Home Blog Page 52

Olè tú àwọn iná ibi tí bàálù ń balẹ̀ sí ní pápákọ̀ òfurufú Èkó

Olè tú àwọn iná ibi tí bàálù ń balẹ̀ sí ní pápákọ̀ òfurufú Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn olè ti jí àwọn iná ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó wà ní papakọ ọkọ̀ òfurufú Murtala Muhammed nílùú Èkó.

Èyí wáyé lẹyìn oṣù díẹ̀ tí wọ́n ṣe àwọn iná náà síbẹ̀.

Àwọn aláṣẹ ní papakọ náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yii múlẹ̀ fún akọroyin.

Àwọn iná tí wọ́n jí ló má a ń ran àwọn awakọ̀ ọkọ̀ òfurufú lọwọ́ láti gbé bàálù fò tàbí balẹ̀ ní alẹ́, òru tàbí tí kùrukùru bá wà.

Kò sí ẹni tó mọ pàtó ìgbà tí wọ́n jí àwọn iná náà.

Ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ sọ pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti mú àwọn tó jí wọn.

Oṣù Kọkànlá, ọdún tó kọjá ni wọ́n fi àwọn iná ọ̀hún síbẹ̀ nítorí pé àìsì wọn n ṣe ìpalára fún ìgbòkègbodò ọkọ òfurufú.

Ẹ gbé Emefiele wá láàrín ọ̀sẹ̀ kan tàbí kẹ́ẹ fi sílẹ̀ – Ilé ẹjọ́ pà ṣẹ fún DSS

Ẹ gbé Emefiele wá láàrín ọ̀sẹ̀ kan tàbí kẹ́ẹ fi sílẹ̀ – Ilé ẹjọ́ pà ṣẹ fún DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní ìlú Abuja ti pàṣẹ pé kí wọ́n fi Gómìnà ilé ifowopamọ tó ga jùlọ tí ìjọba ní kó lọ rọọkun nílé, Godwin Emefiele sílẹ kó máa lọ ní àlàfíà.

Èyí wáyé ní ilé ẹjọ́ lónìí gẹ́gẹ́ bí agbẹjọro fún Emefiele àti agbẹjọro ti ìjọba ‘se jọ ń takurọsọ.

Agbejoro ti ìjọba ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Godwin Emefele jẹ́ àwọn ẹ̀sùn ọ̀daràn.

Ní ti Agbẹjọro fún Godwin Emefele, ó tako bí wọ́n ṣe mú Godwin Emefele to jẹ́ gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà lòdì sí òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

“Bí wọ́n ṣe fi páńpẹ́ òfin mú oníbarà mi, Emefele gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn kò bójú mú àti pé ó lọ́wọ́ òsèlú nínú.”

Torí náà, agbẹjọro fún Godwin Emefele tún ní gbogbo ẹjọ́ ti wón fi kan Godwin Emefele kò lẹsẹ nílẹ̀.

Ààrẹ Tinubu buwọ́lu àwọn èèyàn mìíràn tí yóó jọ tukọ̀ ìlú

Ààrẹ Tinubu buwọ́lu àwọn èèyàn mìíràn tí yóó jọ tukọ̀ ìlú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọ́lu ìyànsípò ogún ènìyàn mìíràn tí yóò máa ba ṣiṣẹ́ nínú ìjọba rẹ̀.

Àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àti àwọn ayàwòrán wà lára àwọn ìyànsípò tuntun náà.

Lára àwọn tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu ìyànsípò ni Tunde Rahman tó jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn tí Tinubu yàn sípò olùrànlọ́wọ́ lórí ètò ìròyìn.

Bákan náà ló tún yan Abdulaziz Abdulaziz àti Ibrahim Masari.

Ìròyìn ní Ààrẹ ti fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ìwé láti wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Ìyànsípò yìí ni ìkẹta gbòógì irú rẹ̀ tí Ààrẹ Tinubu ń ṣe lẹ́yìn tí wọ́n búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún.

Ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹfà ló yan akọ̀wé ìjọba, olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba àti igbákejì rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ló yan àwọn olùbádámọ̀ràn mẹ́jọ àtàwọn olórí Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà
Àwọn mìíràn tí Tinubu tún buwọ́lu ìyànsípò àti ipò wọn ni:

Adekunle Tinubu, Damilotun Aderemi,Toyin Subair, O’tega Ogra,Demola Oshodi,Tope Ajayi,Yetunde Sekoni
Motunrayo Jinadu,Segun Dada,Paul Adekanye
Friday Soton,Shitta-Bey Akande,Nosa Asemota
Kamal Yusuf,Wale Fadairo,Sunday Moses
Taiwo Okanlawon.

