Home Blog Page 83

N kò gba‘Ticket’ tí Mákindé fi lọ̀ mi  … Kola Balogun

N kò gba‘Ticket’ tí Mákindé fi lọ̀ mi  …–– Kola Balogun

Sẹnetọ tó ń ṣoju ẹkùn Gúúsù Ọyọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Kọla Balogun ti ṣàlàyé pé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ṣeyi Makinde gbìyànjú láti fa ojú òun mọ́ra padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣugbọn òun kọ jalẹ.

Èyí ló ń wáyé lẹyìn tí ó fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC).

Balogun ló sọ ọ̀rọ̀ náà lópin ọ̀sẹ̀ lórí ètò òṣèlú kan níléeṣẹ́ redio Fresh FM, ìlú Ìbàdàn.
Ó ní ṣáájú ètò ìdìbò abẹ́lé, nínú eléyìí tí olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹlẹ rí, Joseph Tegbe ti gba ànfàní láti díje gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nẹ́tọ̀ nínú ètò ìdìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lọ́dún 2023, ní Mákindé ti rán àwọn èèyàn ṣí òun láti padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láti díje du ipò Sẹ́nẹ́tọ̀, ṣùgbọ́n ó ti bọ́ sórí nítorí òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, APC.

Ànfàní ti Balogun kò ní láti díje fún sáà ìkejì ló mú kó darapọ̀ mọ́ APC kí ó le dé ibi ìlépa rẹ̀

Àmọ́ olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀ tẹ́lẹ̀rí, Sharafadeen Alli ni ẹgbẹ́ náà fún ní ànfàní láti díje, òun ló sì jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.

Balogun ní ìbá jẹ́ wí pé òun tẹ́wọ́gba ànfàní tí Mákindé fi ṣọwọ́ sí òun ṣáájú àsìkò tí wọ́n gbé e fún Tegbe ni, kò bá tí já sí nǹkan iwọsí nítorí gbogbo ayé ní yóó máa pariwo pé òun ti di alagbere òṣèlú tó ń ti ibì kan bọ́ sí ibì ìkejì.

Balogun fi kún ọrọ̀ rẹ̀ pé oun kò kabamọ pé òun darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, òun kò sì ní yí ìpinnu òun padà bí ànfàní bá tún yọjú láti díje du ipò.

ìròyìn òfegè ni pé Russia tún ti gba ìlú Bakhmut – Ààrẹ Zelensky

ìròyìn òfegè ni pé Russia tún ti gba ìlú Bakhmut – Ààrẹ Zelensky

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ogun kò rí bí iyán,ogun kò rí bí ẹ̀kọ,ogun kò dà bíìgbà téèyàn n najú lórì obìnrin rẹ̀.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ukraine, Volodymyr Zelensky tí ni kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé orílẹ̀ èdè Russia tí gba ìlú Bakhmut.

Èyí kò sẹ́yìn ìròyìn tó gbòde kan pé àwọn ikọ̀ Russia.

Ààrẹ Zelensky ni àwọn ikọ̀ ọmọ ogún wọn wá ní ìlú náà láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan.

Ààrẹ náà ni òun kò ní leè sọ jù báyìí lọ, àmọ́ òun ti òun mọ̀ ni pé ìlú náà kò sì lọ́wọ́ Russia.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ́ ni orílẹ̀èdè Russia àti Ukraine ń ṣe láti gba ìlú Bakhmut nínú ogún tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjèèjì.

Ó ti lè ní ọdún kan tí ogun tí n wáyé láàárín orílẹ̀ èdè Ukraine àti Russia.

Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó ń yọ́lẹ̀ dà, ohun abẹ́nú á má a yọ́ wọn ṣe.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Dare Ogundare ti fojú àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún hàn fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Mẹ́rin nínú àwọn afurasí yìí ni wọ́n ní àwọn nawọ́ gán ní agbègbè Òkè Ako ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ogundare tó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti kò ní fi ààyè gba ìwà ọ̀daràn sọ pé, ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí ọ̀hún lọ sí ilé ẹjọ́.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá Ekiti pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi nawọ́ gán àwọn afurasí meji tí orúkọ won ń jẹ́ Abu Hassan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Danger àti Abubakar Sodiq.

