Home Blog Page 76

Tinubu ni e̩ni tí ayé ń fé̩ ní tòóótó̩ – Toyin Abraham

Tinubu ni e̩ni tí ayé ń fé̩ ní tòóótó̩ – Toyin Abraham

Mary Fágbohùn

Osere tiata Toyin Abraham ti so pe Aare ti a dibo yan, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, je eni ti awon eniyan n fe nitooto.

Abraham tun so pe Gomina ipinle Eko teleri naa lo jawe olubori ninu eto idibo yan aare ti won se ni osu keji 2023.

O so eyi nigba to n da afenifere kan to n fe lati mo ooto to wa nidi jijawe olubori Tinubu ati nnkan ti awon eniyan n fe.

Afenifere naa ti a le sapejuwe bii Celebrity Painter beere wi pe: “Aunti Toyin, se Tinubu ni eni ti awon eniyan n fe nitooto, se oun lo jawe olubori ninu eto idibo naa?”

Ninu ifesi re,iya omo meji naa salaye pe pupo awon eniyan lo dibo yan n gege bi Aare sugbon iberu ipanilaya ati epe lo je ki won dake nipa eni ti won n fe.

O toka sii bi awon kan se bu oun ti won si sepe lori pe oun so nipa Tinubu gege bi oludije ti oun yan laayo.

Amo sa, agberejade naa wi pe gbogbo re je nnkan atijo bi o se ro gbogbo eniyan lati dojuko bi orile-ede yii yoo se dagba si.

“Bee ni onitemi oun ni, opo eniyan ni eru ipanilaya ati epe n ba nitori naa won o so nnkankan ni ori ayelujara sugbon won dibo fun un, mo mo opolopo be e”, ni ohun to so.

“E wo gbogbo epe ti won se fun mu sugbon gbogbo re ti koja, o kere ju Aare wa ni nitori naa e je ka ni adojuko. E je ka dojuko bi a o se ko orile-ede yii ti a o si so di nla. Mo nireti pe iyen dahun ibeere re, ololufe mi.”

Mi ò ní ìrírí ìrè̩wè̩sì o̩kàn rí – Korede Bello

Mi ò ní ìrírí ìrè̩wè̩sì o̩kàn rí – Korede Bello

Mary Fágbohùn

Olorin Olukorede ‘Korede‘ Bello ti so pe oun o ni iriri irewesi okan ri.

Alarinrin eni odun meta-din-ni-ogbon naa so pe oun kan mo nipa itumo nnkan ti a n pe ni irewesi okan ni, bo ti le je pe o ni ilowosi ninu sise alagbawi fun ilera nipa ti opolo.

Eni ti a mo fun orin re ti gbogbo eniyan gba tire “Godwin”, to je apopo orin ihinrere ati orin takasufe eyi to di ti gbogbo eniyan ni orile-ede bi o se leke ni ate awon orin kaakiri Naijiria, Bello daba pe nigba miran oun ko ma n oriruuru imolara ni.

O wi pe oun n gbiyanju ni gbogbo ona lati daabobo ayika oun ki awon ipa kan ma ba a pa lara.

Nigba to n soro ninu iforowero kan pelu The Cable, o wi pe: “Mo je alagbawi fun ilera nipa ti opolo sugbon mi o mo nnkan ti irewesi okan je.

“Nigba ti mo ba so pe mi o mo nnkan ti irewesi okan je ko tumo si pe mi o mo itumo re bi omowe o. Mi o mo nnkan ti won n pe ni mo ni irewesi okan.

“Mo mo pe awon akoko kan wa ti mo ma n ni oniruuru imolara, Mo kan ma n gbiyanju lati daabobo ayika mi bi mo ba se le e da aabo bo.

“Awon igba kan ma n wa ti nnkan ko ni lo bi a ti lero. Mo n sakoso ilera nipa ti opolo mi nitori ko ma ba a de ibe nitori pe yoo je nnkan to buru bi mo ba le e debe.”

