Home Blog Page 49

Ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀ – Adeleke

Ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀ – Adeleke

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tó mojú ògún ní-ín pabì nírè.
Ilu Osogbo ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun mi títí pẹ̀lú bí àwọn ónìṣese káàkiri àgbáyé ṣe péjú pésẹ̀ láti se ayẹyẹ àsekágbá ọdún Ọ̀ṣun Osogbo ti ọdún yìí.

Ataoja tí ìlú Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Olanipekun àti àwọn olorí, ìjòyè àti àwọn ará ìlú gbogbo ló péjú síbi ayẹyẹ Ọdún náà.

Ataoja tí ìlú Osogbo nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ ní àkókò tí ọdún Ọ̀ṣun Osogbo dùn jù ni ti ọdún yìí pẹ̀lú bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀sun se lọ́wọ́ sí ètò gbogbo, tí wọ́n sì ṣe àdúrà fún onílé àti àlejò.

Gómìnà Ademola Adeleke àti ìyàwó rẹ̀ náà kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ ọ̀hún pẹ̀lú gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.

Gómìnà Ademola ni ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo àti ayẹyẹ ọdún náà pẹ̀lú àwọn nǹkan mèremère tí ìjọba túbọ máa se láti gbé àṣà lárugẹ.

Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò, Iba Gani Adams gbóríyìn fún ìjọba Ademola Adeleke fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ lórí ayẹyẹ Ọdún Ọ̀ṣun Osogbo tó mú kí tí
ó yàtò.

Gani Adams tún kìlọ̀ fún àwọn aṣẹ̀bàjé tí wọ́n má ń lo àkókò ayẹyẹ ọdún náà láti ja àwọn àlejò àti onílé lólè láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ náà.

Ó ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Oòduà Peoples Congress, OPC, yóò ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò àbọ̀ tó kú ní ọdún tó ń bọ̀.

Àbọ̀dé Niger, Sanusi gba Tinubu nímọ̀ràn

Àbọ̀dé Niger, Sanusi gba
Tinubu nímọ̀ràn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní n tá ò bá fẹ́ kò bàjẹ́,ó ní bí wọ́n ti í ṣe é.
Ọ̀gá àgbà báńkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa nígbà kan, tó sì tún ti fìgbà kan jẹ́ Ẹmia ilẹ̀ Kano, Alaaji Sanusi Lamido Sanusi, ti ṣàbẹ̀wò sáwọn ṣọ́jà tí wọ́n gbàjọba lórílẹ̀-èdè Niger, bẹ́ẹ̀ ló sì ti lọ̀ọ́ jábọ̀ àbẹ̀wò pàtàkì rẹ̀ ọ̀hún fún Olórí orílẹ-èdè wa, Bọla Ahmed Tinubu.

Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Kẹjọ yìí ni Sanusi ṣàbẹ̀wò rẹ̀ ọ̀hún, tó sì jókòó ìpàdé bònkẹ́lẹ́ kan pẹ̀lú àwọn olórí ṣọ́jà tí wọ́n ń ṣèjọba lọ́wọ́ nílẹ̀ Niger ọ̀hún. Ìlú Niamey, tí í ṣe olú-ìlú orílẹ-èdè Niger ni wọ́n ti gbà á lálejò.

Bákan náà ni Sanusi ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kì í ṣe Olórí àjọ Economic Community of West African States, ECOWAS, ìyẹn Tinubu, ló rán òun lọ sọ́hùn-ún, ó ní òun lo ìdánúsọ ara òun ni, gẹ́gẹ́ bíi èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí Tijjaniya, èyí ti ọ̀pọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ nàà wà lórílẹ̀èdè Niger. Sanusi ló wà nípò Khalifa ẹgbẹ́ Tijjaniya ọ̀hún lọ́wọ́lọ́wọ́.

Nínú fọ́tò àti fídíò kan tó ń jà rànyìn lórí ayélujára, wọ́n ṣàfihàn Ṣanusi, níbi tó ti jókòó àpérò pẹ̀lú àwọn olórí ṣọ́jà Niger, àti bí wọ́n ṣe gba ọkùnrin náà tọwọ-tẹsẹ lásìkò àbẹwò rẹ̀. Sultan ti ìlú Damagaran wa lara awọn to kọwọọrin pẹlu Sanusi lọ sipade ọhun. Ipo kẹta ni ilu Damagaran yii wa laarin awọn ilu to tobi ju lọ nilẹ Niger.

