Home Blog Page 45

Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe fẹ́ràn ìjọba Burkina Faso

Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe fẹ́ràn ìjọba ológun Burkina Faso

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni ọdún mẹ́tadínlógójì ni Ibrahim Traoré tó ń tukọ̀ Burkina Faso, ló ti ṣèlérí láti gba orílè-èdè náà silẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun.

Ọpọ eeyan ni Afrika lo fẹran ohun ti ọkunrin naa duro fun ti wọn si n woye pe o n tọ ipasẹ awọn adari rere to ti ṣejọba ṣaaju ni orilẹede naa bii Thomas Sankara.

Oluwadii kan ninu ajọ Control Risks sọ fun akọroyin pe “Ọpọ eeyan lo gba tirẹ. Mo ti gbọ ti awọn onkọwe atawọn oluṣelu lawọn orilẹede bii Kenya n sọ pe iru ọkunrin naas gan lawọn eeyan n wa.

“Awọn ọrọ to n sọ n ṣapejuwe bi aye ode oni ṣe ri ti pupọ awọn ọmọ ilẹ Afrika si n bere nipa ibaṣepọ ilẹ wọn pẹlu awọn oyinbo alawọ funfun ati eredi ti iya si fi n jẹ ọpọ eeyan ni Afrika lẹyin ti wọn gba ominira tan.

Lẹyin to fi ipa gba ijọba lọdun 2022, Traoré fopin si ibaṣepọ orilẹede rẹ pẹlu orilẹede France, to si tọwọ bọwe ajọṣepọ tuntun pẹlu Russia.

Lara awọn ohun to ṣe ni bo ṣe ṣagbekalẹ ileeṣẹ iwakusa ijọba, to si sọ pe awọn ileeṣẹ iwakusa ilẹ okeere gbọdọ maa san ida 15% owo ti wọn ba n pa fun ijọba ilẹ naa, ki wọn si maa gba awọn ọmọ orilẹ naa siṣẹ.

Lara awọn ti ofin naa kan ni ileeṣẹ Nordgold to jẹ ti orilẹede Russia.

Traoré sọ pe Burkina Faso gbọdọ jẹ lara ọrọ to wa ninu rẹ dipo ki awọn eeyan kan lati ilẹ okere maa ji ko.

Ijọba ologun rẹ tun kọ ileeṣẹ nla kan ti wọn ti n fọ wura, o tun ṣagbekalẹ ile nla ti wọn yoo maa ko wura iyebiye si, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ lorilẹede ọhun.

Eyii n tumọ si pe awọn ileeṣẹ ilẹ okeere yoo maa koju isọro nibẹ.

Laipẹ yii ni ijọba Traoré gba ileeṣẹ iwakusa aladani lati ilẹ okere meji, so ti sọ pe oun ṣi maa ja ọpọ ileeṣẹ iwakusa lati ilẹ okere mii gba mọ awọn to n ṣakoso rẹ lọwọ.
Ọkunrin naa ti di gbajumọ lori ayelujra ti awọn eeyan si n kọ oniruru nnkan nipa rẹ, yala o jẹ ododo abi bẹẹ kọ.

Koda, awọn eeyan ti lo ẹrọ AI lati ṣe fidio bi awọn gbajumọ bii R Kelly, Rihanna, Justin Bieber ati Beyoncé ṣe n kan sara si lọna ati jẹ ki awọn eeyan tunbọ gba tirẹ.

Asiko ti ọkunrin naa sọrọ nibi ipade Afrika ati Russia kan lọdun 2023 ni irawọ rẹ kọkọ buyọ lasiko to sọ fun awọn adari ni Afrika ki wọn dẹkun ati maa sa tọ awọn alawọ funfun lọ fun iranlọwọ ni gbogbo igba.

Awọn ileeṣẹ iroyin ni Russia gbe iroyin naa to bẹẹ to fi tan kaakiri agbaye.

Amọ ṣa, lara awọn ti ko gba ti Traoré ni Aarẹ France, Emmanuel Macron.

Bo tilẹ jẹ pe o kuna lati pari ijijagbara awọn ẹlẹsin Musulumi kan to ti n waye fun ọdun mẹwaa gẹgẹ bi ileri rẹ, awọn eeyan ṣi gba tirẹ.

Ijọba ni o tun fiya jẹ awọn ti ko gba tirẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako.

