Home Blog Page 51

Ẹgbẹ́ PDP gba àwọn alákòóso Mákindé tuntun nímọ̀ràn

Ẹgbẹ́ PDP gba àwọn alákòóso Mákindé tuntun nímọ̀ràn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àmọ̀ràn ti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò níṣèjọba sáà kejì Ẹnjinníà Ṣeyì Mákindé láti gbájú mọ́ṣẹ́ ìlú.Ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP), ní ìpínlẹ̀ Ọyọ , ló gba àwọn ẹni ọ̀rọ̀ kàn ọ̀hún, akọ̀wé ìjọba, olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì Gómìnà àtàwọn kọmíṣánnà láti fìmọ̀ ṣọ̀kan, kí wọ́n sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Gómìnà láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Adelé Alukoro fún ẹgbẹ́ náà, Micheal Ogunṣina, ló gbà wọ́n nímọ̀ràn yìí nínú atẹjade tó fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Keje, ọdún 2023 yìí.

Bákan náà ló kí akọ̀wé ìjọba tuntun, àtàwọn kọmísánnà mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún (16), olùṣirò owó àgbà tuntun, àti àwọn akọ̀wé ìjọba tí Gómìnà Ṣeyi Mákindé ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù yìí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, ó ní, “a gbàgbọ́ nínú àwọn èèyàn tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé yan yìí, nítorí àwọn ipa rere tí wọ́n ti ko nínú iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò.

Àwọn ipa tí wọ́n ti ko tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ káàkiri ti fihàn pé wọ́n yóò wúlò fún àfojúsùn Gómìnà fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

‘ Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ PDP ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, a rọ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yìí láti má fi iṣẹ́ wọn tàfàlà, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ takuntakun fún ìgbélárugẹ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́”.

Ẹgbẹ́ PDP ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹjẹẹ láti fọwọsowọpọ pẹ̀lú akọwe ìjọba tuntun, àwọn kọmísánnà, olùṣirò owó àgbà, àtàwọn akọ̀wé àgbà tuntun yìí, kí ìpínlẹ̀ yìí lè gòkè àgbà.

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá sọsẹ́ n’Íbàdàn, ọ̀pọ̀ dúkìá sòfò

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá sọsẹ́ n’Íbàdàn, ọ̀pọ̀ dúkìá sòfò

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ogunlọ́gọ̀ dúkìá olówó iyebíye làgbàrá òjò wọ́ lọ níjọba ìbílẹ̀ Ido, n’Íbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lẹ́yìn tí arọọda ojo kan rọ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógùn, oṣù Keje, ọdún 2023 yìí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjànbá lòjò alágbára yìí ṣe fún àwọn èèyàn abúlé níbẹ̀, tó sì ba ètò ọrọ̀ ajé wọn jẹ́.

Lara awọn adugbo to fara gba ninu ijamba omiyale naa ni: Ọmi Adio, Apata ati ilu Ido funra ẹ.

Akọ̀ròyìn wa gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀bù àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lojo yii wọ lọ lọja Ọmi Adio, koda, alagbalugbu agbara ojo naa tun wọ ọpọlọpọ odo ẹja lọ lagbegbe naa, o si wọ awọn ẹja ti wọn n sin ninu wọn lọ.

Ọgbẹni Festus Adeṣina, ọkan ninu awọn agbẹ to fara gba ninu iṣẹlẹ yii, ṣalaye pe ko din ni ọgọrin (80) odo ẹja ti omi gbe lọ.

Ó ní bíi mílíọ̀nù mẹwàá Náírà lòun fi ń ṣe okoòwò òun, ṣùgbọ́n níṣe lomi gbe gbogbo rẹ̀ lọ pátápátá.

Obìnrin oníṣòwò kan tóun náà fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Alaaja Alimot Adeleke, rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dìde ìrànwọ́ fóun àti ẹni gbogbo tó kàgbákò ẹ̀kún omi náà.

Adeleke ni ọpọlọpọ baagi gaari, ẹgẹ ati apo ounjẹ lo ba iṣẹlẹ ọhun rin.

Ó fi kún un pé ṣọ́ọ̀bù yìí lòun fi ń gbọ bùkáátà àwọn ọmọ òun látìgbà tóun ti pàdánù ọkọ òun.