Ninu ọrọ ṣoki kan to sọ fawọn oniroyin lori abẹwo rẹ ọhun, Sanusi ni: “Mo wa lati sọrọ ilaja ati ipẹtu-saawọ pẹlu olori ologun, Jẹnẹra Abdourahamane Tchiani, ni. Mo ti ba olori ijọba ologun naa sọrọ, ma a si lọọ fi abọ ajọsọ wa jiṣẹ fun Aarẹ Tinubu,” Amọ o fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe ijọba tabi ECOWAS lo ran oun wa silẹ Niger.

Bi Ṣanusi ṣe pari ijiroro rẹ pẹlu awọn ṣọja naa ti wọn si sin in sọna, taara lo balẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, nibi to ti lọọ jiroro pẹlu Aarẹ Bọla Tinubu, wọn si tilẹkun mọri sọrọ, laṣaalẹ ọjọ Wẹsidee naa.

Bakan naa ni Sanusi sọ fawọn oniroyin l’Abuja pe: “Asiko yii ki i ṣe eyi ta a maa da ọrọ yii da ijọba nikan, ọrọ ifikunlukun ati igbọra-ẹni-ye gidi lo ṣẹlẹ yii. Awọn eeyan Naijiria ati ti ilẹ Niger gbọdọ fọwọ sowọ pọ lati wa ojuutu to maa ṣanfaani fun ilẹ Afrika lapapọ, to si maa ṣe tolori tẹlẹmu loore.

Nígbà ti wọ́n bèèrè bóyá ìjọba Nàìjíríà ló rán an lọ, Sanusi ní, “rara, ìjọba ò rán mi niṣẹ, àmọ́ mo fi ọ̀rọ̀ àbẹwò mi tó àwọn aláṣẹ wa létí, wọ́n sì mọ̀ pé mò ń lọ sọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n ìdánúṣe ara mi ni mo fi lọ, èmi sì ni mo kàn sí àwọn tí mo mọ̀ lọ́hùn-ún tí wọ́n fi ní kí ń máa bọ̀. Gbogbo nǹkan tó bá wà níkàápá mi ni mà á ṣe láti yanjú ìṣòro náà, torí nǹkan tó yẹ kí ń ṣe gẹ́gẹ́ bíi adarí kan ni.” Sanusi.

YIF gba Aare̩ Tinubu nímò̩ràn láti má se yanjú aáwò̩ Niger Republic pè̩lú o̩wó̩ líle

YIF gba Aare̩ Tinubu nímò̩ràn láti má se yanjú aáwò̩ Niger Republic pè̩lú o̩wó̩ líle

Alakoso Yoruba Indigenes Foundation ( YIF ), Dr Olumide Aderibole gba Aare̩ Tinubu ati awo̩n ajo̩ ECOWAS nimo̩ran pe ti okun ba n ho ruru ki awo̩n ma se wa ruru nipa ifipa gbajo̩ba to waye ni orileede olominira Niger.

Ninu atejade iroyin kan, ti Ọgbẹni Sanjo Olawuyi fowo si, Oludari awọn ibara-ẹni-sọrọ ati awọn ilana ti Yoruba Indigenes Foundation ( YIF ). Aderibole sọ pe “ lai bikita, ibara-eni- soro lọna ologun ni Niger Orile-ede olominira yoo ṣe afihan sinu: ipadanu nla ti awọn igbesi aye ati awọn ohun-ini ti awọn ara ilu alaiṣẹ ti Orilẹ-ede Niger.

O le yori si ki awon eeyan sa koja enu ala lai ba ofin mu; ibesile ti ajakale-arun ni Niger Republic, eyi ti yoo tan si awọn orilẹ-ede aladugbo wọn; yoo ja si ipadanu owo ti o po yanturu, eyi ti o le tumọ si awọn ọkẹ àìmọye; yoo fa ibajẹ ati rogbodiyan ilu ni Niger Republic; awọn iṣowo ati awọn iṣẹ-aje yoo ni ikolu lara; ebi ati irora yoo wo ilu wa. ”Alakoso YIF tẹ siwaju nipasẹ tito le̩se̩e̩se̩ nipa awọn ọna omiiran ti o le fi yanju aawo̩ –  awọn ijiroro ti o kun fun iduna-dura, fifi ijoba awa ara wa fidihe  sori isakoso, s̩is̩eto ibo ni orilẹ-ede naa.