A gbọ pe ijọba Traoré tun gbogun ti awọn akọroyin to n kọ iroyin ti ko tẹ lọrun, bẹẹ lo n fi oju awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan ri mabo.

Nigba ti igabkeji adari ajọ International Crisis Group, Rinaldo Depagne, n da si ọrọ naa, o ni awọn eeyan fẹran Traoré ni Afrika latari pe o jẹ ọdọmọde.

O ni “O mọ nipa ori ayelujra daadaa – o si mọ bi wọn ṣe n fun orilẹede ti ogun ti sọ dahoro ni igbagbọ pe wọn ni ọjọ ọla rere.”

Depagne sọ fun akọroyin pe “O ni imọ nipa oṣelu daada o si mọ bi wọn ẹ n wu eeyan lori.”

Ọdun 1983 ni Sankara gori alefa lẹyin iditẹgbajọba kan nigba to wa lẹni ọdun mẹtalelọgbọn ki wọn to gbẹmi oun naa lẹyin ọdun mẹrin ninu iditẹgbajọba mii.

Lẹyin iditẹgbajọba naa ni orilẹede wọn ti wa labẹ ojiji orilẹede France ki Traoré to gba ọpa aṣẹ ilẹ naa bayii.

Onimọ nipa eto abo orilẹede ghana, Ọjọgbọn Kwesi Aning sọ fun akọroyin pe “Ijọba awarawa ti kuna lati fun awọn ọdọ ni ireti ọjọ ọla to dara ni Afrika, ko fun awọn ọdọ naa niṣẹ tabi eto ilera to peye.”

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Traoré n fun awọn ọdọ naa ni ọna abayọ lo mu ki wọn fẹran rẹ.
Traoré lawọn eeyan sọ oju si lara julọ lasiko iburawọle Aarẹ Ghana, John Mahama.

Niṣe lo wọ gbagede eto naa pẹlu aṣọ ologun lọrun rẹ toun ti ibọn ilewọ lẹgbẹ rẹ.

Ọjọgbọn Aning ni “Olori orilẹede mọkanlelogun lo ti wa nibẹ ko to de ṣugbọn nigba ti Traoré wọle, ariwo sọ, koda awọm ẹṣọ alabo Aarẹ mi gan n sare tete tẹle lẹyin.”

Traoré yatọ si awọn Aarẹ ni Afrika to n fi agidi di ipo ijọba mu.

Ninu atẹjade kan ti ajọ IMF fi lede ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, IMF sọ pe bo tilẹ jẹ pe nnkan le ti eto abo si mẹhẹ, eto ọrọ aje orilẹede naa yoo gberu si lọdun yii.
Wayi o, oniruru iroyin lo ti n gbode pe awọn kan n gbe igbesẹ lati fi agidi yọ ọdọkunrin naa lori oye.

Olufẹhonuhan kan to tun jẹ olorin, Ocibi Johann sọ fun ileeṣẹ iroyin Associated Press pe “Nitori Collin Powel pa irọ, wọn sọ Iraq dahoro. Brack Obama parọ, wọn gbẹmi Gaddafi. Ṣugbọn lasiko yii, irọ wọn ko ni tu irun kankan lara wa.”

Yatọ si orilẹede naa, awọn eeyan ṣe iwọde kaakiri agbaye, pẹlu ilu London nilẹ Gẹẹsi, ni atilẹyin fun Traoré.

Lẹyin awọn iwọde naa lo dupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye fun atilẹyin wọn.

Yoo ṣoro lati sọ bi igbẹyin rẹ yoo ṣe ri amọ oun atawọn ologun ni Mali ati Niger ti da rugudu silẹ ni Afrika, awọn orilẹede mii si ti n le awọn ọmọ ogun France kuro nilẹ wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ṣaaju.

Yatọ si eyii, awọn orilẹede mẹta naa tun ti fa ara wọn yọ kuro ninu ẹgbẹ ajọ Ecowas.

Amọ awọn onimọ ti sọ pe Traoré gbọdọ ṣiṣẹ ki alaafia jọba to ba fẹ ni akọsilẹ rere dipo ko maa gbogun ti awọn ti ko ba fẹran rẹ.