 

 

Síse isé̩ pè̩lú Burna Boy jé̩ ìrírí tó dára – Kel-P

Síse isé̩ pè̩lú Burna Boy jé̩ ìrírí tó dára – Kel-P

Mary Fágbohùn

Agborinjade, Udoma Amba, ti a mo si Kel-P, ti soro sita lori iriri to ni nigba to n sise pelu ilumooka olorin, Burna Boy.

Kel-P, eni to sise pelu Burna Boy lori awo orin re ‘African Giant’, so fun Sunday Scoop pe, “Sise ise pelu Burna Boy je iriri to dara. Maa so pe o ko mi lori bi mo se le e ba awon afenifere soro ati bi maa se dari iro ohun. O tun fun mi ni iriri si nipa tito iro ohun.”

Kel-P, eni to ti sise pelu awon ilumooka olorin bii, Wizkid, Rema, Phyno, Niniola ati Seyi Shay, soro lori ohun to je iwuri leyin akole to fun awo orin re, ‘Bully Season’.
O wi pe, “Mo mo itumo ‘ipanilaya’ to ni itumo odi, sugbon fun mi, o je idakeji. Iwuri ati pataki ‘Akoko Ipanilaya (Bully Season)’ je itanna fun irinajo mi to gbe mi de ibi; ise mi, jijawe olubori mi, ipadanu mi, ibasepo, iwa nidi ise, ati oye pe emi ni olufigagbaga pelu ara mi. Idi niyi ti mo fi se ‘ipanilaya’ fun ara mi fun idagbasoke ni gbogbo ona aye mi. Eyi gan an lo wu mi lori lati pe akole naa ni ‘Bully Season’.

Àwo̩n kan ń lo̩ sí ilé ìjó̩sìn láti ni àwo̩n kan lára, ni Mokeme so̩

Àwo̩n kan ń lo̩ sí ilé ìjó̩sìn láti ni àwo̩n kan lára, ni Mokeme so̩

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Chidi Mokeme, ti so pe bo tile je pe oniruuru esin lo wa ni Naijiria, sibe awon eniyan ko loro si. Osere fiimu ‘Shanty Town’ so eyi di mimo ni oju opo Instagram nigba to n ba okan lara awon afenifere re soro laarin ose.

“Ni Naijiria, ibudo adura wa ni gbogbo adugbo. Gbogbo abule lo ni ile ijosin, Mosalasi tabi ile oloogun ibile. A ni opolopo ibudo esin kaakiri sugbon ko si iloro. Ko sowo. Awon eniyan ko lowo ni owo. A ni opolopo okan to ti sonu ti won n lo kaakiri ti won n gbiyanju lati tan Olorun. E o le tan Olorun ,” ni ohun to so.

O wi pe opolopo eniyan n lo si ile ijosin kii se nitori pe won fe josin si Olorun, sugbon ki won le e wa nnkan ti won a fi ni elomiran lara.

“Gbogbo awon eniyan to n lo si gbogbo awon ile ijosin yi lojoojumo, Olorun n gbo. O kan je pe O (Olorun) mo wa ju bi a se mo ara wa ni. Gbogbo awon eniyan yi kan n lo si ile ijosin lati wa nnkan ti won le e lo lati fi ni arakunrin won lara ni,” ni Mokeme fikun n.

 

Àwàdà mi ní ìwòsàn nínú – Guru

Àwàdà mi ní ìwòsàn nínú – Guru

Mary Fágbohùn

Aderinposonu ati olorin, Koffi Nuel, ti a mo si Koffi Tha Guru, safihan nnkan ti awada re n mu ba eniyan, o fikun un pe erin arintakiti le e mu ki awon eniyan bori isoro to niise pelu opolo.

O so fun Sunday Scoop pe, “Awon dokita lagbaye n gbani nimoran nipa iwulo isinmi ati jije gbadun erin arin takiti ti aye ba fun ni. Mo ti ba opolopo eniyan pade ti won si fi idi okodoro re mule pe leyin ti won ba wo mi lori idubule aisan ara won ma n mokun sii. Diderinposonu ko ipa pataki gege bi oogun fun irewesi okan. Ti kii ba se ti fonran ati ona iderinpaniyan awon omo Naijiria ti gbogbo eniyan n gbadun kaakiri ori ayelujara, a o ti ni opolopo oran aarun opolo ni gbogbo ibi.

