Home Blog Page 59

Ọba méjì pàdánù ipò wọn ní ìpínlẹ̀ Kaduna

Ọba méjì pàdánù ipò wọn ní ìpínlẹ̀ Kaduna

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bó ṣe ku ọjọ́ díẹ̀ kó kúrò nípò gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai ti pàṣẹ pé kí wọ́n gba adé, ọ̀pá-àṣẹ, ìrùkẹ̀rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní i ṣe pẹ̀lú nǹkan tí wọ́n fi lè dá àwọn ọba alayé méjì kan, Ọba Jonathan Paragua Zamuna àti Ọba Aliyu Illah Yamman, tí wọ́n ń ṣàkóso lórí agbègbè Pirigi àti Arak, ní ìpínlẹ̀ náà mọ́ lọ́wọ́ wọ́n ní kíá .

Lórí ẹ̀rọ ayélujára tó jẹ́ ti Gomina Nasir El-Rufai lo ti kọkọ kede yiyọ awọn ọba mejeeji ọhun nipo fawọn araalu, ko too di pe Hajiya Umma Ahmed to jẹ Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati fifi eeyan joye niluu naa tun fidi rẹ mulẹ, to si sọ pe yiyọ awọn ọba alaye mejeeji naa bẹrẹ lati lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

El-Rufai kọ ọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára rẹ pe ‘Ijọba ipinlẹ Kaduna n fi akoko yii sọ fawọn araalu gbogbo pe Gomina Nasir El-Rufai ti bu ọwọ lu yiyọ awọn ọba alaye mejeeji yii, Ọba Jonathan Paragua Zamuna ati Ọba Aliyu Illah Yamman, ti wọn n ṣakoso lori agbegbe Pirigi ati Arak, nipinlẹ Kaduna, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii”.

Kọmiṣanna ọhun ni igbesẹ tijọba ipinlẹ naa gbe wa ni ibamu pẹlu ofin to gbe jijẹ oye ọba kalẹ nipinlẹ naa. Ti wọn si ti yan olori agbegbe Garun Karunma, Ọgbẹni Babangida Sule, ko maa dari agbegbe Piriga, titi digba ti wọn yoo fi yan olori tuntun sipo naa. Nigba ti Ọgbẹni Gomna Ahmadu to jẹ akọwe agba ilu Arak, yoo maa dari ilu Arak titi digba tijọba yoo fi yan ẹlomiran.

Ẹsun ti won fi kan wọn ni pe Ọba Illyah Yammah fi awọn oloye mẹrin kan jẹ lai jẹ pe o tẹle awọn ilana to yẹ lori ọrọ oye awọn eeyan naa. Ati pe, ki i gbe inu ilu to n ṣakoso lori rẹ rara.

Ni ti Ọba Jonathan Zamuna, ẹṣẹ toun ṣẹni pe ko mojuto akooso ilu naa rara debii pe ija igboro kan bẹ silẹ níbẹ, to si mu ọpọ ẹmi awọn araalu naa.

Wọn fi kun un pe ọba alaye naa ki i gbe inu ilu to ti jẹ ọba naa rara eyi tawọn alaṣẹ ijoba ipinlẹ naa sọ pe ki i ṣohun to daa rara.

Bẹ́ ò bá gbàgbé, àìpẹ yìí ni Gómìnà Nasir El-Rufai sọ pé ìjọba òun kò ní í yé lé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà danu, àti pé títí di ọjọ́ tóun yóó lò gbẹ̀yìn nínú ìsàkóso òun lòun yóò fi máa wó àwọn ilé kọ̀ọ̀kan tí wọn kò wà ní ìbámu àti ìlànà iìkọ́lé ìpínlẹ̀ náà dànù báyìí.

Ìgbẹ̀jọ ẹ̀hónú ìdìbò Ààrẹ yòó tẹ̀síwájú lẹ́yìn ìbúrawọlé Ààrẹ tuntun

Ìgbẹ̀jọ ẹ̀hónú ìdìbò Ààrẹ yòó tẹ̀síwájú lẹ́yìn ìbúrawọlé Ààrẹ tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ awuyewuye èsì ìdìbò Ààrẹ Nàìjíríà ti sọ pé káwọn tó tẹ̀síwájú padà lórí ìgbẹ́jọ́ di lẹ́yìn ìbúrawọlé sípò Bola Ahmed Tinubu.

Ìròyìn yìí jẹyọ lẹ́yìn ti àwọn alátakò Tinubu ti ṣáájú bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ ṣe àfihàn ìgbẹ́jọ́ náà lórí amóhùnmáwòrán tí ilé ẹjọ́ sì wọ́gilé àbá tí wọ́n mú wá yìí.

