Home Blog Page 85

Destiny Etiko kí òsèré tíátà, Sharon Francis kú aye̩ye̩ o̩jó̩ò̩bí

Destiny Etiko kí òsèré tíátà, Sharon Francis kú aye̩ye̩ o̩jó̩ò̩bí

Ilumooka osere, Destiny Etiko ti lo si ori ayelujara re lati fi aworan ore korikosun re ati gbajugbaju osere tiata, Sharon Francis lede bi o se sajoyo ojo ibi odun kokanle-ni-ogbon. Destiny si gbadura pe ki emi re gun ninu oro pelu ibukun latorunwa. Oro ifori naa ka bayi pe, “Ku oriire ojo ibi Ugegbe Akwa. Mo gba a ladura pe ki emi re gun ninu oro pelu ibukun latorunwa. Opolopo ore-ofe alailabula ati owo yoo je tire”.

Sharon eni to n jegbadun asiko lowolowo ni Seychelles. Ni wakati die seyin, lo si ori ayelujara re lati fi aworan ara re lede. O so pe ojo ibi oun duro fun idagbasoke, o fikun n pe ohun to dara ni lati wa laarin awon ti won nife eniyan ati awon ti won n se abojuto eniyan nitooto.

Awon aworan awotunwo yii ni o ti fa ki awon afenifere ati awon ilumooka ma a fesi nitori ewa re. Ewe, won si soro soke lati ki i fun ti ojo ibi. Awon ilumooka jakanjakan bii Daniella Okeke, Esther Audu, Ruby Ojiakor, Stella Udeze, Alex Cross, ati Ugegbe Ajaelo ni won fi ami ife ranse si i.

 

Àjọ EFCC ṣàwárí N32.4m owó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan fẹ́ fi ra ibò l’Eko

Àjọ EFCC ṣàwárí N32.4m owó tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan fẹ́ fi ra ibò l’Eko

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ó dá bí ẹni pé bí wọ́n ṣe ń gé àwon èèyàn kan lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bọ òrùka.
Akitiyan àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgudujẹra ní Nàìjíríà, EFCC ti bẹ̀rẹ sí so eso rere báyìí látàrí àti gbógun ti katakara atawọn mọkaruru tó níí ṣe pẹ̀lú owó ṣáájú ìdìbò ipò ààrẹ àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí yóò wáyé ló nìí.

Iṣẹ ti yaa bẹrẹ fun wọn naa niyẹn o gẹgẹ bi wọn ṣe fi panpẹ ọba gba owo to to miliọnu mẹtalelọgbọn o le ẹgbẹrun lọna irinwo naira ti wọn fẹsun kan wipe rira ibo ni wọn fẹ fi ṣe ni ipinlẹ Eko.

Awọn oṣiṣẹ ẹka ajọ EFCC to wa ni ipinlẹ Eko naa lo ṣe kongẹ gbigba owo naa wọn si ti ko awọn afurasi to lọwọ ninu ẹsun naa si atimọle fun ifọrọwanilẹnuwo.

Alága àjọ EFCC, Abdulrasheed Bawa ti rọ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ aj6ọ náà tí wọ́n rán láti ṣiṣẹ́ lásìkò ìdìbò yìí pé kí wọ́n ní ìgboyà kí wọ́n sì má fààyè gba àwọn onímọ̀dàrú tàbí oníwà tó lòdì sí òfin láti ta epo sí aṣọ àlà ètò ìdìbò nípasẹ fífi owó ra ìbò.

Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Ó ṣeéṣe kí àwọn kan gbìyànjú áti dá ètò ìdìbò rú, àwa náà gọ dè wọ́n – Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní tí omọ bá gbọ́n gbọ́n-ọn kúkú lẹ́ẹ̀rùn, ìyá a rẹ̀ á gbọ́n gbọ́n àti sin-ìn sí padò.
Ní báyìí, adarí àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu ti ní ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti jí ìbò tàbí da ètò ìdìbò rú yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu, nítorí pé àwọn agbófinró yóò fi ìyà tó tọ́ jẹ onítọhún.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmoud Yakubu sọ èyìí lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Àbújá ní gbọ̀gàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) tó wà nílùú Àbújá.

Gbọ̀ngán ICC yìí ni wọn yóò máa lò láti máa kó gbogbo èsì ìbò tó bá ń wáyé ní gbogbo ìpìnlẹ̀ jọ.

