Home Blog Page 93

Ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ fi ní láti ṣe ti Tinubu nínú ìbò tó ń bọ̀ – Nnamani

Tinubu

 

Senito Chimaroke Nnamani ti se alaye idi ti awon ewe Naijiria fi gbodo ri oludije aare ninu egbe oselu All Progressives Congress (APC), Bola Tinubu, gegebi bi aayo ti o pegede.

Nnamani wi pe bi Tinubu se gun ori aleefa ni odun 1999, se opolopo eto amulo fun ijoba ti o gbogun ti ainise ati oro ti o niise pelu odo ni odun 1999.

Gege bi Nnamani se so lori Twitter, ti o pe ni #Citi_Boy series, Ipinle Eko ni igba naa ri isan awon odo ti o n wa igbe aye to derun. O fi kun un pe, Tinubu tun se idasile aajo ti o ipolongo igbogun ti ilokulo ogun lati le e fi ye awon odomode ewu ti o wa ninu asilo ogun, o toka si pe asilo ogun ni o ti ba aye opolopo odomode je.

Nnamani wi pe ipinle Eko labe idari Tinubu pin owo ti o le ni milinou kan naira fun awon odo ti o foruko sile fun ajo ijowo ara eni sile lati sise, gegebi ohun kekere lati dupe lowo won fun iranlowo ti o yi ironu eni pada ati lati se iwuri siso eso pupo si i fun won.

“Tinubu tun fi kun owo ti won n na si aajo isodi titun ti o fi le ni milionu meta naira, ti o si n fi gbogbo igba se agbekale gbagede fun awon odo lati kopa ninu eto eko ati ise atunse. O ni Tinubu na milionu merinla naira ati milionu merin miiran lati tun gbagede awon odo ti Onikan se ni Lagos Island ati gbagede awon odo ni Ikeja, nigba ti o se atunse awon ohun ameyederun ti won pati.

O wi pe Tinubu se aseyori eyi nipa bi o se ro won lagbara oro aje nipase eko ti ninu ise ona, bata sise, ise onidiri, ati ise pipa aso laro.

O wi pe eto ise kiko yii, eyi ti Tinubu gbekale ni osu kokanla odun 2005, ni o gba opolopo ife eye fun gbigbe idagbasoke omoniyan ro.

O ni, idaraenilokowo awon odo ati eto eko gbogboogbo ni won se agbekale re, o salaye pe opona gbongbo re ni lati ko awujo odo ti o lagbara ti o sagbekale SMEs lati pese owonaa fun awon odomode ati lati wu awon miiran lori.

Nnamani fikun pe eto eko ofe fun awon awon ile iwe ijoba ni ipinle Eko ni Tinubu mu wa ni odun 2000, eyi ti o pelu iforukosile ofe fun idanwo asekagba ile iwe girama WAEC ati NECO.

Ògá Àgbà NYSC gba  àwọ́n àgùnbánirọ̀ níyànjú lórí àkànṣe isẹ́ ìlú

Mary Seunfunmi Fagbohun

Adele Oga Agba NYSC ajo agunbaniro (NYSC), Mrs Christy Ubah, ti ro awon agunbaniro lati se akanse ise ti yoo ni ipa to dara ni ileto won larin aaye odun kan ti won fe fi si ile baba won.

Eyi ni awon oloyinbo n pe ni community development work.

Ubah ni o so oro iyanju yii nigba ti o n ba Ipa keta awon agunbaniro odun 2022 (2022 Batch C Stream 11) soro ni ibudo idanileko ni Iyana-Ipaja ni ilu Eko.

O ni akitiyan won ni yoo se ise idagbasoke ti o nipon ni Naijiria.

“Lesekese ti e ba ti mo ileto yin, ni ki e bere akitiyan, ki e si safihan akanse ise ti e ri ni ileto yin ti yoo ni ipa ni awujo, e mase fi akoko sofo.

“Gbogbo eyi ni yoo lowo si idagbasoke orile ede wa, nitori naa, a gba yin niyanju lati gba ise ti a ba fun yin se ninu igbagbo rere ki e ba le e fi tokantokan se ise sinsin naa.”

Ubah fi kun un pe “E ma se pa ona je, e se ohun gbogbo bi o ti ye. E ni ibasepo ti o dan monran. E o je anfaani re bope boya. Okan lara awon ini ti e o kojo nihin loje, yoo ran yin lowo lojo iwaj.”

Ninu eto idibo odun 2023, adele Oga Agba naa pe awon agunbaniro ti won nifee  lati kopa ninu eto yii lati gba eko ti o ye kooro ki won le e ni imo.