Kìí ṣe nítorí Yari kọ̀ láti gbé ìpè Tinubu là ṣe ránṣẹ́ pè é – DSS

Kìí ṣe nítorí Yari kọ̀ láti gbé ìpè Tinubu là ṣe ránṣẹ́ pè é – DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ẹ̀là lọ̀rọ̀, bí a kò bá làá, kìí yéni. Iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS ti jiyàn ìròyìn pé àwọn ránṣẹ́ pé aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn iwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Zamfara nílé aṣòfin àgbà, Abdulaziz Yari nítorí pé ó kọ̀ láti gbé ìpè Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Afunanya kò sọ ìdí tí àjọ náà fi fọ̀rọ̀ wá Yari lẹ́nu wò, irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ látọwọ́ Iléeṣẹ́ ìròyìn ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń tàbùkù iṣẹ́ ìròyìn.

Ó ní ohun tó dájú ni pé Yari, tó ti fìgbà kan jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Zamfara fúnra rẹ̀ mọ ìdí tí àwọn fi ránṣẹ́ pé òun.

Ó ṣàlàyé pé tí àjọ àwọn bá nílò láti ránṣẹ́ pé ẹnìkan tàbí fi èèyàn kan sí àhámọ́ àwọn kò ní kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ níwọ̀nba ìgbà tí àwọn bá ti tẹ̀lé ìlànà tí òfin là kalẹ̀.

Bákan náà ni Afunanya tún jiyàn àwọn ìròyìn pé àwọn lọ yawọ ọ́fíìsì àjọ ICPC àti CCB tí àwọn sì kó àwọn fáìlì níbẹ̀.

Afunanya fi kun pé láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, àwọn kò lọ sí ICPC tàbí CCB láti lọ kó fáìlì kankan.

Ó ní ìròyìn elẹ́jẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ tó sì rọ àwọn akọ̀ròyìn láti máa ṣe ìwádìí wọn dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn.

Ó fẹnu ọ̀rọ̀ tì pé Iléeṣẹ́ àwọn kò ní jẹ́ kí ìròyìn elẹ́jẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn láti ṣe ojúṣe àwọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Àwọn agbébọn palẹ̀ alága ẹgbẹ́ APC Èkìtì mọ́

Àwọn agbébọn palẹ̀ alága ẹgbẹ́ APC Èkìtì mọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ádùrá ni kí Ọlọ́run máa fi ìṣọ́ Rẹ̀ sọ́ wa lọ́wọ́ àwọn èèyàn búburú.Sùgbọ́n kò jọ pé ádùrá yìí gbà fún ẹni tí ṣe Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Paul Omotosho bí ó se kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé.

Ìròyìn ní òpópónà Agbado-Imesi- Ekiti ní ìjọba ìbílẹ̀ Gbonyin ni àwọn ajínigbé náà ti jí alága ọ̀hún gbé lọ.

Agbenusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, Segun Dipe tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Dipe ṣàlàyé pé alága náà ló dá wà nínú ọkọ̀ Venza rẹ̀ kí àwọn ajínigbé ọ̀hún tó ṣe ìkọlù sí i.

Ó ní àwọn ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá àti Amotekun létí lójúnà àti lè tètè ṣàwárí Omotosho.

Tinubu balẹ̀ sí Guinea-Bissau fún àpérò àjọ ECOWAS

Tinubu balẹ̀ sí Guinea-Bissau fún àpérò àjọ ECOWAS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Bola Ahmed Tinubu ti gúnlẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau láti kópa níbi àpérò àwọn olórí orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS.

Agbẹnusọ Ààrẹ, Dele Alake nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní Tinubu máa lò àkókò yìí láti fi sáwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau.

Ó ní àpérò yìí tó jẹ́ ẹlẹ́kẹtàlélọ́gọ́ta irú rẹ̀ ni àpérò ilẹ̀ Adúláwò àkọ́kọ́ tí Tinubu yóò kópa níbẹ̀ láti ìgbà tó ti dé ipò Ààrẹ.

Ó ṣàlàyé pé àwọn olórí orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógún ni ìrètí wà pé wọ́n máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń bá ilẹ̀ Adúláwọ̀ fínra pàápàá lórí ètò ààbò.

Bákan náà ló ní wọ́n tún máa jíròrò lórí bí àwọn alágbádá ṣe máa gba ìjọba padà ní orílẹ̀ èdè Mali, Burkina Faso àti Guinea, ìṣàmúlò owó ẹyọ kan ṣoṣo láàárín àwọn orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS àti ìdènà tó ń bá ọjà rírà àti títà láàárín Èkó àti Abidjan.

Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau sọ̀rọ̀, Ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá wọn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà.

ÀàrẹTinubu ní ìrètí wà pé yóò tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè kan kí okùn ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè le yi dain fún ìtèsíwájú.

