Home Blog Page 63

“Mùsùlùmí ẹ wojú ọ̀run fún oṣù tuntun Shawwal láti parí ààwẹ̀” – Sultan Sokoto

“Mùsùlùmí ẹ wojú ọ̀run fún oṣù tuntun Shawwal láti parí ààwẹ̀” – Sultan Sokoto

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ẹlẹsin mùsùlùmí orílẹ̀ èdè yìí ni wọ́n ti ké sí láti fojú sọ́nà wá òṣùpá Shawwal 1444 AH láti ọjọ́, Ọjọ́bọ̀ èyí tí yóó ṣàfihàn ìfopin sí ààwẹ̀ gbígbà ọ̀rànyàn fún àwọn mùsùlùmí jákèjádò Orílẹ̀ yìí.

Sultan Sokoto , Alhaji Sa’ad Abubakar,ẹni tó tún jẹ́ olórí àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí ní orílẹ-èdè yìí ló fi ìròyìn náà léde látọwọ́ amúgbá lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ tó wà fún ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣìn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sambo Junaidu.

Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún Sultan ni,”Èyí ni láti kéde fún àwọn Mùsùlùmí òdodo pé láti Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yìí, tó tún jẹ́ ọjọ́ tí ààwẹ̀ yóó di ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni yóó jẹ́ ọjọ́ tí wọn ó wo òru Shawwal 1444 AH.

Sultan ṣàdúrà kí Ọlọ́run ka ààwẹ náà sí ìbùkún fún àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí jákèjádò Nàìjíríà.

Rírí òṣùpá ni yóò mú òpin bá ààwẹ̀ gbígbà èyítí ó jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn Mùsùlùmí,Shawwal jẹ́ oṣù Kẹwàá nínú Kàlẹ́ńdà àwọn Mùsùlùmí.

Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé gómìnà sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Adamawa

Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé gómìnà sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Adamawa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa, Ahmadu Umaru Fintiri, ti wọlé gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún sáà kejì.

Fintiri borí ìbò ọ̀hún pẹ̀lú ìbò tí iye rẹ̀ jẹ́ 430,861 nígbà tí ti olùdíje nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Sẹ́nẹ́tọ̀ Aisha Dahiru ní ìbò tí iye rẹ̀ jẹ́ 396,788.

Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta ọdún tí a wà yìí ni ètò ìdìbò Gómìnà ọ̀hún wáyé àmọ́ ìdìbò náà kò kẹ́sẹ járí, èyí tó mú kí wọ́n kéde àtúndì ìbò tó wáyé lópin ọsẹ tó kọjá.

Ètò ìdìbò ọ̀hún lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ṣáájú kí aṣojú INEC ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún tó kéde pé Aisha Dahiru, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Binani ló jáwé olúborí, èyí tó dá wàhálà sílẹ̀.

Àmọ́ aṣojú àjọ INEC ní ìpínlẹ̀ kò láṣẹ lábẹ́ òfin láti kéde ẹni tó jáwé olúborí nígbà tí wọ́n ṣì ń ka ìbò náà lọwọ́.

Ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé Aisha Dahiru, tí INEC kọ́kọ́ kéde ṣáájú yìí, ni yóó jẹ́ Gómìnà obìnrin àkọkọ ní Nàìjíríà, àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ.

N’Íbàdàn,ó lé lógójì afurasí oníjìbìtì ayélujára tó kó sí gbaga àjọ EFCC

N’Íbàdàn,ó lé lógójì afurasí oníjìbìtì ayélujára tó kó sí gbaga àjọ EFCC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀,wọ́n níṣẹ́ tó bá le koko lọ̀lẹ yóó ṣe jẹhun.
Àwọn afurasí ọ̀dọ́ tó ń lu jìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára mẹ́rìnlélógójì ni àjọ EFCC ti fi kélé òfin mú ní Ìbàdàn olúìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú atẹjade tí àjọ EFCC fi léde lórí ìtàkùn ayélujára Twitter rẹ̀, àjọ náà ní agbègbè Apẹtẹ àti Bódìjà nipinlẹ Oyo ni àwọn ti mú àwọn afurasí ọdọ náà.