O ro won lati ma se kopa ninu oselu tabi yan egbe oselu kan laayo, ki won ni ife si orile ede won, ki won ma si se yese, ki won si se ohun ti o to nigba idibo.

Wọ́n ti dá iléeṣẹ́ Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ lẹ́bi ìwà ọ̀daràn owó orí

Wọ́n ti dá iléeṣẹ́ Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ lẹ́bi ìwà ọ̀daràn owó orí

Ọrẹ Òtítọ́jù

À ṣé kò síbi téṣe kò sí, ìgbìmọ̀ ìdájọ́ kan ní New York lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ti dá ẹ̀bi fún iléeṣẹ́ ìdílé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, Donal Trump lórí ìwà ọ̀daràn tó rọ̀ mọ́ owó orí.

Wọn da ileeṣẹ Trump Organisation lẹjọ lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an lọjọ Iṣẹgun lẹyin ọjọ meji ti wọn fi jiroro lori ọrọ naa ni New York.

Ileeṣẹ naa sun mọ aarẹ ana lorilẹede Amẹrika naa atawọn mọlẹbi rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ kọ ni wọn pe lẹjọ.

Wọn da ileeṣẹ Aarẹ Donald Trump lẹbi pe o n da awọn alaṣẹ rẹ lọla pẹlu awọn ọla ti ko si ninu akọsilẹ fun bi ọdun mẹwaa.

Lara awọn dukia ti wọn fun awọn adari ileeṣẹ naa lai san owo ori lori wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ ati owo ilẹ iwe aladani.

Awọn olupẹjọ ni eyi mu ki owo oṣu wọn ati owo ori to tọ si wọn lati san wa kere pupọ.

Faini miliọnu kan ati ẹgbẹta dọla lo ṣeeṣe ki wọn koju. O si tun ṣeeṣe ki ipenija wa fun wọn lọjọ iwaju lati ya owo.

Aarẹ Trump bu ẹnu atẹ lu igbẹjọ naa leyi to ni o lọwọ oṣelu ninu.

Bakan naa lo tunkoju oro si alamojuto iṣuna ileeṣẹ rẹ fun ọjọ pipẹ, Allen Weisselberg, o fi ẹsun kan an pe o lu jibiti owo ori.

Awọn olupẹjọ fi ẹsun kan ileeṣẹ aarẹ Trump naa pe “iwa itanjẹ ati jibiti ti di mọọliki mọ wọn lara”

Awọn olupẹjọ ni ile iṣẹ naa mu ki awọn adari rẹ o lanfani ati ‘din iye owo ti wọn n kede pe awọn n gba ku ki owo ori ti wọn n san lee kere.”

Ọkùnrin kan gún ìyàwó rẹ̀ pa nítorí omi ní ìpínlẹ̀ Eko

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọkùnrin kan gún ìyàwó rẹ̀ pa nítorí omi ní ìpínlẹ̀ Eko

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọkùnrin kan. Lawrence Itape ni ó ti ṣekúpa ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí àríyànjiyàn wáyé láàrin wọn nítorí omi ní agbègbè Ajah ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Itape, ẹni mọkanlelaadọta ni o fi ọbẹ gun iyawo naa titi to fi gbe ẹmi mi lẹyin ti rogbodiyan waye laarin wọn nitori bi lilo omi ṣe safẹrẹ ni agbegbe ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni kete ti awọn gbọ iroyin ni ikọ ileeṣẹ ọlọpaa gbera lọ si agbegbe naa lati bẹrẹ iwadii.
Hundeyin, ẹni to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ni ọwọ ti tẹ ọkunrin naa pẹlu ọbẹ to fi sisẹ ibi naa fun iyawo rẹ.

Bakan lo ni awọn ti gbe oku iyawo lọ si ile oku, Mainland General Hospital, to wa ni Yaba fun ayẹwo ati awọn iwadii miiran.

“Lori iṣẹlẹ naa, a ti gbe afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti ni Yaba fun iwadii.

“Oku iyawo naa ti wa ni ile igbokuusi Mainland General Hospital fun ayẹwo ati awọn iwadi orisirisi.”

 

 

Ọmọ ogun orí omi gún ọlọ́pàá pa l’Ékòó

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọmọ ogun orí omi gún ọlọ́pàá pa l’Ékòó

 

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àrìnfẹsẹ̀sí ò nílé fún ẹni orí bá ti kọ ìjàǹbá mọ́, à fi kí Ẹlẹ́dàá ṣáà má a pawámọ́ nínú ewu
gbogbo.
Ńṣe ni ọ̀rọ̀ di bó ò lọ o yàgò fún mi nígbà tí ìjà ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́pàá àti òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ojú omi ní agbègbè Satelite Town ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ìkọlù náà ló ṣokùnfà ikú ọ̀gá ọlọ́pàá kan, ASP Abion Hezikel.