Dr Aderibole gunle̩ o̩ro̩ pe̩lu imo̩ran yii – ti Alakoso Bola Tinubu ba ṣaṣeyọri ninu yiyanju aawo̩ ilu naa ni itubi inubi, oruko won yoo maa je kiko sile ninu iwe itan ayeraye.

Wole:Sanjo Olawuyi

Oludari Awọn ibaraẹnisọrọ ati Awọn ilana,Yoruba Indigenes Foundation.

*ATUMỌ ÈDÈ SÍ YORÙBÁ ***OMOBA LAWAL ONÍKẸ̀KẸ́ ÒRÌSÀ WÁLÉ AROLE OODUA **

Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, Taiwo Odukoya jáde láyé

Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, Taiwo Odukoya jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sééyàn tí kò ní-ín kú, kò séèyàn tóko baba rẹ̀ kò ní-ín dìgbòrò. Olùdásílẹ̀ ìjọ Fountain of Life Church, pásítọ̀ Taiwo Odukoya ti jáde láyé.

Àwọn aláṣẹ ìjọ ọ̀hún ló fi ìkéde ìpapòdà rẹ̀ léde lójú òpó Facebook ìjọ náà.

Ìròyìn sọ pé àná, ọjọ́ keje, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 ni olùṣọ àgùtàn náà fi ayé sílẹ̀.
Àtẹ̀jáde náà ni “ Àwa ọmọ ìjọ Fountain of Life Church, ní gbígba àmúwá Ọlọ́run kéde ikú bàbá wa, olùkọ àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè Daniel Taiwo Odukoya tó jáde láyé lọ́jọ́ keje, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 nílẹ̀ Amẹ́ríkà.

“A ti gbà fún yín Ọlọ́run.”

“ Adúpẹ́ fún ìgbé ayé rere tí adarí wa gbé lókè èèpẹ̀.”

Ọjọ́ karùndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 1956 ní wọ́n bí Taiwo Odukoya nílùú Kaduna, níbi tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà.

Òun ni olùṣọ́àgùtàn àgbà ìjọ Fountain of Life Church tó wà ní Ìlúpéjú nílùú Èkó, tí iye àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ.

Ọdún 1980 ni olóògbé náà pàdé ìyàwó rẹ̀, Bimbo Williams, tí wọ́n sí ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 1984.

Lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù Kejìlá, ọdún 2005, Bimbo Odukoya kú sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú Sosoliso tó já lulẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún lé méjì èèyàn mìíràn.

Lọ́dún 2010, Taiwo Odukoya fẹ́ ìyàwó míràn, Rosemary Simangele Zulu, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa.

Àmọ́ nígbà tí yóò fi di oṣù Kọkànlá, ọdún 2021, ó pàdánù ìyàwó rẹ̀ kejì ọ̀hún ṣọ́wọ́ àrùn jẹjẹrẹ

Ọlọ́pàá,Frsc àti Lastma tó n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ bọ́ sọ́wọ́

Ọlọ́pàá,Frsc àti Lastma tó n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ bọ́ sọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí kólékólé bá fi gbaṣẹ́ aṣọ́de, a jẹ́ pé ìlú kànjàngbọ̀n kó má baà wá rí bẹ́ẹ̀,ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó fi ṣe àfihàn àwọn jàǹdùkú agbèrò tó ń gba owó lójú pópó lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kọ̀ ńlá àti awakọ̀ míì lágbègbè Mile 2.

Yàtọ̀ sí àwọn èèyàn mẹ́ẹ̀dógún tí ọwọ́ wọn tẹ̀, a tún rí àwọn agbófinró ọlọ́pàá, òṣìṣẹ́ àjọ ẹ̀sọ́ aláàbò ojú pópó FRSC tó ń darí lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó Lastma.

Ọlọ́pàá mẹ́ta, òṣìṣẹ́ Lastma kan àti ẹnìkan ni wọ́n fihàn pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ agbèrò láti máa gba owó lọ́wọ́ àwọn awakọ̀.

Benjamin Hundeyin tó jẹ́ alukoro ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó sọ pé kọmíṣánà Idowu Owohunwa ló pàṣẹ káwọn ọlọ́pàá tọ pinpin àwọn aláburú yìí tó ń gba owó lọnà àìtọ́ lọ́nà Mile 2.