Adebutu takú pé ẹbu ìwé ẹ̀rí WAEC ni Abiodun ń lò, WAEC kọ̀ láti fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ránṣẹ́ sí ‘Tribunal’ l‘Ogun

Adebutu takú pé ẹbu ìwé ẹ̀rí WAEC ni Abiodun ń lò, WAEC kọ̀ láti fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ránṣẹ́ sí ‘Tribunal’ l‘Ogun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun ń tẹ̀síwájú láti gbọ́ awuyewuye tó wáyé nínú ìbò gómìnà Dapo Abiodun wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà.

Ní ọjọ́bọ̀ ni òṣìṣẹ́ West African Examination Council (WAEC), Olufemi Olaleye yọjú sí ilé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Abiodun àmọ́ kò mú èsì ìdánwò WAEC gómìnà náà dání.

Ṣáájú ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà ti kàn sí WAEC láti pèsè ẹ̀dà èsì ìdánwò èyí tí gómìnà Abiodun ṣe ní ọdún 1978.

Èsì ìdánwò yìí ni gómìnà Abiodun fà kalẹ̀ fún àjọ INEC pé òun yege nínú ìdánwò òun.

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà kàn sí àjọ WAEC láti pèsè ẹ̀dá ìwé ẹ̀rí mo yege gómìnà Abiodun lẹ́yìn tí olùdíje sípò gómìnà Ìpínlẹ̀ náà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Ladi Adebutu fẹ̀sùn kan Abiodun pé ayédèrú ni ìwé ẹ̀rí èsì ìdánwò WAEC tó ń lò.

Ẹ kéde mi bí ẹni jáwé olúborí ìbò Ààrẹ – Atiku sí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò

Ẹ kéde mi bí ẹni jáwé olúborí ìbò Ààrẹ – Atiku sí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, nínú ètò ìdìbò tó kọjá, Alhaji Atiku Abubakar ti rọ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò láti kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò náà.

Atiku Abubakar ní àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC gbà wí pé ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni òun ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Atiku sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ẹtì nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn èyí tí òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà láti fi tako ìjáwe olúborí Tinubu.

Nínú ọ̀rọ̀ náà èyí tí agbẹjọ́rò rẹ̀, Chris Uche ní INEC kò sọ wí pé àwọn ṣe àṣìṣe bí wọ́n ṣe ti ṣaájú sọ wí pé òun jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí.

INEC nínú èsì sí ẹjọ́ tí Atiku pè ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni Atiku tí jáwé olúborí.

Àwọn Ìpínlẹ̀ tí INEC kà kalẹ̀ pé Atiku tí jáwé olúborí ni Adamawa, Akkwa Ibom, Bauchi, Bayelsa, Borno, Delta, Ekiti, Gombe, Jigawa, Kaduna, Katsina, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Sokoto, Taraba, Yobe àti Zamfara.

Ó ní láti ìgbà náà títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí kò sí ìgbà tí INEC fi yí ọ̀rọ̀ náà padà.

Ó ní èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ẹni tó yẹ kí wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ nítorí náà kí Adájọ́ gbé ipò náà fún òun.

Ìròyìn òfegè ni pé wọn ó forò lé àjòjì kúrò l’Ékò ó – Ìjọba

Ìròyìn òfegè ni pé wọn ó forò lé àjòjì kúrò l’Ékò ó – Ìjọba

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìròyìn òkèrè, bí ò bá lékan,a dínkan,ní báyìí, Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ní kí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀hún má tẹ́tí sí ìròyìn kan tó gba orí ayélujára kan pé orò fẹ́ jáde ní àwọn agbègbè kan.

Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn àdúgbò kan lọ́jọ́bọ̀, ogúnjọ́ àti ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Keje láàárín aago méjìlá sí aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí àwọn ọjọ́ náà.

Lára àwọn àdúgbò tí wọ́n ní orò náà ti máa wáyé ni Ikate,Ijora-Badiya, Amuwo-Odofin, Ojota, Ikorodu àti Somolu-Bariga àti agbègbè rẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n tún dárúkọ Igbobi-Sabe, Ojodu-Isheri, Isolo-Okota-Ilasamaja, Ejigbo-Idimu, Isheri-Ijegun, Ikotun-Igando, Iba, Lawanson-Itire àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ohun tí wọ́n kọ sórí ìròyìn náà ni pé kí àwọn obìnrin àti àwọn tí kìí bá ṣe ọmọ Eko ó fi ara pamọ́ láwọn àsìkò tí orò fi fẹ́ jáde náà pé ọmọ onílùú fẹ́ ṣe orò.

Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Gboyega Akosile nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní Alausa, Ikeja ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Akosile rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé kò sí nǹkan tó jọ pé orò kankan fẹ́ wáyé.