Ohun tí eléyìí túmọ̀ sí báyìí ni pé Tinubu yóó ti wà lórí ipò ààrẹ lásìkò tí igbẹjọ yii bá ń wáyé.

Igbẹjọ náà ti tó bí ọsẹ méjì kọjá díẹ̀ tó bẹrẹ tó sì lè tó oṣù mẹta kí wọ́n tó kasẹ ẹjọ́ náà nilẹ.

Àwọn alatako Atiku Abubakar àti Peter Obi ló lewaju nínú àwọn tó láwọn fẹ́ kí ilé ẹjọ́ wọgile èsì ìbò tó gbé Tinubu wọlẹ .

Láàyè arawọn lọtọọtọ sì ni wọ́n láwọn fẹ́ kí adájọ kéde àwọn gẹgẹ bí oludije tó jáwé olúborí.

Ní ọjọ́ Ajé tíí ṣe jọ kọkandinlọgbọn oṣù Kaarun ni iburawọle sípò Tinubu yóò wáyé ní olú ìlú Nàìjíríà tíí ṣe Abuja.

Wọ́n fẹ́ bá àjọṣepọ̀ gómìnà Ganduje àti Tinubu jẹ́ ni – Ìjọba Kano

Wọ́n fẹ́ bá àjọṣepọ̀ gómìnà Ganduje àti Tinubu jẹ́ ni – Ìjọba Kano

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olójú ò ní-ín yajú rẹ sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ ó yí wọ̀ ọ́.
Ìjọba ìpínlẹ Kano ti bu ẹnu àtẹ lu bí àwọn kan ṣe fẹ́ bá ìbásepọ tó wà láàárín Gómìnà ìpínlẹ Kano àti Ààrẹ ti wọ́n dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu.

Ìjọba Kano ní àwọn ènìyàn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn ni wọ́n fẹ́ bá ìjọba tuntun náà jẹ́.

Wọ́n ní àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan náà ń pín ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lórí fóònù láàrin Gómìnà Umar Ganduje àti Ibrahim Masari.

Gómìnà náà ní ayédèrú ni ohùn náà, tí kò sì òtítọ́ nínú ìròyìn tó ń káàkiri lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Nínú ayédèrú ìròyìn náà ni àwọn méjèèjì tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìjíròrò tó wáyé láàárín Tinubu àti adarí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Rabiu Kwankwaso.

Ìjọba ìpínlẹ Kano ní àwọn èèyàn tó ti gba owó láti bá nǹkan jẹ́ ló ń pín àwọn ọ̀rọ̀ náà lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Wọ́n ní àwọn kò ní gbà àwọn ènìyàn yìí láàyè láti ba ìjọba tó ń bọ̀ yìí jẹ́.

Ní May 29 ni ìbúrawọlé yóò wáyé fún Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Kẹrìndínlógún tí wọ́n dìbò yàn ní Nàìjíríà

N kò gba‘Ticket’ tí Mákindé fi lọ̀ mi  … Kola Balogun

N kò gba‘Ticket’ tí Mákindé fi lọ̀ mi  …–– Kola Balogun

Sẹnetọ tó ń ṣoju ẹkùn Gúúsù Ọyọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Kọla Balogun ti ṣàlàyé pé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ṣeyi Makinde gbìyànjú láti fa ojú òun mọ́ra padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣugbọn òun kọ jalẹ.

Èyí ló ń wáyé lẹyìn tí ó fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC).

Balogun ló sọ ọ̀rọ̀ náà lópin ọ̀sẹ̀ lórí ètò òṣèlú kan níléeṣẹ́ redio Fresh FM, ìlú Ìbàdàn.
Ó ní ṣáájú ètò ìdìbò abẹ́lé, nínú eléyìí tí olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹlẹ rí, Joseph Tegbe ti gba ànfàní láti díje gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nẹ́tọ̀ nínú ètò ìdìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lọ́dún 2023, ní Mákindé ti rán àwọn èèyàn ṣí òun láti padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láti díje du ipò Sẹ́nẹ́tọ̀, ṣùgbọ́n ó ti bọ́ sórí nítorí òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, APC.

Ànfàní ti Balogun kò ní láti díje fún sáà ìkejì ló mú kó darapọ̀ mọ́ APC kí ó le dé ibi ìlépa rẹ̀

Àmọ́ olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀ tẹ́lẹ̀rí, Sharafadeen Alli ni ẹgbẹ́ náà fún ní ànfàní láti díje, òun ló sì jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.