Lára ohun tí àjọ EFCC gbà lọwọ́ àwọn afurasí ọdọ tó ń lu jibiti ni ọkọ̀ bọgini mẹwa, kẹkẹ alupupu méjì, ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ mẹtaleladọta, ẹ̀rọ kọnputa mẹ́rin, gbohun gbohun Jbl kan, ẹ̀rọ eré ìdárayá playstation kan àti àwọn ohun èlò mìíràn.

Lára àwọn afurasí tí àjọ EFCC fi páńpẹ́ òfin mú ni

Alonge Timilehin Israel, Akinlade Tolulope Seyi, Taiwo Oluwatobiloba Daniel, Adesina Sodiq Ishola, Victor Paul Shedrack, Olawale Oladapo Olaleye, Muili Olamilekan Sodiq, Babalola Afeez Bolaji, Adeagbo Stephen Adegbenro, Ephraim Isaiah Joshua àti àwọn mìíràn tí àpapọ̀ gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàlẹ́lọ́gọ́ta .

Àjọ EFCC ṣèlérí láti gbé wọn lọlé ẹjọ́ nikete ti ìwádìí bá ti parí .

Ọwọ́ tẹ àwọn arúfin tó kó igbó pamọ́ sí inú ìrẹsì

Ọwọ́ tẹ àwọn arúfin tó kó igbó pamọ́ sí inú ìrẹsì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí èèyàn bá mọ nǹkan an tọjú, kó má gbàgbé ẹni tó mọ ọn wá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí fún àwọn oníṣòwò igbó méjì kan, Aminu Saudi, ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta àti Abdulahi Sani, ẹni ọdún márùndínlógójì tọ́wọ́ àjọ tó ń gbógun ti lílò àti gbígbé òògùn olóró lorilẹ-ede yìí (NDLEA), tẹ nílùú Ọgbẹsẹ, nijọba ibilẹ Àríwá Akurẹ, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ igbó tí wọ́n kó sínú ìrẹsì.

Alukoro fún àjọ ọ̀hún, Fẹmi Babafẹmi, ló fìdí èyí múlẹ̀ nínú atẹjade kan tó fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún yìí.

Babafẹmi ní inú àpò ìrẹsì làwọn afurasí náà kó igbó ọ̀hún pamọ́ sí, kí wọ́n lè fi tan àwọn agbófinró jẹ pé ìrẹsì tòótọ ló wà nínú àpò náà, kì í ṣe igbó. Igbó tí wọ́n bá ní ikawọ àwọn èèyàn náà gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ọ̀hún ṣe sọ,ó tó bíi igba àti mọ́kànlá kílógíràmù (211 kg)

Ó ní àwọn aráàlú kan ló ta àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà lólobó tí wọ́n fi ri àwọn onígbó méjèèjì ọ̀hún mú l’Ọgbẹsẹ.

Ó ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹrin yìí, kan náà làwọn tún ṣàwárí oko igbó tó tó bíi sarè ilẹ̀ mẹ́fà nínú igbó kìjikìji kan nílùú Uṣo, níjọba ìbílẹ̀ Ọwọ.

Babafẹmi ní àwọn ti dáná sun oko ọ̀hún, tí àwọn sì rí i dájú pé gbogbo rẹ̀ di eérú kí àwọn tóó kúrò níbẹ̀.

Afurasí agbébọn jí òṣìṣé ìjọba kan gbé lọ́nà márosẹ̀ Èkó si Ìbàdàn

Afurasí agbébọn jí òṣìṣé ìjọba kan gbé lọ́nà márosẹ̀ Èkó si Ìbàdàn

Fẹ́mi Akìnṣọlá

Àwọn afurasí agbébọn ti jí oṣiṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn kan Popoola Olasupo gbé lójú ọnà marosẹ ìpínlẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn.

Olasupo tó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ tó ń ṣe àbójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun ìyẹn, ‘Trace’ ni àwọn afurasí agbébọn náà gbé lágbègbè Eledumare sí Fidiwo lójú ọnà marosẹ Èkó sí Ìbàdàn.