Ó ní kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá àti pé kìí ṣe ohun tó yẹ kí ìjọba tilẹ̀ máa dá sí ni.

NLC fọnmú lórí èlé owó epo

NLC fọnmú lórí èlé owó epo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá àgbà àjọ Iléeṣẹ́ tó ń rí sí epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà, NNPCL, Mallam Mele Kyari ti ní bí ọ̀rọ̀ ọjà epo bẹntiróòlù ṣe ń lọ sí ló fa àlékún tó bá owó epo bẹntiróòlù lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Kyari nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣèpàdé pẹ̀lú igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima ní Aso Rock, Abuja.

Ó ṣàlàyé pé pẹ̀lú àyípadà tó bá ẹ̀ka epo rọ̀bì báyìí, bí ọjà bá ṣe ń lọ sí ni àyípadà yóò ṣe máa bá iye owó epo bẹntiróòlù.

Ó ní nígbà mìíràn ó ṣeéṣe kí owó náà gbé ẹnu sókè, ó sì lè já wálẹ̀.

Ọ̀gá àgbà NNPCL náà tún ṣàlàyé pé àlékún tó bá owó jálá lítà epo kan láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà sí ẹgbẹ̀ta náírà lé díẹ̀ sọ àrídájú rẹ̀ pé epo bẹntiróòlù wà nílẹ̀ jaburata àti pé kìí ṣe àìsí epo ló fa àlékún tó bá owó epo.

Ó ní epo bẹntiróòlù tó wà ní Nàìjíríà báyìí máa tó àwọn ọmọ Nàìjíríà fún ọgbọ̀n ọjọ́ nítorí náà kí àwọn ènìyàn má fòyà.

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba àpapọ̀ lórí bí àlékún tún ṣe bá owó epo bẹntiróòlù lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

NLC nínú àtẹ̀jáde kan tí Ààrẹ wọn, Joe Ajaero fi léde fi ẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé níṣe ni wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn aláìní láti fi bùn kún àwọn ọlọ́rọ̀.

Ajaero ní ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún fi kún owó epo bẹntiróòlù tún ti mú àlékún bá ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.

Ó ní ó jọ wí pé àwọn kan ń tan Tinubu tí kò fi mọ àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ lásìkò tó yẹ ní èyí tó ń kó ìpalára gidi bá àwọn ará ìlú.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ó jẹ́ ohun tó ń bá àwọn lọ́kàn jẹ́ pé ìjọba kọ̀ láti ṣe ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ń fẹ́ tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ apàṣẹ wà á lórí àwọn ìpinnu tó ń mú ìnira bá ará ìlú.

Bákan náà ni wọ́n tún bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba lórí ìpinnu rẹ̀ láti máa fún àwọn tálákà ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà lóṣù fún oṣù mẹ́fà nítorí ìrànwọ́ orí epo tí wọ́n yọ.

Ajaero tẹ̀síwájú pé tí kìí bá ṣe pé ìjọba kò nání ará ìlú, wọn ò ní gbèrò láti máa fún odidi ìdílé kan ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà lóṣù àmọ́ kí wọ́n fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àádọ́rin bílíọ̀nù náírà.

Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ yìí fi hàn pé ìjọba kò mọ irú ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú láti bí oṣù méjì tí ìjọba tuntun ti wà lórí ipò.

Owó EPO pe̩tiró tún fò sókè

Owó EPO pe̩tiró tún fò sókè

Yínká Àlàbí

Owuro̩ oni yii tii se o̩jo̩ Ise̩gun, o̩jo̩ kejidinlogun o̩dun 2023 ni EPO pe̩tiro tun fo fe̩re̩ lati N488, N535 si N617.
Iyale̩nu nla ni eleyii je̩ fun awo̩n ara ilu nitori pe agbegbe e̩e̩de̩gbe̩ta naira to wa gan-an ti je̩ ki o̩po̩ eniyan pa mo̩to wo̩n ti.
Ibi to wa fo si bayii ko tile̩ je̩ ki e̩nikankan mo̩ odo to maa ds o̩runla si. Eyi si fun awon e̩gbe̩ alatako le̩nu o̩ro̩ si ijo̩ba Tinubu. Orisiirisii o̩ro̩ ti ko bojumu ni wo̩n ti n ro̩jo si ijo̩ba emi lo kan bayii lori e̩ro̩ ayelujara, koda awo̩n o̩mo̩ e̩gbe̩ APC gan-an n mi amikan nitori o̩ro̩ to ba ti ju e̩kun lo̩, erin laa fii rin.
Eyi je̩ iroyin yajo-yajo to n lo̩ lo̩wo̩ bayii. Bi ayipada ba se n lo̩ ni iroyin owuro̩ maa fi to ara ilu leti.