Àyẹwò orúkọ parí, El-Rufai kò sí níbẹ̀

Àyẹwò orúkọ parí, El-Rufai kò sí níbẹ̀
Ọrẹ Òtítọ́jù

Ilé aṣòfin àgbà Naijiria ti kéde orúkọ márùndínláàdọ́ta gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ti ilé ṣe àyẹ̀wò fún sípò Mínísítà lábẹ́ ìjọba Orílẹ̀ yìí Bola Tinubu.

Títí di àsìkò táa ń ṣe àkójọ ìròyìn yìí, orúkọ Gómìnà tẹleri rí ni ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai ko si nínú àwọn tí ilé ṣàyẹ̀wò fún.

Òun nìkan kọ, àwọn méjì mii Sani Abubakar Danladi láti ìpínlẹ̀ Taraba ati Stella Okotete láti Delta.

Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà Sẹnẹtọ Godswill Akpabio,sọ pé àwọn ń retí àbọ̀ ìwádìí àwọn agbófinró lórí àwọn èèyàn mẹta wọ̀nyí kí wọ́n tó lè ṣayẹwọ wọn sípò mínísítà ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

Láti ọjọ́ Ajé tó kọjá tí wọ́n ti bẹrẹ àyẹ̀wò ni wọ́n tí forukọ wọn ránṣẹ́ àmọ́ kò padà síwájú ilé débi pé wọn yóò kéde wọn pẹ̀lú àwọn marundinlaadọta yoku.

Orúkọ àwọn ti ilé ti ṣàyẹ̀wò fún rèé gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nẹ́tọ̀ Godswill Akpabio ti ṣe kà wọ́n jáde:

Abubakar Momoh – Edo
Betta Edu – Kuros Riba
Uche Nnaji – Enugu
Joseph Utsev – Benui
Hannatu Musawa – Katsina
Nkeiruka Chidubem Onyejocha – Abiya
Stella Okotete – Delta
Uju Kennedy-Ohanenye – Anambra
Ahmed Dangiwa – Katsina
Olawale Edun – Ogun
Imaan Suleman Ibrahim – Nasarawa
Bello Muhammad Goronyo – Sokoto
Nyesom Wike – Rivers
David Umahi – Ebonyi
Mohammad Badaru Abubakar – Jigawa
Lateef Fagbemi – Kwara
Doris Aniche Uzoka – Imo
Yusuf Maitama Tuggar – Bauchi
Professor Ali Pate – Bauchi
Ekerikpe Ekpo – Akwa Ibom
Mohammed Idris – Nigeria
Olubunmi Tunji Ojo – Ondo
Dele Alake – Ekiti
Waheed Adebayo Adelabu – Oyo
John Eno – Profit Cross
Abubakar Kyari – Borno
Abdullahi Tijjani Gwarzo – Kano
Dr Mariya Bunkure – Kano
Isaac Salako – Ogun
Bosun Tijjani – Ogun
Tunji Alausa – Lagos
Tanko Sununu – Kebbi
Adegboyega Oyetola – Osun
Atiku Bagudu – Kebbi
Bello Matawalle – Zamfara
Ibrahim Geidam – Yobe
Simon Lalong – Plato
Lola Adejo – Lagos
Shuaibu Abubakar – Kogi
Tahir Mamman – Adamawa
Aliyu Sabi Abdullahi – Nigeria
Judge Ahmed Saidu – Gombe
Heneken Lakpobiri – Bayelsa
Father Maigari – Taraba
Zephaniah Jissalo – Abuja

Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí …

Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí …

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní àìrìnjìnà làì rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Bí ẹ bá
gbọ́ tẹnu ẹlòmí-ìn ,bí èyì n kọ́?
“A ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nínú ibojì yìí ju nínú ilé wa gangan lọ, bí a bá sì fẹ́ jẹun, a máa ń lo àwọn pálí táa fi sin àwọn òkú láti jókòó jẹun tàbí dùbúlẹ̀ tí a bá fẹ́ sùn”.

Ní ààrin gbùngbùn ibojì òkú ńlá tó wà ní ìlú yìí, ó ní àwọn géńdé ọkùnrin kan tí wọ́n ti fi ayé wọn jì fún ṣíṣe iṣẹ́ níbẹ̀.