Ìròyìn ní Ọlasupọ ń lọ sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àbọ̀ òwúrọ̀ ni, kí wọ́n tó jí i gbé lọ.

Lára àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó ń gbé e lọ sí ibi iṣẹ́ ṣàlàyé pé ṣàdédé ni àwọn agbébọn jáde láti inú igbó, “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n dàbọn bolẹ̀ tí wọ́n sì jí Olasupo nìkan gbé láàrin àwọn tí ó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé akérò ọ̀hún.

Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn DSP Abimbola Oyeyemi nígbà tí ó ń fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní,”àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń risi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti wà nínú igbó láti ṣe àwárí àwọn ajínigbé ọ̀hún “a sì ní ìgbàgbọ́ pé a ó rí wọn mú”.

“Ìpínlẹ̀ Ògùn kìí ṣe ibi tí àwọn ọdaràn ti le máa ṣọsẹ, gbogbo wọn lọwọ́ ọlọ́pàá máa tẹ, nínú kí wọ́n kúrò nílùú fún wa àbí ká fi imú wọn dánrin”

E̩ máa gbé àsà láruge, Òsèré tíátà Lalude ro̩ àwo̩n òǹkò̩tàn Yorùbá

E̩ máa gbé àsà láruge, Òsèré tíátà Lalude ro̩ àwo̩n òǹkò̩tàn Yorùbá

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Fatai Oodua, ti a mo si Lalude, ti ro awon onkotan Yoruba lati fi ebun atinuda won han pelu itan won.

Osere naa, eni to soro nibi ayeye kan lati se ayajo ojo ede abinibi olodoodun (Annual Mother Language Celebration Day), ti won se ni gbogan awon odo (BNI Youth Centre), ni fasiti Ibadan, tenumo pataki awon itan Yoruba, o ro awon onkotan lati gbe asa laruge nipa ede naa.

Ayeye naa, ti Atelewo Cultural Initiative sagbekale re ni opin ose, ni won se lati sajoyo ede Yoruba ati asa re.
Nibi ayeye naa ni won tun ti se ifilole itan iseju marun-din-ni-aadota ti oloogbe Pa Gabriel Onibonoje, ogbontarigi onkotan Yoruba, ti won si kede eni to jawe olubori ninu idije eleeketa fun Atelewo ninu itan Yoruba.

Ninu oro re, Lalude nipa akitiyan egbe ibile naa ti won n gbe ede Yoruba laruge nipa ise agbese fun Ogbontarigi iwe ase (‘Ogbontarigi Docuseries Project’) ati ebun Atelewo fun itan Yoruba. O tun ki awon to bori ninu idije naa ku oriire, o si ro won lati tesiwaju lati maa to ipa iperegede naa siwaju si i.

O wi pe, “Mo fe ro gbogbo awon onkowe Yoruba lati fi ebun atinuda won han sii ninu ohun ti won n ko. Bi ise atinuda ba se po to ninu ede Yoruba, bee ni yoo se maa mu ki didara itan Yoruba goke si ni Nollywood. Nitori naa, e je ka tesiwaju lati maa so awon itan ti o mu ewa asa Yoruba jade ki a si je ki ebun atinuda gbori ninu bi a n se n ko itan.”

Awon to jawe olubori ninu idije itan naa ni won kede nibi ayeye naa. Mr. Babatunde Shittu ni won kede pe o jawe olubori ni gbogbo re pata fun itan re to ko “Láàdì” ti o si gba ebun owo ọ̀kẹ́ méjìlá àbọ̀ naira.
Jimoh Aderoju ni won yan fun ise afowoko re ‘Àròfọ̀ Àsìkò; Alimi Omosalewa fun aayan ogbufo si ede Yoruba to se fun itan ‘Women of Owu’ lati owo Prof. Femi Osofisan si ‘Awon Obinrin Owu,’ ati Rasheed Adeniyi fun iwe afowoko re ti o pe akole re ni ‘Nǹkán Yan.’ Gbogbo won si gba ebun owo oke marun naira ni eni kookan.

