Home Blog Page 60

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu ìyànsípò, Oluwatoyin Sakirat Madein gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìyànsípò náà ló jẹ jáde nínú lẹ́tà kan tí olórí òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, Dókítà Folasade Yemi-Esan fi léde.

Ó ní Ààrẹ Buahri ti buwọ́lu ìyànsípò náà.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta ọdún 1965 ni wọ́n bí Oluwatoyin Sakirat ní Iperu Remo, ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ṣaájú ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà, Sakirat ni adarí ẹ̀ka ìsúná ní ọ́fíìsì olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè yìí.

Oluwatoyin Shakirat ló ń gba ipò yìí lọ́wọ́ Ahmed Idris tó jẹ́ olùṣirò owó tẹ́lẹ̀ tí Ààrẹ Buhari ní kó lọ rọ́kún nílé fẹ́sùn wí pé ó kojú ẹ̀sùn pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù 109 náírà.

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kò sí, kóówá ń relé lẹyìn ìnájà ayé dandan ni. Ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ìròyìn gbòde pé olóyè Subomi Balogun tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) jáde láyé.

Ìròyìn sọ pé ní ìlú London, United Kingdom ni bàbá náà dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́. Ó ṣeéṣe kí nífẹ̀ẹ́ àti mọ̀ irúfẹ́ èèkàn iràwọ̀ àwùjọ tí à n perí, gbàyí wò.
Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 1943 ni wọ́n bí olóògbé Subomi Balogun sáyé tó sì pé ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún kó tó dágbẹre fáyé pó di kése.
Ọmọ ìdílé Ọba Tunwase ti Ijebu-Ode ni Subomi Balogun.
Òun ni Otunba Tunwase gbogbo Ijebu, tó sì tún jẹ́ Olori gbogbo ọmọọba Ijebu àti Asiwaju àwọn onígbàgbọ́ ní Ijebu.
Ìdílẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n bi sí kó tó yípadà sí onígbàgbọ́ nígbà tó wà ní ilé ẹkọ girama.
Ilé ẹ̀kọ́ Igbobi College ló ti kẹ́kọ̀ọ́ girama, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí London School of Economics níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kó tó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ kàwé, tó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ nígbà tó padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Ní ọdún 1979 ni ó gba ìwé àṣẹ láti dá ilé ìfowópamọ́ First City Merchant Bank sílẹ̀ tí báǹkì náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1983.
Subomi Balogun dá ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọdé kalẹ̀ ní Ijebu Ode èyí tó fún ile ìwòsàn ńlá UCH tí Ibadan.
Aṣọ funfun ni ó sábà máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà. Olóògbé Subomi Balogun fi ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọọmọ sáyé lọ .
Kín la á sọ nípa tèmi tì ẹ?

Labour Party,Alágá ẹ̀gbẹ́ di mèjì tó fẹ́̀ rojọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Labour Party,Alágá igun ẹ̀gbẹ́ di mèjì tó fẹ́̀ rojọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ èyí tó ń lọ ní Abuja ti sún ìgbẹ́jọ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi èyí tó pè tako Ààrẹ tí ìlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu síwájú.

Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú LP, Julius Abure báwọn péjú silé ẹjọ́ tí Lamidi Apapa tí òun náà jẹ́ alága ikọ̀ kan ní ẹgbẹ́ náà sì wà ní ìkàlẹ̀.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìgbìmọ̀ ọ̀hún ti ṣáájú sún sí ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Karùn-ún nígbà tí Peter Obi tọrọ ààyè láti sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú.
Nígbà tí Adájọ́ tún dé ibi ìjókòó lọ́jọ́rú láti tẹ̀síwájú ètò náà ló tún kọ̀ láti ṣe ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Labour Party yàtọ̀ sí Obi nìkan.

Lẹ́yìn náà ni ohun tó fẹ́ jọ bí eré orí ìtàgé tún wáyé ní ilé ẹjọ́ nígbà tí wọn ò mọ ẹni tí yóò ṣojú ẹgbẹ́ nílé ẹjọ́ nínú àwọn alága méjèèjì tó wà níkàlẹ̀.

