Home Blog Page 94

Àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, àmì Ọlọ́run wà lára rẹ̀ – Ọọ̀ni

Àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, àmì Ọlọ́run wà lára rẹ̀ – Ọọ̀ni

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀, Kábíyèsí Ẹnitan Ogunwusi Ọjaja Kejì ti kan sáárá sí ìjáwé olúborí Bọla Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ọọ̀ni Ogunwusi nígbà tó ń kópa lórí ètò ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán TVC ṣo pe àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu nítorí náà ló ṣe jáwé olúborí.

Ó ní àwọn àmì Ọlọ́run kan wà lára Tinubu tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún-ún láti rí i pé ó gbégba orókè níbi ìdìbò náà.

“Èyí fi hàn pé àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, tó ní àwọn ẹ̀mí mímọ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ ire fún un láti dé ipò náà.”

“Ọlọ́run dá Tinubu lárà ọ̀tọ̀ ni tó jẹ́ wí pé ó ní iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run fẹ́ fi jẹ́ fún àwùjọ ni. ”

Ọọ̀ni ní òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìránṣé Ọlọ́run kan ń bá Tinubu gbé ló fi jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tó jẹ́ wí pé àwọn tí kò fẹ́ pọ̀ ju àwọn tó fẹ nípò lọ.

Ṣáájú ni Ọọ̀ni ti ránṣẹ́ ìkíni kú oríire sí Tinubu tó sì rọ àwọn olùdíje yòókù tó fìdí rẹmi láti gba kádàrá, kí wọ́n ṣe àrídájú rẹ̀ pé àláfíà jọba ní Nàìjíríà.

Inú mí dùn pé ipò ààrẹ ti padà si ìhà Gúùsù Orílẹ̀ yìí – Nyesom Wike

Inú mí dùn pé ipò ààrẹ ti padà si ìhà Gúùsù Orílẹ̀ yìí – Nyesom Wike

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní kú u iṣẹ, ní-ín mórí oníṣẹ́ ẹ́ yá.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó dìbò láti dá agbára padà sí Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Wike ní inú òhun dùn pé òpin ẹnu àwọn tó lòdì sí kí ipò ààrẹ máa yí láti ẹkùn kan sí òmíràn ti gbẹ nu dakẹ báyìí pẹ̀lú bí Bọ la Ahmed Tinubu ṣe borí ní ìdìbò sípò ààrẹ.

Bọla Tinubu tó borí pẹ̀lú ìbò tó lé ní mílíọ̀nù méjọ ló wá láti ìhà Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Gómìnà Wike ọ̀hún ló sọrọ lásìkò tí ó darapọ̀ mọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde láti ṣí ilé epo 5,000,000-litre Aviation Fuel Dispensing Depot ní agbegbe pápákọ̀ òfurufú ní Alakia, ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ṣáájú ìdìbò sípò ààrẹ náà ni Wike ti fi ìdí rẹmi nínú ìdìbò abẹ́lé láti díje du ipò ààrẹ.

Lẹ́yìn náà ni Wike ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi a àìdùnú rẹ hàn sí bí Atiku Abubakar sẹ jáwé olúborí nínú ìdìbò náà.

Bákan náà ni Wike fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde fún bí ó ṣe ṣe àtìlẹ́yìn fún kí agbára ìjọba padà sí Gúúsù orílẹ-èdè Nàìjíríà .

Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe yìnbọn pa aya mi ní àgọ́ ìdìbò rẹ̀”

“Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe yìnbọn pa aya mi ní àgọ́ ìdìbò rẹ̀”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ètò ìdìbò sípò Ààrẹ àti sáwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìlú Abuja ti wá, tó sì ti parí lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà, INEC ti kéde ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.

Àmọ́ fún ìdílé Owie, ètò ìdìbò náà dá ọgbẹ́ ọkàn sílẹ̀, tí kò lè tán sí ìgbé ayé wọn títí láé.