Ọlọ́pàá ń lo àyẹ̀wò DNA fún àwọn ọmọ tí wọ́n rí he nírònà

Ọlọ́pàá ń lo àyẹ̀wò DNA fún àwọn ọmọ tí wọ́n rí he nírònà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ọlọpaa ní East London ti bẹrẹ sí ní ya ojúlé sí ojúlé báyìí láti ṣàwarí ìyá ọmọ kékeré jòjòló kan tí wọ́n rí lẹ́ẹ̀bá ọ̀nà.

Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ti ya ojule to le ni irinwo bayii ninu igbiyanju awọn lati ṣawari iya ọmọ naa.

Inu apo kan ni wọn ti sawari ọmọ ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Elsa lagbegbe Newham ki ẹnikan to n mu aja rẹ rin to ri.
Nigba ti wọ n ṣayẹwo ẹjẹ DNA rẹ, wọn ṣawari pe ọmọ naa n ibatan meji mii – ọkunrin ati obinrin – ti wọn ti kọkọ ṣawari lẹba ọna bii tirẹ lọdun 2017 ati 2019.

Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ti n rawọ ẹbẹ pe ki awọn obi ọmọ naa jade, wọn ko tii mọ ẹyẹ to ṣu awọn ọmọ mẹta naa titi di asiko yii.
Lati ọsẹ marun un sẹyin lawọn agbofinro ilẹ Gẹẹsi ti jawe sobi akitiyan wọn lati ṣawari awọn obi awọn omọ naa, wọn si fun akọroyin lanfani lati maa tẹle wọn kiri bi wọn ṣe n ṣiṣẹ ọhun.

Ọlọpaa ti bẹrẹ si ni kan ilẹkun ile awọn eeyan lagbegbe naa bayii lati maa gba DNA wọn lati ṣayẹwo rẹ boya o ba ti ọmọ tuntun naa mu.

Wọn tun ti n kan si awọn ti wọn fi DNA wọn silẹ lọdọ ijọba lati wo o boya o ba ti awọn ọmọ ọhun mu.
Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2017 ni wọn kọkọ ri Harry ni nnkan bii maili kan sibi ti wọn ti ṣawari Elsa yii.

Inu igbo kan ni ọmọ naa wa pẹlu aṣọ ti wọn fi we lara.

Ọdun kan ati oṣu mẹrin lẹyin naa ni wọn ri ibatan rẹ obinrin, Roman, lori ijoko gbọrọ kan ni gbagede ti awọn ọmọde ti n ṣere.

Ọlọpaa ni inu apo ti wọn fi n ta ounjẹ nile itaja igbalode ni wọn gbe ọmọ naa si ninu aṣọ kan lasiko otutu.

Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to ṣawari awọn ọmọ ọhun lo fun wọn lorukọ ti wọn n jẹ.

Ayẹwo DNA fi han gbangba pe iya kan naa lo bi awọn mejeji.

Ọdun marun un lẹyin awọn mejeji ni wọn ri Elsa ti ayẹwo wọn si fi han pe iya kan naa lo bi awọn mẹtẹta.

Ninu oṣu Kinni ọdun 2025 yii ni ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba kede pe oun yoo san £20,000 fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ijọba yoo ṣe ri iya tabi awọn obi ọmọ naa.

Ìdí tí Tinubu ṣe fi òfin de kíkó àwọn ọjà kan wọlé sí Nàíjíríà

Ìdí tí Tinubu ṣe fi òfin de kíkó àwọn ọjà kan wọlé sí Nàíjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Tinubu ti fòfin de kíkó ọjà wọlé láti ilẹ òkèèrè sí Nàìjíríà pàápàá jùlọ àwọn nǹkan tí orílè-èdè Nàìjíríà lè ṣe.

Aarẹ Tinubu tun sọ gbedeke iye awọn akọṣẹmọṣẹ ilẹ okeere to le wọ Naijiria lati wa ṣiṣẹ tawọn ọmọ Naijiria naa le ṣe funra wọn.

Minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris, lo fidi ọrọ yii mulẹ lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ to waye nileeṣẹ ijọba l’Abuja lọjọ Aje eyi ti Aarẹ Tinubu dari rẹ.
Minisita ni igbesẹ nla ti yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje Naijiria ni igbesẹ ti aarẹ gbe yii, ati pe yoo tun mu igbelarugẹ ba awọn nnkan ti orilẹede Naijiria n pese.