Awọn ọkunrin yii to bii mẹtadinlogun ti wọn si maa n gbẹ ilẹ ibi itẹ, awọn kan naa lo maa n ba awọn eeyan sin oku bẹẹ si ni awọn ni wọn n gba ilẹ, ṣe itọju iboji okun Tundun Wada to wa ni ipinlẹ Kaduna lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Abdulwahid Abdulsalam to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta jẹ ọkan lara wọn, o si sọ fun BBC pe oun ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹẹdọgbọn bayii ti inu iboji oku si ti di ile oun.

Awọn oṣiṣẹ iboji oku
Abdulwahid ni ago meje abọ owurọ loun maa n fi ile oun silẹ lojoojumọ lati lọ bẹrẹ iṣẹ titi di alẹ si oun yoo to pada sile.

“Igba miran ti a ba ti pari iṣẹ lalẹ, awọn mii le pe wa wipe awọn fẹ gbe oku wa, bẹẹ si ni a o pa lilọ sile ti ayafi bi a ba sin ẹni naa tan.”

O ṣalaye pe iṣẹ yii jẹ iṣẹ ti awọn n ṣe lai ni ojulowo adehun iye owo oṣu wọn latọdọ ijọba ṣugbọn awọn ṣi n ṣe e lati gba ere lati ọrun wa.

“Idi ti a fi n ṣe iṣẹ yii ni pe ibi yii ni ibi isinmi ikẹhin fun gbogbo eniyan, a si tun n ṣe e nitori Ọlọrun.”

“Mo ni awọn mọlẹbi ti a sin sibi ati pe o ṣe e ṣe gan ko jẹ pe ibi yii naa ni wọn maa sin emi naa si nitorinaa, eleyi jẹ iṣẹ isin fun ara mi gan.”

“Nigba miran, lẹyin isinku, a o kan ṣi fila ori wa lati fi tọrọ agbe lọwọ awọn to wa lati sin oku lara eyi si la ti n fi bọ ara wa ati idile wa.”
Akẹgbẹ rẹ to tun jẹ ọga fun un lẹnu iṣẹ, Abdulaziz Ibrahim bẹrẹ iṣẹ yii ni ọdun mọkanlolọgbọn sẹyin o si sọrọ pe bi oun ṣe fi aye oun ji fun iṣẹ naa mu ki o wu oun bi ikankan ninu awọn mọ oun yoo ba le tọ ipasẹ oun.

“Inu mi yoo dun ki ọkan lara awọn ọmọ mi to ba fẹ ko ṣe iṣẹ yi toripe ohun to dara ni fun igbẹyin wọn”.

Abdulaziz ni wọn baba oun ati aburo baba oun sibẹ ti oun si maa n lọ bẹ oroori wọn wo lati gbadura fun wọn.

“nibi ni awọn naa ti ṣiṣẹ ki wọn to ku koda baba mi gan maa n wa ṣiṣẹ lasiko to ni ijamba kan lẹnu ibode ibi eyi to ja si iku rẹ.”

Awọn oṣiṣẹ iboji wa ke si ijọba atawọn ọlọdani lati nawọ iranwọ si wọn paapaa bo ṣe jẹ pe pupọ ninu irinṣẹ ti wọn n lo ni wọn maa n ya.

“Koda, sọburu ati diga yii, a maa n ya a wa sibi iṣẹ nitorinaa, a nilo iranlọwọ gidi lati le tẹsiwaju ninu iṣẹ yii.”

“Ilana yii ni a maa n gba sin ẹni to ba ti ku”
Gẹgẹ bi Abdulwahid ṣe ṣalaye, bi wọn ba ti gba ipe pe eeyan kan ku, wọn yoo tete bẹrẹ iṣẹ.

“Ohun akọkọ ni pe ẹni naa gbudọ jẹ musulumi niwọn igba to ti jẹ wipe iboji oki fun awọn musulumi ni eleyi lẹyin naa, a o bere lọwọ eeyan to pe wa lati sọ nipa iku ẹni naa fun wa lati bere boya oku naa jẹ ẹni to sanra tabi tiinrin”.

“Idi ti a fi maa n bere bi oku naa ṣe sanra si ati giga rẹ ni pe bi gbogbo eniyan ṣe yatọ naa ni oroori wọn naa yoo ṣe yatọ”.

O ni: “iṣẹ temi ni lati rii pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ nigba ti wọn ba si gbe oku naa de, a o gbe e sinu iboji.”

‘Fiimu ló máa ń tan àwọn èèyàn nípa àwọn oku’
Abdulaziz sọ pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ wípé oku ń wà láyé bí àwọn fíìmù ṣe máa ń ṣe àpèjúwe wọn, ó ní igbakiigba tí òun bá rí i òun kàn máa ń rẹrin ni.

