Home Blog Page 58

Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí Ọlọ́run bá ti kọ mọ́ ẹ̀dá, dandan ni kó wá sí ìmúṣẹ.
Ṣọun tuntun nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye, Orumagẹgẹ III, ti ní bótilẹ̀ jẹ́ pé òun ti fi iṣẹ́ Pásítọ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ìjọ ìràpadà, RCCG, tó tóbi jùlọ lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, òun ti di Olùṣọ́ Àgùntàn fún gbogbo ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ báyìí.

Ọba Laoye fi ọ̀rọ̀ yìí léde lẹ́yìn tí ó gba ọ̀pá àṣẹ láti ọwọ́ Gómìnà Ṣeyi Makinde níbi ayẹyẹ ìgbọ̀pá àṣẹ tó wáyé ní pápá ìṣeré Ṣọ̀ún ti ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́.

Ó ní Ọba tí òun jẹ kìí ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn Kírísítẹ̀nì nìkan, bíkòṣe Mùsùlùmí, àwọn Ẹlẹ́sìn àbáláyé àti gbogbo ẹni tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan.

Ṣọ̀ún tuntun ní bótiwù kí ẹ̀dá làkàkà tó, Ọlọ́run nìkan ló lè fini jẹ ọba.

Ó pàrọwà sí àwọn tí wọ́n jọ du ipò náà pé kí wọ́n gbaàgbé ọ̀rọ̀ àná, kí wọ́n sì sowọ́pọ̀ láti gbé ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ dé ibi gíga.

Ọba Laoye ní gbogbo ìmọ àti ìrírí tí òun ní nípasẹ̀ iṣẹ́ Pásítọ̀ àti okoòwò nílùú Amẹ́ríkà ni òun yóò papọ̀ láti mú ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ gun òkè àgbà.

Ó ní òun yóó ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìdàgbàsókè ọlọ́dún márùndínlọ́gbọ̀n fún ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ láti di ìlú tó ṣee mú yangàn jù báyìí lọ.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Gọmina Ṣeyi Makinde lóríi bí ó ti fi ọmọnìyàn ṣe láti mú kí ìfẹ́ Olódùmarè ṣẹ lórí ìyànsípò òun gẹ́gẹ́ bíi Ṣọun ìkọkànlélégún nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́

Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìjàngbọ́n kìí bímọ re.
Ilé-ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Òǹdó kan, tó fìlú Àkúrẹ́ ṣe ibùjókòó , ló ti rán àwọn mẹfa kan lẹwọn ọdún méjì fún dída omi àlàáfíà ìlú Ayetoro níjọba ìbílẹ̀ Ìlàjẹ ní ìpínlẹ̀ náà rú.

Àwọn mẹfa náà ni Oluwambe Ojagbohunmi, tó jẹ́ olórí ìjọ The Holy Apostles’ Church, Aiyetoro, tó sì tún pera rẹ̀ ní adarí ìlú náà, Victor Akinluwa, Isaac Ikuyelorimi, Lawrence Lemamu, George Eyekole àti Segun Okenla.

Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà ni ọlọ́pàá mú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní, ọdún 2018 lórí ẹsùn pé àwọn ni wọ́n wà nídìí rògbòdìyàn tó bẹ sílẹ̀ nílùú Ayetoro lé yìí tó fa ìpalára fáwọn kan, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bàjẹ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ igbẹjo, ẹsùn mẹwàá ni agbẹjọro olupẹjo, Babatunde Falodun kà sí wọn lẹsẹ nileẹjọ tó fi mọ́ ìwà ipá, ìdàlúrú, ìdigunjalè àti bíba dúkìá onídúkìá jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí Falodun ṣe wí, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí ló tako àlàkalẹ̀ abala kọkanleaadọtalenirinwo nínú òfin ọdaràn, ìdì kẹtadinlogoji, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà, George Eyekole, ni wọ́n fi ẹsùn ìgbìyànjú láti paniyan kàn nítorí ó yìnbọn mọ́ ọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Olu Obolo, tí eléyìun sì tako àlàkalẹ̀ abala okòólélọ́ọ̀dúnrún nínú òfin ọ̀daràn, ìdì kẹtàdínlógójì, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀daràn náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan wọ́n, ilé-ẹjọ́ dẹ̀bi rù wọ́n lórí mẹ́ta nínú àwọn ẹsùn náà tó níí ṣe pẹ̀lú bíba dúkìá jẹ́.

