A kú ọdún

Lagelu FM, ẹbí àti ọ̀rẹ́ sèdárò Kọ́lá Ọládàpọ̀
*Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́*
Hùn! Kín ló dé
Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́
Kín ló ń kán ọ lójú
Kín lo fẹ́ gbà
Irú ebi kín ló ń pa ọ́
Tó ò lé mébi mọ́nú
Kín ló dé tó ò mójú nù
Kín ló dé tó ò le yááfí
Kín ló dé tó lè ṣàpamọ́ra
Kín lo fi ń sọrí
Tó o fi gbẹ̀mí ìràwọ̀ àṣẹ̀ṣẹ̀yọ
Tó o fi wólé ọlá kanlẹ̀ lógìdo
Tó o fi sọ̀kò ọ̀fọ̀ sílé aláyọ̀
Tó o fi dáṣọ ìbànújẹ́ dípò ìdùnú
Iṣẹ́ kín ló jẹ́ fún Kọ́lá
Àrọwà wo lo fi tù ú lójú
T’ọmọ Ọládàpọ̀ fi jẹ́ ọ ní hòo!
KỌ́LÁ ÒÒÒÒ!
Hàààà! KỌ́LÁ
Kín gan ló wọ̀ ọ́ lójú nílé ikú?
Ọjà wo gan ló wá títí
Tó o fi já sílé ikú dandan
Láníntán kan kìí níwo ẹṣin
Mo gbà láì janu
À mọ́ tó bá jẹ́ ti ọgbọ́n
Èdùwà fún lọ́gbọ́n
Tó bá jẹ́ ti ìmọ̀
Adániwáyé Ò gan ìmọ̀ fún ọ dénú agbárí
Bá a bá ń perí làákàyè baba ọgbọ́n
Bì ibú omi ni nínú agbárí Kọ́lá Ọládàpọ̀
Ẹ̀mì ìtẹríba níbi gbogbo
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ dójútáyé
Ká ṣọ̀yàyà nínú ìfẹ́ dódò ikùn
Ká gbani nímọ̀ràn àtàtà ká sì tẹ́ti bẹ̀lẹ̀jẹ́
Kọ́lá Ọládàpọ̀ ò lábùyẹ
Báyé bá rí ẹni ẹni tó kú
Ẹ bí Kọ́lá ,ẹ pé irọ́ ni mo pa
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́
Ó tó torí tá a bá ṣèdárò ẹni wa
Ilẹ̀ ń gbé èèyàn mi
Kọ́lá Ọládàpọ̀ ti dáṣọrọ̀gún
Olórí dúkìá mí kanlẹ̀
Kọ́lá Ọládàpọ̀ bó sọnù ẹ̀mi ò ṣe é rí he bí owó
Láwújọ akọ̀ròyìn kàròyìn
Kọ́lá ti pà ‘lẹ̀kùn ìmọ̀ dé
Kọ́lá pàlẹ̀kùn ìmọ̀ dé
pẹ̀lú àgádágodo láéláé gbére
Ìràwọ̀ tó ń tàn níṣẹ́ ìròyìn Kọ́lá darapọ̀ máwùjọ ẹbọra
A ṣìpẹ̀ ṣìpẹ̀ kíkú ó jọ̀wọ́ ẹ̀
Àlọ̀ lá rí Kọ́lá lọ kò náání àbọ̀.
Ẹni tó bá mọ ilé agbe
Kó bá ni wò ó
Ṣé ó tún ń dá aró bí ìsaájú?
Ẹni tó bá mọ ilé àlùkò kó bá ni wò ó
Ṣó sì ń ṣe osùn láì rẹ̀wẹ̀sì?
Èèyàn tó bá mọ ilé lékeǹké ó wí
Ṣé ò tẹ̀tì nínú ìkẹfun?