Ìròyìn ní àwọn ọmọ ogun orí omi náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Central Pay Office, Apapa tún ṣe àwọn ará ìlú mìíràn tó gbìyànjú láti pẹ̀tù sí ááwọ̀ léṣe.

Ní nǹkan bí i aago mẹ́jọ alẹ́ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá wà lẹ́nu iṣẹ́ ní agbègbè Oluti, Agboju dá àwọn òṣìṣẹ́ Navy náà dúró lórí ọ̀kadà tí wọ́n gùn wí pé wọ́n lòdì sí òfin ètò ìrìnnà.

Àwọn mẹ́rin ni àwọn ọmọ ogun orí omi tí wọ́n gbé ọ̀kadà méjì láti gba tí kìí ṣe ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà.

À mọ́ àwọn ọlọ́pàá náà kò mọ̀ wí pé ẹ̀ṣọ́ ojú omi ni wọ́n nítorí wọn kò wọ aṣọ iṣẹ́ wọn tí wọn kò sì sọ irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún.

Óṣojúmikòró kan tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàlàyé pé nígbà tí àríyànjiyàn tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọmọ ogun náà le díẹ̀ ni ọmọ ogun ọ̀hún bínú fọ ọlọ́pàá kan létí.

Steven Ogbodo nígbà tó ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wáyé fún ilé iṣẹ́ ìròyìn Daily Sun ní ọlọ́pàá ọ̀hún fi ìbínú gba ọmọ ogun ọ̀hún létí padà kí ọ̀rọ̀ ọ́hún tó di iṣu ata yán-an-yàn-an.

Ogbodo, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà bá fa ọ̀bẹ yọ tó sì fi gún ọlọ́pàá náà àti àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ tí wọ́n gbèrò láti báwọn parí ìjà tó wáyé láàárín wọn.

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n gún ṣùgbọ́n àwa tètè bá ẹsẹ̀ wa sọ̀rọ̀ nítorí àwọn ọmọ ogun náà kò kọ̀ láti pa ẹnikẹ́ni.”

Nígbà tí wọ́n fi máa gbé àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ará ìlú tó farapa dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, ASP Abion Hezikel ti darapọ̀ mérò ọ̀run.”

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣàlàyé pé ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọlọ́pàá tó tètè débẹ̀ lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ìjàmbá tí àwọn ọmọ ogun ọ̀hún kò bá ṣe kò bá jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Hundeyin ní àwọn méjì nínú àwọn ọmọ ogun mẹ́rin náà ló wà ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti fún ìwádìí kíkún.

Bákan náà ló ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó iléeṣẹ́ ológun létí àti pé àwọn ti bèrè lọ́wọ́ wọn láti fa àwọn méjì yòókù tó na pápá bora lé àwọn lọ́wọ́.

Messi ti kópa nínú ìdíje e̩gbè̩rún pè̩lú àmì ayò bii e̩gbè̩rin

Messi ti kópa nínú ìdíje e̩gbè̩rún pè̩lú àmì ayò bii e̩gbè̩rin

Yínká Àlàbí

Ogunna-gbongbo o̩do̩mo̩de, elege ara, e̩le̩se̩ ayo ti ina bo̩o̩lu re̩ si n jo wowo lo̩wo̩, Lionel Messi ti kopa ninu idije e̩gbe̩run(1000) bayii. O pe iye yii pe̩lu eyi to kopa ninu re̩ pe̩lu ife̩ e̩ye̩ Agbaye to n lo̩ lo̩wo̩ ni Qatar. Eyi to gba pe̩lu orileede Switzerland lo mu ko pe e̩gbe̩run.
Iye ami ayo to gba wo̩le awo̩n alatako ninu e̩gbe̩run idije je̩ e̩gbe̩rin- din-mo̩kanla (789). Ojo si n ro̩ lo̩wo̩, a ko tii le so̩ pe ko to tana…

 Omo Niger Delta ni iyawo mi – Bola Tinubu

Tinubu ati Remi

Mary Seunfunmi Fagbohun

Oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti se alaye pe Omo bibi agbegbe Niger Delta ni iyawo oun, Senito Remi Tinubu.

Koda, o wi pe, leyin ti oun ti gba oye ibile lati Gbaramotu ni ipinle Delta ni oun ti di okan lara won.

O fi kun un pe oun kun oju osuwon lati le je omo Niger Delta nitori iyawo oun wa lati ibe.

