Home Blog Page 86

Iró ń parọ́ fúnró̩ Ọ̀wọ́n gógó epo petiró tún gbàlú kan

“Egbinrin ote, bi a ti n pakan ni okan n ru ni oro orileede yii”. A ko tii bo lowo eto aabo to mehe kaakiri orileede ati owon ounje ni orisiirisii ti owon gogo epo petiro tun ti gba ilu kan. Bi ere, bi awada ni o se koko bere ni agbegbe Ariwa ki o to wa di pe o kari aye. Awon alase kan n fowo soya pe owon gogo naa ko le lo wakati merinlelogun tii se ojo kan.

Bayii, ni ipinle Eko ati agbegbe re naa ti n foju wina oda epo. Igbagbo awon ara ilu ni pe epo yii wa sugbon, awon aje-nidii-madaru ni won n wowọ mọ epo naa. Won ni ọpọ won lo ni epo sugbon ti won kan fe maa ni ara ilu lara.

Awon kan tilẹ ti n taa ni igba naira(N200), ọgọsan-an(N180), igba din mẹwaa naira(N190) ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọpọ won ni won ko yi mita won pada kuro ni aadosan-an naira(N170) sugbon won n fi kakuletọ si iye epo ti ẹ ba ra. Won si n je ki o ye onibara pe iye bayii ni epo ti awon, ni eyi to tumọ si pe iwọfun ni.

Ọwọn gogo ti won ni ko ni ju ọjọ kan lo ti wọ ojo kẹta lonii Ọjọ’ru, ojo kẹrindinlọgbọn osu kẹwaa ọdun okoolelẹgbaale-meji(26/10/2022). Alaga ẹgbẹ epo petiro ti aladaani ni agbegbe Gusu IPMAN (Independent Petroleum Marketers Assosiation of Naigeria), Ogbeni Dele Tajudeen ni epo tile ti won wa lati Apapa ti awon ti n gbee, awon oga kan ni ẹkun omi n se akoba fun awon oko lati gbe epo, awon kan ni ijoba apapo ko tile lepo bayii, won ni awon aladaani to ni epo lo n se eyi to wu won, awon kan ni gbese ti ijoba apapo je naa n se awon akoba kan.

Bayii, a ko mo eyi ti a fe di mu ninu gbogbo awijare awon alase epo petiro naa. Ju gbogbo re lo , Epo ti won kaakiri orileede yi.

G. O Adeboye ló fún mi ní Abraham (Bàbá orílèèdè) – Tinubu

Oludije du ipo Aare labe Asia egbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo n salaye foniroyin leyin ipade to se pelu awon ajo CAN (Christian Association of Nigeria) ati awon ijo MusulumiTijaniyya ni ilu Kano.

Ijo Redeem to wa lara awon ipago to tobi to si lero ju ni orileede yii ni Baba Enoch Adeboye n dari. Tinubu ni oro naa jade lenu baba naa ni igba ti Oluremi Tinubu to je aya oun n gba oye Pasito.

Tinubu n fi eleyii salaye fun araye pe asepo to dan moran wa laarin oun ati awon elesin kirisiteeni lorileede yii. O ni ki awon ti o mo oun maa salaye faraye pe oun o ki n se elesinmesin tabi eleyameya.

Àgbàrá òjò fẹ́ gbé ìlú Goodluck Jonathan lọ

Agbara ojo to ba awon ipinle kan finra ni orileede yii ti doju so  Otuoke tii se ilu Aare ana Omowe Goodluck Jonathan ni ipinle Bayelsa.

Gege bi akoroyin NAN se salaye nipa abewo re si Fasiti ijoba apapo to wan i ilu naa, o ni aseju woo se ti omi se si ile-iwe naa nitori pe ko tile see wo rara. O ni bi awon eniyan se n lo oko oju om I wo ile won naa ni awon ni lati wo oko oju omi de itosi ile-iwe naa.

Akoroyin NAN ran wa leti pe omi sose ni ipinle naa ni odun 2012 amo ti odun yii po ju. Lara awon ara ilu to salaye oun toju n ri ni Ogbeni Azibalau Oru ti o n rawo ebe si ijoba apapo lati siju aanu wo awon ni ijoba ibile Ogbia ti Otuoke wa. Oru ni opolopo dukia awon lo ti baje sinu omi naa. O tun ni eyi to buru ju nibe ni awon eran omi bii ejo ati awon eran omi buruku miiran lo ti gba inu omi yii kan.