“Ilera nipa ti opolo n di bibaje si ni Naijiria nitori ipa ti ona lati gbe igbe aye to rorun n ko ni laarin awon eniyan. Ounje to dara ati ayika to rewa lati sinmi nikan ni ona abayo, ati pe diderinposonu n di alafo naa.”

Nigba to n soro lori idi to fi pe ilumooka olorin, Obesere, si inu atunko orin re ‘Aroma’, Koffi wi pe, “Aroma je orin mi akoko ti gbogbo eniyan gbayi re ati pe lati bu iyi kun irinajo naa, ati lati mo riri ati sajoyo ogun odun aseyori orin naa, mo ro pe o ye ki n fun ni emi tuntun, paapaa julo fun awon olutetisile ati afenifere Afrobeats, ti won n fi gbogbo igba beere fun nnkan tuntun. Mo tun ro pe ki n da ara kan sinu re ti enikan ko da ri, nibi ti Fuji ati orin takasufe ti n lo ni fegbekegbe.”

Lori bo se n wa ni ibadogba pelu ayidapa to de ba ile-ise alarinrin, o wi pe, “Ayipada naa wa lorisirisi ati pe o si lagbara. Ayelujara paapaa tun ko ipa to le lori re. Mo je okunrin to maa n fi gbogbo igba gbaradi fun ojo iwaju ati iru nnkan wonyi. Mo je eni to maa n se fonran ti mo si maa n fi won si ipamo daadaa fun ojo iwaju ni oju awe yi. Mo n wa ni ibadogba pelu akoko ni irorun.”

 

Wó̩n ti san e̩gbè̩rún kan náírà fún mi rí láti sere, ò jé̩ ohun ìyàlé̩nu– Elenu

Wó̩n ti san e̩gbè̩rún kan náírà fún mi rí láti sere, ò jé̩ ohun ìyàlé̩nu– Elenu

Mary Fágbohùn

Aderinposonu, Babatunde Akinlami, ti a mo si Elenu, ti soro lori ohun to je idoju fun un ju lenu ise re bi igba ti won san egberun kan naira fun un ni ibi ayeye kan. O fi kun un pe bi oun se ko lo si United States of America ran oun lowo lati le e so ona imowo wole fun oun di pupo.
Ninu iforo-wani-lenu-wo pelu Sunday Scoop, Elenu wi pe, “Ni 2005, mo lo ibi ayeye kan won si san egberun kan naira fun mi. O ye ki won san ẹ̀ẹ́dẹ́gbè̩jọ naira, sugbon won san egberun kan naira. O je ohun idojutini.
“Nigba ti mo si wa ni Naijiria, mo le e so pe ise alarinrin lo n mu owo wole ju fun mi ti mo si fi n gbera, sugbon leyin ti mo ko lo si United States, oye ninu opolopo ona to n mu owo wole wa ye mi. Ni US, mo je Alase agba/oga agba agberejade fun ile-ise igberejade mi. Mo se opolopo ayeye; mo n se ayeye temi ni odoodun; mo ni oko ti mo fi n sise iyalo bii marun-din-ni-ogun, laarin awon nnkan miran.”

O so pe opolopo eniyan gbagbo pe awon aderinposonu aladuro se maa n pa owo wole gidi bii ti awon akegbe won ni ile-ise alarinrin, bi aderinposonu ati eni to n se ayeye, o n pa owo wole gidi nitori pe o fi igbiyanju gidi mo ise re.

“Gege bi aderinposonu aladurose ati eni to n se agbakale ayeye, mo mo pe mo n pa owo wole gidi to si je pe kii se iyen nikan. Mo gbagbo pe igbiyanju onikaluku tabi eya ti won fi si ise won ni yoo pinnu bi won yoo se mu owo wole sii”.

