Kà nípa àtunṣe márùn-un ti INEC fẹ́ẹ́ ṣe sí òfin ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà

Mahmood Yakubu, alaga ajo eto idibo INEC
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀  Nàìjíríà, (INEC) ti pè fún àtúnse lẹ́ẹ̀kan sí i lórí òfin Nàìjíríà, kí ayípadà lè bá ìlànà ètò ìdìbò.
Agbẹnusọ INEC, Hajiya Zainab Aminu, ṣalaye fun akọroyin pe o ti mọ ajọ naa lara lati maa ṣe atunṣe si eto idibo, gẹgẹ bi ofin ṣe faaye gba a.
“Ẹ ma jẹ ka gbagbe pe a gbe iru igbesẹ yii kan naa ni 2020, nigba ti ile igbimọ mejeeji sọ fun INEC lati tun ofin eto idibo ṣe”
Hajiya Zainab lo sọ bẹẹ.
O fi kun pe lasiko naa ni wọn ṣe atunyẹwo ofin idibo ọdun 2010, eyi ti wọn yi orukọ rẹ pada si ofin idibo 2022, ti orilẹede yii n lo lọwọ bayii.
Kí àwọn elétò ìdìbò máa di tiwọn ṣáájú ọjọ́ ìbò Ọkan lara awọn atunṣe pataki ti INEC n beere ni pe kawọn oṣiṣẹ eleto idibo, awọn agbofinro, oniroyin, dokita ati bẹẹ bẹẹ lọ, maa dibo tiwọn ko too di ọjọ idibo gan-an.
Hajiya Zainab ṣalaye pe iru ilana yii ti n waye ni ọpọlọpọ orilẹede, titi to fi mọ Ghana.
O ni eyi yoo fun awọn eeyan to maa n wa lẹnu iṣe lasiko ibo naa laaye lati di tiwọn ṣaaju asiko ti iṣẹ ko ni i gba wọn laye lati dibo mọ.
Ìdìbò ilẹ̀ òkèèrè Atunṣe keji ti INEC n fẹ ni lati fun awọn ọmọ orilẹede yii to wa loke okun ni anfaani lati dibo.
“ A fẹ kawọn ọmọ Naijiria to n gbe loke okun ni anfaani lati dibo.”
Agbẹnusọ INEC lo sọ bẹẹ.
O ni eyi yoo fun wọn laaye lati ṣe ojuṣe wọn bii ọmọ Naijiria lati ibikibi ti wọn wa. Gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe wi, atunṣe ti yoo waye yoo kan kaadi idibo alalopẹ pẹlu.
Ajọ naa sọ pe oun fẹẹ mu ofin to de lilo kaadi alalopẹ kuro, lati ṣẹgun magomago to maa n waye lasiko ibo.
“Atunṣe tuntun naa yoo wa fun pe ẹnikẹni to ba ni kaadi idanimọ ti INEC lu lontẹ yoo le dibo.”
Muhammad Kuna, oludamọran si Alaga INEC lo sọ eyi lasiko to n ba igbimọ eleto ijọba apapọ sọrọ.
Lọwọlọwọ yii, awọn eeyan to ba ni kaadi idibo alalopẹ (Permanent Voter’s Card) nikan lo le dibo ni Naijiria.
Ọpọ eeyan lo si forukọ silẹ fun kaadi alalopẹ naa ti wọn ko ri i gba.
Bakan naa lawọn mi-in gba tiwọn ṣugbọn wọn ti kuro lagbegbe ti wọn ti fi orukọ silẹ, eyi ko si ni i jẹ ki wọn le dibo bi asiko ba to.
Ajọ INEC tun fẹ kijọba foun ni anfaani lati le yan awọn alabojuto ibo lawọn ipinlẹ funra oun.
INEC ṣalaye pe eyi yoo ro awọn obinrin lagbara lati le ṣakoso ibo lawọn ẹka agbara mẹtẹẹta ti i ṣe tijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ.
Yiyan awọn ti yoo maa pẹtu si aawọ idibo
INEC fẹẹ da ajọ meji silẹ, awọn naa ni ‘Electoral Crimes Commission’, ti yoo maa ṣewadii awọn to ba lufin idibo, ti yoo si maa gbọ ẹjọ wọn.
Ikeji ni ‘Political Parties Regulatory Commission’’.
Eyi yoo maa ri si iṣe awọn ẹgbẹ oṣelu, lati ri i pe wọn n tẹle ofin ti ajọ INEC ba la kalẹ.