Home Blog Page 55

Ààrẹ Tinubu yóò rìnrìnàjò lọ Paris fún ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé

Ààrẹ Tinubu yóò rìnrìnàjò lọ Paris fún ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bọla Tinubu yóó darapọ̀ mọ́ àwọn adarí orílẹ-èdè lágbàáyé láti kópa níbi ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé, Global Financial Pact ti yóò wáyé ní ìlú Paris lórílẹ̀ èdè France.

Àtẹ̀jáde kan láti ilé iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ṣàlàyé pé Tinubu pẹ̀lú àwọn Ààrẹ yòókù lágbàáyé yóò péjú lọ́jọ́bọ ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹfà láti jíròrò lórí àdéhùn ìrànwọ́ ìṣúná fún àwọn orílẹ-èdè tó ku díè káàtó fún.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí yóó jàńàní ìṣúná tó bá jáde lábẹ́ àdéhùn náà làwọn orílẹ-èdè ti wàhálà ọ̀rọ̀ àyíká, wàhálà nǹkan àmú ṣágbára àti àtúnbọ̀tán àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 bá fínra.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ààrẹ Tinubu yóò máa rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ òkèèrè láti ìgbà tí ó ti gun orí àga Ààrẹ orílẹ-èdè Nàìjíríà lóṣù kàrún un.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé wọ́n fẹ́ da ilé wo nínú ọjà Alaba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ará ilé ẹni bá ń jẹ kòkòrò tí kò dáa, tí a kò bá sọ fún un, hẹ̀rẹ̀hùrù rẹ̀ kò ní-ín jẹ á fojú lóorun.
Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LASBCA), Gbolahan Oki ló fi ìkéde náà síta nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sínú ọjà náà lọ́jọ́ Ẹtì.

Oki ní láti ọdún 2016 ni àwọn ti ń ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ilé náà, tí àwọn sì ti ń ṣe àmì si wí pé àwọn máa wó wọn àti pé àbẹ̀wò òun náà wáyé láti sọ fún àwọn tó ń gbébẹ̀ láti kó kúrò lẹ́yẹ ò sọkà.

Èyí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa pòkìkí ọjà Alaba, níbi tí wọ́n ti máa ń ta ohun èlò ilé bíi ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, fírìjì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lórí ayélujára.

Àwọn ẹ̀yà Igbo ló pọ̀ tí wọ́n ń ta ọjà nínú Alaba tí àwọn kan sì ń sọ wí pé nítorí à ti gbẹ̀san ohun tó wáyé ní Eko lásìkò ìbò tó kọjá ló fa ìgbésẹ̀ ìjọba yìí.
Ẹ̀wẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oki ní láti ọdún 2016, 2020, 2022 títí di ọdún yìí ni àwọn ti ń fún àwọn ènìyàn tó ni àwọn ilé náà ni ìwé pé kí wọ́n kúrò níbẹ̀.

Ó ní àkíyèsí ọdún méje náà tó láti fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀ láti kúrò àmọ́ dípò kí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ìkìlọ̀ níṣe ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tí wan bá ti dé ibẹ̀.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ilé náà kò bá wà lára àwọn ilé 349 tí àwọn fi léde ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí pé àwọn fẹ́ wó àmọ́ nítorí àwọn kìí ríbi ṣe iṣẹ́ àwọn tí àwọn bá dé ibẹ̀ nítorí ìkọlù tí wọ́n máa ń ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn kò jẹ́ kí àwọn le fi wọ́n sínú rẹ̀.

“Ohun tí à ń ṣe báyìí ni láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ “Task Force” Eko láti lè ri wí pé á ri àwọn ilé náà wó palẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.

“Ó pọn dandan fún wa láti wó àwọn ilé náà báyìí nítorí wọ́n ti di ẹgẹrẹ mìtì, tí wọ́n sì lè ṣe àkóbá fún àwọn ilé mìíràn tó wà ní agbègbè wọn àti àwọn tó ń ta ọjà níbẹ̀ pàápàá.”

Ó fi kun pé ìjọba yóò tẹ̀síwájú láti máa pàtàkì ẹ̀mí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láì fi ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe, kí ìgbé ayé le rọrùn fún mùtúmùwà.

 

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta ọjà nínú Alaba International Market, Theo Ezeani sọ fún akọ̀ròyìn pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ń gbọ́ pé ìjọba fẹ́ wó àwọn ilé kan nínú ọjà náà.

Ezeani ní àwọn kò rí ìwé ìkìlọ̀ kankan láti ọdún 2016 èyí tí ìjọba ní àwọn fi ṣọwọ́.

Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ kò mọ̀ nípa ìwé tí ìjoba ní àwọn ti ń kó ránṣẹ́ tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun nítorí ó ti pẹ́ tí òun ti wà nínú ọjà náà.