Ọgbẹni Idris ni ọkan gboogi ni igbesẹ yii jẹ ninu akitiyan ijọba aarẹ Tinubu lati mu ọrọ aje Naijiria pada bọ sipo.
O ni Tinubu n wo awokọṣe Aarẹ Donald Trump Amẹrika pẹlu bi Trump ṣe kede wi pe orilẹede Amẹrika ni akọkọ ninu gbogbo nnkan ti ijọba oun n ṣe lọwọ yii.

Minisita eto iroyin sọ pe igbesẹ yii ko ni jẹ ki orilẹede Naijiria gbẹkẹle ọja ilẹ okeere nikan mọ

”Eto yii yoo jẹ ki aṣa okowo tuntun eyi to ni ṣe pẹlu orilẹede Naijiria nikan gbilẹ daadaa.

Igbesẹ yii yoo tun jẹ kawọn ọmọ Naijiria jẹ anfaani okowo ijọba pẹlu bi ijọba ṣe n nawo, ra ọja ati bi wọn ṣe n mu eto ọrọ aje gbooro,” Minisita lo sọ bẹẹ.

Minisita eto iroyin ati ilanilọye sọ pe aarẹ ti sọ fun agbẹjọro agba ni Naijiria lati sọ igbesẹ naa di ofin.

O ni igbesẹ yii ti yoo maa ṣe igbelarugẹ nnkan ti orilẹede Naijiria n pese jẹ ọkan gboogi ninu eto imugbooro ọrọ aje ijọba Aarẹ Tinubu.

Ọgbẹni Idris sọ pe ajọ Bureau of Public Procurement (BPP) gbọdọ ri pe gbogbo ẹka ijọba lo n lo nnkan ti wọn ṣe ni Naijiria bayii.

Minisita ni ajọ BPP yoo ṣe akojọpọ awọn olokowo ọmọ Naijiria ti wọn yoo maa ta nnkan ti wọn n ṣe fun gbogbo ileeṣẹ ijọba.

Ọgbẹni Idris fikun ọrọ rẹ pe ajọ BPP ti fi awọn oṣiṣẹ wọn si gbogbo ileeṣẹ ijọba lati maa tọpinpin bi wọn ṣe n lo nnkan tawọn ileeṣẹ ati olokowo Naijiria n ṣe.

O ni lati akoko yii lọ ko si ileeṣẹ ijọba to gbọdọ ra nnkan ti wọn n ṣe ni Naijiria nilẹ okeere mọ.

Minisita ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ti o ba pọn dandan ki ijọba tabi ẹnikẹni lo agbaṣẹṣe lati ilẹ okeere, iru agbaṣẹṣe bẹẹ gbọdọ lo imọ ẹrọ ni Naijiria tabi ko kọ awọn ọmọ Naijiria ni iru imọ ẹrọ to ba n gbe bọ wa Naijiria.

Idris ni gbogbo ileeṣẹ ijọba ni lati sọ erongba wọn lori nnkan ti wọn ba fẹ ra fun ijọba bayii.

O ni ijiya wa fun ileeṣẹ ijọba to ba kọ lati ṣe bẹẹ, ati pe ijọba yoo fagile nnkan ti wọn fẹ ra nilẹ okeere.

Minisita ni ileesẹ ti wọn ti n ṣe ṣuga wa lara awọn ileeṣẹ to nilo itaji ni Naijiria.

Idris ni nnkan ti ko bojumu ni bi Naijiria ti n ko ṣuga wọle lati ilẹ okeere nigba ti ileeṣẹ to n ṣe ṣuga ni Naijiria ti dẹnukọlẹ.

O ni awọn agbaṣẹṣe ko ni lanfaani lati maa ko ọja to ba wu wọn wọle si Naijiria mọ, nigba tawọn ileeṣẹ Naijiria n ku lọ.

Minisita ni owo ijọba gbọdọ maa ṣiṣẹ fawọn ọmọ Naijiria bayii.