Bákan náà, gbọ̀ngàn ilé ìgbàlejò International Conference Centre (ICC) yìí ni wọn yóò lò láti kéde ẹni tó bá jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Ààrẹ ọ̀hún.

Lára àwọn tó wà níbí ìpàdé náà ni adarí ilé isẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà Usman Alkali Baba, àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè òkèèrè, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn akọ̀ròyìn.

February 25: Naijiria tún setán láti gbé àìlera rẹ̀ lé dókítà míràn lọ́wọ́

Bi e ba n gbo kangokango bayii, agogo ibo lo n ro o.

Eyin ni ibo Aaare to n waye lonii, ojo keedogbon osu keji yii – February 25, 2023.

Gege bi awon omo Naija se n wa olori miran, bi a ko ba ni tan ara wa, o dabi alailera eniyan to n wa dokita tabi adagunse miran leyin opolopo odun ti ara re ko ti ya, ti oniruuru onisegun si ti n ti i si ara won ni.

Aare Ologun, Aare alagbada ti n ti i si ara won lati 1960. Sibesibe,  bo se wa lo wa, tabi ko tun buru ju bee lo lawon apa ibi kan.

Lowolowo yii, owo Muhammadu Buhari ni Naija ti n gbawosan lati 2015. O ti koko wa bi Ologun, ko to wa pada bii alagbada.

Bo seere, bi ko seere, orile ede kan oun naa ni gbogbo wa wa y ii.

Sugbon ohun to se koko julo ni pe laarin Asiwaju Bola Tinubu (All Progressives Congress), Atiku Abubakar (Labour Party), (Peter Obi) Labour Party ati Rabiu Kwakwaso (NNPP) ni o jo  pe olori yoo ti jade.

Bo tile je pe awon ibo elerefee kan  lori Intaneeti n so pe Obi n gbegba oroke, ti Atiku naa kii si se ei ti eni kan le fowo ro seyin, opo eniyan ri Tinubu gege bi eni to le la awon to ku julo.

Lara ohun ti iru awon eni bee n wo ni bi o se je pe o moo po eniyan to se koo kaakiri Naijiria, o ni iriri ati owo to le fi hu ibo jade, awon gomina to le ni ogun lo wa leyin re. Ni Oke Oya ti ibo si o si ju naa, Tinubu ni awon gomina to lenu ti won n sise fun un karakara.

Lara won ni Nasir El-Rufai ti Kaduna ati Abdullahi Ganduje ti Kano.

Sugbon sa o, yoo kun ni, yoo fa ni o, oni lonii je!

Làásìgbò naira: Buhari takú, ó ní N500 àti N1,000 ti lulẹ

Emefiele ati Buhari

̀ Ó ktí ̀gbin sí àwn babaláwo Ilé j́ Gíga

–        IPAARO OWO: Emefiele da ipaya ati rogbodiyan silu

–        APC n korin anjuwon o see wi lejo, won  ni tori Tinubu ni oro naira ati epo se dogun-dode

Paahee si n joba ni oile ede yii latari ipawoda to  ba naira, lati owo banki to ga julo, iyen Central Bank of Nigeria, CBN.

Oro atunse lori naira naa to bere bi ere ti di nnkan nla, to n mu laasigbo ba ilu, ti ko si je ki tomode-tagba moo do ti won yoo da orunla si mo.

Oga Agba ni CBN, Ogbeni Godwin Emefiele, pelu Aare Muhammadu Buhari ni won mo ibi ti won di kinni naa si.

Awon mejeeji ni iyipada n ba awo N1,000, N500 ati N200 lati ba awon alakatakiti terrorists to ti ko owo pamo ja, lati ma je ki owo to le fa esuke ba oro aje po ni ita, ati lati ma je ki awon oloselu o ri owo ra ibo lasiko idibo to n bo.

Leyin wi pe opo eniyan ro pe ejo lowo ninu, ose bii marun-un pere ni Central Bank fi ni ki awon eniyan da naira atijo pada. Eyi fa waduwadu, tori ko si eni to fe ki owo di lunte moo un lowo.

Ibi ti wahala ti wa de baye ni pe owo tuntun to ye ki awon eniyan maa ri gba ni banki ko si nibe, ti ero alatagba Internet naa n ja bute bute, ti ko si je ki awon eniyan maa ni isoro lati lo banki olofurufu.

Nnkan ti daru debi pe naira ni awon eniyan fi n ra naira, paapaa lodo awon  to n sise POS, ti won n gba bii egberun meji naira – tabi ju bee lo – lori N10,000.