Baálẹ̀ méjì dèrò ẹ̀wọn, ‘ilẹ̀ òòṣà’ ni wọ́n jí tà

Baálẹ̀ méjì dèrò ẹ̀wọn, ‘ilẹ̀ òòṣà’ ni wọ́n jí tà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Baálẹ̀, ọkọ ìlú méjì kan, Alàgbà Ọlalekan Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdún mejidinlọgọta, tí í ṣe Baálẹ̀ abúlé Agejo, àti Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Konigbagbe, ẹni àádọ́ta ọdún, tóun jẹ Baálẹ̀ Abúlé Ake ti méjèèjì wà nijọba ìbílẹ̀ Ọbafẹmi Owode, ní ìpínlẹ̀ Ogun, ti ń fẹnu fẹ́ra bíi abẹbẹ ní keremọnje báyìí. Ohun tó gbé wọn debẹ ni pé wọ́n wọnú ilẹ̀ ìjọba tó jẹ́ tí ileeṣẹ redio ìpínlẹ̀ Ògùn, Ogun State Broadcasting Corporation (OGBC), wọn bu apá kan ilẹ̀ ọ̀hún tà fáwọn oníbàárà kan, wọ́n sì tún bẹrẹ sí i kọle sáwọn apá mìíràn.

Àwọ́n mẹ́rin mí-ìn tí wọ́n jọ lọ́wọ́ nínú àṣà pálapàla ọ̀hún ni Wasiu Ogunṣina, ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́ta, Babatunde Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, Kabiru Ọlafẹnwa, ati Dare Awodele.

Àlàyé tí Agbèfọ́ba, rìpẹ́kítọ̀ Adekanmi Adeusi, ṣe niwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Abẹokuta lọjọ, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje yii, lasiko tawọn afurasi ọdaran naa n fara han fungba akọkọ ni pe atawọn to jẹ baalẹ laarin afurasi yii, atawọn ti ki i ṣe baalẹ, o ni iṣẹ ajagungbalẹ ni wọn n ṣe rẹbutu, iwa agba-lọwọ-merii, ati ilaalaṣi ọmọlakeji ẹni lori dukia rẹ lo kun ọwọ gbogbo wọn.

Ó ní ìwà irufin yìí náà ló mú káwọn agbófinró lọọ fi pampẹ gbé wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, nigba tawọn alaṣẹ ileeṣẹ redio OGBC kọwe ẹsun ṣọwọ si ọfiisi Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun nipa bi awọn atilaawi yii ṣe wọnu ilẹ onilẹ, ti wọn si n ta a, ti wọn n fowo ẹ ṣara rindin.

Ó lẹ́sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ọ̀hún ta ko iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, ati pe ijọba ipinlẹ ọhun ko fẹẹ gbooorun ẹnikẹni to ba n huwa ajagungbalẹ rara, mimu lawọn n fọwọ ṣinkun ofin mu ẹnikẹni to ba lọ n ṣe bii akilapa lori dukia ẹni ẹlẹni.

Nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ àwọn afurasí náà bóyá wọn jẹbi tàbí wọn kò jẹbi, gbogbo wọn láwọn kò jẹbi rárá.

Èyí ló mú kí Onídàájọ́, Ọṣibajo paṣẹ pe ki wọn rọ gbogbo wọn da sẹwọn na. Ọgba ẹwọn to wa lagbegbe Ibara, ni ki wọn ko wọn lọ, ibẹ ni wọn yoo si wa fun saa ọgbọn ọjọ, lati faaye silẹ ki wọn gbe faili ẹjọ lọ sọfiisi ajọ to n gba awọn adajọ nimọran.

Adájọ́ náà ní òun kò tí ì lánfààní láti gba béèlì wọn.

Lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ tó kan sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kẹjọ, ọdún yìí.

Kìí ṣe agbe ni kí ẹni nílò ìrànwọ́ ó bèèrè—Yomi Fabiyi

Kìí ṣe agbe ni kí ẹni nílò ìrànwọ́ ó bèèrè—Yomi Fabiyi

Fẹ́mi Akinṣọlá

Àwọn àgbà ní tẹni tó dé larí,tẹni tó n bọ̀, a ò mọ̀ ọ́, àti pé èèyàn tí kò tíì kú , kò tíì lè sọ irúfẹ́ ikú tí yóó pa á.
Gbajúmọ̀ òṣèré fíìmù Yorùbá, Yomi Fabiyi náà ti jáde láti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn àgba òṣèré kan ṣe ń bọ sórí ayélujára láti pariwo fún ìrànwọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́yinjú àánú.