Elomiran to tun ba akoroyin NAN soro ni Emmanuel Peter, eni yii ni yato sip e oko oju omit i awon n lo wole, o n I awon ole ko tun je ki awon gbadun, o wa rawo ebe si ijoba ipinle naa lati ma se je ki iya meji je awon gbe.

Elomiran tun ni Godknows Frank ti o je olori awon odo agbegbe naa, o ni lati igba ti ajalu omi yii ti bere ni awon ko ti ri oluranlowo Kankan siju aanu wo awon. O ni eni ti eniyan bar i lasiko isoro ni enikeji eniyan, o ni asiko niyi ti o ye ki gbogbo awon oludije du ipo kan siju aanu wo awon, ki ipolongo ibo won ma kan lo je ileri asan nitori pe ounje ti eniyan ba je ni igba tie bi n paa ni oba ounje.

Orí kó akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok méjì àti ènìyàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún mìíràn yọ

Ogagun Waidi Shaibu lo n salaye foniroyin lanaa ojo Jimo nipa akitiyan won lati je ki alaafia joba lorileede yii. Ogagun ti Commading 7 Division ati Sector 1 Joint Task Force, North East Operation HADIN KAI ni leyin idojuko ti awon se pelu awon Boko Haram ni awon ti yọ awon akẹkọọbin Chibok meji, ekinni ni Rejoice Sanki omo odun merinlelogun(24) pelu omo meji nigba ti ekeji n jẹ Yagana Poly ti oun naa je omo odun merinlelogun pelu omo merin.

Ogagun yii ni ninu igbiyanju awon naa ni awon ti doola awon mokandinlogunrun-un(99) miiran, ti metadinlaadota (47) ninu won je obinrin ti awon to ku si je okunrin.

Ogagun Waidi ni igbiyanju awon yii waye laarin ojo kokandinlogbon(29) osu kesan-an si ojo keji osu kewaa odun yii.

Ẹni Ọlọ́run kò pa, kò ní kú – Apostle Suleiman

Ojise Olorun Johnson Suleiman ti awon onise ibi kọ lu ni ana ọjọ  Ẹti, ojo kokanlelogun, osu kewaa odun yii lo n forere pe, lati odun 2017 ni awon eniyan bururku yii ti n lepa ẹmi oun.

Apostle ni o yẹ ki oun darukọ awon onisẹ ibi naa, amọ o ku die nitori pe oun mọ daju pe won maa ko jalẹ peawon ko lepa emi ẹni Kankan. O ni isele ojo Jimo naa buru pupo nitori awon emi ti won ko le da ni won se lofo. Eniyan meje tan lo ba isele naa lo nigba ti won doju ibon kọ mọto oun ati awọn ti awon jọ n lọ.

Apostle jẹ ki o ye awon onise ibi naa pe “iku ati ọdọ Olorun nikan lo le mu oun lọ”. O ni oun si mo daju pe ẹlẹsẹ Kankan ko ni lo lai jiya. O ni gbogbo awon to n lepa emi oun ni asiri won maa tu faye laipe nitori pe oun ko mọ oun ti o n bi won ninu pelu ise Olorun ti oun gbe dani ti o si n te siwaju.

Apostle ni asiko oro ko tii to bayii nitori pe awon si n se idaro awon Olopaa merin pelu awon omo olomo meta to ba ajalu naa lo ni opopona Benin si Auchi.

 

Ọmọ Yahoo gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n

Ọmọ Yahoo gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Ajo EFCC to n foju to awon onijibiti ni won ti ko awon omo Yahoo marun-un fun esun orisiirisii lo ile-ejo ni ilu Lafia to wa ni ipinle Nasarawa.

Awon omo Yahoo naa ni Francis Chukwuka Okwechime, Olaniyi Odunayo Precious, Israel Stephen Auta, Oluwabori Azeez Rafiu ati David Stephen. Okwechime dibon pe oun ni Joshep Michael to je Oga Soja ni orileede America. O se eyi lati lu enikan to n je Molly ni jibiti owo dola oodunrunlelaadota ($350). Nigba ti Olaniyi n lu jibiti tire lori ero ayelujara lati fi gba Ogbeni Samuel Mayona. Isreal naa n dibon pe oun ni Ivy Jordan omo orileede America lati maa fi lu jibiti orisiirisii lori ero ayelujara,Oluwabori n dibon pe oun ni John Albert ati Raymond Lee lati orileede Singapore fun jibiti ori ero ayelujara naa ni gbogbo re, Stephen ni tire ni oun ni Major_hack007 lati maa fi lu jibiti gbogbo eni to ba ko si lowo lori ero ayelujara.