“Ninu fíìmù, nígbà mìíràn ẹ o máa rí i ti òkú yóò máa lé ènìyàn, itanjẹ lásán ni gbogbo ẹ nítorípé lójú ayé gangan, kò sí nǹkan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.

“Mo ti ń ṣiṣẹ́ níbi láti Oṣù Keje ọdún 1992 mi ò sì tíì gbọ ìròyìn kankan tàbí rí nkànkan tó leè mú mi bẹru.”

Abdulaziz ni ọjọ́ kan tí òun kò le láyé láyé gbàgbé ni ọjọ́ tí ìjàǹbá pa èèyàn mejidinlogun tán yan-an-yan tí wọ́n ń rinrinajo tí wọ́n wá gbé oku gbogbo wọn wá sí ibojì òkú àwọn.

“Ó jẹ́ ọjọ́ tí mi ò le gbàgbé láyé lẹnu iṣẹ́ yìí. Ọjọ yẹn jẹ́ ọjọ́ aburú pẹlú bí àwọn obìnrin àti ọmọdé gan ṣe tún wà lára àwọn tó kú.”

Abdulwahid àti Abdulaziz ní yóò wu àwọn kí àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn sin òkú àwọn sí ibojì Tundun Wadda lẹ́yìn tí àwọn bá dágbére fáyé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe lára àwọn mọ̀lẹ́bí wọn kan tí wọ́n ti sin síb.ẹ̀

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọdún eégún ọlọ́dọọdún

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọdún eégún ọlọ́dọọdún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní tẹni n tẹni, ìran ọlọ́jẹ̀ ló lẹ̀kún, olórò ló lawo.
Yàtọ̀ sí ọdún eégún tó máa ń wáyé lọdọọdun lásìkò tó yàtọ síra wọn nílùú kan sikeji káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìjọba Gómìnà Ṣeyi Mákindé ti pinnu láti ní ọdún eégún kan lọtọ tí yóó jẹ́ tìjọba.

Gbogbo àwọn atọkùn eégún tá a mọ̀ sí Alágbàáà jákè -jàdò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọ́n ti fara mọ́ ìpinnu ìjọba yìí nínú ìpàdé tí àwọn aṣojú ìjọba ṣe pẹ̀lú wọn l’Ojọbọ, ọjọ́ kẹta, oṣù kẹjọ, ọdún 2023 yìí.

Nígbà tó ń kéde ìpinnu ọhún fún gbogbo ayé gbọ́, Kọmiṣanna fétò ìròyìn, àṣà àti irinna afẹ níìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀mọ̀wé Wasiu Ọlatubọsun, sọ pé ìjọba yóò ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ọdún eégún, níbi tí gbogbo eégún ìpínlẹ̀ náà yóó ti máa dá àwọn lárayá, níbì kan náà, lọ́jọ́ kan náà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ Kí àwọn eégún máa fi eré dá àwọn èèyàn láyayá jẹ́ nǹkan ọ̀tun, èyí tí kò tí ì sírú ẹ̀ níbi kan rí lórílèdè yìí. Èyí yóò ṣàfihàn wa gẹ́gẹ́ bíi àwòṣe rere fáwọn ìpínlẹ̀ yòókù gẹ́gẹ́ bíi àkọmọ̀nà ìpínlẹ̀ yìí tó sọ pé

“Ajíṣe bíi Ọ̀yọ́ là á rí …”

“ Ṣíṣe irú nǹkan báyìí yóò jẹ́ ọ̀nà tí owó yóò fi máa wọlé sápò ìjọba, nítorí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ yóó lè máa kó owó wọn wá láti wòran àwọn eégún láti ilẹ̀ òkèèrè káàkiri”.

Yàtọ̀ sí pé gbogbo àwọn alágbàáà tó wà níbi ìpàdé ọhún ni wọ́n fara mọ́ ìpinnu ìjọba náà, gbogbo wọn ni wọ́n ti ṣèlérí pé àwọn yóó ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba lórí ìpinnu náà.