Ìdìbò Ààrẹ 2027! Seyi Makinde ń palẹ̀mọ́

Ìdìbò Ààrẹ 2027! Seyi Makinde ń palẹ̀mọ́

Oriyọmi Lukman

Ko le si iyalẹnu kankan ti o le ba eniyan ti o ba sele wi pe gomina ipinle Oyo onimo ero Seyi Makinde ba dupo Aare ni odun 2027 lati inu egbe oselu PDP.
Siwaju ibo odun 2023, ireti opolopo eniyan ni wi pe omo  bibi agbegbe Gusu ni yio di Aare. Ni odun 2023, Onimo ero Seyi Makinde se gudu gudu meje ati yaaya mefa ki Asiwaju le de ipo Aare naa.
Fun idi eyi awon igbimo awon omo egbe PDP wa pe birikoto birikoto ti gbogbo won si panupo fa onimo ero Seyi Makinde kale fun ipo Aare l’odun 2027.
Nibi ipade yii pelu olokan o jokan oniroyin, gbogbo omo egbe PDP fi idi e mule sinsin pe Seyi Makinde ni eni ti o ni akaki, danto, ati pe o dangangia lati le fa kale fun ise ribiribi ni ilu Oyo.
Dr. Adetokunbo Pearse, Alhaja Olorunkemi ati bee bee lo soro, won si fa komokun re yo nibi ipade yii ti o waye ni ojo Weside, ojo kerinla, osu yii (14th May, 2025). Won ni Seyi Makinde gege bi o se je Oloooto, Onisuuru, Onifarada, Omowe, Oniwatutu pelu ogbon atinuda ti eniyan le fi dari ilu.

 

 

 

Ọ̀gá Àgbà àjọ JAMB banújẹ́ , lórí èsì ìdánwò UTME ọdún 2025 tó jáde

Ọ̀gá Àgbà àjọ JAMB banújẹ́ , lórí èsì ìdánwò UTME ọdún 2025 tó jáde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ JAMB tó ń ṣàkóso ìdánwò àti gbaniwọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì àt’àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn ní Nàìjíríà ti sọ pé àṣìṣe wà ninú èsì ìdánwò UTME tọdún 2025 yìí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.

Ọgagba àjọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, bú sẹ̀kun gbaragada nígbà tó fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn lónìí Ọjọ́rú nílùú Àbújá.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Oloyede ní “nǹkan tó yẹ kó jẹ́ ayọ̀ ti di ìbànújẹ́ nítorí àṣìṣe tó wáyé.”
Akòwé àgbà JAMB náà kéde pé bíi 379,997 àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe ìdánwò naa ni yóò tún ìdánwò ọhun ṣe báyìí.

Eyi ko ṣẹyin awọn kudiẹ kudiẹ to waye to ṣokunfa bi ọpọ akẹkọọ ṣe fidirẹmi ninu idanwo naa.
Ajọ JAMB fidi rẹ mulẹ loju opo X rẹ pe mẹtadinlọgọjọ (157) ninu aadọrun-un le lẹẹgbẹrin din mẹta (887) ibi ti idanwọ ọhun ti waye ni aṣiṣe ti waye.

Ajọ naa sọ pe eyi gan lo ṣokunfa bi maaki ọpọ akẹkọọ ti ṣe idanwo lawọn ibikan ṣe lọọlẹ gan an.

NI bayii, gbogbo awọn akẹkọọ tọrọ kan ni ajọ JAMB yoo kan si lati tun idanwo naa ṣe laipẹ.

Lọjọ Aje to kọja ọjọ kejila oṣu Karun un yii ni ajọ JAMB kede pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo esi idanwo UTME ọdún 2025 t’awọn gbe sita.
Agbẹnusọ ajọ JAMB, Fabian Benjamin, ṣalaye pe igbimọ alaṣẹ ajọ naa yoo ṣe agbeyẹwo ọhun ni kiakia.

O ni gbogbo ohun to ni ṣe pẹlu idanwo naa ni wọn yoo ṣe agbeyẹwo rẹ fínífíni.

Eyi ṣẹlẹ tori bi ọpọ eeyan ṣe sọrọ nipa esi idanwo UTME ọdún yìí eyi ti ọpọ akẹ́kọ̀ọ́ fìdírẹmi ninu rẹ.

Ọgbẹni Benjamin sọ saaju wipe ajọ JAMB yoo ṣe ohun to tọ tó bá jẹ pe loootọ ni kudiẹ kudiẹ wa ninu eto idanwo naa.
Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa julọ awọn ti esi idanwo naa kan gbọngbọn, ti bọ sori ayelujara lati fi ẹdun ọkan wọn han.

Ọpọ akẹkọọ lo ni esi idanwo tawọn gba kọja gan-an ko buru to ti 2025 yii.