Ìgbìmọ̀ náà kọ̀ láti gbà kí Lamidi Apapa àti olórí àwọn obìnrin ẹgbẹ́, Dudu Manugu dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ nígbà tí wọ́n ní kí wọ́n yọjú.

Adájọ́ Haruna Tsamani ní tí ènìyàn méjì bá ń dúró fún ẹgbẹ́ kan ṣoṣo, àwọn kò ní gbà wọ́n wọlé.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀, agbejọ́rò Labour Party, Livy Uzoukwu sọ fún ilé ẹjọ́ pé àsìkò tí wọ́n fún àwọn láti fi kó àwọn ẹ̀rí wá sílé ẹjọ́ kò tó rárá nítorí àjọ elétò ìdìbò náà kò ì tíì fún àwọn ní gbogbo nǹkan tí àwọn ń bèèrè fún.

Uzoukwu ní ìdá ọgbọ̀n nínú gbogbo àwọn ìwé tí àwọn ń bèèrè fún ni INEC ṣẹ̀ṣẹ̀ pèsè fún àwọn.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn ẹ̀rí tí àwọn ń bèèrè láti ìpínlẹ̀ Rivers ni wọn kò ì tíì pèsè fún àwọn bí ọ̀gá àgbà àjọ INEC ìpínlẹ̀ ṣe ní àwọn kò ní fọ́ọ̀mù EC8A, tó sì kọ̀ láti kọ ìwé láti fi èyí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe sọ fun.

Nígbà tó ń fèsì, agbẹjọ́rò INEC, Abubakar Mahmoud ní gbogbo nǹkan tí agbẹjọ́rò Labour Party ń sọ ya òun lẹ́nu gidi nítorí àwọn ni wọ́n kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé tí àwọn pé.

Mahmoud ní nígbà tí àwọn tún fi ìpàdé sí ọjọ́ mìíràn, wọ́n tún bínú jáde kúrò níbẹ̀.

Bákan náà ló ní gbogbo ohun èlò ìbò ti ìpínlẹ̀ Sokoto àti Rivers ló wà nílẹ̀ àmọ́ Labour Party kọ̀ láti san owó mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà fún ìpínlẹ̀ Sokoto àti pé fọ́ọ̀mù EC8A tí Rivers ni àwọn kò ì tíì fún wọn.

Ó fi kun pé àwọn ìwé kan náà wà tí àwọn fún ẹgbẹ́ wọn ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti gbà, tí wọ́n ní àfi ìgbà tó bá pé.

Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo nǹkan tó yẹ ni àwọn ń ṣe láti ri dájú pé àwọn ran ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀.

Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san àbọ̀ saájú ikú rẹ – Golugo

Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san àbọ̀ saájú ikú rẹ – Golugo

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ohun tó pamọ́ ojú adẹ́dàá tó o. Ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé, yóó dìín .” Irọ́ ni ìròyìn kan tó ń jà kiri pé àwọn aláwo ti gé orí àti etí Murphy Afolabi lẹ́yìn tó jáde láyé.”

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Adekola Tijani tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Golugo ti sọ̀rọ̀ nípa bí ìrìnàjò gbajúgbajà òṣèré tíátà tó di olóògbé, Murphy Afolabi se wá sópin lọ́jọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀ yìí nílùú Èkó.

Golugo, lasiko to n ba sọ̀rọ̀ níbi ètò ìsìnkú olóògbé ọ̀hún tó wáyé ni Adamọ nílùú Ikorodu ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nítorí òun pẹ̀lú Murphy sọ̀rọ̀ ọgbọ̀n ìsẹ́jú sẹ́yìn kí òun tó gbọ́ ìròyìn pé ó subú.

“Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni ago mẹ́sàn àbọ̀, ó ṣubú ní ago mẹ́wàá ni wọ́n pè mí pe o ṣubu”.