A ti ri eni to ku sori ila nibi ti won ti fe gba ATM.

Rogbodiyan ti n be sile kaakiri, ti awon eniyan kan si ti gbemii mi ni Ibadan ati Edo.

Bee, idibo lo ku ojo meloo yii, to si je pe epo petrol naa ti won bii imi egungun.

Idi niyi to fi ya awon eniyan lenu pe Aare Buhari je ki wahala naa  tan kaye bee, lai gbe igbese gidi kan to moyan lori.

Bee, bi awon eniyan kan se n ro pe Tinubu ni awon ota ikoko re ni Abuja, ti won n pe ni cabal fe fi ba loja je, Buhari si n polongo pe tie – ti Jagaban – loun n se. O ni obinrin to loyun, toKO re lo n se. Koda, o n tele Tinubu lo si awon ipinle kan fun kampeeni.

Gomina Ipinle Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, so ni tire pe awon cabal lo wa nidii yanponyanrin to n jalu lori epo ati naira.

Sibesibe, awon kan ni Buhari le ma ni nnkan ti ko dara lokan si Tinubu, ko kan gbagbo ninu ohun ti Emefiele ba so fun un.

Pabambari sele lojo Alamisi TO LO LOHUN, nigba ti Buhari kede pe N500 ati N1,000 ti di owo aina ni Naijiria. Eyi lodi si ohun ti ile ejo giga Supreme Court pa lase pe ki gbogbo owo si w ani nina titi ejo ti awon gomina kan bii El-Rufai ati Yayaha Bello gbe was siwaju re yoo se lojutuu.

Bàbá àti ọmọ yanṣẹ́ adigunjalè láàyò

Bàbá àti ọmọ yanṣẹ́
adigunjalè láàyò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Onírúurú ìwà èérí sá lá ó máa rí gbọ́ lákàtà àwọn èèyàn láabi
Ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣàníyàn láti fi iṣẹ́ rere lé ọmọ wọn lọ́wọ́, à mọ́ ní ti bàbá arúgbó ẹni ọdún márùúndínlọ́gọ́rin tí wọ́n lórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Weniwọn Abioro yìí, olè jíjà pọ́ńbélé lòun kọ́ ọmọ bíbí inú ẹ̀, oko olè ọ̀hún sì ni wọ́n ti mú òun atọmọ rẹ̀, Zaccheous Abioro, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, wọ́n ti wà ní ìgbèkùn àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ báyìí.

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ìṣẹlẹ yìí wáyé lọjọ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdílógún, oṣù Kejì yìí, nígbà táwọn afurasí náà yọ́ kẹ́lẹ́ wọnú oko tó jẹ́ ti Alaaji Moruf Kaka, èyí tó wà nílùú Ihunbọ, níjọba ìbílẹ̀ Ipokia, ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Àwọn aládùúgbò kan tó rí wọn níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti jáde lóko ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n ti jí àwọn dúkìá ẹni ẹlẹ́ni tán, ni wọ́n pariwo olè lé wọn lórí, wọ́n ṣì mú wọn, ni wọ́n bá ké sáwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò So-Safe lórí aago.

Nígbà tí wọ́n dé bẹ, wọ́n rí àwọn ẹrù tí wọ́n jí, lára ẹ̀ ni ìwé ilẹ̀ méjì, èròjà ọkọ̀ kan, àti àwọn wíńdò alumí tí wọ́n yọ férémù rẹ̀ gbogbo.

Ǹ jẹ́ kí ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ẹrù tí wọ́n jí kó yìí ṣe, wọ́n ní àwọn fẹ́ lọ tà á fáwọn ṣalẹ̀-ṣalẹ̀ tí wọ́n máa ń ràá ni, wọn tiẹ darukọ kọsitọma kan ti wọn lo maa n ra alumi lọwọ awọn, Ọgbẹni Bapa Madaki, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n.

Kíá làwọn ẹ̀ṣọ́ So-Safe ti wá òun náà kàn, tí wọ́n sì gbé e janto.

Wọ́n láwọn afurasí náà ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ làwọn ń jalè, kí wọ́n ṣàánú àwọn.

Alukoro ilé-iṣẹ́ So-Safe sọ pé àwọn ti fa àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ó ní iṣẹ́ ìwádìí ń tẹ̀síwájú lórí i wọn.

Ilẹ̀ rírì mìíràn tún ṣọṣẹ́ ní Turkey, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tún ṣèṣe !