 

Amadu Fintiri ni àjo̩ INEC padà kéde gé̩gé̩ bí i gómìnà Adamawa kìí se Aishatu mó̩

 

Yínká Àlàbí

Ijo̩ba Mohammadu Buhari fitan bale̩, nigba ti ajo eleto idibo ile̩ wa (INEC) kede Arabinrin Aishatu Binani ge̩ge̩ bi e̩ni to jawe olubori ninu eto idibo to waye ni ipinle̩ Adamawa.
Arabinrin yii jawe olubori ninu eto idibo ti wo̩n tun di nitori rogbodiyan to waye ninu osu keji ti o ye ki idibo naa pari.
E̩gbe̩ oselu APC ni arabinrin naa ti dije ni eyi ti o je̩ ki o tete maa fe̩mi imore han si Aare̩ Buhari, Aare̩ ase̩se̩ dibo yan, Asiwaju Tinubu, olori e̩gbe̩, olori ile igbimo asofin kekere ati nla, o̩ko̩ re̩ ati gbogbo awo̩n to dibo yan ge̩ge̩ bi gomina ako̩ko̩ ni Naijiria.
Arabinrin naa ni oun maa gbiyanju lati ma se je̩ ki wo̩n kabamo̩ pe wo̩n dibo yan oun.
Alaye yii waye le̩yin ti ajo̩ INEC kede re̩ tan. Ikini ku oriire si ti n waye nile ati le̩yin odi.

N kò lè jẹ́ ọmọ Nàíjíríà mọ́ bí Tinubu ti di Ààrẹ – Igbákejì gómìnà àná l‘Eko

N kò lè jẹ́ ọmọ Nàíjíríà mọ́ bí Tinubu ti di Ààrẹ – Igbákejì gómìnà àná l‘Eko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tí kò bá gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ni yóó pè é lẹ́yẹ oní wótòwótò.
Igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Eko, Alhaja Sinatu Ojikutu ní òun ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yí jíjẹ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà.

Ojikutu nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú ní torí pé Tinubu ló jáwé olúborí ìdìbò Ààrẹ ni òun ṣe fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ ọ̀hún.

Ó ní gbogbo ètò ti ń lọ láti parí ìgbésẹ̀ náà kó tó di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún tí wọ́n máa búra wọlé fún Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ó ṣàlàyé pé kí èsì ìbò Ààrẹ tó jáde ni òun ti kéde pé tí Tinubu bá wọlé Ààrẹ, òun máa fi Nàìjíríà sílẹ̀.

“Àwọn agbẹjọ́rò ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yí jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà, mà á rí orílẹ̀ èdè kan tí inú mi yóò ti máa dùn gbé.”

“Mà á lọ máa gbé orílẹ̀ èdè tí ìwà ìbàjẹ́ wọn kò ti pọ̀ tó ti Nàìjíríà.”

Ojikutu tún tẹnu bọ̀rọ̀ pé òun ké gbàjarè síta nígbà tí òun gbọ́ pé Tinubu ń wádìí bóyá òun ṣì wà láyé.

Ó ní tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí òun, ọwọ́ Tinubu ni kí àwọn ènìyàn ti bèèrè.

Ó fi kun pé gbogbo ìgbìyànjú láti parí aáwọ̀ tó wà láàárín òun àti Tinubu ló já sí pàbó.

Igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ rí náà ní òun wà lára àwọn tó ní ìgbàgbọ́ pé ó yẹ kí Ààrẹ Nàìjíríà wá láti gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà lásìkò yìí.

Ó ní ìdí nìyí tí òun ṣe kún Peter Obi lọ́wọ́
lásìkò ìpolongo ìbò.

Ojikutu tẹ̀síwájú pé ọ̀rọ̀ ti débi pé òun kì í fẹ́ sọ pé òun dipò òṣèlú mú rárá nígbà kan rí nítorí gbogbo ìpìlẹ̀ tí àwọn fi lélẹ̀ ló ti bàjẹ́ tán.

Ó fi kun-un pé gbogbo àwọn tó ti sin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tọkàntọkàn ni inú wọn kò dùn sí ipò tí orílẹ̀ èdè yìí wà báyìí.