Ọ̀pọ̀ ìròyìn ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ àmọ́ àwọn àwòrán àti fídíò kan ṣàfihàn pé làásìgbò wáyé ní àwọn agbègbè kan lásìkò ìbò náà.

Lára irú ibi tí wàhálà bẹ́ẹ̀ ti wáyé ni ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edo.

Elizabeth Owie, ẹni ọdún méjìlélógójì gbéra nílé rẹ̀ láti lọ dìbò lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni agbègbè Ogheghe, ìjọba ìbílẹ̀ Ikpoba Okha, ìlú Benin, ìpínlẹ̀ Edo.

Àmọ́ kò padà sí ilé rẹ̀ láàyè, bí ọta ìbọn ṣe bá a, tó sì ṣekú pa á.

Ọkọ Elizabeth, Owie Osadebamwen sàlàyé fún akọròyìn bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, tó fi di ẹni tí kò láya mọ́ lójijì.

Ó ní ọmọkùnrin mẹ́ta ni àwọn ti bí, tí ìgbéyàwó náà kò bá sì pé ọdún mẹ́wàá nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún yìí, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bá wáyé.

Àgbà Alfa ni ọkọ ọ̀ mi n‘Ìbàdàn, kàyéfì ni pé wọ́n ká orí àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́fíìsì rẹ̀”

Àgbà Alfa ni ọkọ ọ̀ mi n‘Ìbàdàn, kàyéfì ni pé wọ́n ká orí àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́fíìsì rẹ̀”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbàlagbà ní bí èèyàn bá ń yọ́ ilẹ̀ ẹ́ dà, dájú sáká ohun burúkú a máa yọ́rú u won ṣe, àṣamọ̀ yìí ló díá fún bí
ọwọ́ Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣe tẹ afurasí mọ́kànlá pẹ̀lú orí gbígbẹ mẹ́sàn-án, orí tútù kan, ìfun àti àwọn ẹ̀yà ara èèyàn mìíràn nílùú Ìbàdàn.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adewale Osifeso ló kéde ọ̀rọ̀ náà nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí ọ̀hún níbi tí wọ́n sá pamọ́ sí ní agbègbè Orita Aperin.

Osifeso ní àwọn afurasí náà ló ń ṣe oko òkòwò orí àti ẹ̀yà ara èèyàn fún àwọn ohun ètùtù.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá fikún un pé “Àwọn èèyàn mọ́kànlá náà ló ti jẹ́wọ́ pé àwọn kópa nínú okoòwò náà nígbàtí a fi ọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú u wọn.

“Wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn máa ń lọ hú àwọn orí gbígbẹ náà ní itẹ́ òkú káàkiri.

“Bákan náà ni wọ́n jẹ́wọ́ pé orí tútù àti àwọn ẹ̀yà ara èèyàn tí a kà mọ́ wọn lọ́wọ́ ló jẹ́ ti ọ̀kan lára wọn, tó ń jẹ́ Amuludun.

Àwọn afurasí náà ní Amuludun ló pa ẹni tó ni orí náà, tó sì bẹ́ orí ọ̀hún bó se pa ẹni náà tán, à mọ́ tí afurasí náà ti sálọ.”

Ọ̀kan lára àwọn afurasí tí ọwọ́ tẹ̀ ló jẹ́ ìyàwó Alfa, ẹni tó jẹ́ olórí àwọn ọ̀daràn náà, tí òun náà ti sálọ, sọ pé òun kò mọ̀ pé ọkọ òun ní orí èèyàn nínú ọfiisi rẹ̀ nítorí alfa mùsùlùmí ni òun mọ̀ ọ́ sí, tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu.

Ó sàlàyé pé òun lọ sí ọọ́fíìsì ọkọ òun láti gba owó oúnjẹ ni àwọn ọlọ́pàá wọlé dé láti wá tú ọọ́fíìsì , tí wọ́n sì rí orí èèyàn.

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀, ó yẹ kí á kíì kú ewu.
Iléeṣẹ́ Ààrẹ Amẹ́ríkà ti kéde pé ààrẹ orílẹ̀ èdè náà, Joe Biden ti ṣiṣẹ́ abẹ láti yọ àìsàn jẹjẹrẹ ara tó ń yọ ọ́ lẹ́nu dànù.