Ó ní àwọn afurasí méjéèjì yìí ló jẹ́ ògbóǹtarigì ajínigbé tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Iyemero/Oke-Ako/Irele/Ipao-Ekiti.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ni àwọn tó ti kó sí páḿpẹ́ àwọn afurasí yìí ló dá wọn mọ̀ tí wọ́n sì nawọ́ sí wọn pé àwọn ló jí àwọn gbé.

Ó ní ìbọn tiwa-n-tiwa kan, àti ọta ni àwọn bá lọ́wọ́ wọn lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n. Bákan náà ló ní ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti ṣe àwárí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn mìíràn tó ti sá lọ.

Ó fi kun pé ọwọ́ òfin tún tẹ àwọn afurasí mìíràn, Umar Hassan àti Yusuf Lawal fẹ́sùn wí pé wọ́n yawọ agbègbè Ayenco ní Eda-Ile Ekiti tí wọ́n sì jí obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mary Olajumoke gbé.

Ó ní lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà gba owó ìtúsílẹ̀ ni wọ́n tó tú ọmọbìnrin náà sílẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé àdá méjì àti ₦82,200 tó jẹ́ owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ná kù ni àwọn bá ní ọwọ́ wọn nígbà tí ọwọ́ òfin bà wọ́n. Ó fi kun pé àwọn afurasí yòókù ni ọwọ́ bà fún ìwà ṣíṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn àti olè jíjà.

Iléẹjọ́ da èsì ìdìbò tó gbé ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party wọlé ní Abia nù

Iléẹjọ́ da èsì ìdìbò tó gbé ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party wọlé ní Abia nù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kano, Mohammed Yunusa ti gbégilé èsì ìdìbò tó gbé Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ dìbò yàn ní Abia, Dr Alex Otti wọlé.

Bákan náà ni adájọ́ gbégilé èsì ìdìbò ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Kano àti Abia.

Adájọ́ ní bí wọ́n se dé orí ìwé ìdìbò kò tẹ̀lé òfin ètò ìdìbò ti ọdún 2022.

Ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n fi ìdájọ́ náà ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn.

Nínú ẹjọ́ tí Arákùnrin Ibrahim Haruna Inrahim pè tako ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ati INEC ló ti ní ẹgbẹ́ òṣèlú Labour party kò se ìforúkọsílẹ ní ọdọ INEC láàrin ọgbọ̀n-ọ́n-jọ tí òfin sọ kí wọ́n tó se ìdìbò abẹ́lé.

Ó ní nítorí wọn kò tẹ̀lé òfin náà, ìdìbò tó gbé wọn wọlé kò ní ẹṣẹ̀ nílẹ̀.

Ó ní Labour party kò leè sọ pé òun ní olùdíje nínú ìdìbò náà, nítorí náà wọn kò leè jáwé olúborí.

Adájọ́ ní èyí fihàn pé àwọn ìbò tí kò kẹ́sẹjárí ló gbé Alex Otti wọlé gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn ní ìlú Abia.

Gómìnà Adeleke tú ìgbìmọ aláṣẹ Fásitì Ọ̀ṣun ká

Gómìnà Adeleke tú ìgbìmọ aláṣẹ Fásitì Ọ̀ṣun ká

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sẹ́nétọ̀ Nurudeen Ademọla Adeleke, ti kéde títú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso Fásitì Ọ̀ṣun ká.

Lásìkò Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ ọhún ni wọ́n yan àwọn ìgbìmọ̀ tí Agbẹjọ́rò Àgbà, Yusuf Alli, jẹ́ alága fún ọhún lọ́dún 2006.

Lẹ́yìn tí wọ́n parí sáà àkọ́kọ́ ọlọ́dún márùn-ún ni Gómìnà àná, Alhaji Gboyega Oyetọla, tún tún wọn yàn láti lo sáà mìíràn.