Ilé aṣòfin Osun gbórúkọ àwọn Kọmíṣọ́nà tuntun síta

Ilé aṣòfin Osun gbórúkọ àwọn Kọmíṣọ́nà tuntun síta

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní bí àwọn èèyàn kan ṣe n gbée pòòyì ẹnu pé ó ti yẹ kí gómìnà Ademola Adeleke kọ orúkọ àwọn tófẹ́ yàn sípò kọmíṣọ́nà jáde, ní báyìí, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ti ṣe àgbéjáde àwọn orúkọ ènìyàn tí gómìnà Ademola Adeleke kọ ránṣẹ́ sí pé kí wọ́n dipò kọmíṣọ́nà àti àwọn olùbádámọ̀ràn ní ìpínlẹ̀ náà mú.

Níbi ìjókòó ilé ní ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Keje oṣù Keje ni Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Adewale Egbedun ti ka lẹ́tà kan tí orúkọ àwọn ènìyàn náà èyí tí gómìnà Adeleke kọ ránṣẹ́ sí etí gbogbo àwọn ọmọ ilé.

Egbedun ní àwọn máa ṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tó máa kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà ní abẹ́nú kí ilé tó tún wá ṣe ìdánwò fún wọ́n kí wọ́n tó buwọ́lù wọ́n.

Lára àwọn orúkọ tó wà nínú lẹ́tà gómìnà náà ni Agbẹjọ́rò Oladosu Babatunde, Ọmọọba Bayo Ogungbangbe, Sesan Epharaim Oyedele, Agbẹjọ́rò Kolapo Alimi, Soji Ajeigbe, Moshood Olalekan Olagunju, George Alabi, Sunday Olufemi Oroniyi, Abiodun Bankole Ojo, àti Dókítà Basiru Tokunbo Salami.

Àwọn mìíràn ni Morufu Ayofe, Sola Ogungbile, Ẹni ọ̀wọ̀ Bunmi Jenyo, Ayo Awolowo, Agbẹjọ́rò Wole Jimi Bada, Dipo Eluwole, Alhaji Rasheed Aderibigbe, Ọ̀jọ̀gbọ́n Morufu Ademola Adeleke, Adeyemo Festus Ademola, Olabiyi Anthony Odunlade, Agbẹjọ́rò Jola Akintola, Mayowa Adejori, Adenike Folashade Adeleke, Tola Faseru, àti Alhaji Ganiyu Ayobami Olaoluwa.

Ilé aṣòfin náà ti wá gbé ìgbìmọ̀ tí yóò kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà kalẹ̀ tí wọ́n sì ní kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ní kíákíá.

Tinubu mú àyípadà bá àfikún owó orí tí Buhari ṣe

Tinubu mú àyípadà bá àfikún owó orí tí Buhari ṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọ́lu àwọn òfin tuntun mẹ́rin kan léyìí tí àyípadà òfin kan tí Ààrẹ àná Muhammadu Buhari ṣe kó tó kúrò lórí ipò.

Ọ̀kan lára àwọn òfin náà ni ìdádúró ṣíṣe àfikún owó orí àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ àti àwọn ọjà tí wọ́n ń pèsè lábẹ́lé pẹ̀lú ìdá márùn-ún.

Òfin mìíràn ni yíyí ọjọ́ tí ètò Finance Act yóò gbéra sọ di ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 dípò kọ bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù Karùn-ún tí ààrẹ àná fi sí tẹ́lẹ̀.

Olùbádámọ̀ràn Ààrẹ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́, ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n inú, Dele Alake ló fi ìkéde yìí síta lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje ọdún 2023 ní gbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Abuja.

Alake ní àwọn ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti lè jẹ́ kí àádọ́run ọjọ́ tó yẹ kí wọ́n fún àjọ tó ń rí sí owó orí nílò láti fi mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ náà pé.

Bákan náà ni Tinubu tún buwọ́lu àtúnṣe owó orí, ọ̀rọ̀ àwọn àjọ ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè tọdún 2023 tó yẹ kọ bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹta sí ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ọdún 2023 pẹ̀lú ìbámu ètò National Tax Policy.

Ó fi kun pé ààrẹ tún ṣe ìdádúró gbígba owó orí lórí àwọn ìgò, iké tí wọ́n fi ń kó ọjà sí.

Ààrẹ tún ṣe ìdádúró owó orí tuntun tí ìjọba àná gbé lórí àwọn ọkọ̀ kan tí wọ́n ń gbé wọ orílẹ̀ èdè yìí láti òkè òkun.

Agbẹnusọ ààrẹ náà fi kun pé àwọn àṣẹ tuntun tí ààrẹ buwọ́lu yìí wáyé láti mú àdínkù bá ìpalára tí àwọn owó orí yìí ń kó bá àwọn iléeṣẹ́ àtàwọn ìdílé káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.

Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé ààrẹ ní ìfarajìn láti wá ojútùú àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ sísan owó orí lọ́nà tó pọ̀ lórí ọjà ẹyọ̀kan tí yóò sì ri pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tí yóò mú kí ọjà gbèrú síi.