Lalude soro lori pataki sise itoju ati gbigbe ede ati asa Yoruba laruge nipa itan. O wi pe awon onkotan Yoruba ni won ni ojuse lati ri pe ede ati asa naa n tesiwaju lati ma a gbeeru, o si pe won lati fi ebun atinuda won ati ogbon won han ninu ohun ti won n ko.
Ifilole itan nipa igbesi aye oloogbe Pa Onibonoje je ohun miiran to laami nibi ayeye naa. Itan iseju marun-din-ni-aadota naa so nipa bi won se bii, ibere aye re, bi o se bere ise gbigbe iwe jade, awon ipenija re, awon aseyori re, ati ilowosi re ninu agbejade omo onile titi de igba to feyinti lenu okowo re.

E̩ já o̩kùnrin gidi gbà ló̩wó̩ obìnrin tó bá jáfara – Osere tiata Sarah Martins

E̩ já o̩kùnrin gidi gbà ló̩wó̩ obìnrin tó bá jáfara – Osere tiata Sarah Martins

Mary Fágbohùn

Osere tiata alariyanjiyan, Chukwukere Sarah Ujunwa, ti a mo si Sarah Martins, ti gba awon obinrin niyanju lati ja awon okunrin ti won ba ti se igbeyawo gba lowo iyawo won gege bi bi o se so awon ti won ba buru ti won o si bikita.

O wi pe awon okunrin lo ye ki won ri ife gba lowo awon obinrin miran ti won ko ba ri gba lodo obinrin won.

Osere naa so eyi di mimo ni oju opo Instagram re ni Ojoru.
Amo sa, Martins, wi pe, oro naa ko yo awon obinrin seyin bo se je pe ko si eni ti ko se e ja gba.

O wi pe, “E mase beru lati ja okunrin gidi gba lowo obinrin to buru ti ko si bikita! O ye ki okunrin ri ife ti o to…

Bakan naa ni awon obinrin…Ko si eni ti oro jijagba ko kan nitori pe gbogbo eniyan lo ye ko ri ife ti o to.”

Ìdí tí Falz fi ń sò̩rò̩ ìdójútini sí ìjo̩ba – Falana

Ìdí tí Falz fi ń sò̩rò̩ ìdójútini sí ìjo̩ba – Falana

 

Agbejoro agba feto omoniyan, Femi Falana (SAN), ti soro lerefe lori idi ti omokunrin re, Folarin Falana ti a mo si Falz fi tesiwaju lati maa soro idojutini si ijoba.

Falana so pe itoju ti omokunrin oun ri dagba kii se lati so di iru okunrin to je lonii sugbon o je idi pataki fun ise re si odo ijoba.

O salaye pe omokunrin oun dagba si riri oun ti won n fi ofin gbe oun ti won si n ti oun mole ni gbogbo igba, o wa n woye pe boya odaran ni baba oun.

Nigba to n soro nibi idanilekoo ajodun keji fun Oluyinka Odumakin ni Eko, Falana wi pe: “Okan lara awon okunrin yii lojo kan wi pe, ‘Falana ba omo re soro; ko jewo ninu a n soro idojutini si ijoba’. Mo so pe ijoba wo? O n so pe omokunrin to ti di agbalagba yi? Se mo le fun o ni nomba ibanisoro ki o le e ba soro? Sugbon sora nitori pe nigba ti omo naa n dagba, gbodo igba ni won n fi ofin gbe mi lati igba de igba. Nitori naa, ede kan to yee ni atimole, fifi ofin gbeni, ati awon to ku re.

“Ni ojo kan, nigba ti omo naa wa ni odun mefa, o beere lowo iya re, “Oluko wa ko wa pe awon odaran ni won maa n fi ofin gbe. Se odaran ni baba mi ni? Ki lo de ti won n fi gbogbo igba fi ofin gbe won? Iya re si da lohun pe ni Naijiria, ni abe ologun, awon meji ni won maa n fi ofin gbe: afunrasi odaran ati afunrasi oselu. Awon afunrasi oselu ni awon ti won n tu asiri iwa odaran ti ijoba n hu. Nnkan to ri to n lo niyen.”