Ilẹ̀ rírì mìíràn tún ṣọṣẹ́ ní Turkey, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tún ṣèṣe !

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hun-ùn hún, à fi kí Ọlọ́run sá à máa kó wa yọ nínú ewu gbogbo. À ń jèkuru ọran kó tán, lọ̀rọ̀ ilẹ̀ ríri ní ìlú yìí ọ,bí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì mìíràn tó wọlé tó jìn tó ìwọ̀n 6.4 tún ti ṣọṣẹ́ ní ẹkùn gúúsù orílẹ-èdè Turkey, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ rírì tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní orílẹ̀èdè náà wáyé.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀èdè náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Àwọn óṣojúmikòró sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Antakya.

Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kejì ni ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì wáye gbẹ̀yìn níbẹ̀ níbi tí ènìyàn 44,000 ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní Turkey àti Syria.

Mayor ìlú Hatay ní gúúsù Turkey ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló há sábẹ́ ilẹ̀.

ààrẹ Turkey ní kò dín ní ènìyàn mẹ́jọ tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tuntun yìí.

Àwọn aláṣẹ Turkey ní kò dín ní ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó wáyé ní ọjọ́sí dá ìbẹ̀rù sí lára àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ BBC tó wà ní agbègbè náà ní èyí tó wáyé lónìí lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n gbúròó rẹ̀ ní Syria, Egypt pati Lebanon.

Kò ì tíì sí àrídájú kankan báyìí bóyá ẹnikẹ́ni bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ àti iye ìjàmbá tó fà.

Muna Al Omar sọ fún Reuters pé òun wà lábẹ́ àtíbàbà kan ni òun gbọ́ tí ilẹ̀ rírì náà tún wáyé.

Ó ní òun lérò wí pé lábẹ́ ẹsẹ̀ òun ni ilẹ̀ náà yóò ti lanu ni bó ṣe mú ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún méje dúró ṣinṣin.

Akọ̀ròyìn AFP tó wà ní agbègbè náà ní inú fu àyà fu ni àwọn ènìyàn tó wà ní Antakya wà báyìí pẹ̀lú ọṣẹ́ tí èyí tó wáyé kọjá ti dà sí wọn lára.

Iléeṣẹ́ AFP jábọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ń pè fún ìrànlọ́wọ́.

Ali Mazlum ní òkú àwọn ẹbí òun tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó kójá lọ ni òun ń wá kí òmíràn yìí tó tún wáyé.

Ní Syria, àjọ tó ń mójútó ààbò ìlú ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló farapa bí àwọn ilé ṣe ń dàwó.

Àwọn ọmọlooku láwọn kò gba owó àtijọ, ni wọn bá gbé POS kalẹ̀ fáwọn èèyàn

Àwọn ọmọlooku láwọn kò gba owó àtijọ, ni wọn bá gbé POS kalẹ̀ fáwọn èèyàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ burúkú sòde kánrin, Ó dà bí ẹni pé ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ ń túbọ̀ fẹsẹ̀ rinlẹ̀ síi lojoojúmọ́ ni o pẹ̀lú ìsesí àwọn èèyàn àwujọ lásìkò yìí.
Ọrọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín, à fi bí àwàdà kẹríkẹrì ni ọ̀rọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé kan ní ìpínlẹ̀ Anambra, tí wọ́n gbé ma-n-ṣí-ìn-nì pélébé tí wọ́n fi ń gbowó, POS, sórí i tábìlì, wọ́n ní kí àwọn tí wọ́n wá á bá wọn kẹ́dùn èèyàn wọn tó kú lè ríbi fún wọn lówó. Eléyìí kìí ṣe ijokoo aláàáfà tàbí àwọn pásítọ̀ Kankan o. Ètò ìsìnkú ni wọ́n ń ṣe, fúnra àwọn mọ̀lẹ́bí ni wọ́n sì sọ ọ́ di mímọ̀ fáwọn èèyàn tó wà níkàlẹ̀ níbẹ̀.