Eyín ká ilé
Ilé ẹ̀rín wó wómúwómú
Ẹyẹ lọ ìtẹ́ dòfò ó dòfo
Aya,ọmọ, ẹbí, ọ̀rẹ́, ìyekan
Ewúrẹ́ wọn bojú wò réré
Gbogbo wọn dúró gbári
Wọn ò réléèpo
Àgùtàn wọn bojú wò réré
Gbogbo wọn dúró gbári
Wọ́n fi eléèrí ṣàpèdáhùn
Kọ́lá Ọládàpọ̀ ò sí mọ́
Ikú ti jàwá lólè sùúná tuntun
Òkú ló jìírọ̀ orúkọ ọmọ
Kọ́lá ò dà pọ̀ mọ́ lá mọ́
Òṣùpá Kọ́lá wọ́ọ̀kùn
Bàtá Ọlá jákùn ó dìkàlẹ̀
Bá a bá tún gbìyànjú tomi lójú títí bí egbére
Ṣá a rómi ojú rojọ ṣèràpadà ẹ̀mí Kọ́lá bí
Bá a bá ràròkàn dé góǹgó ẹ̀mí
Ẹ gbọ́ ṣé ikú fojú ibẹ̀ ṣọ̀fọ̀ di ẹ̀rín
Ẹni a ròyìn ròyìn tí tí tí
nílànà àlà funfun bí aṣọ
Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n láròyé
Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n ní ìwíjọ́
Ẹ jẹ́ á yin Èdùwà
Ikú ló jẹ̀bi
Ìkú ti gbó tayọ ewú
Ikú ti gbó tayọ òǹkà
Ikú ti gbó tayọ ìdùnú
Ikú ń fìbànújẹ́ ṣe ayọ̀ ọ́ yọ̀ ni
Ikú lèèyàn tó dáná sunlé ìran rẹ̀ tẹ̀rín tọ̀yàyà
Ìránṣẹ́ ni gbogbo ajogun
Èdùwà Ó ṣèdájọ́ ikú
Lorí èyí Èdùwà ó gbẹ̀san ikú Kọ́lá fún wa
Ọmọ tí Kọ́lá Ọládàpọ̀ bí
kí gbogbo wọn pátá ò yàn ,kí wọn ó gbó hewú gbúrúgbúrú
Kí ẹ̀mí ìyàwó ó gùn, kí ẹbí,ọ̀rẹ́,ìyekan ó yọjú
ṣàjọyọ̀ nínú ìṣerere
Ọmọ tó fi sáyé lọ
A bèèrè ẹ̀san èyí Èdùwà
Ẹ̀bẹ̀ kan túnrè é
Má wo gbogbo ibi orí Kọ́lá Ọládàpọ̀ ti mì ní dúníyàn
gbégi lé ‘dùnú ẹ̀ ní párádísè
Àànú la bèèrè má wo àlésọ̀ wa bí ẹlẹ́ran ara.
*Fẹ́mi Akínṣọlá kí ọ pé, ó dàárọ̀ gbére, Kọ́lá Ọládàpọ̀ ,Mr Nice Guy Lagelu FM.*
Anthony Joshua fara pa nínú ìjàm̀bá mọ́tò tí ènìyàn méji ti kú
Anthony Joshua fara pa nínú ìjàm̀bá mọ́tò tí ènìyàn méji ti kú
Ìròyìn òwúrọ̀
Ori lo ko arakunrin abẹsẹ ku bi ojo l’agbaye, Anthony Joshua yọ ninu ijamba mọto to waye ni oni ọjọ kọkandinlọgbọn, osu kejila ọdun yii.
Ijamba mọto naa waye ni adugbo Makun ti ipinle Ogun ni opopona marosẹ Lagos/Ibadan.
Mọto Lexus jeep rẹ pẹlu nọmba KRD 850 HN lo lọ fori sọ mọto nla kan. Oju ẹsẹ ni eniyan meji j’Ọlọrun nipe.
Ọgbẹni Adeniyi Orojo to jẹ osisẹ ileesẹ iroyin Punch ti isẹlẹ naa soju rẹ lo gbee sori afẹfẹ.

Kailani Mohammed ní kí Dangote jèbùrẹ́
Kailani Mohammed ní kí Dangote jèbùrẹ́
Yínká Àlàbí
Ọgbẹni Kailani Mohammed lo fẹsun owo ti ko mọ kan Aliko Dangote lori tẹlifisọn laipe yii. Ọrọ naa waye nitori ẹsun sise owo ilu makumaku ti Dangote fi kan ọgbẹni Farouk to jẹ ọga ile ifọpo Naijiria.
Kailani ni ki Dangote wa salaye bi o se di olowo paapaa julọ isẹ to se ni port Harcourt ni ọdun 1980.
Oju ẹsẹ ni agbẹjoro Dangote da lohun pe ko ko awọn ẹri rẹ wa si ile ẹjọ, bi bẹẹ kọ yoo san biliọnu kan naira owo ibanilorukọ jẹ.
Kia ni Ọgbẹni Kailani sare pada si ori ẹrọ tẹlifisọn kan naa lati rawọ ẹbẹ si Dangote. O ni ọrọ ohun da bi eedi ki Dangote jọwọ fori ji ohun ki o si ma se jẹ ki awọn lọ ile ẹjọ.
E wo fidio naa ki ẹ gbọọ funra yin.
AFCON 2025: Ibi tí ọpọ́n bọ́ọ̀lù náà sún dé
AFCON 2025: Ibi tí ọpọ́n bọ́ọ̀lù náà sún dé
Ìròyìn òwúrọ̀
Super Eagles sì n gbégbá orókè.
Ó mà ṣe o! Gbajú-gbajà ọ̀dọ́ òsèré Nollywood jẹ́ pè Ọlọ́run
Ó mà ṣe o! Gbajú-gbajà ọ̀dọ́ òsèré Nollywood jẹ́ pè Ọlọ́run
Ìròyìn òwúrọ̀
Iku doro, lojiji ni iku tun dede mu Allwell Ademola lọ. Ẹni ọdun mẹtalelogoji ni arabinrin naa.