Nínú ìdájọ́ rẹ̀, Onídájọ́ David Kolawole wí pé àwọn ọ̀daràn náà jẹ̀bi bíba dúkìá onídúkìá jẹ́, ó sì ní kí wọ́n lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára àbí kí wọ́n sanwó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà.

Bákan náà ló ní kí oníkálùkù wọn ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún náírà gẹ́gẹ́ bíi owó gbà má bínú fún àwọn dúkìá tí wọ́n bàjẹ́.

Ẹ̀wẹ̀, Eyekole ni kò níí ní ànfààní láti san owó ìtanràn tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ́ san ní bí adájọ́ tún ṣe fún-un ní ọdún márùn míràn pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára nítorí ìgbìyànjú láti pànìyàn lákòókò làásìgbò náà.

Gbogbo àwọn ọ̀daràn náà ni Onídàájọ́ Kolawole ní kí wọn tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn láti gba àlàáfíà láàyè nínú ìlú náà.

Kolawole fi kún-un pé, àwọn ọdaràn náà ni yóò forí fá ti ìdàrúdàpọ̀ kankan bá tún wáyé nínú ìlú ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n bá sanwó ìtanràn tí wọ́n sì padà sáàrin ìlú, àti pé owó ìtanràn náà ni yóó di dídápadà fún wọn.

Ìjọba Nàìjíríà kéde ẹ̀dínwó 50% lórí owó ọkọ̀ lásìkò ọdún

Ìjọba Nàìjíríà kéde ẹ̀dínwó 50% lórí owó ọkọ̀ lásìkò ọdún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Tinubu ti buwọ́lu adin kù ida aadọta lori iye owo ọkọ ti awọn ọmọ Naijiria to ba rinrinajo lasiko ọdun.

Ètò ẹdinwo náà yóò wáyé láàrin ọjọ́ kọkànlelógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2023, sí ọjọ́ kẹrin, oṣù Kínní, ọdún 2024.

Nínú ìkéde ti olùdámọ̀ràn fún Ààrẹ lórí ètò ìròyìn, Bayo Onanuga, fi síta, wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ rìnrìn àjò fún ọdún, lè bẹrẹ láti ọjọ́ kọkànlelógún, kí wọ́n ò sì san ìlàjì owó tó yẹ kí wọ́n ó san.

Ó nì ìjọba àpapọ̀ ni yóó san ìdá àádọ́ta tó kù fún àwọn iléeṣẹ́ ọkọ̀ tó bá kó èrò.

Bákan náà ni wọ́n lè rìnrìnàjò wọn láì san owó kankan tí wọ́n bá wọ ọkọ̀ rélùwéè lásìkò ọdún.