Ni Oporoza, Gbaramotu ni o ti so eyi, nibi ti o ti se ileri lati maa ba awon adari Niger Delta se asaro lati le seto ati se agbekale awon eto isejoba ati ipilese ti yoo mu ki agbegbe naa dagba soke.

O soro niwaju awon loba-loba ti won n dari agbegbe naa eyi ti Pere ti Gbaramotu, Kabiesi Oboro Gbaraun keji, se akoso won.

Ninu ipade naa, oludije fun ipo aare naa tun gba oye tuntun  miiran ‘Iyelawei’ ti Gbaramotu, oye yi ni o tumo si agbenaru gbegbe naa.

Nigba ti o gba Asiwaju lalejo ni aafin re, Pere ti Gbaramotu gboriyin fun oludije egbe oselu APC naa,  ti o si gbadura fun aseyori re ninu idibo fun ipo aare naa.

Gegebi oro kan lati offisi alukoro Tinubu, ti agbenuso re, Tunde Rahman, bu owo lu, Oba naa ro Tinubu pe ti won ba dibo yan, lati ri daju pe o da ibudo oko oju omi nla kan si Gbaramotu, ibudo ile ise, ati popona ti o ja geere ati afara ti o wo agbegbe naa.

Ninu ifesi re, Asiwaju Tinubu se ileri lati sise ki o le mu ki idagbasoke agbegbe naa ya ni kankan, o wi pe oun yoo ba awon adari se asaro loorekoore lati le se ipinlese ati ise akanse ti yoo ran agbegbe naa lowo.

“Okan lara yin ni mi, Omo Niger Delta ni iyawo mi. Ana yin ni mo je. Abi bee ko?’, Tinubu so fun won.

O ni oun mo si ise ti won bere sise re ni popona Warri-Escravos/Gbaramotu, o si jeje pe ise naa yoo di pipari nipa gbigba osise ti o mo nipa ise naa lati se e bo ti ye.

O tun so wi pe, bi won ba dibo yan oun, eeka ijoba Niger Delta ati ajo ti o n ri si idagbasoke Niger Delta yoo sise takuntakun fun idi ti won fi da won sile.

“Okunrin ti o duro niwaju yin yii yoo se ohunkohun ti o ba so. E nilo ooto, e nilo ifarasin lati sise. Mejeeji ni mo ni. Mo mo ona naa, ma a si ko gbogbo awon eniyan Niger Delta dani. A o se asaro pelu awon adari yin fun idagbasoke Gbaramotu ati awon agbegbe ti o so mo.”

Ìdí pàtàkì tí mo fi fẹ́ di Ààrẹ Naijeria – Peter Obi

Peter Obi

 

 

Oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu Labour Party (LP), Ogbeni Peter Obi, ti so pe ilepa ipo aare re wa fun ojo iwaju orile ede yii lai fi ti esin tabi eya se.

Obi so eyi ni Enugu ni ibi  apejo “Seto ojo iwaju” ti ajo kan to n je Boys Champion (BC) se agbekale re.

Obi gba awon odomokunrin naa niyanju lati mase dibo fun eya tabi esin, o tenumo pe ko si esin kan tabi eya kan ti yoo ra bugan tabi iresi ni edinwo bi orile ede ti se wa bayii.

“Mo je eni ti o n wa ise, idi niyi ti mo fi wa niwaju eyin olugbasise mi (odo, youths) ati wi pe akoko awon odo Naijeria niyi lati gba orile ede won.

“Mo je olufarasin fun ise naa, ki e si fa mi laso bi mo ba ja yin kule. Ti e ba se ohun ti ko dara leni, ojo iwaju yoo gbesan lara yin,” o se ikilo fun won.

Obi ro awon odo lati dibo fun eni ti o kun oju osuwon nikan ati adari ti o se e gbagbo ti yoo le e yi ojo iwaju won pada leyin idibo odun 2023 to n bo.

“Mejidinlogun ninu wa ni yoo so ohun kan sugbon e gbodo ri aridaju ohun ti won n so fun yin. Ko si aaye fun agbeyewo ni 2023.

“A o yo agbekale oran dida won, a o si dipo re pelu agbekale idagbasoke,” ni ohun ti Obi so.

Gomina ipinle Anambra tele ri naa so pe oun yoo se ipese aabo to daju fun gbogbo omo Naijeria ki aaye le gba awon agbe lati le pada si oko won ki owon gogo ounje le e dinku.

“A o pese awon osise aabo nipa gbigba awon eniyan si ise olopa ati fifun won ni ohun elo lati le gbogun ti aisi aabo.