Ṣùgbọ́n nínú àtẹ̀jáde kan ti olórí àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, S. A. Aina, fi síta ló ti sọ pé Gómìnà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ náà fún ifara-ẹni-jìn wọn fún ìdàgbàsókè UNIOSUN.

Ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run túbọ̀ mú wọn ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ìdáwọ́lé wọn.

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu ìyànsípò, Oluwatoyin Sakirat Madein gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìyànsípò náà ló jẹ jáde nínú lẹ́tà kan tí olórí òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, Dókítà Folasade Yemi-Esan fi léde.

Ó ní Ààrẹ Buahri ti buwọ́lu ìyànsípò náà.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta ọdún 1965 ni wọ́n bí Oluwatoyin Sakirat ní Iperu Remo, ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ṣaájú ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà, Sakirat ni adarí ẹ̀ka ìsúná ní ọ́fíìsì olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè yìí.

Oluwatoyin Shakirat ló ń gba ipò yìí lọ́wọ́ Ahmed Idris tó jẹ́ olùṣirò owó tẹ́lẹ̀ tí Ààrẹ Buhari ní kó lọ rọ́kún nílé fẹ́sùn wí pé ó kojú ẹ̀sùn pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù 109 náírà.

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kò sí, kóówá ń relé lẹyìn ìnájà ayé dandan ni. Ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ìròyìn gbòde pé olóyè Subomi Balogun tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) jáde láyé.

Ìròyìn sọ pé ní ìlú London, United Kingdom ni bàbá náà dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́. Ó ṣeéṣe kí nífẹ̀ẹ́ àti mọ̀ irúfẹ́ èèkàn iràwọ̀ àwùjọ tí à n perí, gbàyí wò.
Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 1943 ni wọ́n bí olóògbé Subomi Balogun sáyé tó sì pé ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún kó tó dágbẹre fáyé pó di kése.
Ọmọ ìdílé Ọba Tunwase ti Ijebu-Ode ni Subomi Balogun.
Òun ni Otunba Tunwase gbogbo Ijebu, tó sì tún jẹ́ Olori gbogbo ọmọọba Ijebu àti Asiwaju àwọn onígbàgbọ́ ní Ijebu.
Ìdílẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n bi sí kó tó yípadà sí onígbàgbọ́ nígbà tó wà ní ilé ẹkọ girama.
Ilé ẹ̀kọ́ Igbobi College ló ti kẹ́kọ̀ọ́ girama, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí London School of Economics níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kó tó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ kàwé, tó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ nígbà tó padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Ní ọdún 1979 ni ó gba ìwé àṣẹ láti dá ilé ìfowópamọ́ First City Merchant Bank sílẹ̀ tí báǹkì náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1983.
Subomi Balogun dá ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọdé kalẹ̀ ní Ijebu Ode èyí tó fún ile ìwòsàn ńlá UCH tí Ibadan.
Aṣọ funfun ni ó sábà máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà. Olóògbé Subomi Balogun fi ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọọmọ sáyé lọ .
Kín la á sọ nípa tèmi tì ẹ?

Labour Party,Alágá ẹ̀gbẹ́ di mèjì tó fẹ́̀ rojọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Labour Party,Alágá igun ẹ̀gbẹ́ di mèjì tó fẹ́̀ rojọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ èyí tó ń lọ ní Abuja ti sún ìgbẹ́jọ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi èyí tó pè tako Ààrẹ tí ìlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu síwájú.

Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú LP, Julius Abure báwọn péjú silé ẹjọ́ tí Lamidi Apapa tí òun náà jẹ́ alága ikọ̀ kan ní ẹgbẹ́ náà sì wà ní ìkàlẹ̀.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìgbìmọ̀ ọ̀hún ti ṣáájú sún sí ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Karùn-ún nígbà tí Peter Obi tọrọ ààyè láti sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú.
Nígbà tí Adájọ́ tún dé ibi ìjókòó lọ́jọ́rú láti tẹ̀síwájú ètò náà ló tún kọ̀ láti ṣe ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Labour Party yàtọ̀ sí Obi nìkan.