Nǹkan dé ! Portable ati Pasuma ti di ìṣòro fún ṣọọsi ṣẹ̀lẹ

Nǹkan dé ! Portable ati Pasuma ti di ìṣòro fún ṣọọsi ṣẹ̀lẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Túláàsì ní òhun yóó jókòó, ẹnìkan ní kò sáyè,bíí ṣe igiimú onítọ̀ún…..
Àfi bíi ẹni pé àṣà tí gbajúgbajà òǹkọrin hípọọ̀pù nnì, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, táwọn èèyàn mọ̀ sí Portable olórin , máa ń dá, tó máa ń sọ pé, “wàhálà, wàhálà, wàhálà” ti ṣẹ sí i lára ni, látàrí bí ọkan-o-jọkan awuyewuye ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí ọkùnrin táwọn ọdọ fẹ́ràn orin rẹ̀ náà bá lọ. Tuntun tó ṣẹlẹ̀ báyìí ni awuyeyewu tó ń lọ láàrin àwọn wòlíì àti adarí ṣọọṣi Ṣẹ̀lẹ́, látàrí bí Portable àti Wasiu Alabi Pasuma, Ọganla onífújì, ṣe lọ kọrin níbi ayẹyẹ àṣálẹ́ ìyìn ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún kan. Èyí bi àwọn àgbààgbà ìjọ náà nínú gidigidi.

Ètò ìjọsìn ọ̀hún ti wọ́n pè ní Ankara/Praise Night, ló wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kejìlá yíì, nínú ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ Land of Goshen Cathedral, lágbègbè Ogudu/Ọjọta, l’Ekoo, níbi tí wọ́n ti fìwé pe Portable, tó tún máa ń pe ará ẹ̀ ní Ìdààmú Àdúgbò, àti Pasuma sí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan, àti àwọn adarí ìjọ Ṣẹ̀lẹ́ kan korò ojú sí bí wọ́n ṣe pe àwọn tí kì í ṣe olórin ẹ̀mí síbi ètò ìjọsìn yìí, tí wọ́n sì kìlọ̀ gidigidi fún Portable láti má ṣe yọjú síbi ètò náà, àmọ́ Portable ati Pasuma lọ. Sùtánà Sẹ̀lẹ́ funfun kinniwin ni Portable wọ̀, àwọn méjéèjì sì kọrin gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lóde àríyá, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn náwó fún wọn, táwọn olólùfẹ́ wọ́n sì dárayá gidi.

Èyí ló fa wàhálà báyìí, nítorí ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ àwọn àgbààgbà tí Olùdarí ẹsìn ọhún kan nínú, tí wọn si ti n sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn.

Nínú fídíò kan tó bọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá yìí, Olùdarí ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ kan, Wòlíì Tayọ Ọkẹ, fi àìdùnnú rẹ̀ hàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó ní nǹkan àbùku àti ìtìjú pátápátá gbáà ni báwọn olórin wọ̀nyí ṣe wáá ṣeré ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn, ó ní irú nǹkan báyìí kò wáyé nínú àwọn ìjọ Ọlọ́run tó dé lẹ́yìn Sẹ̀lẹ́, bíi Rìdíìmù, Àpọ́sítólíkì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì mí-ìn.

Iná jólé Alao Akala, ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Iná jólé Alao Akala ní ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní airotẹlẹ ni iná dédé ṣẹ́yọ nínú ọ̀kan lára àwọn ilé tó n bẹ nínú ọgbà Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní ìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóògbé Ọ̀túnba Adebayọ Alao Akala l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

Ọ̀kan lára àwọn olùgbé ilé náà, tí a fi orúkọ bò l’áṣìírí, fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn pé ní nnkan bíi aago méje ààbọ̀ sí mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Olùgbé ilé náà ní, “Iná ẹ̀lẹ́ntíríìkì ló dé lójijì l’ówùúrọ̀ ọjọ́ náà tí ó sì jó ẹni kan. Ẹlòmíràn náà tún fi ara pa.”

Ṣùgbọ́n, ìròyìn kan tí a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sọ pé èèyàn méjì ló kú nínú iná tó jó ọ̀hún .

Bákan náà ni ìròyìn sọ pé obìnrin méjì ló jóna nínú ilé náà, àmọ́ àwọn aláṣẹ kò tíì fìdí èyí múlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí iléṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára “Ogbomoso Insight “ṣe sọ, inú ilé alájà kan ọhún ni Olóògbé Àlàó Akálà gbé títí tó fi di igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 2003.