Lásìkò tí ètò ìsìnkú bàbá wọn àgbà ọhún ń lọ lọ́wọ́ làwọn mọ̀lẹ́bí tí kéde pé àwọn ò fẹ́ owó àtijọ́, kí àwọn tí kò bá sì ní owó tuntun lọwọ́ mú káàdì ATM wọn láti fi sanwó tí wọ́n bá fẹ́ fún àwọn. Wọ́n ní kò sí àwíjàre fẹ́nikẹni láti ma ṣe fi owó sílẹ, kí ẹni tí kò bá lówó tuntun ṣe tiransifáà, àbí kí wọ́n fi POS sanwó. Bákan náà ni wọ́n tún kọ nọmba àkáùǹtì, nítorí àwọn ti ATM wọn kò bá sí pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n lè fowó ṣọwọ́ sí wọn láti orí fóònù wọn.

Pẹ̀lú èdè Íbò wọn yìí náà ni ọkùnrin kan nínú ẹbí ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún bí wọ́n ṣe yẹ́ wọn sí, lẹ́yìn náà ló rọ̀ wọ́n pé, “ látàrí bí orílẹ-èdè yìí ṣe rí báyìí, tí ìjọba sì ń kéde owo-ina ori ẹrọ ayelujara ti ko ni i ṣe pẹlu owo beba, a ti ṣeto ẹrọ POS ati a àkáùǹtì báńkì fún àwọn tí kò bá ní owó tuntun lọ́wọ́. Ẹ lọ sí àwọn orí tébùrù káàkiri, ẹ ó rí POS níbẹ̀, ẹni tí kò bá sì ní káàdì ATM lọwọ́ , àkáùǹtì nọmbà la kọ síbi bébà ńlá tá a so kọ yẹn. Mò lérò pé ọrọ̀ mi yé wa? Ẹ ṣeé o.

Èyí wáyé látàrí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe léde pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) Náírà ti di kọ̀ǹdẹ̀ , kò ní í jẹ́ níná mọ́, kí àwọn tí wọ́n bá ní in lọ́wọ́ sì kó o lọ sí báńkì àpapọ̀ ìpínlẹ̀ wọn, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tẹ̀lé àlà kalẹ̀ ètò tí báńkì àpapọ̀ fún wọn.

Nínú fídíò tí wọ́n gbé sórí ẹ̀rọ ayélujára yìí, bíi ọ̀nà mẹ́ta tí wọ́n gbé tebu kalẹ̀ sí ni wọ́n kó ma-n-síìnì ìyẹn ẹrọ POS méjì méjì sí, àwọn tí wọ́n jókòó síbẹ̀ láti dá àwọn èèyàn lóhùn sì jókòó tì í gbágbágbá bíi ẹni pé wọ́n wà nídìí ọjà a wọn ni. Owó péréte ló wà nínú tíréè nlá kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti máa fi gbowó, ó jọ pé inú àpò báńkì ọ̀hún ni púpọ̀ èèyàn ń sanwó sí, nígbà tí kò tí ì sí owó rẹpẹtẹ nílùú.

Níwájú tébùrù kọ̀ọ̀kan yìí náà ni wọ́n tún so bébà fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan si, orukọ, nọ́ńbà àti irú bánkì tí wọ́n máa fowó ránṣẹ sí, ni wọ́n kọ síbẹ̀, wọ́n sì gbé òkúta lé e nítorí kí atẹ́gùn má ba à gbé e lọ. Níwájú fọ́tò bàbá tó kú yìí bákan náà, wọ́n tún gbé àwo ìjẹun kékeré ayé àtijọ́ kan síbẹ̀, fún ànfààní àwọn tí wọ́n bá fẹ́ sọ owó síbẹ̀

Akérédolú sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Emfiele, lórí ìṣòro àìsí owó náírà tuntun

Gomina Ipinle Ondo, Rotimi Akeredolu

Akérédolú sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Emfiele, lórí ìṣòro àìsí owó náírà tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbàlagbà ní bí ọrọ ńlá kò bá tí ì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi àròyé.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú, SAN, ti ké sí Ààrẹ Muhammadu Buhari kó jáwọ nínú ìlànà owó náírà tuntun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú.

Akérédolú tún bu ẹnu àtẹ́ lu Gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ìyẹn Godwin Emefiele fún ìlànà owó náírà tuntun náà.

Gómìnà Akérédolú ló sọ ọrọ̀ náà nínú atẹjade kan tó fi léde lójú òpó Facebook rẹ .

Nínú atẹ̀jáde ọ̀hún ló ti bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Buhari bo ṣe fòfin de niná owó ₦500 ati ₦ 1000 àtijọ́.

Tí ẹ kò bá gbàgbé, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Buhari bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀, níbi tó ti sọ pé òun ti pàṣẹ fún CBN kó kó ₦200 àtijọ́ síta kí àwọn aráàlú ṣì máa ná a títí di ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹrin, ọdún yìí.