Dókítà Biden ní pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ yìí, Biden kò nílò ìtọ́jú kankan mọ́ lórí àìsàn jẹjẹrẹ.

Àmọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ìtọ̀jú awọ ara rẹ̀ láti mójútó ìlera rẹ̀.

Nínú oṣù Kejì ọdún yìí ni Biden tún àyẹ̀wò ṣe, tí iléeṣẹ́ ààrẹ sì ní ara rẹ̀ ti le, tó sì ti gbádùn láti máa bá iṣẹ́ ìlú lọ.

Dókítà Kevin O’Connor nínú àkọọ́lẹ̀ kan tó tẹ àwọn akọ̀ròyìn lọ́wọ́ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kejì ni wọ́n yọ àìsàn jẹjẹrẹ náà kúrò ní àyà Biden ní ilé ìwòsàn “Reed National Military Medical Center ” èyí tó wà ní ìta Washington DC.

“Kò nílò ìtọ́jú kankan mọ́ àti pé ibi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ náà ti ń san”, O’Connor sọ.

Àkọọ́lẹ̀ náà fi kún-un pé irú àìsàn jẹjẹrẹ tí wọ́n bá lára ààrẹ náà ni -basal cell carcinoma- èyí tí kìí sábà ràn mọ́ ìbòmíràn.

Basal àti squamous ni irúfẹ́ àìsàn jẹjẹrẹ awọ ara tó wọ́pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí àjàkálẹ̀ àrùn àti àmójútó rẹ̀, CDC ṣe sọ.

Àjọ “Skin Cancer Foundation” ní èèyàn mílíọ̀nù 3.6 ló máa ń ní àìsàn náà ní ọdọọdún. Ó máa ń pẹ́ kó tó dàgbà, ó ṣe é wòsàn, tí kò sì ní bá ẹya ara jẹ́ tí wọ́n bá tètè ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Ní oṣù Kìíní ọdún, ìyàwó ààrẹ, Jill Biden náà ṣiṣẹ́ abẹ láti yọ àìsàn jẹjẹrẹ mẹ́ta ṣùgbọ́n tí ọ̀kan nínú wọn padà di “basal cell carcinoma”.

Kí Biden tó di ààrẹ ló ti ń yọ àìsàn jẹjẹrẹ ẹ̀yà ara kúrò lára rẹ̀.

Biden àti ìyàwó rẹ̀ ti ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sọ̀rọ̀ lórí àìsàn jẹjẹrẹ tí wọ́n sì ń tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà lórí rẹ̀.

Ní ọdún 2015 ni ọmọkùnrin wọn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ọpọlọ.

Àwọn ènìyàn ènìyàn ti ń retí bóyá Biden máa kéde láti tún du ipò ààrẹ fún sáà kejì.

Asíwájú ti síwájú gbogbo wo̩n

Asíwájú ti síwájú gbogbo wo̩n

Yinka Alabi

Ajo eleto idibo ile̩ wa(INEC) ti O̩jo̩gbo̩n Mamood Yakubu n dari wo̩n ti kede Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ge̩ge̩ bi e̩ni to jawe olubori ninu awo̩n mejidinlogun ti wo̩n jo̩ n dije di ipo Aare̩ ile̩ Naijiria.
Ibo naa waye ni o̩jo̩ ke̩e̩do̩gbo̩n osu keji odun yii.
APC ni iye ibo 8,794,726, PDP ni 7,984,520, LP ni 6,101,533 nigba ti egbe̩ oselu NNPP se ipo ke̩rin pe̩lu iye ibo1,496,687, SDP ni 80,267 ati be̩e̩ be̩e̩ lo̩.