Àgbàrá òjò pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀pọ̀ ènìyàn di àwátì l’Ógùn

Àgbàrá òjò pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀pọ̀ ènìyàn di àwátì l’Ógùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní lọ́jọ́ tí ẹ̀dá yóó
bá sọnù, gá gá lara á yáwọn.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàm̀bá omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ni agbègbè kan ní ìlú Sagamu, ìpínlẹ̀ Ogun.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún di àwátì lásìkò tí ẹ̀kúnwọ́ omi ṣọṣẹ́ ní àwọn agbègbè bíi Ajaka, Express Junction, Ogunyanwo, Ọlayinka àti Isale-Ojumele ní ìlú Sagamu lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ọmọ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ girama Agbele gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní orí ọ̀kadà tí ọmọ ọ̀hún wà ni ẹ̀kúnwọ́ omi ti wọ lọ.

Bákan náà ni ìròyìn tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ dúkìá ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ló tún sọnù sínú ìjàm̀bá náà ní agbègbè Makun tí ọ̀pọ̀ ará ìlú sì farapa.

Àwọn ará àdúgbò náà kọminú pé bí nǹkan ìní àwọn ṣe máa ń bàjẹ́ ní gbogbo àsìkò òjò nìyí nítorí kò sí kòtò ìdaminù tó já gaara ní agbègbè náà.

Lára àwọn ará àdúgbò náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé lọ́dún to kọjá tí àwọn sì ké gbàjarè lọ sọ́dọ̀ ìjọba.

Wọ́n ní àìsí ibi tí omi máa gbà kọjá ló ń fà á tí omi fi ń ya wọ ilé àwọn tí àwọn sì rò pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún to kọjá máa mú kí ìjọba tètè dìde sọ́rọ̀ àwọn.

Wọ́n ní ó ṣeni láàánú pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lórí ìjàm̀bá yìí kan náà.

Kọmíṣọ́nà fún ètò àyíká ìpínlẹ̀ Ogun, Ọla Ọrẹsanya nígbà tó ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìwé ìlànà bí àwọn ṣe ń kọ́ ilé ti pọn dandan báyìí.

Ọrẹsanya ké sí ìjọba àpapọ̀ láti ran ìpínlẹ̀ Ogun lọ́wọ́ lórí àjálù ọ̀hún.

Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun náà yóò gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ nípa kíkọ́ kòtò ìdaminù sí agbègbè náà láìpẹ́.

A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó lójijì – LASEMA

A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó lójijì – LASEMA

Fẹ́mi Akínṣọlá

À fi kí Ọlọ́run ṣá à má a pawá mọ́ nínú ewu gbogbo.
Kò dín ní ènìyàn méje tí wọ́n móríbọ́ nínú ilé tó dà wó lulẹ̀ lọ́jọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.

Ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣàdédé dà wó lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.

Ìròyìn ní pé àwọn òṣìṣẹ́ kan mórí bọ́ láì farapa, tí àwọn mìíràn sì farapa kékeré, tí àwọn mìíràn sì tún há sábẹ́ ilé náà.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA ní àwọn ṣì ń wá ènìyàn kan tó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ó há sábẹ́ ilé náà.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní orí àjà kẹfà ilé náà ní àwọn ṣiṣẹ́ dé láti gbé àjà keje le lórí kí ilé náà tó dà wó lulẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde ní ìwádìí fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó ń po sìmẹ́ǹtì ló ṣokùnfà bí ilé náà ṣe dàwó.

Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé náà, Anthony Onah ka àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó ku òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń wá tó sì ṣeéṣe kó ṣì wà lábẹ́ ilé ọ̀hún.

Ó ní iṣẹ́ ń lọ láti ṣàwárí ọkùnrin náà, àti pé gbogbo àwọn ohun èlò tí àwọn nílò láti fi ṣiṣẹ́ ló ti wà níbẹ̀.

Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní ènìyàn méje ni àwọn ti yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa.

Adeseye ní ènìyàn kan ló ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí iṣẹ́ kò sì dúró láti yọ ẹni ọ̀hún.