Nínú oṣù kínní ọdún 2022 ni Ọ̀túnba Adébayọ̀ Àlàó-Akala jáde láyé.

Ó jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrin ọdún 2007 sí 2011

Láti ìgbà tí Gómìnà tẹ́lẹ̀rí náà ti re ibi àgbà n rè gìrìgìrì ẹsẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní ilé náà, kí ó tó di pé iná sọ níbẹ̀ l’ówùúrọ̀ ọjọ́ Ajé.

Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Túláàsì lóhun ó jókòó, ò lóò ráyè.
Iwájú Onídàájọ Abilékọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan tó wà ní Mapo, nílùú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni àwọn tọkọ-taya méjì kan, Ọ̀gbẹ́ni Kazeem Jẹjẹ àti Abilekọ Kafilat Jẹjẹ, gbé ara wọn lọ. Kazeem ló gbé ẹjọ́ ìyàwó rẹ̀ lọ sile-ẹjọ ọ̀hún, nǹkan tó sì ń fẹ́ ni kí adájọ́ tú ìgbéyàwó tó wà láàrin àwọn méjèèjì ká.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Kazeem ti sọ pé, ‘‘Oluwa mi, ẹ̀bẹ̀ kan ṣoṣo ti mo bẹ̀ báyìí ni pé kẹ́ ẹ tú ìgbéyàwó ogún ọdún tó wà láàrin èmi àti ìyàwó mi yìí ká, kẹ́ ẹ sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ wáá bá mi lẹ́nu iṣẹ́ mi mọ́ láti fa wàhálà pẹ̀lú mi. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti sú mi pátápátá, mi ò ṣe mọ́ , kò sífẹ̀ẹ́ láàrin àwa méjèjì mọ́, ojoojúmọ́, ìjà ni nínú ilé. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ní nǹkan bíi ogun ọdún sẹ́yìn ni mo pàdé rẹ̀, gbogbo ìwà rẹ̀ ló tẹ́ mi lọ́rùn pátá, a ṣètò ìdána, bẹ́ẹ̀ ni mo sanwó orí rẹ̀ fáwọn ẹbí rẹ̀. Kò sóhun tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ mi tí mi ò fún wọn. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ rárá tá a fẹ́ra wa sílé tán tí ìyàwó mi yìí bẹ̀rẹ̀ sí í yọwọ́-kọ́wọ́, wàhálà ni lójoojúmọ́, nígbà tó tún yá ló bá tún ń lọ rojọ mi níta pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó lòun kò ṣe rí ọmọ bí látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó.

‘‘ Kò síbi tí mo lè dé báyìí, ṣe làwọn èèyàn á máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, bẹ́ẹ̀ kí í ṣe pé mo lówó lọ́wọ́ ká baà sọ pé lóòótọ́ ni mò lo nǹkan ọmọkùnrin mi fún oògùn owó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti lọ fẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀ nínú ìṣesí rẹ̀. Bí mo gbé igbá nínú ilé, mi ò mọ̀ ọ́n gbé ni, kò sígbà tí má a jáde kúrò nínú ilé, ṣe nìyàwó mi á máa tú gbogbo ẹrù mi láti wò ó bóyá mo lóògùn kan tí mo fi pamọ́ fún un. Nígbà tó yá ni bàbá ìyàwó mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí ń lọ fẹ́yàwó kejì síta. Àmọ̀ràn pàtàkì ọ̀hún ni mo tẹ̀lé tí mo fi lọ fẹ́yàwó mìíràn síta báyìí. Ọlọ́run sì ti ṣe é, ìyàwó ọ̀hún ti bímọ fún mi, èyí tó fihàn gbangba pé irọ nìyàwó mi ń pa mọ́ mi pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó. Ẹ ṣáà bá mi lé e kúrò nínú ilé mi lohun tí mo ń fẹ́ báyìí ’’.