Yomi ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí èsì sí fídíò kan tí àgbà òṣèré bìnrin, Jaiye Kuti fi síta nínú èyí tó ti ń fẹnu sáátá bi àwọn òṣèré kan ti sọ ara wọn di alágbe.

Yomi Fabiyi bu ẹnu àtẹ́ lu ìwòye wí pé àwọn tó ń tọrọ fún ìrànlọ́wọ́ ń dójú ti àwọn òṣèré tókù ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dárúkọ tàbí na ìka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Jaiye Kuti, Yomi Fabiyi ní kò tọ́ kí ẹnikẹ́ni bú wọn pé wọ́n ń bọ sí gbangba láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ lásìkò ìṣòro wọn.

“Gbogbo àwọn iṣẹ́ tó kù lóríṣiríṣi ẹ̀ka ló wà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn nítorí ìdí èyí, ìpèníjà ìlera wọn ń rí àmójútó. Bẹ́ẹ̀ sì ni àkànṣe ètò adójútòfò wà fún owó ìfẹ̀yìntì àti ìlera wọn.”

Yomi jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà òṣèré yìí tí wọ́n ní ẹ̀bùn eré ṣíṣe ni wọ́n ti yànjẹ gidi gan lórí ìtàgé tí wọ́n sì ti lo àtàwọn àti òógùn wọn láàrin agbo tíátà àti níta tí kò sì sí ẹni tó bá wọn wá ojútùú síi pàápàá ní ti ọ̀rọ̀ jí jí iṣẹ́ oníṣẹ́ tàbí wíwo fíìmù wọn lọ́nà àìtọ́.

“Ìbànújẹ ló tún wá jẹ́ pé àwọn òṣèré ayé òde òní ti ń pa wọ́n tì, dípò kí wọ́n máa lo àwọn àgbàlagbà yìí fún fíìmù kí wọ́n lè máa rí owó, wọ́n á kun ojú àwọn ọ̀dọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n jọ arúgbó.”

Ṣáájú ni Jaiye Kuti ti sọ nínú fídíò tó fi sí ojú òpó sítágíràmù rẹ̀ pé ìwà tí àwọn tó ń bẹ̀bẹ fún ìrànwọ́ yìí ń hù ń tàbùkù bá ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn òṣèré (TAMPAN) àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́.

GWR, Àmì ẹ̀yẹ òṣèré tíátà tó dàgbà jùlọ tọ́ sí Àgbákò’ -Muyiwa Ademola

GWR, Àmì ẹ̀yẹ òṣèré tíátà tó dàgbà jùlọ tọ́ sí Àgbákò’ -Muyiwa Ademola

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé bẹ́ẹ̀, èèyàn tí kò gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ni yóó pè é lẹ́yẹ aláròyé .
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Muyiwa Ademola ti ké sí àjọ àmì ẹ̀yẹ Guinness World Record láti fún àgbà òṣèré Charlse Olúmọ ní àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tó dàgbà jù, tí ara rẹ̀ jí pépé ni ẹni ọgọrùn ọdún.

Èyí wà lára ọ̀rọ̀ ìkíni kú oríire ọjọ́ ìbí ọgọ́rùn ọdún tí Muyiwa Ademola fi sí ojú òpó ayélujára rẹ̀ láti fi kí èèkàn eré tíátà Yorùbá tí ọ̀pò mọ̀ sí Àgbákò.

Muyiwa Authentic, ní bí èèkàn òṣèré tíátà náà ṣì se ń ta kébékébé lẹ́ni ọgọ́ọ̀rùn ọdún tó èyí tó yẹ kí àjọ afún ni lámì ẹ̀yẹ, Guiness World Records (GWR) ó bojú wò fún ìgbéláruge.

Muyiwa Ademọla ni ohun ìwúrí ni yóó jẹ́ bí bàbá Àgbákò bá gba àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tíátà tó dàgbà jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà báyìí.

Àmọ́ṣá, kò sí ẹni leè sọ bóyá àjọ GWR máa ń gbé irú àmì ẹ̀yẹ bẹ́ẹ̀ kalẹ̀.