Tinubu sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba kò ní èròǹgbà láti mú àlékún bá owó orí ti àwọn ènìyàn ń san tẹ́lẹ̀ tàbí ṣe ìgbéjáde owó orí tuntun.

Ìpínlẹ̀ Ogun, Ọ̀yọ́, Kwara àtàwọn míì gba kọmísọ́nà ọlọ́pàá tuntun

Ìpínlẹ̀ Ogun, Ọ̀yọ́, Kwara àtàwọn míì gba kọmísọ́nà ọlọ́pàá tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Olukayode Egbetokun, ti pín kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá márùndínlógójì káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà.

Alukoro iléeṣẹẹ́ náà, Olumuyiwa Adejobi ló fi ìròyìn ọhún ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn nílùú Abuja.

Ìgbésẹ yìí ló ń wáyé lẹyìn tí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá, Police Service Commission, buwọ́lu ìgbésẹ̀ ọ̀hún.

Egbetokun ní ìgbésẹ ọ̀hún wà lára àfojúsùn iléeṣẹ́ náà láti pèsè ààbò tó dájú fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà.

Lára àwọn kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá tuntun náà ni CP Adelesi E. Oluwarotimi sí Kwara, CP Adebola Ayinde Hamzat, lọ sí Ọ̀yọ́ àti CP Alamatu Abiodun Mustapha lọ sí ìpínlẹ̀ Ògùn.

Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, ìpínlẹ̀ Kebbi, Bauchi àti Ebonyi náà yóò tún ní kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá tuntun.

Egbetokun rọ àwọn èèyàn náà kí wọ́n mú iṣẹ́ wọn ní pàtàkì, kí wọ́n sì jẹ́ àpẹrẹ rere fún àwọn tó wà lẹ́yìn wọn àtàwọn aráàlú.

Ìgbésẹ̀ àti yan àwọn Kọmíṣọ́nà l’Ọ́ṣun kò ní pẹ́ mọ́–Adélékè

Ìgbésẹ̀ àti yan àwọn Kọmíṣọ́nà l’Ọ́ṣun kò ní pẹ́ mọ́–Adélékè

Fẹ́mi Akínṣọlá

Láti ìparí oṣù Kẹfa ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn kan ti ń kùn pé tí a bá kà á ní ení, èjì, ó ti tọ́ oṣù méje tí gómìnà Ademola Adeleke ti gba ọ̀pá àṣẹ láti máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun fún ọdún mẹ́rin.

Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni wọ́n búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun lẹ́yìn tó fi ẹ̀yìn gómìnà àná, Gboyega Oyetola lulẹ̀.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje ọdún 2022 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà Osun wáyé tí àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà sì kéde pé Ademola Ademola tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ló jáwé olúborí ìbò náà pẹ̀lú ìbò 403,371.

Gómìnà àná ní Osun, Gboyega Oyetola tó díje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó ní ìbò 375,027 ni òun kò gbà èsì ìbò tó gbé Adeleke wọlé.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Supreme Court Kéde pé Ademola Adeleke ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bí gómìnà Adeleke ṣe ti wọ ọ́fíìsì ni wọ́n ti ń fẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àyípadà ní ìpínlẹ̀ Osun pàápàá lórí yínyan àwọn Kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣe ìjọba.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ ń bèèrè pé kí ló dé tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn oṣù méje gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun, gómìnà Ademola Adeleke kò ì tíì yan Kọmíṣọ́nà kankan títí di àsìkò yìí.

Nígbà tí Agbẹnusọ Gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed yóó fèsì, ó ní Gómìnà Adeleke ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.
Rasheed ní gbogbo àwọn ìpèníjà tí ìjọba àwọn kojú nígbà tí àwọn gba ọ̀pá àṣẹ láti tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun wà lára àwọn nǹkan tó ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo bí àwọn ṣe ń ti ilé ẹjọ́ kan bọ́ sí òmíràn lórí ta ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò ṣe ìdádúró àwọn ìgbésẹ̀ kan tó yẹ kí ìjọba ti gbé.

Agbẹnusọ gómìnà náà wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gómìnà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣiṣẹ́ tó sì ti ń ṣe àkójọ àwọn orúkọ kan.

“Láìpẹ́, láì jìnà ni gómìnà máa fi orúkọ àwọn kọmíṣọ́nà ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin.”

“Iṣẹ́ ti fẹ́ parí lórí àwọn tí wọ́n fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà, gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ ni ìjọba sì ti ń gbé báyìí.”

Ó fi kun pé ètò ìdìbò gbogbogbo tó wáyé ní Nàìjíríà náà wà lára ohun tó ṣe ìdádúrọ yíyan àwọn kọmíṣọ́nà náà di ìwòyí.