“Kò sí pigbà kankan tí a sọ ohun tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìpàdé wa, àwọn tí a gba ipò lọ́wọ́ wọn náà kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ fún wa, lórí amòhúnmáwòrán ni mo ti kọ́kọ́ rí ìròyìn náà lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì. ”

Ezeani ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn tó ni ilé gangan ni ìjọba kọ̀wé ránṣẹ́ sí àmọ́ àwọn tí àwọn ń ta ọjà níbẹ̀ kò gbọ́ nǹkankan.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́jà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ẹrù wọn kúrò níbẹ̀ nítorí ohun tí àwọn gbọ́ ni pé ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndílógún, oṣù Kẹfà ni ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwó àwọn ilé náà.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rọ Russia àti Ukraine láti jógun ó mí

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí ọrọ ńlá kò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín tíì sinmi àròyé.
Ààrẹ orílẹ̀ èdè South Africa, Cyril Ramaphosa ti rọ Ààrẹ Russia, Vladimir Putin láti fòpin sí ogun tó ń gbé ti Ukraine.

Ramaphosa pàrọwà yìí nígbà tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú Putin ní St Peterburg lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ààrẹ South Africa ọ̀hún àtàwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ adúláwọ̀ mẹ́fà mìíràn ni wọ́n ṣe àbẹ̀wò lọ sí Russia àti Ukraine láti lọ bẹ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti dáwọ́ ogun dúró.

Ṣáájú ni Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky sọ fún àwọn ikọ̀ náà lọ́jọ́ Ẹtì pé òun kò ní bá Putin jíròrò nígbà tó bá ṣì gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ àwọn.

Putin náà sọ fún àwọn adarí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà pé Ukraine kọ̀ láti jíròr]o pẹ̀lú òun.
Ramaphosa tún rọ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì láti tú àwọn ènìyàn wọn tí wọ́n fi sí àhámọ́ sílẹ̀ àti pé kí Russia dá àwọn ọmọdé tó kó lórí ilẹ̀ Ukraine padà sílé wọn.

Àmọ́ Putin fèsì padà pé Russia ń dá ààbò bo àwọn ọmọdé náà lọ́wọ́ ogun ni.

Ó ní àwọn kó àwọn ọmọ náà kúrò ní ibi tí pgun ti ń wáyé láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti ìlera wón ni.

Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ tọ ń rí sí ìwà ọ̀daràn ní àgbáyé ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ogun kan Russia lórí bó ṣe kó àwọn ọmọ náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹebí wọn.

Wọ́n ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Russia fi tipátipá kó àwọn ọmọdé ilẹ̀ Ukraine lọ sí Russia lọ́nà àìtọ́.

Ramaphosa tẹmpẹlẹmọ pe ipa tí ogun náà ń ní lórí àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò kéré rárá tó sì gbọdọ̀ wá sí òpin láìpẹ́.

Ó ní ogun ti ṣokùnfà ìdènà gbígbé oúnjẹ oní wóóró láti ilẹ̀ Ukraine àti ajílẹ̀ láti Russia wọ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ èyí tó ti ń fa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ.

“Ogun kò lè máa lọ títí láé, ó yẹ kí gbogbo igun wá ọ̀nà láti fòpin sí ogun yìí, a sì wá láti sọ fún-un yín pé ogun tó ń wáyé yìí kò tẹ́ wa lọ́rùn.

Àmọ́ Putin ní kìí ṣe ogun tó ń wáyé náà ló jẹ́ kí gbígbé àwọn oúnjẹ wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ dáwọ́ dúró àti pé òun kan sáárá sáwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà fún akitiyan wọn.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lọ síbi ìpẹ̀tù sááwọ̀ náà South Africa, Egypt, Senegal, Congo-Brazzaville, Comoros, Zambia àti Uganda.

Àwọn alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà

Àwọn alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olè kò ní-ín jà gbà, kó má ṣe é lójú fìrí,
amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbà fún Gómìnà Akeredolu lórí ọrọ̀ àkànṣe iṣẹ́, Ọmọwe Doyin Ọdẹbọwale ti bu ẹnu àtẹ lu àwọn olóṣèlú kan tó ní wọ́n ń ṣe ìpàdé bonkẹlẹ kiri láti fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lólè

Ọmọwe Ọdẹbọwale nínú atẹjade kan èyí tó fi síta ṣàlàyé pé àwọn olóṣèlú kan ní ìpínlẹ̀ Ondo ń lo àìsíńlé ologini Gómìnà Akeredolu láti fi sọ araa wọn di èkúté ilé tó fẹ́ ti ẹnu bọ aṣuwọn ìpínlẹ̀ náà,

Ó ní ọgbọn tí àwọn olóṣèlú ọhún ń dá ni láti dá iná èdè àìyédè sílẹ̀ láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan lọnà àti leè fi gba àkóso agbára ní ìpínlẹ̀ náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ OAU kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ OAU kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Treasure Salako.