Balogun ní ìbá jẹ́ wí pé òun tẹ́wọ́gba ànfàní tí Mákindé fi ṣọwọ́ sí òun ṣáájú àsìkò tí wọ́n gbé e fún Tegbe ni, kò bá tí já sí nǹkan iwọsí nítorí gbogbo ayé ní yóó máa pariwo pé òun ti di alagbere òṣèlú tó ń ti ibì kan bọ́ sí ibì ìkejì.

Balogun fi kún ọrọ̀ rẹ̀ pé oun kò kabamọ pé òun darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, òun kò sì ní yí ìpinnu òun padà bí ànfàní bá tún yọjú láti díje du ipò.

ìròyìn òfegè ni pé Russia tún ti gba ìlú Bakhmut – Ààrẹ Zelensky

ìròyìn òfegè ni pé Russia tún ti gba ìlú Bakhmut – Ààrẹ Zelensky

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ogun kò rí bí iyán,ogun kò rí bí ẹ̀kọ,ogun kò dà bíìgbà téèyàn n najú lórì obìnrin rẹ̀.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ukraine, Volodymyr Zelensky tí ni kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé orílẹ̀ èdè Russia tí gba ìlú Bakhmut.

Èyí kò sẹ́yìn ìròyìn tó gbòde kan pé àwọn ikọ̀ Russia.

Ààrẹ Zelensky ni àwọn ikọ̀ ọmọ ogún wọn wá ní ìlú náà láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan.

Ààrẹ náà ni òun kò ní leè sọ jù báyìí lọ, àmọ́ òun ti òun mọ̀ ni pé ìlú náà kò sì lọ́wọ́ Russia.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ́ ni orílẹ̀èdè Russia àti Ukraine ń ṣe láti gba ìlú Bakhmut nínú ogún tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjèèjì.

Ó ti lè ní ọdún kan tí ogun tí n wáyé láàárín orílẹ̀ èdè Ukraine àti Russia.

Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó ń yọ́lẹ̀ dà, ohun abẹ́nú á má a yọ́ wọn ṣe.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Dare Ogundare ti fojú àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún hàn fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Mẹ́rin nínú àwọn afurasí yìí ni wọ́n ní àwọn nawọ́ gán ní agbègbè Òkè Ako ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ogundare tó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti kò ní fi ààyè gba ìwà ọ̀daràn sọ pé, ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí ọ̀hún lọ sí ilé ẹjọ́.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá Ekiti pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi nawọ́ gán àwọn afurasí meji tí orúkọ won ń jẹ́ Abu Hassan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Danger àti Abubakar Sodiq.

Ó ní àwọn afurasí méjéèjì yìí ló jẹ́ ògbóǹtarigì ajínigbé tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Iyemero/Oke-Ako/Irele/Ipao-Ekiti.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ni àwọn tó ti kó sí páḿpẹ́ àwọn afurasí yìí ló dá wọn mọ̀ tí wọ́n sì nawọ́ sí wọn pé àwọn ló jí àwọn gbé.

Ó ní ìbọn tiwa-n-tiwa kan, àti ọta ni àwọn bá lọ́wọ́ wọn lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n. Bákan náà ló ní ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti ṣe àwárí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn mìíràn tó ti sá lọ.

Ó fi kun pé ọwọ́ òfin tún tẹ àwọn afurasí mìíràn, Umar Hassan àti Yusuf Lawal fẹ́sùn wí pé wọ́n yawọ agbègbè Ayenco ní Eda-Ile Ekiti tí wọ́n sì jí obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mary Olajumoke gbé.

Ó ní lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà gba owó ìtúsílẹ̀ ni wọ́n tó tú ọmọbìnrin náà sílẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé àdá méjì àti ₦82,200 tó jẹ́ owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ná kù ni àwọn bá ní ọwọ́ wọn nígbà tí ọwọ́ òfin bà wọ́n. Ó fi kun pé àwọn afurasí yòókù ni ọwọ́ bà fún ìwà ṣíṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn àti olè jíjà.

Iléẹjọ́ da èsì ìdìbò tó gbé ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party wọlé ní Abia nù

Iléẹjọ́ da èsì ìdìbò tó gbé ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party wọlé ní Abia nù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kano, Mohammed Yunusa ti gbégilé èsì ìdìbò tó gbé Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ dìbò yàn ní Abia, Dr Alex Otti wọlé.

Bákan náà ni adájọ́ gbégilé èsì ìdìbò ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Kano àti Abia.

Adájọ́ ní bí wọ́n se dé orí ìwé ìdìbò kò tẹ̀lé òfin ètò ìdìbò ti ọdún 2022.

Ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n fi ìdájọ́ náà ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn.