Ẹ má fẹnu dá làásìgbò sílẹ̀, ẹ kí Tinubu kú oríire – APC

Ẹ má fẹnu dá làásìgbò sílẹ̀, ẹ kí Tinubu kú oríire – APC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ohun tó dájú ni pé bí a bá ń tayò dandan ni kí ẹnìkan sáà jáwé olúborí. Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ìròyìn fún ìgbìmọ̀ ìpolongo ìbò ààrẹ fún Aṣíwájú Bọ́lá Tinubu, Délé Aláké, ti rọ àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti Labour, ìyẹn Alaaji Atiku Abubakar àti Peter Obi, láti tọ ọ̀nà àlàáfíà lórí àbájáde ètò ìbò yìí. Ó ní pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé èsì ìdìbò náà yóò ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ báyìí láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣojú ẹgbẹ́ kóówá wọn, kí wọ́n ṣe bí Jonathan, ìyẹn ààrẹ ilẹ̀ wa tẹ́lẹ̀ , ti ṣe lọ́dún 2015, kí wọ́n pe Aṣiwaju Tinubu, kí wọ́n kí i kú oríire pé òun ló wọlé ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ Sátidé. Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ló sọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé oníròyìn kan tó ṣe nílùú Abuja. Aláké ní, ‘‘Lọ́dún 2015, ààrẹ àná kò dúró kí Alága àjọ elétò ìdìbò kéde èsì ìdìbò náà tán tó fi pe Ààrẹ Muhammadu Buhari, tó sì kí i kú oríire, ní ìlànà ìfẹ àti àjọṣe ti ìjọba a àwa-ara-wa pè fún. Ó wá rọ Atiku Abubakar àti Peter Obi láti tẹlé ìgbésẹ yìí kan náà, dípò tí wọn yóò máa sọrọ tó lè dá ogun tàbí wàhálà sílẹ̀. Aláké ní ohun tó ti dáa jù lọ ni kí àwọn olùdíje méjèèjì fún ipò ààrẹ yìí pe Tinubu báyìí báyìí, kí wọ́n sì kí i kú oríire.

Sirbalo sàfihàn ìdí tó fi ń lo àwo̩n o̩mo̩bìnrin tí O̩lo̩run bùkún ìhà ara wo̩n nínú fó̩nrán re̩

Sirbalo sàfihàn ìdí tó fi ń lo àwo̩n o̩mo̩bìnrin tí O̩lo̩run bùkún ìhà ara wo̩n nínú fó̩nrán re̩

Mary Fágbohùn

Ilumooka onifonran apanilerin, Timothy Obotuke, ti a mo si Sirbalo, ti so pe oun n lo awon omobinrin ti Olorun bukun iha ara won ninu fonran oun nitori pe nnkan to n lo ni ile-ise naa ni.

O so fun Saturday Beats, “Mo kan n tele said ohun to n lo ni o. Lilo omobinrin ti Olorun bukun iha ara won ti wa di ohun to n mowo wole fun awon to n se fonran apanilerin. Emi nikan ko ni mo n se bee; opolopo awon onifonran apanilerin miiran lo wa bii temi. Ni igba kan ri, ki se nkan to niise pelu omobinrin ti akoyinsi re po. Sugbon ni bayii, o ti wa di nkan ti o n mu owo wole ni ile-ise fonran apanilerin. Nnkan ti awon omo Naijiria n fe ni. Mo kan n fun awon afenifere mi ni nkan ti won fe ni.”

Aderinposonu naa tun fidi re mule pe iru eniyan ti oun je leyin ayaworan yato si isesi oun ninu fonran. O wi pe, “A ni isesi to yato si ara won patapata. Sirbalo  n fun awujo ni ohun ti won fe ri ati ti won fe wo, nigba ti Timothy ni nkan miiran to n fe yato si isesi Sirbalo.”

Sirbalo tun so pe yato si nkan ti awon eniyan kan le ro, oun ti wa ni eka idaraya fun igba to ti pe, bi mo ti sise ri gege bi bi oludari ere. O fikun un pe, “Didawole fonran apanilerin je nnkan ti mi o mo pe ma a se bi mo ti se je oludari ere ri tele. Dida onifonran apanilerin ko rorun rara, nitori pe mo je eni to n tiju, owo ti mo nilo (lati se fonran jade) ko rorun riri pelu. Lati se aseyori gegebi onifonran apanilerin, o gbodo setan lati ko latodo awon eniyan ki o si maa sise fun idagbasoke ogbon atinuda re.”