Lẹ́yìn náà ni ohun tó fẹ́ jọ bí eré orí ìtàgé tún wáyé ní ilé ẹjọ́ nígbà tí wọn ò mọ ẹni tí yóò ṣojú ẹgbẹ́ nílé ẹjọ́ nínú àwọn alága méjèèjì tó wà níkàlẹ̀.

Ìgbìmọ̀ náà kọ̀ láti gbà kí Lamidi Apapa àti olórí àwọn obìnrin ẹgbẹ́, Dudu Manugu dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ nígbà tí wọ́n ní kí wọ́n yọjú.

Adájọ́ Haruna Tsamani ní tí ènìyàn méjì bá ń dúró fún ẹgbẹ́ kan ṣoṣo, àwọn kò ní gbà wọ́n wọlé.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀, agbejọ́rò Labour Party, Livy Uzoukwu sọ fún ilé ẹjọ́ pé àsìkò tí wọ́n fún àwọn láti fi kó àwọn ẹ̀rí wá sílé ẹjọ́ kò tó rárá nítorí àjọ elétò ìdìbò náà kò ì tíì fún àwọn ní gbogbo nǹkan tí àwọn ń bèèrè fún.

Uzoukwu ní ìdá ọgbọ̀n nínú gbogbo àwọn ìwé tí àwọn ń bèèrè fún ni INEC ṣẹ̀ṣẹ̀ pèsè fún àwọn.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn ẹ̀rí tí àwọn ń bèèrè láti ìpínlẹ̀ Rivers ni wọn kò ì tíì pèsè fún àwọn bí ọ̀gá àgbà àjọ INEC ìpínlẹ̀ ṣe ní àwọn kò ní fọ́ọ̀mù EC8A, tó sì kọ̀ láti kọ ìwé láti fi èyí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe sọ fun.

Nígbà tó ń fèsì, agbẹjọ́rò INEC, Abubakar Mahmoud ní gbogbo nǹkan tí agbẹjọ́rò Labour Party ń sọ ya òun lẹ́nu gidi nítorí àwọn ni wọ́n kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé tí àwọn pé.

Mahmoud ní nígbà tí àwọn tún fi ìpàdé sí ọjọ́ mìíràn, wọ́n tún bínú jáde kúrò níbẹ̀.

Bákan náà ló ní gbogbo ohun èlò ìbò ti ìpínlẹ̀ Sokoto àti Rivers ló wà nílẹ̀ àmọ́ Labour Party kọ̀ láti san owó mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà fún ìpínlẹ̀ Sokoto àti pé fọ́ọ̀mù EC8A tí Rivers ni àwọn kò ì tíì fún wọn.

Ó fi kun pé àwọn ìwé kan náà wà tí àwọn fún ẹgbẹ́ wọn ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti gbà, tí wọ́n ní àfi ìgbà tó bá pé.

Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo nǹkan tó yẹ ni àwọn ń ṣe láti ri dájú pé àwọn ran ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀.

Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san àbọ̀ saájú ikú rẹ – Golugo

Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san àbọ̀ saájú ikú rẹ – Golugo

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ohun tó pamọ́ ojú adẹ́dàá tó o. Ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé, yóó dìín .” Irọ́ ni ìròyìn kan tó ń jà kiri pé àwọn aláwo ti gé orí àti etí Murphy Afolabi lẹ́yìn tó jáde láyé.”

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Adekola Tijani tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Golugo ti sọ̀rọ̀ nípa bí ìrìnàjò gbajúgbajà òṣèré tíátà tó di olóògbé, Murphy Afolabi se wá sópin lọ́jọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀ yìí nílùú Èkó.