Àmọ́ o ní ₦500 àti ₦1000 àtijọ́ kìí ṣe owó tí àwọn aráàlú lè máa ná mọ́.

Akérédolú ní àṣẹ tí Buhari pa nínú ọrọ̀ rẹ̀ sí àwọn aráàlú lórí owó tuntun náà kò bójúmu.

Àtẹ̀jáde náà ni “Mo fẹ́ fi àkókò yìí bẹ Ààrẹ Muhammadu Buhari kó wu ìwà bàbá, kó sì fòpin sí ìlànà owó náírà tuntun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú yìí .”

“ Láì sí àníàní, Gómìnà CBN, Emefiele ti ṣe àṣìṣe nípa ìlànà owó náírà tuntun náà, ìlànà ọ̀hún sì ti kùnà .”

Nítorí oúnjẹ tó pé̩ Azeez dáná sun ìyàwó ẹ n’Íbògún

Nítorí oúnjẹ tó pé̩ Azeez dáná sun ìyàwó ẹ n’Íbògún

 

Lati ọwọọ Adefunkẹ Adebiyi

Ẹka to n ri si i ipaniyan ni ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ bayii pe ki wọn gbe ọkunrin yii, Azeez Hassan lọ. Eyi waye latari bi ọkunrin naa ṣe da epo bẹntiroolu lu iyawo ẹ, Ọlayinka, to si ṣana si i lara nitori ounjẹ to ni obinrin naa ko tete gbe foun, iyẹn nile wọn to wa n’Ibogun, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi fi sita lọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2023 yii ṣe ṣalaye, ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 niṣẹlẹ naa waye. Ṣugbọn bi Azeez ṣe ri i pe oun ti daran lo ti fẹsẹ fẹ ẹ ti ẹnikẹni ko si ri i mọ.

SP Oyeyẹmi ṣalaye pe Baba Ọlayinka tọkọ rẹ dana sun lo waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ibogun lọjọ naa, pe ọkọ ọmọ oun da epo bẹntiroolu si i lara, o si sọ ina si i nitori ọrọ ti ko to nnkan. Ati pe ileewosan kan lawọn sare gbe ọmọ naa lọ fun itọju, n’Ibadan.

Ifisun Baba iyawo lo jẹ kawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe ri Azeez mu,nigba to si di ọjọ kejilelogun oṣu kin-in-ni ọdun 2023 yii, ọwọ wọn ba a, eyi si jẹ oṣu kẹta geerege lẹyin to sa lọ.

Ninu alaye Azeez to dana sun iyawo ẹ, o sọ fawọn ọlọpaa pe orilẹ-ede Olominira Bẹnẹ loun sa lọ lẹyin iṣẹlẹ naa. O jewọ fun wọn pe loootọ loun dana sun iyawo to ti bimọ kan foun naa, ṣugbọn ẹjọ oun naa kọ, Eṣu lo jẹbi.

Azeez, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46), ṣalaye pe oun ni kiyawo oun dana ounjẹ foun lọjọ naa ni,ni ko ba dahun,lo ba n fi oun fọ aṣọ lọ.

O ni aṣọ to n fọ lai ba oun gbe ounjẹ wa naa lo bi oun ninu, nitori ebi to n pa oun lọjọ naa legba kan jọrin lọ. O ni nigba ti Ọlayinka ko si yee fọṣọ, ti ko foun lounjẹ ni ibinu ru bo oun loju. Loun ba gbe epo bẹntiroolu nilẹ, loun da a si i lara, oun si ṣana si i.

Bẹẹ ni iyawo Azeez bẹrẹ si i jona, ọkọ rẹ to dana sun un si nana papa bora foṣu mẹta gbako kọwọ ọlọpaa to o ba a.

Awọn ọlọpaa tilẹ beere lọwọ ẹ, pe ta a lo ni aṣọ tiyawo naa n fọ lọjọ yii, ọkunrin naa si dahun pe aṣọ oun ni.

Iwa to le gba ẹmi lẹnu eeyan ni baale ile naa hu, eyi ni ọga ọlọpaa ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ sẹka to n gbọ ẹjọ awọn aṣekupani.

Lati ibẹ ni iwadii yoo ti tẹsiwaju, ti wọn yoo si gbe Azeez to dana sunyawo ẹ lọ sile-ẹjọ.