Akọle kan ti i ṣe #thisisnotmyresult, ni awọn eeyan naa n lo lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si n pe fun atunyẹwo esi idanwo yii.

Esi ti JAMB fi sita kede pe bii miliọnu kan aabọ akẹkọọ (1.5 million candidates), ni ko gba to maaki igba (200) ninu idanwo naa.

Itumọ eyi ni pe ida ọgọrin (80%) akẹkọọ ni ko gba maaki igba ninu irinwo (400).

Iṣẹ mẹrin ti maaki ọkọọkan jẹ ọgọrun-un (100) ni awọn akẹkọọ naa jokoo ṣe ninu UTME, apapọ rẹ lo jẹ irinwo (400).

JAMB ṣalaye pe akẹkọọ yoo kọkọ fi orukọ silẹ, yoo jokoo ṣedanwo, esi yoo si jade. Igbesẹ mẹta naa ko ju bẹẹ lọ.

Àjọ NAPTIP k’ọ́mọ Naijiria 78 padà wálé lóko ẹrú Abidjan

Àjọ NAPTIP k’ọ́mọ Naijiria 78 padà wálé lóko ẹrú Abidjan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò dín ní ọmọ orilẹede Naijiria méjì dínlọ́gọ́rin (78), ti àjọ tó n gbógun ti fífini sọ̀kọ̀ sílẹ̀ ibòmí-ìn; National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP), kó padà sí orílẹ-èdè yìí báyìí láti Abidjan, orílè-èdè Côte d’Ivoire.

Nnkan bii aago mọkanla ku iṣeju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ Satide ni baaluu to gbe wọn balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed, l’Ekoo.

Binta Adamu Bello, ọga agba NAPTIP to tẹwọ gba awọn eeyan naa, ṣeleri pe awọn to wa nidii iwa ifinisọko silẹ okeere lọna aitọ naa yoo koju ofin.

”Ṣaaju ni a ti kọkọ mu awọn eeyan kan to wa nidii okoowo to lodi sofin yii, wọn yoo si foju bale-ẹjọ.

”Si ẹyin ti ẹ pada wale yii, a ba yin yọ, a si fẹẹ kẹ ẹ mọ pe orilẹede Naijiria wa pẹlu yin”
Bẹẹ ni ọga NAPTIP wi.

Bakan naa ni ajọ yii ti bẹrẹ ajọsọ pẹlu awọn alẹnulọrọ l’Abidjan, eyi to n ṣe akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria to foju wina ilokulo naa.
Gẹgẹ bi ọga NAPTIP ṣe wi nipa awọn ṣẹṣẹ de ọhun, o ni o to awọn mẹrin ninu awọn ọmọbinrin aarin wọn ti wọn wa ninu oyun.

Ọjọ ori awọn ọmọ naa ko to nnkan kan, gẹgẹ bi alaye NAPTIP.

Wọn fi kun un pe ọjọ ori awọn eeyan naa wa laaarin ọdun mẹtala si ọgbọn ọdun.

Bakan naa ni NAPTIP fidi ẹ mulẹ, pe awọn ọmọ ọwọ tun wa lara awọn ṣẹṣẹ de lati Abidjan naa.

Lapapọ, obinrin marundinlọgọrin (75) lo wa ninu ni awọn ti wọn ko de naa, ọmọ ọwọ meji.

Wọn fi kun un pe awọn ọkunrin meji kan naa tun wa ti wọn mu kuro loko ẹru ilokulo ti wọn ba ara wọn l’Abidjan.

Irisi awọn eeyan naa fi han pe ọhun o rọgbọ rara, ebi ati iṣẹ han lara wọn.

Ọkan lara wọn, Clara( ki i ṣe orukọ rẹ gan-an) ṣalaye pe oun le ma bọ ninu idaamu toun pa pade l’Abijan.

O ni awọn ọga fi gbogbo iya jẹ awọn patapata, ko si jọ pe oun le gbagbe gbogbo ohun oju ri lẹyin odi.

Ìdí tí omijé fi jábọ́ lójú mi léyìn àmì-ẹ̀yẹ AMVCA – Femi Adebayo

Ìdí tí omijé fi jábọ́ lójú mi léyìn àmì-ẹ̀yẹ AMVCA – Femi Adebayo

Oṣere ati agberejade Femi Adebayo ti ṣalaye idi ti o fi bu omije loju lẹyin ti o gba ami ẹyẹ Oṣere Asiwaju to Dara julọ nibi ayẹyẹ Africa Magic Viewers’ Choice Awards (AMVCA) ikokanla iru re fun ipa to ko ninu “Seven Doors.”