Níwọ̀n ìgbà tí kò sí olùjẹ́jọ́, ìyẹn Abilékọ Kafilat Jẹjẹ, nílé-ẹjọ́, adájọ́ ilé-ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 tó ń bọ̀ yìí.

Bákan náà ló kàn án nípa fáwọn akọ̀wé kóòtù pé kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n fún olùjẹ́jú níwèé ìpẹ̀jọ́, kó lè yọjú sílé-ẹjọ́ lọ́jọ́ tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ máa tún wáyé.

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà ni mo ta orí àti ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ – Akeem

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni bá hùwà kòtọ́, ó di dandan kó fojú winá òfin.
Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ní Eléwéeran, nílùú Abẹokuta, ìpínlẹ̀ Ògùn, ni Ọ̀gbẹ́ni Akeem Usman wà, níbi tó ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe láti lè fọwọ́ òfin mú gbogbo àwọn oníbàárà rẹ̀ gbogbo tó ń ta àwọn ẹ̀yà ara òkú fún, ní pàtàkì , ti ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University’ (OAU) kan, Olóògbé Quadry Salami, tó dẹ́mìí rẹ̀ lẹ́gbòodò láìpẹ̀ yìí, tó sì ta àwọn ibi pàtàkì ẹ̀yà ara rẹ̀ fáwọn oníṣẹ́ ibi kan.

Ohun tí a gbọ́ ni pé Alàgbà Salami tí i ṣe bàbá Quadry ló lọ fẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá agbègbè Kenta, nílùú Abẹokuta, lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2023 yìí, pé òun ń wá ọmọ òun, Quadry, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọkọ́ 100 level nílé -ẹ̀kọ́ ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University,’ (OAU). Bàbá náà ṣàlàyé fáwọn ọlọ́pàá pé láti ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí lòun ti fojú kàn án gbẹyin, ó lóun pe gbogbo fóònù rẹ̀, kò lọ, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, S.P Ọmọlọla Odutọla, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ kẹfà, oṣù Kejìlá, sọ pé fúnra ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn, C.P Abiọdun Alamutu, ló ṣaájú ikọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ agbègbè ‘Mile 6’, tó wà nílùú Ajebọ, láti lọ fọwọ́ òfin mú Akeem Usman, lẹ́yìn ti òhun tí wọ́n fi n wá fóònù olóògbé náà tọ́ka sí i pé ọwọ́ rẹ̀ ló wà. Wọ́n gbá a mú, ó sì mú wọn lọ síbi tó sìnkú olóògbé náà sí.

Akeem yìí ló tọ́ka sí oníṣèègùn kan, Ọ̀gbẹ́ni Ifadowo Niyi, tó pé ní ọ̀rẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ló jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pín ẹ̀yà ara olóògbé náà fún òògùn owó.

Alukoro ní, ‘‘Akeem ti jẹ́wọ́ fáwọn ọlọ́pàá, ohun tó sọ ni pé òun pẹ̀lú Ifadowo làwọn jọ pa olóògbé náà, táwọn sì pín ẹ̀yà ara rẹ̀, orí olóògbé náà àti ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ni Ifadowo kó lọ, ó sì san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún Náírà sínú àkáùǹtì Akeem.

‘‘Lẹ́yìn náà ni Akeem ń ta àwọn ẹ̀yà ara olóògbé náà lẹ́yọkọ̀ọ̀kan fáwọn èèyàn tó nílò rẹ̀ láti fi ṣòògùn Àwúre. Lópin ohun gbogbo, Akeem lọ ri ìyókù mọ́lẹ̀ nígbà tí kò wúlò fún un mọ́.

‘‘ Kódà àwọn méjèèjì ti tún jẹwọ́ fáwọn ọlọ́pàá pé kì í ṣe olóògbé yìí làwọn kọ́kọ́ pa, wọ́n ní àwọn ti fìgbà kan pa àwọn mẹ́rin kan sẹ́yìn, táwọn sì ti forí wọn ṣètùtù Oṣólẹ̀’’.

Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alukoro ní ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ní ìpínlẹ̀ Ògùn tí lóun kò ní í fojú tó dáa wo àwọn ọ̀daràn gbogbo tí wọ́n fẹ́ sọ ìpínlẹ̀ Ògùn di ibùgbé wọn, àfi kí wọ́n fi agbègbè ọhún sílẹ̀ ní kíá.

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama mẹ́fà rí ẹ̀wọ̀n he

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama mẹ́fà rí ẹ̀wọ̀n he

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé,ẹni bá ṣe ohun tẹ́nìkan ò ṣe rí, kò sí n tó burú, bí ojú u rẹ̀ bá rí n tẹ́nìkan ò rí. Àsamọ̀ yìí ló lọ pẹ̀lú bí à Nlwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú olùkọ́ wọn kan ní orílẹ̀ èdè France ti rí ẹ̀wọ̀n he.

Ní ọdún 2020 ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní orílẹ̀ èdè France níbi tí àwọn kan ti gé orí olùkọ́, Samuel Paty fẹ́sùn wí pé ó fi àwòrán ẹ̀fẹ̀ Ànọ́bì hàn ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ní ìwájú ilé ẹ̀kọ́ tó ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni wọ́n pa Paty sí.

Ilé ẹjọ́ ní ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ̀bi pé ó parọ́ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní kíláàsì gan-an, tí wọ́n sì ní àwọn yòókù jẹ̀bi ẹ̀sùn pé wọ́n tọ́ka Paty sí ẹni tó pa á.

Ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́rìnlá sí ọdún méjì ni ilé ẹjọ́ dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó jẹ́ obìnrin ni wọ́n ní ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé Paty lé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ mùsùlùmí kúrò ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kó tó fi àwòrán náà hàn.

Àmọ́ ìwádìí ní ọmọbìnrin náà kò sí ní kíláàsì lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí ilé ẹjọ́ sì ní ó jẹ̀bi irọ́ pípa àti pé ó sọ àwọn nǹkan tó da omi àláfíà rú.

Àwọm márùn-ún yòókù, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí mẹ́ẹ̀dógún lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ni ilé ẹjọ́ ní wọ́n jẹ̀bi pé wọ́n fi olùkọ́ náà sínú ewu.

Ẹni tó ṣekúpa olùkọ́ náà, Abdoullakh Anzorov, ọmọ ọdún méjìdínlógún ni àwọn ọlọ́pàá yìbọn pa lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Sáà kejì mi yìí , iná mọ̀nàmọ́ná yóó dúróore – Dapo Abiodun

Sáàkejì mi yìí , iná mọ̀nàmọ́ná yóó dúróore – Dapo Abiodun

Fẹmi Akinsola

Sé wọ́n ní ohun tó bá n dunni,n náà ní-ín pọ̀lọ́rọ̀ ẹni. Gómìnà Dapo Abiodun ti ìpínlẹ̀ Ògùn ti ní òun yóó sa akitiyan láti ríi pé ìṣòro iná mọ̀nàmọ́ná dópin kí òun tó kúrò ní ìṣèjọba gẹ́gẹ́ bí i Gómìnà.

Abiodun, ẹni tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kéde pé òun ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Gómìnà tó kọjá, sọ fún iléeṣẹ́ Channels TV pé òun ṣetán láti se ju bí òun sese tẹ́lẹ̀ lọ ní ìpínlẹ̀.

“Èròngbà mi fún ọdún mẹ́rin sáà kejì yìí ni láti rí i pé iná mọ̀nàmọ́ná kò sẹ́jú mọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun kí ń tó kúrò ní ìṣèjọba.”

Gẹ́gẹ́ bí ó se ṣàlàyé ó ní ìjọba òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní má a tún àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ṣe fún ìgbáládùn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ káàkiri ìpínlẹ̀.