Ní ọjọ́rú ni ìròyìn ní wọ́n bá òkú Treasure ní ilé àkọ́kù kan ní agbègbè Lagere, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun.

Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n bá ìgò ogun apẹ̀fọn sniper ní ẹ̀gbẹ́ òkú ọmọbìnrin náà tí ọ̀pọ̀ sì ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

Àmọ́ agbenusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola nígbà tó ń bá iléeṣẹ́ PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú ọmọbìnrin náà.

Opalola ní àwọn ti gbé òkú Treasure sí ilé ìgbókùúpamọ́sí tí ilé ìwòsàn olùkọ́ni OAUTH, Ile Ife.

Ó ní nítorí àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà ni wọ́n fi ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú náà láti le fìdí ohun tó gba ẹ̀mí Treasure.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn nǹkan tó bá yẹ kí àwọn ṣe ni àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, alukoro OAU, Abiodun Olanrewaju ní kìí ṣe inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé tó sì bá àwọn òbí ọmọbìnrin náà kẹ́dùn lórí àdánù ńlá náà.

Olanrewaju ní ikú Treasure kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà nínú rárá.

Bákan náà ló rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù àti àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti máa ṣe àmójútó ara wọn, kí wọ́n sì máa wòye ẹni tó bá wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn dáradára.

Ó fi kun pé nǹkan tí àwọn gbọ́ ni pé ọmọbìnrin náà ń la àwọn ìdojúkọ kan kọjá èyí tó fa ìporúru ọkàn fún un bóyá nítorí náà ló ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ̀.

Ó ní “a bá àwọn òbí Treasure kẹ́dùn, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni gbé irú ìgbésẹ̀ yìí bí ó ti wù kí nǹkan tí onítọ̀hún bá ń là kọjá ṣe lè lágbára tó.”

Abdulrasheed Bawa wà ní àhámọ́ DSS fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò

Abdulrasheed Bawa wà ní àhámọ́ DSS fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí ọrọ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Alága àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu, EFCC, Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìyẹn DSS.

Lẹ́yìn tí Ààrẹ Tinubu fọwọ́ òsì ilé júwe fún Bawa ni DSS ránṣẹ́ pè é láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.

Ìròyìn ní alẹ́ pátápátá lọ́jọ́rú ni Bawa balẹ̀ sí àgọ́ àwọn DSS náà.

Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya, nínú àtẹ̀jáde kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bawa ti wà ní àhámọ́ àjọ àwọn.

Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ti ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Bawa lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

“DSS ti ránṣẹ́ pé alága EFCC tí Ààrẹ ní kó lọ rọ́kún nílé.”

“Bawa ti wà ní àgọ́ wa báyìí, àwọn nnkan tí a torí rẹ̀ pe Bawa kò ṣẹ̀yìn àwọn ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ nípa rẹ̀.” Afunanya sọ nínú àtẹ̀jáde náà.

Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn EFCC, Abdulrasheed Bawa.

Tinubu ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé fún àìní gbèdéke ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ààrẹ ní nítorí à ti fún àwọn tó ń ṣe ìwádìí Bawa láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni òun fi ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lọ́kan-ò-jọ̀kan, èyí tó lágbára kan Bawa.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbenusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní Ààrẹ ní kí Bawa kó gbogbo àkóso àjọ náà lé adarí ètò gbogbo lọ́wọ́ títí tí wọ́n máa fi parí ìwádìí Bawa.
Abdulrasheed Bawa ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí wọ́n máa yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC láti ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀ lọ́dún 2003.

Ọmọ ogójì ọdún ni Bawa wà nígbà tó fi máa gba ipò náà nínú oṣù Keje ọdún 2020 lẹ́yìn tí Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari yọ Ibrahim Magu lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.

Láti ọdún 2005 ni Bawa ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ́físà ní EFCC.

Òun ni ó ṣe ìwádìí ẹ̀sùn màkàrúrù owó tabua tí wọ́n fi kan Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ epo rọ̀bì, Diezani Alison-Madueke.

Ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, kó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti òṣìṣẹ́ yóò máa wọkọ ọfẹ ní Kwara—-Gómìnà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti òṣìṣẹ́ yóò máa wọkọ ọfẹ ní Kwara—-Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní ọmọ onílù ú kò níín fẹ kó tú ,láti mú kí irọrun dé bá àwọn aráàlú, pàápàá jù lọ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe gbowó lórí nítorí owó ìrànwọ́ epo tí wọ́n yọ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulraman AbdulRazaq, ti sọ pé láti Ọjọ́, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹfà, ọdún 2023 yìí, ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga níìpínlẹ̀ náà, pàápàá jù lọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì wọn, Kwara State University (KWASU), àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láwọn ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún yóó bẹ̀rẹ̀ sí i máa wọkọ̀ ọ̀fẹ́ lọ síbi iṣẹ́ wọn láàrin inú ìlú Ìlọrin àti gbogbo àgbègbè rẹ̀.

Lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹfà, ọdún yìí, ni AbdulRazaq fi àtẹ̀jáde yìí léde fáwọn oníròyìn látọwọ́ Akọ̀wé ìròyìn rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Rafiu Ajakaye.

Nínú àtẹ̀jáde náà ni Gómìnà ti sọ pé láti Ọjọ́rú, ìjọba yóò kó àwọn bọ́ọ̀sì nlá sáwọn ààyè kan nílùú Ìlọrin, tí yóó máa kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ wọn lọ́ fẹ̀ẹ́ fún ìrọ̀rùn lílọ bíbọ̀ wọn. AbdulRazaq tẹ̀síwájú pé gbogbo ọ̀nà ni òun yóó sán láti rí i pé ìrọ̀rùn dé bá àwọn òṣìṣẹ́ àti gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Kwara lápapọ̀, tí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà yóò sì máa rúgọ́gọ́ sí i. Ó fi kún un pé láìpẹ́, àwọn adarí iléeṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà yóò máa sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ètò yìí kan náà.

Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi —Mimiko

Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi…..
—Mimiko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ ,wọ́n ní èèyàn tó wẹjú lẹ̀rù ń bà.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ondo, Olusegun Mimiko ti ṣèkìlọ̀ pé pẹ̀lú bí àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ ilẹ̀ òkèrè le padà ṣe àkóbá ńlá fún ẹ̀ka ètò ìlera orílẹ̀ èdè yìí.

Mimiko sàsọyán rẹ̀ pé, tí Nàìjíríà kò bá tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ àwọn dókítà tó ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ ní lemọ́lemọ́ yìí, ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà bọ́ sódì tó bá máa fi tó ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí àsìkò yìí.

Ó ní ó ṣeni láàánú pé ìjọba ń fi owó kún owó ẹ̀kọ́ àwọn dókítà yìí, síbẹ̀ ní kété tí wọ́n bá ti gba ìwé ẹ̀rí wọn ni wọ́n ń mórílé ilẹ̀ òkèrè.

Níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àkọ́kọ́ àwọn dókítà ilé ẹ̀kọ́ giga University of Medical Sciences, UNIMED tó wà ní ìlú Ondo, ìpínlẹ̀ Ondo ni Mimiko ti sọ̀rọ̀ yìí.

Ó ní òun ṣe àgbékalẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà, lójúnà àti sàmójútó bí kò ṣe sí àwọn tó gbero iru nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gomìnà tẹ́lẹ̀ rí náà rọ ìjọba láti tètè dìde sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí kìí ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

Bákan náà ló fi kun pé ìjọba nílò láti máa ṣe kóríyá fún àwọn dókítà kí wọ́n yé fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ mọ́.

Ó tẹ̀síwájú pé tí ìjọba bá ń pèsè àwọn ohun tó le fa kóríyá fún àwọn dókítà yìí, wọn ò ní máa wá ilẹ̀ ọlọ́ràá lọ sí ilẹ̀ òkèrè mọ́.

Mimiko ní ìjáfàra léwu lórí ọ̀rọ̀ náà nítorí bí a kò bá ṣọ́ra, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn babaláwo ni àwọn aláìsàn yóò máa wá ìtọ́jú lọ tó bá yá.

Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀

Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí n tó níbẹ̀rẹ̀ tí kìí lópin, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti pàṣẹ fún Gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà (CBN), Godwin Emefiele pé kó lọ rọọ́kún nílé náà.

Àṣẹ Ààrẹ Tinubu farahàn nínú àtẹ̀jáde kan tí ọfíísì akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fi síta lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì.

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé, Ààrẹ gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí ìwádìí tó ń lọ lọwọ́ lọ́fíìsì Gómìnà báńkì àpapọ ọ̀hún àti àwọn àtúntò tó fẹ́ wáyé lórí ẹ̀ka ìṣúná lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

“ Ààrẹ Bọla Tinubu ti pàṣẹ fún Gómìnà Banki àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele CFR pé kó lọ rọọ́kún nílé lẹ́yẹ ò ṣọkà.

“ Èyí ń wáyé nítorí ìwádìí tó ń lọ lówó lórí ọfíísì rẹ̀ àti àtúntò ẹ̀ka ìṣúná tí ìjọba ń gbèrò láti ṣe.”