Ìdí tí ìran ìbálòpò̩ se gbo̩dò̩ wà nínú fíìmù— Bo̩laji Ogunmo̩la

Ìdí tí ìran ìbálòpò̩ se gbo̩dò̩ wà nínú fíìmù— Bo̩laji Ogunmo̩la

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Bolaji Ogunmola, ti so pe iran ibalopo nigba miiran ye ko maa wa ninu fiimu ki itan naa ba le e ni itumo.

Ninu iforowero kan pelu Saturday Beats, o wi pe, “Mo ro pe inilo wa ni igbamiran lati le e mu ki awon ise kan han daadaa. Eniyan ko le maa soro nipa asewo tabi awon adikala, ki gbogbo won si wo aso to bora. Ti itan naa ba gba bee; e je ki won safihan re. Nigba ti fiimu ba dara, awon iran ibalopo kii se nnkan akoko ti eniyan yoo ranti. Yoo je imolara ti fiimu naa fun won.”

Ogunmola eni to n jegbadun atunyewo ipa to ko ninu fiimu, ‘Before Valentines’ wi pe, “Gbigbawole fiimu naa je eyi to ni irele to si mu inu dun. Fun ise eniyan lati kan awon eniyan o je ohun to ye ki eniyan dupe fun.

Iriri mi nipa biba ‘Chika’ sere je iyanu. Mo nilo lati lo ore kan ti mo mo lati ile-iwe giga to je eni to ni iru isesi bee. Mo ranti pe mo ka iwe akosile fiimu kan ati pe mo fe ki a se bee. Mo ro pe gbogbo eniyan mo tabi ni iriri pelu Chika teleri; bo ya lai si ere naa sugbon gbogbo wa la mo omobinrin Kristeeni ti o je pe Jesu ni oko re.”

Ìyà ti je̩ mí rí débi wì pé mo fé̩ je̩ oúnje̩ Ajá — Kelvin Great

Ìyà ti je̩ mí rí débi wì pé mo fé̩ je̩ oúnje̩ Ajá — Kelvin Great

Mary Fágbohùn

Aderinposonu , Kelvin Eboyem, ti a mo si Kelvin Great, ti so pe nigba ti oun n la igba ti nkan le koja, o ti se oun bi ki n je ounje aja re nitori pe oun o ni ona ounje miiran.

Ninu oro kan to fi ranse si Saturday Beats, o wi pe, “Jijowo nnkan (gege bi aderinposonu ) kii je asayan fun mi ri, nitori pe lati igba kekere mi ni mo ti la nnkan to le ju bee lo koja ri. Mo padanu iya mi nigba ti mo wa ni omo odun meji. Lati igba kekere, ni mo ti la asiko iponju pupo koja, iyen ni mi o feran lati so nipa re. Amo sa, Olorun wa fun mi; lati igba ti mi o ti nile ti mo si ti n ta ounje laarin ona ni Eko ti mo si n se awon ise kekeeke miiran lati le je eniyan.

Igba miiran wa ti ounje aja ma n dabi nnkansoso to ku funmi lati je ni ale. Ti mi o ba jowo gbogbo re ni igba naa, mi o ro pe mo le e de ikorita ti maa fi jowo nnkankan mo.”

Nigba to n soro lori are alawada to n bo lona, Kelvin, eni to bere ise re ni 2009, wi pe, “Ma a se awada mi akoko ni osu kerin, ati pe mo seleri pe yoo je okan lara awon are awada to dara julo ni Eko. Ma a darapo mo awon aderinposonu miiran, bii Gordons, Destalker, Acapella, Omobaba, Ajebo ati Edo Pikin. Mo tun maa ya awon afenifere mi lenu pelu awon alejo ti yoo fun won ni igba to dara.”