Afihan Falana yii waye leyin ojo die ti ilumooka olorin omo re, Falz se agbejade orin tuntun kan ti o pe akole re ni ‘Yakubu,’ eyi ti oun ati akegbe re olorin, Vector jo ko.

 

 

Àwo̩n obìnrin tó ti mo̩ o̩kùnrin máa ń se ìpinnu tó dára– OAP Nedu

Àwo̩n obìnrin tó ti mo̩ o̩kùnrin máa ń se ìpinnu tó dára– OAP Nedu

Mary Fágbohùn

Olootu eto Chinedu Ani Emmanuel ti a mo si Nedu ti jiyan pe awon obinrin to ti mo okunrin maa n se ipinnu to dara ju eni ti won je lo.

O so pe opolopo awon obinrin ti ko ti mo okunrin ri ibaale won bi nnkan ti kii se iyi tabi nnkan to se iyebiye fun won julo nikan sugbon bii gbogbo nnkan fun won, o jiyan pe won ko ni nnkan miran ju iyen lo.

Ni ori eto kan o woye nnkan ti won yoo da bi o ba sele pe won so ibaale won nu.

“Bi mo ba fe se igbeyawo, Mi o le fe obinrin ti ko ti mo okunrin,” ni oun to si ni ori eto kan to sese se ‘Honest Bunch Podcast’.

“Pe o je eni ti ko ti mo okunrin ko tumo si pe iwo ni obinrin to dara ti okunrin kan le e fe.

“Fun emi o, kinni idi ti mo ro pe o ye ki o fe obinrin ti o ti mo okunrin, awon obinrin to ti mo okunrin, bi ero temi, maa n se ipinnu to dara nitori pe awon obinrin ti ko ti mo okunrin gbagbo pe ibaale won ni nnkan iyi ati iyebiye ti won ni,

“Won a so pe ibaale mi ni eni ti mo je gege bi obinrin. Gbogbo nnkan ni. Mo je omo ogbon odun mi o si ti mo okunrin.

“Eyi tumo si pe, gbogbo iyi gege bi obinrin ni ibale won, nitori naa ti won ba se igbeyawo ti oko won ba si ja ibale won, kinni yoo pada di ti won?

“Ni iru oro bayii, gbogbo nnkan ti okunrin ba so fun won ni akoko naa, won a faramo, sugbon obinrin to ti ni iriri, o ni erori lati mo pe nnkan to dara ni tabi nnkan ti ko dara.

“Sugbon iyen ko so pe nnkan buburu ni pe ki obinrin je eni ti ko ti mo okunrin, ero temi ni.”

 

Nancy Isime kò sí nínú mílíò̩nù kan obìnrin tó rewà jù – Mr Jollof

Nancy Isime kò sí nínú mílíò̩nù kan obìnrin tó rewà jù – Mr Jollof

 

Ilumooka aderinposonu Mr Jollof ti so pe osere to gba ife eye Nancy Isime ko si laarin awon obinrin bi milionu kan to rewa ju ni Naijiria.

Aderinposonu naa so eyi nigba to n tako oro ti agbaboolu teleri fun iko Golden Eaglets, Abba Bichi so pe Isime lo rewa ju lobinrin ni Naijiria.

Omo Alakoso-Gbogboogbo (Director-General) fun eso alaabo ipinle (State Security Service, SSS) Yusuf Bichi so pe onirawo fiimu naa ni obinrin to rewa ju ni Naijiria ti ko si eni to le e jiyan re, o so fun awon olupegan lati gba ile-ejo lo ti won ko ba faramo ohun ti oun so.

O wi pe: “Ko si obinrin ni Naijiria to rewa ju Nancy! Ti e o ba faramo e gba ile-ẹjo lo ki e lo so pe e se baba.”

Nigba to n fesi si oro naa, Mr Jollof ninu ifesi labe oro Bichi, wi pe: “O gbiyanju ni pato sugbon ko papo mo milionu kan obinrin akoko!!! Ko si arifin mo kan n so okodoro oro ni.”