“Mo ni ki lo sẹlẹ, wọn ni ki n ṣaaa maa bọ, bi mo ṣe de ibẹ, mo ni ki a gbe e sinu ọkọ ka maa lọ ile iwosan ṣugbọn Murphy ti dakẹ ki a to de ile wosan

“Ko si nnkan ti a le ba Ọlọrun fa nitori a ko gbọn ko Ọlọrun, ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a maa pada si. Gbogbo nnkan Murphy lo ti di ohun igbagbe.

“Ọmọ kekere ni Murphy, a jọ bẹrẹ ni, emi ni mo baa ya sinima rẹ akọkọ, nnkan da emi ati Murphy papọ gan”.
Pẹlu omije loju ni Osere tiata, Nofisat Olayiwola ti ọpọ mọ si Ọmọ Ẹja fiṣalaye ibaṣepọ rẹ pẹlu Oloogbe Murphy Afolabi nibi eto isinku rẹ.

Nofisat ni igba ti oun fẹ ṣe sinima rẹ akọkọ, oun ko ni owo kankan lọwọ ṣugbọn oloogbe ni ki oun lọ mu iyekiye ti oun ba ni wa lati fi se sinima to di ilumọọka naa.

“Murphy ni kí ń lọ mú iyekiye wa, ó dẹ ya sinimá ọhún, apá kìíní àti ìkejì nílùú Osogbo.

“Mi o le gbagbe Murphy laye, mi o ni ile niluu Eko, Murphy lo tẹwọgba gba mi sile rẹ fun ọdun marun un”.

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣeré tíátà ni wọ́n ya wọ iléègbé olóògbé nílùú Ikorodu láti ṣe ádùrá ìkẹyìn fún un

Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báa kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti bá àwọn ẹbí, ará àti akẹgbẹ́ Murphy Afolabi tó di olóògbé lọ́jọ́ Àìkú kẹ́dùn lórí àdánù ńlá yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbénusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ìlú Osogbo júwe Murphy Afolabi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣojú ìpínlẹ̀ Osun dáradára nígbà ayé rẹ̀.

Adeleke ní Afolabi lo ìgbé ayé rẹ̀ láti farajìn sí iṣẹ́ eré tíátà tó gbé dání, tó sì fi hu ìwà ọmọlúàbí títí tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Afolabi ṣe àbẹ̀wò sí òun kó tọ di wí pé ọlọ́jọ́ dé, ó ní ọ̀rọ̀ àwọn ìpèníjà tó ń bá ẹ̀ka ètò eré ìdárayá ni àwọn jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“A fẹnukò lórí àwọn ètò tó le sọ ìpínlẹ̀ Osun di oríko ilé àṣà àti ibi ìnàjú ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà.”

“Afolabi jẹ́ òṣèré Yorùbá tó nífẹ̀ẹ́ láti máa gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá pẹ̀lú ẹ̀bùn eré tí Ọlọ́run fún-un.”

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú Murphy Afolabi jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́, àwọn gbà pé ó gbé ìgbé ayé tó ṣe é fi yangàn, tó sì máa ń fi ìpínlẹ̀ Osun síwájú nínú gbogbo nǹkan tó máa ń ṣe nígbà ayé rẹ̀.

“Mo bá àwọn ẹbí, akẹgbẹ́, ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ Murphy Afolabi káàkiri àgbàyé kẹ́dùn lórí ìpapòdà rẹ̀.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.

Ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ni Afolabi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta kí ọlọ́jọ́ tó dé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karun-ún ọdún 2023.

Murphy Afolabi ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bí i Ifá Olókun, Omowunmi, Wasila Coded àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tí ogun lé ní Sudan láti dá padà sílé-NIDCOM

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tí ogun lé ní Sudan láti dá padà sílé-NIDCOM

Ọrẹ Òtítójù

Ìsí kẹẹ̀ẹ́dógún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà tí ogun lé kúrò ní Sudan ti padà sílé.

Pẹ̀lú ìgbésẹ yìí,gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tí wọ́n gbé láti pákákọ̀ òfurufú Egypt padà sílé ni wọ́n ti kó tán báyìí.