Gbogbo won ni won gba pe awon jebi esun naa. Onidajo Afolabi ju Olaniyi ati Stephen si ewon odun meji tabi ki won san egberun lona aadojo si igba naira (#150,000 – #200,000). Isreal ati Oluwatobi gba ewon osu mefa tabi owo itanran egberun lona aadota naira (#50,000), Owo itanran ti Okwechime je egberun lona ogorun-un naira (#100,000).

Ile-ejo si je ki Olaniyi mo pe ko ni ri foonu Infinix Note 10 to fi n lu jibiti gba mo nitori pe ijoba apapo ti gbese lee.

 

Adájọ́ kọ̀ láti gbẹ̀bẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá lò

Adájọ́ kọ̀ láti gbẹ̀bẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá lò

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Omo odun merindinlogun to n gbe ni Satellite Town ni ipinle Eko ni adajo Ejiro Kubeinje ti ni ki won da pada si Oregun nitori pe o fipa ja ibale omo odun mewaa kan. Oregun ni ibi ti won ti n se atunse fun awon omo ti ko ba tii to odun mejidinlogun sugbon ti won daran.

Ojo kejidinlogun osu kejo ni igbejo maa waye lori esun naa. Oga olopaa DSP Kehinde Ajayi ni isele buruku yii waye ni ojo kejilelogun, osu kefa ni ile-iwe Lead College to wa ni Satellite Town. DSP Ajayi ni arakunrin naa fipa ba omo naa lo ni eyi to ta ko iwe ofin ti abala iwa odaran to wa ni abala 137 ti odun 2015.

Awon eniyan ni boya ojo ori nikan lo le ko arakunrin naa yo nitori pe ti o ba je agbalagba lo da iru oran bee, ewon gbere ni . Idajo di inu osu kejo.

 

 

 

EFCC f’ọwọ́ sìnkún òfin mú Ààfáà méjì tó sòògùn tí kò jẹ́ l’Ekiti

EFCC f’ọwọ́ sìnkún òfin mú Ààfáà méjì tó sòògùn tí kò jẹ́ l’Ekiti

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Omo ile igbimo asoju kan ni o ti fi esun kan awon Aafaa meji ni ipinle Ekiti, ni eyi ti awon ajo EFCC to n foju to awon to se owo maku-maku ti lo ko awon Aafaa mejeeji naa.

Ija lo de lorin dowe ni oro naa. Omo ile igbimo asofin ti a n soro re yii lo ko ejo lo si odo awon Aafaa naa. O ni gege bi asa agbegbe Oye Ekiti ati Ikole Ekiti. Ti Ikole ba se fun odun merin, Oye maa se fun odun merin miran. Ni igba ti o dori Onorebu ti a foruko bo lasiri yii. N se lo ko ejo lo si odo awon Aafaa pe ki won jowo gba oun sile.

O ni oun ko fe ki iyipada ti awon n tele ni agbegbe oun te siwaju mo. O ni Oye-Ekiti ti oun n soju ni oun fe ki o si maa se ijoba lo. O ni oun ni oun fe se odun mejeejo.

Ni igbeyin, gbogbo ewe ati egbo ti awon eniyan yii ja ko je. Iyipada naa de, awon eniyan ranti, won si gbe ipo Onorebu naa lo si Ikole-Ekiti. Eyi lo mu ki Onorebu to ti nawo naira to le ni milionu merinlelogun gba odo awon ajo EFCC lo lati lo fejo sun.

Aafaa Abiodun Ibrahim ati Wale Adifala jewo pe loooto ni awon gba awon owo naa lati ba Onorebu sise, gbogbo eronja bii Maluu dudu, funfun, alawo koko, Agbo, pafuumu oloorun didun, Ooka ati awon nnkan miiran to ye lati lo ni awon ra.  Won ni awon tun pe Ogbeni Ifawole Ajibola mora ki ise naa le ya lati se.