Bàbá ogójì ọdún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta lò pọ̀ ti rẹ́wọ̀n he

Bàbá ogójì ọdún tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta lò pọ̀ ti rẹ́wọ̀n he

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó bá ṣe ohun tẹ́nìkan kò ṣe rí, kò láìfì kójú onítọ̀hún ó rí n tẹ́nìkan kò rí.
Ṣé wọ́n ní ràdàràdà kìí báwọn lágbà,nì báyìí,wọ́n ti wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Abdulahi Lawal, ẹni ogójì ọdún lọ iwájú Onídàájọ A.B Olagbegi Adelabu, tilé-ẹjọ́ Májísírétí kan tó wà nílùú Ikorodu, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ẹsùn tí wọ́n fi kàn án ni pé ó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta kan tó jẹ́ ọmọ aráalé rẹ̀ sùn.

Ọlọ́pàá olùpẹ̀jọ́, Abilékọ Ọlawumi Ọsinbajo, tó fojú Lawal balé-ẹjọ́ sọ pé inú oṣù Kẹfà, ọdún yìí, ní Lawal hùwà rádaràda náà l’Ójúlé kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Òpópónà Owutu, lágbègbè Agric, nílùú Ikorodu, ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ó ní ṣe ni Lawal gbé ọmọ ọdún mẹ́ta ọ̀hún wọnú yàrá rẹ̀ lákòókò tó ń bá a ṣeré lọ́wọ́ níwájú òbí rẹ̀, tó sì fipá bá a sùn.

Nígbà tí màmá ọmọ ọhún ń wá a káàkiri, tó sì ń pariwo rẹ̀ lọmọ náà jáde nínú yàrá Lawal, tí ẹjẹ́ sì wà lára aṣọ rẹ̀ yánna- yànna

Lójú-ẹ̀sẹ̀ ní màmá ọmọ ọ̀hún ti lọọ fọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà létí, tí àwọn agbófinró yìí sì lọọ fọwọ́ òfin mú un nílé rẹ̀.

Gbogbo ẹsùn tí ọlọ́pàá náà fi kàa Lawal pátá ló ní òfin ìlú Èkó kò fààyè gbà rárá.

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ náà, Abilékọ A.B Olagbegi, kò tiì tẹ́tí gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ rárá. Ó ní kí wọ́n lọ̀ọ́ gbà àmọ̀rán wà lórí ẹjọ́ náà lọdọ àjọ kan tó ń gba ilé-ẹjọ́ nímọ̀ràn, ‘Lagos State Directorate Of Public Prosecution’ DPP.

Bákan náà ló ní kí wọ́n lọ̀ọ́ jù ú sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà nílùú Èkó, títí ìgbẹ́jọ́ máa fi wáyé.

Ó sún ìgbẹ́jọ́ sọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí.

Àwọn ọmọ-ọwọ́ nìkan ni ọyàn mímu wà fún – ìyàwó Mákindé

Àwọn ọmọ-ọwọ́ nìkan ni ọyàn mímu wà fún – ìyàwó Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹ̀là lọ̀rọ̀ bí a ò bá làá , kìí yéni ní báyìí,Ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abilekọ Tamunominini Makinde, ti ṣàpèjúwe ọyàn gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ tó dáa, tó dùn, tó ṣara lóore, tó sì dáa fún gbogbo èèyàn láti máa mu.

Àmọ́ ṣáá, àwọn ọmọ ọwọ́ nìkan níyàwó Gómìnà yìí tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó nílò oúnjẹ aṣara lóore náà.

Níbi ètò ọlọ́dọọdún tí wọ́n fi ṣàmí ayẹyẹ fífún ọmọ lọ́yàn lo ti sọ̀rọ̀ náà n’Íbàdàn, l’Ójọ́bọ, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 yìí.
Nígbà tó n sọ pàtàkì fífún ọmọ lọ́yàn nìkan fún àwọn obìnrin, Abilékọ Mákindé fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọyàn loúnjẹ tó dáa jù tí ìkókó gbọdọ̀ mu láìjẹ oúnjẹ mí-ìn rárá láàrin oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ tí wọ́n bí i sáyé.

Àkòrí ayẹyẹ tọdúun yìí ló dá lórí bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe lè máa fún ọmọ wọn lọ́yàn dáadáa.

Ó ṣàpèjúwe omi ọyàn gẹ́gẹ́ bíi omi tó mọ́, tó sì jẹ́ oúnjẹ aṣaralóore tó dáa jù fáwọn ọmọ ọwọ́.

O wáá dúpẹ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ẹnjinnia Ṣeyi Mákindé, fún bó ṣe ń sàtìlẹyìn fún àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ní ìpínlẹ̀ náà.