Bẹẹ ni Abike Dabiri Erewa to jẹ ọga agba ajọ Naijiria to n risi ọrọ ọmọ ilẹ Naijiria nilẹ okere ti ṣe kede loju opo Twitter rẹ.

Dabiri sọ pe awọn akẹkọọ 147 to gbera lati papakọ ofurufu Port Sudan balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe,Abuja, ni nkan bi ago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Abamẹta.

”Ni paapa gbogbo awọn akẹkọọ wa lo ti dari pada sile bayii”

Lapapọ ajọ naa sọ pe awọn ti ribi gbe awọn ọmọ Naijiria 2,518 pada sile.

Bẹẹ ni wọn fi kun pe ko si ẹmi eeyan kankan to padanu lasiko ti wọn n gbe wọn pada sile.

A kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ọmọ Nàìjíríà tí ogun lé ní Sudan ló padà sílé báyìí nítorí ọpọ ni kò gba ọnà ti Egypt sa àsálà torí ogun Sudan.

Àṣà Yorùbá

Àsà àti ìṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mu ọ̀nà tí ó gún gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ pé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó’ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà. Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a ń mú ẹnu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni’ Àṣà ìkíní nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi ma ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-o kò-jíire bí tòótọ́ ní gbogbo ààyè tí wọ́n bá dé.
Ṣé bẹ́ẹ̀ náà sì tún ni nnkan rí lásìkò yìí? Kó máa ró kì lóókan àyà èmi àti ìwọ.Lábala ìkíni àsìkò yìí, a fi sọrí èèkàn ìlú, ẹlẹ́yinjú àánú tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Orílẹ̀ yìí n bù lá nínú ọrọ̀ t’Édùwà fi dasọ àṣírí bòó.Ìdí nìyí tí mo fi pè é ní Oríkádún.

APC ti fi àwòrán Tinubu àti ti ìgbákejì rẹ̀ tuntun síta

APC ti fi àwòrán Tinubu àti ti ìgbákejì rẹ̀ tuntun síta

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti fi àwòrán Aàrẹ tí aráàlú dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu síta pẹ̀lú ti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima.

Eyi n waye saaju iburawọle ti yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn,oṣu Karun un, ọdun 2023.

Agbẹnusọ fun Bola Tinubu, Bayo Onanuga,lo fi aworan naa lede loju ọpọ Twitter.

Bakan naa lo fikun un pe ajọ to n risi iburawọle aarẹ ati gbakeji rẹ ti araalu dibo yan buwọlu aworan tuntun naa.

O ni ọpọ eeyan ni yoo maa lo aworan naa ,ti wọn yoo si maa fi si ọfisi wọn gẹgẹ bi aworan aarẹ ati ti igbakeji rẹ.

Saaju ni agbẹnusọ aarẹ naa ti kede pe Tinubu rin irinajo lọ si oke okun nitori awọn to fẹ ri fun ipo kan tabi omiran ti pọju bi o se yẹ lọ.

O ni irinajo naa yoo fun ni anfaani lati gbaradi bi o se yẹ fun iburawọle naa ti yoo waye ni aipẹ.

Bi ọjọ iburawọle yi ṣe n kan lẹkun dẹdẹẹ, bẹẹ naa ni awọn ikọ kan n pe fun ki wọn ma burawọle fun aarẹ ti ilu dibo yan yi.

Wọ́n ní àwọn ń pe ìpe yìí nítorí magomago lásìkò ìdìbò náà tó gbé Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn náà wọlé.