“Ó tó ẹgbẹ̀rún kan ilé ẹ̀kọ́ tí a ti tún kọ́, tí a dẹ̀ tún se àtúnṣe sí wọn láàrin ọdún mẹ́rin.”

Ó fikún pé ìṣèjọba òun ti ṣe àtúnṣe àwọn ojú pópónà, kíkọ́ ilé ìwòsàn àti pípèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́.

Bákan náà Gómìnà tún fi ogun rẹ̀ gbárí pé ìpínlẹ̀ Ògùn lè dá dúró láì gba owó lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ nítorí bí ọrọ̀ ajé ṣe ń gbòòrò si ní ìpínlẹ̀ náà.

“Ó dá mi lójú pé ẹ mọ̀ pé ìpínlẹ̀ Ògùn ló ń léwájú nínu àwọn ohun àmúṣajé wọn.

Ìjọba àpapọ̀ kọ̀ faramọ́ bówó gáàsì ìdáná ṣe gbẹ́nu ókè

Ìjọba àpapọ̀ kọ̀ faramọ́ bówó gáàsì ìdáná ṣe
gbẹ́nu ókè

Fẹmi Akinṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ti kọminú lórí owó gọbọi tí aráàlú ń ra gáàsì ìdáná, léyì í tó ti mú kí wọ́n gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti ṣètò bí owó orí gáàsì ìdáná yóò fi wálẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan ti kò sì níí sí ìdíwọ́ fún ìpèsè rẹ̀.

Mínísítà abẹ́lé fọ́rọ̀ epo rọ̀bì (tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ gáàsì), Ekperikpe Ekpo, n ló ti dá sí àwọn ìpèníjà tó ń dojú kọ ìpèsè gáàsì náà àti oye tí wọ́n n tà á nígboro.

Olùrànlọ́wọ́ lórí ètò ìròyìn fún Mínísítà ọ̀ún, Louis Ibah, n lo wí pé bí owó kílò gáàsì kan ṣe fò sókè láti ẹẹdẹgbẹrin náírà sí ẹẹdẹgbẹrun náírà bí oye tó kéré jù láwọn agbègbè kan ló mú kí Mínísítà náà ó dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Ìròyìn fi yé ni pé owó orí kílò kan gáàsì ti ń rá bàbà láàrin ẹgbẹ̀fà náírà sókè láwọn agbègbè kan.

Ibah ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde tó fi síta pé, lára àwọn kókó tó mú kí owó gáàsì ìdáná ó gbẹ́nusókè ni ọwọ́n gógó dọ́là àti bí àwọn tó n ta gáàsì nígboro kò ṣe ríi gbà tó látọwọ́ àwọn tó n pèsè rẹ̀.

Àwọn lọ́gàálọ́gàá níléeṣèẹ́ ìwapo bíi Chevron, NMDPRA àti NNPCL ló péjú síbi ìpàdé tí Mínísítà náà pè ní olú iléeṣẹ́ àjọ NNPC l’Abuja.

Mínísítà náà tó wòye pé Nàìjíríà ní ànító àti àníṣẹ́kù àlùmọ́ọ́nì gáàsì wí pé bí àwọn iléeṣẹ́ ìwakùsà gáàsì àti epo rọ̀bì ṣe mú ṣíṣu gáàsì lóṣùká lọ òkè-òkun láì ṣe ìpèsè tí yóò kájú lílò rẹ̀ nílẹ̀ yí ni kò bójú mu tó.

Èyí ló mú kí Mínísítà náà ó gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí ọ̀gá-àgbà iléeṣẹ́ NMDPRA, Farouk Ahmed, yóó jẹ́ Alága rẹ̀, láti wo sàkun bí ìpèsè gáàsì lọ́pọ́ yanturu láàrin ìlú yóó ṣe wáyé láàrin ọ̀sẹ̀ kan tí owó rẹ̀ yóó sì wálẹ̀ dáadáa.