Ile iwosan Ancilia Catholic ti Agege ni wọn sare gbe e lọ bi Àárẹ̀ ọkan se dede mu u.
Allwell Ademola ti wa lori itage lati bii ọdun mẹẹdogun.
O ti kopa ninu ọpọlọpọ ere bii – False Flag, Badcop and Murder at the Bar pelu awọn ere ni ede Oyinbo ati Yoruba.
Ibanikẹdun si ti n lọ lorisiirisii lori ayelujara.
Àsìta ìbọn ni àdó olóró tó balẹ̀ sí Kwara- Minisita Ìròyìn
Àsìta ìbọn ni àdó olóró tó balẹ̀ sí Kwara- Minisita Ìròyìn
Yínká Àlàbí
Minisita eto iroyin ati asa ni orileede yii, Mohammed Idris ni ijọba apapọ ati gbogbo awọn ologun to yẹ ko mọ lo mọ nipa ado oloro to wọlẹ si igbo Bauni ni ijọba ibilẹ Tangaza, to wa ni ipinlẹ Sokoto.
O ni asita ni eyi to balẹ si ilu Offa ni ipinlẹ Kwara ati Jabo to wa ni ijọba ibile Tambuwal ni Sokoto.
Minisita ni ọdọ awọn apaniyan ati ajinigbe agbaye (ISIS) ni awọn ado naa wa fun.
Ko tii si ẹni to mọ iye awọn ISIS to pa, eyi to balẹ si ipinlẹ Kwara naa ko mu ẹmi kankan dani sugbọn o ba ile marun-un jẹ.
Ìyàlẹ́nu àdó olóró Trump sí Naijiria
Ìyàlẹ́nu àdó olóró Trump sí Naijiria
Yínká Àlàbí
Ko ki n se iroyin mọ ti a ba ni Aare Amerika pada ṣe iranlọwọ to seleri fun Naijiria.
Iyalenu awọn eniyan ni pe bawo ni awọn ado naa se de Sokoto?
Ṣe ko lewu ti baluu ba kọja si asiko naa?
Awọn ọmọran ni wọn dahun gbogbo awọn ibeere naa. Wọn ni lati orileede Spain ni awọn ado naa ti gbera. Wọn ni bi wọn se seto rẹ, “ibi ti a ba fi ẹlẹmọsọ sọ nikan lo maa n sọ”.
Awọn kan ni ọkan ninu awọn orileede to sun mọ wa ni ado oloro naa ti gbera. Awọn kan tilẹ darukọ orileede Ghana. Gbogbo eyi o wi ki o jẹ, ado oloro wọ ipinlẹ Sokoto, o si foji awọn asebi ri mọ̀bo.
Tinubu sèdárò àwọn asòfin méjì tí wọ́n jé pè Olorun
Tinubu sèdárò àwọn asòfin méjì tí wọ́n jé pè Olorun
Yínká Àlàbí
Aare Bola Tinubu ti Naijiria ransẹ ibani kẹdun si ipinlẹ Kano. Isẹ yii da lori awọn asofin ile igbimọ asofin kekere to gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Isẹlẹ buru yii waye laarin wakati kan si ara wọn ni ọjọ buruku esu gbomi mu ni ọjọ wẹside, ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu kejila ọdun 2025.
Ìdí tí iná iléesẹ́ alájà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Eko fi wọ ọjọ́ kérésì
Ìdí tí iná iléesẹ́ alájà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Eko fi wọ ọjọ́ kérésì
Yínká Àlàbí
Margaret Adeseye, to jẹ ọga ileesẹ panapana l’Eko lo n salaye fun oniroyin ni oni ọjọ keedọgbọn, osu keji ọdun 2025 idi ti ina to sẹyọ ni Great Nigeria insurance to wa ni opopona Martins ni Eko fi wọ ọjọ keji.
Oga panapana yii salaye pe wọn pe awọn ni aago marun-un ku iseju mọkandinlogun ni irọlẹ (4:41pm), awọn si de ibẹ ni nnkan bii isẹju mẹwaa si ara wọn.
O ni ina naa soro lati pa nitori bi wọn se kọ ile ati awọn ile to yi ileesẹ naa po. O ni eyi to buru ju ni awọn nnkan ti wọn ko si ile iko nnkan si ti ọja naa si wa lara nnkan to yara jona.
Margaret Adeseye ni awọn sare beere iranlowo lati Ebute Elefun, Dolphin, Sari Iganmu, Bolade, Isọlọ ati Alawusa.
Ọga panapana yii ni pẹlu gbogbo igbiyanju yii, awọn ko ri ina naa pa ni keresimesi ku ọla titi di ọjọ keresi ki awon to ri ina naa pa tan patapata.
Ile alaja mẹẹdọgbọn ni ile naa. Eniyan mẹwaa ni awọn alaabo ilu gbe jade ti wọn ni ifarapa lorisiirisii. Ko si ẹni to gbe ẹmi mi titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.