Èèyàn méje tó sọ̀kò gbẹ̀mí Ọlọ́pàá dèrò àtìmọ́lé n’Ìbàdàn

Èèyàn méje tó sọ̀kò gbẹ̀mí Ọlọ́pàá dèrò àtìmọ́lé n’Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìpátá kìí bímọ re, bí ò bá bí ikú a sì bí ẹ̀wọ̀n gbére.
Àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé wọ́n lu ọlọ́pàá kan, Rìpẹ́tọ̀ Augustine Okoro títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀ ní ibùdó ọlọ́pàá tó n bẹ ní pópónà Iṣẹyin, íi agbègbè Mọniya nílùú Ìbàdàn ti fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Àwọn afurasí náà ni: Sarafa Lateef (ẹni ọgbọ̀n ọdún), Saminu Ibrahim (ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n), Oloso Sikiru (ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì), Fatai Yusuf (ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta), Moruf Olanrewaju (ẹni ọdún méjìlélógójì), Isiaka Rafiu (ẹni ogójì ọdún), àti Anuoluwa Akinola (ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n).

Agbèfọ́ba, ASP Amos Adewale sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà gbìmọ̀pọ̀ lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ní òpópónà Ìṣẹ́yìn ní agbègbè Mọniya Ìlú Ìbàdàn, tí wọ́n sì ṣe ikú pa Rìpẹ́tọ̀ Augustine Okoro, ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì.

Adewale fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà lu Okoro, wọ́n sì sọ òkò paá lẹ́nu iṣẹ́ ní agbègbè náà.

Ó ní ìtàpásófin yìí tako òfin ìwà ọ̀daràn ti ọdún 2000 n’ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ Májísírètì, E. A. Idowu ti ilé ẹjọ́ Májísírètì Iyaganku tí ó kọ láti tẹ́wọ́gba ẹ̀bẹ̀ àwọn ẹni afẹ̀sùn kàn náà ló pa àṣẹ pé kí wọ́n sọ wọ́n sí àtìmọ́lẹ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi.

Adájọ́ náà tọ́ka ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn fún àmọ̀ràn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje.

Ọlọ́pàá pa olórí ikọ̀ adigunjalè

Ọlọ́pàá pa olórí ikọ̀ adigunjalè

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní ẹni tó jàde tó padà wọlé ẹ̀, ló rìnrìn àjò.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Oyo, ti pa Balógun ikọ̀ adigunjalè tí wọ́n fura sí pé ó pa ọlọ́pàá kan nílùú Ìbàdàn láìpẹ́ yìí. Bakan náà ni àwọn ọlọ́pàá tun mu afurasí mẹ́ta mìíràn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá fún ìpínlẹ̀ Oyo, SP Adewale Osifeso, ló kéde ìgbésẹ̀ náà fún àwọn akọ̀ròyìn, lásìkò tó fi ojú àwọn afurasí náà hàn ní olú ileeṣẹ ọlọ́pàá tó wà ní Eleyele nílùú Ìbàdàn.

SP Osifeso ṣàlàyé pé, àwọn afurasí adigunjalè náà pa ASP Daniel Ogunleye, lásìkò tí wọ́n yabo ilé rẹ̀ ní àdúgbò Odo-Ona Kékeré, nílùú Ìbàdàn, lọ́jọ́. kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin.

Àwọn afurasí náà, tó jẹ́ márùn-ún yabo agbègbè Orí-Agogo, Odo-Ona, ní bíi aago kan òru, tí wọ́n sì ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùgbé ibẹ̀ lólè.

Lára àwọn tí wọ́n jà lólè ni ASP Ogunleye wà.

“Àwọn afurasí náà pa Ogunleye lẹ́yìn tí wọ́n ja òun àti ẹbí rẹ̀ lólè tán.

” Ẹ̀ka iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń wádìí ìwà ọ̀daràn, SCID, ní Iyaganku, ni Daniel ti ń ṣiṣẹ́ ṣaájú ikú rẹ̀.”

Bákan náà ló ní fóònù tí ẹnìkan lára àwọn afurasí ọ̀hún gbàgbé sí ibi tí wọ́n ti jalè, ló ṣe atọ́nà bí ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ pé ọwọ́ tún tẹ oníṣègùn ìbílẹ̀ tó ń tọjú wọn.

” Lásìkò tí wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọlọ́pàá ní ibùba wọn, ní ìbọn pa olórí wọn.

Ọwọ́ tún tẹ obìnrin oníṣòwò tó má a ń ra àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ara lọ́wọ́ wọn.