Won ni awon se bi o se ye ki awon se e ti awon si ni igbagbo pe o ye ki o ri bi awon se fe ki o ri., Sugbon iyalenu lo je fun awon nigba ti Onarebu ko Olopaa de pe awon lu oun ni jibiti. Igbagbo awon ni pe ile-ejo maa da awon lare.

 

 

Ilé-ẹjọ́ fi ọkọ àti ìyàwó s’ẹ́wọ̀n Kirikiri nítorí àbùkù tí wọ́n fi kan ọ̀gá ọlọ́pàá

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ilé-ẹjọ́ fi ọkọ àti ìyàwó s’ẹ́wọ̀n Kirikiri nítorí àbùkù tí wọ́n fi kan ọ̀gá ọlọ́pàá

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Ogbeni Clintin Ayobami ati iyawo re ni ile ejo to wa ni ilu Eko ti ni ki won lo fara pamo si ogba ewon to wa ni kirikiri fun abuku ti won fi kan awon olopaa to da won duro ni ojo kerinla osu keje odun yii. Eyi waye ni adugbo Oluwaga to wa ni Iyana-ipaja . Isele naa si waye ni deede aago meji aabo osan ojo naa ni ipinle Eko.

Gege bi Hundeyin to je oga olopaa Ipaja se salaye, o ni awon olopaa kan da tokotaya yii duro ni osan ojo naa nitori oko mesi oloye ti ko ni nomba ida oko mo lara. Oga olopaa ni ki awon olopaa to wa ni ita to beere nnkankan lowo ogbeni Ayobami ni iyawo re ti fa ibinu yo to si bere si ni bu awon olopaa naa. Koda o see de bi wi pe o lo aso ijoba mo okan ninu awon olopaa naa lorun, ti o si bere si ni naa olopaa naa.

Awijare obinrin yii naa ko ju pe kin lo de ti awon olopaa naa ko da awon moto to n lo niwaju awon duro., to fi je awon nikan ni won da duro? Gbogbo bi arabinrin yii se n fa ijongbon yii ni oko re naa n kin leyin. Ni eyi to mu ki ile-ejo ni ki awon mejeeji lo fi aso penpe roko oba ki moto won naa si wa ni ago olopaa fun igba die.

 

 

Àjọ CAN kẹ̀yìn sí Pásítọ̀ Ade tó fẹ́ fi Bàálù kó àwọn ọmọ ìjọ lọ pàdé Jésù

Aare CAN, Alagba Daniel Okoh

Àjọ CAN kẹ̀yìn sí Pásítọ̀ Ade tó fẹ́ fi Bàálù kó àwọn ọmọ ìjọ lọ pàdé Jésù

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Ajo CAN ni ajo elesin Kirisiteeni ti agbojo won ga ju lo ni orileede Naijiria. Ajo yii kan naa lo keyin si Alagba Ade Abraham to gba oodunrun le mewaa naira (N310) lowo awon omo ijo re.

Iroyin pe o gba owo lo ta si ajo yii leti ni ipinle Kaduna ati Ekiti ti won fi gbe igbese akin. Won ni awon ko tile ri oruko alagba naa ninu iwe itan awon ni ipinle Kaduna, Won ni koda ko si oniroyin to gbo oruko re ri gege bii Pasito ri ni ipinle Kaduna.

Alagba John Joseph Hayab ti o je alaga ajo naa ni ipinle Kaduna ni iwa adojutini patapata ni Pasito naa wu. Alagba yii ko ogoji omo ijo si inu ile ijosin, o si wa won lo si agbegbe kan ni ipinle Ekiti ti Baalu ti maa wa gbe won lo si orun rere gege bi alaye re.

Alagba Ade ni emi Olorun ni o fi oro ye oun, o ni oun ko le dede gb e iro kale ti oun ko ba gbo eyi lati odo emi mimo.

Olori ajo naa ni ipinle Kaduna gba awon eniyan ni imoran pe ki awon eniyan naa ma se se ole, ki won maa ka Bibeli won daadaa. O ni eyi ni ko ni je ki enikankan le maa pa iro fun won. O ni iyalenu ni oro naa je, o si je nnkan idojuti pe awon agbalagba ti kii se omode le gba pe ki Baalu maa gbe awon lo pade Jesu, ki awon naa si maa dawo fun enikan.