“Ona kan soso re ti a fi le gbe Naijeria lati ipo jegudujera si ipo awujo ti o leso ni nipa ninawo sori awon odo ati wi pe Naijeria gbodo bo ara re.

“Ijoba mi yoo yo owo iranwo lori epo, yoo si lo owo naa lati da ise sile fun awon odo, eyi ni ojo iwaju ti a fe mu wa,” Obi se afikun.

Sanwo-Olu pelu Ara

Mary Seunfunmi Fagbohun

Gomina Babajide Sanwo-Olu ni Ojoruu, iyen Alaaruba, ni anfaani lati fi ijo re han nigba ti obinrin inilu, Ara, ba a lalejo.

Bi Ara se n lu ni Sanwo-Olu n jo, ti tapa-tese re si n ba gangan mu.

Arabinrin naa, Araoluwa Olumuyiwa lo si odo Sanwo-Olu lori awon omo alarinka to ti kojo, to n se eto iwuri fun.

Ijoba Eko lo n ran an lowo lori eto yii.

Gomina wa ro awon omobinrin ati omokunrin igboro ti won gba sile naa lati ma dekun lori ala won lati di eni nla lawujo.

Sanwo-Olu gba won niyanju ni ile ijoba ni Ikeja, Eko, nigba ti o gba alejo ayanbinrin ti oruko re gangan n je, Aralola Olumuyiwa, ati awon omo ti o n gbe popona ti o gba mora ti o si gba sile labe eto “Eko wu mi lori” eyi ti ijoba ipinle Eko n se atileyin fun.

Die lara won je eni ti awon obi won ko ko mora ati awon ti ipinya wa laarin ebi won. Awon miiran kuro nile nitori iya asilo, nigba ti awon miiran gba lati jiya loju popo leyin ti baba ati iya won ku tan.

Gbogbo ala won ati ireti won ni o di korofo, won wa di aninilara kiri adugbo, won si ri won gegebi ewu ilu ki won to gba won sile.

Awon ti oro kan naa ni igbe aye won ti n yi pada si rere nipase eto “Eko wu mi lori” ti Gomina Sanwo-Olu se atileyin fun. Gomina naa ro awon ti won gba sile naa lati mase so ireti nu lori ala won, sugbon ki won se amulo eto naa lati le e mu ki ebun abinibi won ru gege si i.

Gomina gboriyin fun ayanbinrin naa fun dida eto ti o n gba awon omo popona naa la, o si jeje lati gbaruku ti eto naa ati pe yoo lo o fun awokose rere lati mu ki awujo tesiwaju.

Sanwo-Olu fwa owosi ipese elo ise ati irinse fun ogorun lara awon omo naa ninu ise ti onikaluku won yan laayo.

 

Ikú òjijì: Mọ̀lẹ́bí Sammie Okposo gbà f’Ọ́lọ́run. Wọ́n ní ańgẹ́lì ló ń bá kọrin báyìí.

Okposo

Mary Seunfunmi Fagbohun

Molebi akorin igbala to gbese lojo die seyin, Sammie Okposo, ti soro lori ipapoda re o.

Won ni  olokiki olorin ihinrere naa ti lo ba Olorun re, koda, won ni awon angeli lo n ba korin po bayii.

“A tu ara wa ninu nitori ti a mo pe odo Jesu lo wa ti o si n korin pelu awon angeli,” ni won so ninu oro won lojo Eti, ninu iwe ikede kan ti Hecter Okposo bu owo lu.

O ni,  “Pelu okan wuwo sugbon pelu ijowo fun Olorun ni mo fi kede ipapoda oko, baba, egbon, aburo wa owon ati iranse Olorun, Sammie Okposo, eni ti o sun ninu Oluwa ti o si lo ba Oluwa pade ni ojo Eti, ojo karundinlogbon osu kokanla, odun 2022.

“A tu ara wa ninu nitori ti a mo pe odo Jesu lo wa ti o si n korin pelu awon angeli. A toro aaye fun molebi naa lati kedun ni alafia ni akoko yii.”

O ga ju! Sanwo-Olu ki ijo mole bo se gba obinrin onilu Ara lalejo.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ni Ojoruu, iyen Alaaruba, ni anfaani lati fi ijo re han nigba ti obinrin inilu, Ara, ba a lalejo.

Bi Ara se n lu ni Sanwo-Olu n jo, ti tapa-tese re si n ba gangan mu.

Arabinrin naa, Araoluwa Olumuyiwa lo si odo Sanwo-Olu lori awon omo alarinka to ti kojo, to n se eto iwuri fun.