugua Ngunjiri kọ ọ soju opo Facebook rẹ.
Ṣugbọn ọmọ aarẹ Kenya yii sọ fun awọn akọroyin pe o ti mọ wọn lara lorilẹede awọn lati maa fi orukọ awọn eeyan kọwe lai gbaṣẹ lọwọ wọn.
O ni ko yẹ ko ri bẹẹ.
Iwe to ko ẹni to kọ ọ si aroye yii ko si lori ayelujara, eeyan diẹ bayii lo si mọ onkọwe naa paapaa, ẹni ti wọn ni ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹẹdọgbọn (25) lọ.
Yatọ si pe ko si lori ayelujara, wọn ko pin iwe naa sori atẹ rẹpẹtẹ pẹlu, awọn eeyan ko si mọ ohun ti iwe ọhun da le lori.
Awọn lọọya to n gba ẹjọ naa ro fun Webster to kọ ọ, sọ pe ohun to kọ ko lodi sofin.
Amofin Kennedy Mong’are, sọ fun awọn oniroyin pe oun gan-an ti kọwe nipa awọn eeyan pataki lawujọ ri, titi kan Raila Odinga to jẹ oloṣelu nla ati Aarẹ ilẹ America, Donald Trump.
Lọọya mi-in, Evan Ondieki, sọ pe awọn eeyan to wa nipo agbara gbọdọ mọ, pe araalu yoo gbọn wọn yẹbẹyẹbẹ nita gbangba.
To ba ti di pe araalu ko le sọ nipa wọn mọ, o tumọ si pe ẹtọ lati sọrọ ti n di titẹmọlẹ ni Kenya niyẹn gẹgẹ bo ṣe sọ.
“Ko yẹ ko le de ibi pe araalu yoo lufin nitori wọn lo aworan rẹ tabi kọ nipa rẹ.”
Bi a ba n sọ nipa eekan ọmọ aarẹ, ọkan ni Charlene Ruto laaye ara rẹ.
Igba kan wa ti wọn maa n fi ọmọbinrin yii we Ivanka Trump, ọmọ aarẹ America.
Ọpọ igba ni wọn ti fi Charlene ṣe alejo pataki lode, o si ti ba awọn olori ilu pade daadaa ni awọn ipade agbaye kiri.
Ni 2022, Charlene Ruto kede pe owo ilu kọ loun n lo lati fi gbọ bukaata ọfiisi ọmọ aarẹ ti wọn ya sọtọ fun un to si n dari ni Kenya.
Igbesẹ to gbe nipa orukọ rẹ ti wọn fi kọwe to di ẹjọ yii ko dun mọ awọn eeyan Kenya ninu.
Bẹẹ ni ile ẹjọ paapaa ti n kọminu si ai le sọrọ araalu ti wọn fẹẹ ko maa lọ bẹẹ yii.
Wọn fi eyi we bi wọn ṣe ti obinrin kan, Rose Njeri, mọle nitori ẹka oju opo ayelujara to ṣe fun araalu.
Oju opo naa wa fun ki araalu le fi aidunnu wọn han si kudiẹ-kudiẹ ijọba.
Ọjọ Ẹti ni wọn mu Njeri fun ẹka to n tako bijọba Kenya ṣe n nawo lọdọọdun naa.
Ẹsun iwa ọdaran lori ayelujara ni wọn fi kan an, ati lilo kọmputa nilokulo.
Wọn pada fi aaye beeli silẹ fun un di ogunjọ oṣu Kẹfa yii, nigba ti kootu yoo sọ boya yoo maa jẹjọ lọ tabi bẹẹ kọ.
Njeri paapaa ti dupẹ gidi lọwọ awọn eeyan Kenya, fun bi wọn ṣe panupọ gbeja rẹ, ti wọn jẹ kijọba mọ pe bi wọn ṣe mu un ti mọle ko yẹ rara ni.