O ka isesi atokanwa rẹ si awọn idi ti ara ẹni ti o je pe oun ati Allah nikan lo mọ si nigba to n fi imoore han si gbogbo eniyan ti o ṣe alabapin si aṣeyọri rẹ. Oṣere naa ṣapejuwe ami-eye naa gẹgẹ bi ohun “ti o tọ si nitootọ” o si mọriri idanimọ naa.

O kowe lori Instagram, “Ami-ẹyẹ ti o tọ si mi ni otitọ, ati pe mo dupẹ pupọ fun akoko yii pẹlu gbogbo okun ti ẹmi mi. Idi kan pato fun omije to jabo loju mi jẹ mimọ si emi ati Allah nikan.

“E ṣeun pupo gbogbo eniyan ti o ṣe alabapin si akoko manigbagbe yii.”

 

 

Olórin lè lu àlùyọ láì lu jìbìtì ní Naijiria – Spyro

Olórin lè lu àlùyọ láì lu jìbìtì ní Naijiria – Spyro

Olorin Oludipe David, ti a mọ si Spyro, igbagbọ idi to fi se bẹẹ nínú ìfọ̀rọ̀werọ kan pẹ̀lú Saturday Beats, ó ṣàkíyèsí pé, “A kò tijú ìhìnrere Jesu Olugbala, ìdí niyi tí mo fi wà níhìn-ín pẹ̀lú Bibeli mi, tí mo sì máa ń wọ fìlà ọmọ Jesu mi nígbà gbogbo.

Fun awọn afenifere ti won n woye boya ki won nireti eyi gẹgẹ bi asayan aṣa deede, akọrin naa fi han pe, “Mi o kii lo sibi gbogbo pẹlu Bibeli mi. Mo kan pinnu lati ni Bibeli mi gẹgẹ bi apakan ti ẹya eso mi ni alẹ oni. ”

Ni ile-iṣẹ kan ti won n dalebi nigba gbogbo bi o se n satileyin fun awon ohun ti ko dara to ati awon ti o fa tibeere, Spyro sọ pe iṣẹ iranse rẹ ni lati ṣe orin ti o mọ ati di mimọ fun un.

Nigba ti o n gba awọn ọdọmọkunrin ni iyanju pe wọn le ṣaṣeyọri laisi ibajẹ awọn iwulo wọn, akọrin naa sọ pe, “Idi ti ọpọlọpọ awọn eniyan fi ye adehun ni nitori pe wọn lero pe ti o ko ba ṣe bẹẹ, won ko le ni owo. Ṣugbọn emi jẹ ẹri. Wo mi, Mo n ṣe ati mo si n ri ṣe. Ati pe o mọ, mi o ṣe orin ti o ni inira. Mo ṣe orin ti o mọ ati pe mo si n la ni ile-iṣẹ naa. Nitori naa, maṣe yese. Awọn ti o mọ Ọlọrun wọn yoo jẹ alagbara won yoo si se rere; iṣoro naa kii se orin, iṣoro naa ni mimo Ọlọrun.