Nínú ẹjọ́ tí Arákùnrin Ibrahim Haruna Inrahim pè tako ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ati INEC ló ti ní ẹgbẹ́ òṣèlú Labour party kò se ìforúkọsílẹ ní ọdọ INEC láàrin ọgbọ̀n-ọ́n-jọ tí òfin sọ kí wọ́n tó se ìdìbò abẹ́lé.

Ó ní nítorí wọn kò tẹ̀lé òfin náà, ìdìbò tó gbé wọn wọlé kò ní ẹṣẹ̀ nílẹ̀.

Ó ní Labour party kò leè sọ pé òun ní olùdíje nínú ìdìbò náà, nítorí náà wọn kò leè jáwé olúborí.

Adájọ́ ní èyí fihàn pé àwọn ìbò tí kò kẹ́sẹjárí ló gbé Alex Otti wọlé gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn ní ìlú Abia.

Gómìnà Adeleke tú ìgbìmọ aláṣẹ Fásitì Ọ̀ṣun ká

Gómìnà Adeleke tú ìgbìmọ aláṣẹ Fásitì Ọ̀ṣun ká

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sẹ́nétọ̀ Nurudeen Ademọla Adeleke, ti kéde títú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso Fásitì Ọ̀ṣun ká.

Lásìkò Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ ọhún ni wọ́n yan àwọn ìgbìmọ̀ tí Agbẹjọ́rò Àgbà, Yusuf Alli, jẹ́ alága fún ọhún lọ́dún 2006.

Lẹ́yìn tí wọ́n parí sáà àkọ́kọ́ ọlọ́dún márùn-ún ni Gómìnà àná, Alhaji Gboyega Oyetọla, tún tún wọn yàn láti lo sáà mìíràn.

Ṣùgbọ́n nínú àtẹ̀jáde kan ti olórí àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, S. A. Aina, fi síta ló ti sọ pé Gómìnà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ náà fún ifara-ẹni-jìn wọn fún ìdàgbàsókè UNIOSUN.

Ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run túbọ̀ mú wọn ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ìdáwọ́lé wọn.

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Ààrẹ buwọ́lu ìyànsípò olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu ìyànsípò, Oluwatoyin Sakirat Madein gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìyànsípò náà ló jẹ jáde nínú lẹ́tà kan tí olórí òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, Dókítà Folasade Yemi-Esan fi léde.

Ó ní Ààrẹ Buahri ti buwọ́lu ìyànsípò náà.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta ọdún 1965 ni wọ́n bí Oluwatoyin Sakirat ní Iperu Remo, ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ṣaájú ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà, Sakirat ni adarí ẹ̀ka ìsúná ní ọ́fíìsì olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè yìí.

Oluwatoyin Shakirat ló ń gba ipò yìí lọ́wọ́ Ahmed Idris tó jẹ́ olùṣirò owó tẹ́lẹ̀ tí Ààrẹ Buhari ní kó lọ rọ́kún nílé fẹ́sùn wí pé ó kojú ẹ̀sùn pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù 109 náírà.

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kò sí, kóówá ń relé lẹyìn ìnájà ayé dandan ni. Ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ìròyìn gbòde pé olóyè Subomi Balogun tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) jáde láyé.

Ìròyìn sọ pé ní ìlú London, United Kingdom ni bàbá náà dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́. Ó ṣeéṣe kí nífẹ̀ẹ́ àti mọ̀ irúfẹ́ èèkàn iràwọ̀ àwùjọ tí à n perí, gbàyí wò.
Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 1943 ni wọ́n bí olóògbé Subomi Balogun sáyé tó sì pé ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún kó tó dágbẹre fáyé pó di kése.
Ọmọ ìdílé Ọba Tunwase ti Ijebu-Ode ni Subomi Balogun.
Òun ni Otunba Tunwase gbogbo Ijebu, tó sì tún jẹ́ Olori gbogbo ọmọọba Ijebu àti Asiwaju àwọn onígbàgbọ́ ní Ijebu.
Ìdílẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n bi sí kó tó yípadà sí onígbàgbọ́ nígbà tó wà ní ilé ẹkọ girama.
Ilé ẹ̀kọ́ Igbobi College ló ti kẹ́kọ̀ọ́ girama, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí London School of Economics níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kó tó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ kàwé, tó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ nígbà tó padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Ní ọdún 1979 ni ó gba ìwé àṣẹ láti dá ilé ìfowópamọ́ First City Merchant Bank sílẹ̀ tí báǹkì náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1983.
Subomi Balogun dá ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọdé kalẹ̀ ní Ijebu Ode èyí tó fún ile ìwòsàn ńlá UCH tí Ibadan.
Aṣọ funfun ni ó sábà máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà. Olóògbé Subomi Balogun fi ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọọmọ sáyé lọ .
Kín la á sọ nípa tèmi tì ẹ?