Golugo, lasiko to n ba sọ̀rọ̀ níbi ètò ìsìnkú olóògbé ọ̀hún tó wáyé ni Adamọ nílùú Ikorodu ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nítorí òun pẹ̀lú Murphy sọ̀rọ̀ ọgbọ̀n ìsẹ́jú sẹ́yìn kí òun tó gbọ́ ìròyìn pé ó subú.

“Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni ago mẹ́sàn àbọ̀, ó ṣubú ní ago mẹ́wàá ni wọ́n pè mí pe o ṣubu”.

“Mo ni ki lo sẹlẹ, wọn ni ki n ṣaaa maa bọ, bi mo ṣe de ibẹ, mo ni ki a gbe e sinu ọkọ ka maa lọ ile iwosan ṣugbọn Murphy ti dakẹ ki a to de ile wosan

“Ko si nnkan ti a le ba Ọlọrun fa nitori a ko gbọn ko Ọlọrun, ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a maa pada si. Gbogbo nnkan Murphy lo ti di ohun igbagbe.

“Ọmọ kekere ni Murphy, a jọ bẹrẹ ni, emi ni mo baa ya sinima rẹ akọkọ, nnkan da emi ati Murphy papọ gan”.
Pẹlu omije loju ni Osere tiata, Nofisat Olayiwola ti ọpọ mọ si Ọmọ Ẹja fiṣalaye ibaṣepọ rẹ pẹlu Oloogbe Murphy Afolabi nibi eto isinku rẹ.

Nofisat ni igba ti oun fẹ ṣe sinima rẹ akọkọ, oun ko ni owo kankan lọwọ ṣugbọn oloogbe ni ki oun lọ mu iyekiye ti oun ba ni wa lati fi se sinima to di ilumọọka naa.

“Murphy ni kí ń lọ mú iyekiye wa, ó dẹ ya sinimá ọhún, apá kìíní àti ìkejì nílùú Osogbo.

“Mi o le gbagbe Murphy laye, mi o ni ile niluu Eko, Murphy lo tẹwọgba gba mi sile rẹ fun ọdun marun un”.

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣeré tíátà ni wọ́n ya wọ iléègbé olóògbé nílùú Ikorodu láti ṣe ádùrá ìkẹyìn fún un

Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báa kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti bá àwọn ẹbí, ará àti akẹgbẹ́ Murphy Afolabi tó di olóògbé lọ́jọ́ Àìkú kẹ́dùn lórí àdánù ńlá yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbénusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ìlú Osogbo júwe Murphy Afolabi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣojú ìpínlẹ̀ Osun dáradára nígbà ayé rẹ̀.

Adeleke ní Afolabi lo ìgbé ayé rẹ̀ láti farajìn sí iṣẹ́ eré tíátà tó gbé dání, tó sì fi hu ìwà ọmọlúàbí títí tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Afolabi ṣe àbẹ̀wò sí òun kó tọ di wí pé ọlọ́jọ́ dé, ó ní ọ̀rọ̀ àwọn ìpèníjà tó ń bá ẹ̀ka ètò eré ìdárayá ni àwọn jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“A fẹnukò lórí àwọn ètò tó le sọ ìpínlẹ̀ Osun di oríko ilé àṣà àti ibi ìnàjú ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà.”

“Afolabi jẹ́ òṣèré Yorùbá tó nífẹ̀ẹ́ láti máa gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá pẹ̀lú ẹ̀bùn eré tí Ọlọ́run fún-un.”

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú Murphy Afolabi jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́, àwọn gbà pé ó gbé ìgbé ayé tó ṣe é fi yangàn, tó sì máa ń fi ìpínlẹ̀ Osun síwájú nínú gbogbo nǹkan tó máa ń ṣe nígbà ayé rẹ̀.

“Mo bá àwọn ẹbí, akẹgbẹ́, ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ Murphy Afolabi káàkiri àgbàyé kẹ́dùn lórí ìpapòdà rẹ̀.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.

Ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ni Afolabi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta kí ọlọ́jọ́ tó dé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karun-ún ọdún 2023.

Murphy Afolabi ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bí i Ifá Olókun, Omowunmi, Wasila Coded àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.