JAMB ní àwo̩n aké̩kò̩ó̩ máa tún ìdánwò se

JAMB ní àwo̩n aké̩kò̩ó̩ máa tún ìdánwò se

Yínká Àlàbí

Ajo̩ JAMB ti jade lati be̩be̩ lo̩wo̩ awo̩n ake̩ko̩o̩ to se idanwo o̩dun yii, paapaa julo̩ awo̩n ake̩ko̩o̩ ipinle̩ Eko ati Owerri.
Esi idanwo yii jade ni o̩jo̩ ke̩san-an osu yii ni eyi to mu ki awo̩n ake̩ko̩o̩ to po̩ fidi re̩mi.
Ninu awo̩n ake̩ko̩o̩ bii milio̩nu meji, milio̩nu kan aabo̩ ni maaki wo̩n ko wo̩ ilaji. Eyi tii se igba ninu irinwo maaki.
Esi idanwo yii si n fa ede aiyede lori gbogbo redio ati telifiso̩n. Be̩e̩ ni e̩rin ko yato̩ to fi de ori ayelujara.
Ede aiyede ifidire̩mi o̩po̩ ake̩ko̩o̩ da lori ta ni o ye̩ ki a da e̩bi aise daadaa awo̩n ake̩ko̩o̩ naa ru?. Awo̩n kan tile̩ ti mu awo̩n ake̩ko̩o̩, wo̩n ni ere wo̩n ti po̩ ju, wo̩n o ki n ka iwe. Yahoo, Yahoo ni gbogbo wo̩n n se. Awo̩n kan ti sare da e̩bi ru awo̩n obi, wo̩n ni awo̩n obi naa kuna nipa abala tiwo̩n, wo̩n ni ileewe “pari is̩e̩” ni o̩po̩ wo̩n n wa kiri.
Awo̩n kan tile̩ mi awo̩n oluko̩ ni ko kun oju osuwo̩n. Wo̩n ni o̩po̩ oluko̩o̩ ni ko raaye ko̩ awo̩n ake̩ko̩o̩.
Awo̩n kan ni ileewe aladaani ni ki a di e̩bi naa fun, wo̩n ni awo̩n ni wo̩n da awo̩n ileewe ti ko yanranti sile̩, wo̩n ni awo̩n ileewe ti ko ni yara ikawe to dara, ti ko ni yara awo̩n saye̩nsi to kun oju owo.
Awo̩n kan ni ijo̩ba lo ni gbogbo e̩bi, nitori pe awo̩n olube̩wo wo̩n ko sise̩ wo̩n bii is̩e̩, apo iwe owo ni wo̩n n lo̩ gba ni awo̩n ileewe ti wo̩n n lo̩ s’abe̩wo si.
Ju gbogbo re̩ lo̩, o̩ga patapata ajo̩ JAMB O̩jo̩gbo̩n Is’haq Oloyede ti jade pe, irins̩e̩ awo̩n kan lo baje̩ ti awo̩n ko si tete mo̩ ti awo̩n fi gbe esi idanwo jade, sugbo̩n awo̩n maa se atunse nipa ki awo̩n ake̩ko̩o̩ to kan tun idanwo naa se.
Koda wo̩n ti sise̩ po̩ pe̩lu ajo̩ WAEC to n lo̩ lo̩wo̩ ki awo̩n ake̩ko̩o̩ yii ma baa nis̩e̩ ni o̩jo̩ Aje, o̩jo̩ ke̩rindinlogun osu yii.
Wo̩n ni awo̩n ake̩ko̩o̩ to sun mo̩ e̩gbe̩run lona irinwo lo maa tun idanwo naa se ge̩ge̩ bi ajo̩ JAMB se salaye.

 

 

 

 

Gọngọ sọ lọ́jọ́ tí Ọba Ẹlẹ́gùshì se ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dógún lórí ìtẹ́

Oba Elegushi
 
Mudasir Alabi

Mewa sele, gongo so laipe yii lojo ti Oba ti ilu Ikate, Oba Elegushi, se ayeye odun keedogun to ti de ipo baba re.

Opolopo awon otookulu ko ba Kabiyesi lalejo, ti won ba won jo, ti won ba won yo, ti won si ki won ku oriire.

Koda, Aare Bola Tinubu ati Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu, naa ki Kabiyesi ku oriire.

Lara awon ohun ti Kabiyesi se ajoyo le lori ni idagbasoke to de ba ilu lasiko ti won.

Oba Elegushi ati Olori Sekinat Elegushi

Se inu eni kii dun ka pa a mora, Kabiyesi wa kede yiya igba milionu naira (N200m) soto fun iranwo awon onise okowo keekeeke ni agbegbe Eti-Osa.

Lojo ayeye naa, Komisanna kan ni Ipinle Eko tele, Dokita Muiz Banire, se alaye pe labe ajo fandesan Kabiyesi, awon omo ile-iwe naa yoo je anfaani iranlowo owo.

Bi a ko ba gbagbe, Oba Elegushi ko gbongan nla kan ti won pe ni  Lagos History Research Centre ni ile eko giga ti Lagos State University (LASU) ni Ojo.

Adura wa ni pe ki Edumare tubo maa daabo re bo Kabiyesi ati awon ara ilu.

O Oba o gbo, ki Oba o to o.

Koda, irukere a di okinni, ninu alaafia ati idunnu.